REALITIES MINISTRIES

Eko Bibeli

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 24, BELU 2021

AKỌRI: ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ AYỌKA: 1Timoti 5:3-16

AKỌSORI: “Bi obinrin kan ti o gbagbọ ba ni awọn ibatan ti i ṣe opo, ẹ jẹ ki o maa ran wọn lọwọ, ki o ma si ṣe di ẹru naa le ijọ, ki wọn ki o le maa ran awọn ti i ṣe opo nitootọ lọwọ.” (1Timoti 5:16)

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe ri ni inu bibeli, ko si alaini kankan ninu awọn ọmọ Ọlọrun ti o kọkọ gbagbọ ninu Jesu ni igba aye awọn Apọsiteli akọkọ (Iṣe Apọsiteli 4:32-34). Ki si ni idi? Idi ni pe gbogbo wọn, paapaa julọ awọn ti a le pe ni ọlọrọ laarin wọn, n ran ara wọn lọwọ pẹlu awọn nkan ini wọn. Ọpọ ni o ta nkan ini wọn ni akoko yi, ti wọn si fun awọn apọsiteli ni owo ti wọn n pa nibẹ, ki wọn ba le lo wọn lati ran awọn alaini arin wọn lọwọ. Nigba ti o si ṣe, gbogbo wọn ti wọn gbagbọ kuro ni ipo alaini si ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe o ṣeeṣe ni ijọ wa kọọkan loni ki gbogbo wa ti a jẹ ọmọ Ọlọrun wa ni ipo ẹni ti o ni anito ati aniṣẹku. Awa naa kan nilo lati tọ ipasẹ awọn aṣaaju wa ni, ki a si fi ara wa jin lati ran ara wa lọwọ de ibi ti a o ti le sọ pe ko si alaini kankan ni aarin wa. Amọ ṣa o, ti a ko ba mọ ọna ti o tọ lati ṣe eleyi, o ṣeeṣe ki ififunni wa tabi iran ara wa lọwọ ma mu ete tabi erongba wa wa si imuṣẹ.

Bi a ti ṣe mọ, ọpọ ni o ti ri oniruuru iranwọ gba ninu ijọ ti ko si ja mọ nkankan fun wọn. Ọpọ ni a ti fun ni owo fun okowo tabi lati lọ si ile-ẹkọ, ti wọn si fi gbogbo nkan ti a fun wọn ṣofo. Awọn miran kan tilẹ pa irọ gba iranwọ ninu ijọ ni, ti wọn si wa jẹ ki awọn ti o ran wọn lọwọ ti ika abamọ bọ ẹnu. Idi si niyi ti o fi jẹ pe ọpọ ijọ Ọlọrun loni ni ko ki fi taratara kọbiara si ṣiṣe etọ iranwọ fun awọn ọmọ ijọ wọn. Mo ti lẹ ti gbọ lẹnu ẹnikan ri pe awọn adari ijọ kan sọ wipe, “Ṣọọṣi ko ki i ṣe baba keresi ti o ma n pin ẹbun ọfẹ.” Eyi si bi ẹni ti o gbọ ọrọ yi ninu gidigidi, to bẹẹ gẹẹ ti o fi sọ wipe, “Ti ṣọọṣi ko ba ki i ṣe baba keresi, ta wa ni o yẹ ki o jẹ baba keresi?”

Ti a ba si wo nitootọ, ko da bi ẹni pe nkan ti o buru ni ti ijọ Ọlọrun naa ba n ṣe bi baba keresi. Ṣugbọn ti a ba fi ẹsẹ ọrọ Ọlọrun tọ ọ, a o ri pe ijọ Ọlọrun ko ki i ṣe baba keresi ni tootọ, ti o kan ma n pin ẹbun lọfẹ lofo, lalai fi ti iru eni yowu ti o tọ ọ wa ṣe. Ka tilẹ sọ otitọ, baba keresi gan ti n fi ọgbọn ṣe bayi o. Awọn ti o ba sanwo lati wo o nikan ni o n pin ẹbun fun. Awọn ti ko ba sawọn iworan ko ni ri soju debi pe wọn yoo tilẹ gba ẹbun lọwọ rẹ. Eyi ko wa tunmọ si pe awọn ti o ba fi owo wọn mọ ijọ nikan ni o yẹ ki ijọ Ọlọrun ma ran lọwọ ni igba iṣoro tabi ipọnju. Ko tunmọ si rara pe awọn ti o ba n da idamẹwa ati ọrẹ deede nikan naa ni o yẹ fun iranwọ ijọ. Dipo eyi, o tunmọ si pe ilana wa ninu bibeli ti ijọ Ọlọrun gbọdọ ma tẹle ti wọn ba fẹ ṣe iranwọ fun ẹnikẹni, paapaa julọ ninu ijọ.

ILANA FUN IRANWỌ GBIGBA NINU IJỌ
Lakọkọ naa, a gbọdọ mọ pe ojuṣe wa ni gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun kọọkan lati ma ran ara wa lọwọ nipa ti ẹmi ati nipa ti ara. Nitori naa, ko bojumu rara, ko si tun fi han pe a gbagbọ ninu Jesu nitootọ ati pe ifẹ rẹ n gbe inu ọkan wa ti a ba n wo awọn ara wa ti o wa ni ipo aini niran, ti a ko si gbe igbesẹ kankan lati ran wọn lọwọ nigba ti a wa ni ipo lati ṣe bẹẹ (Jemisi 2:14-17; 1Johanu 3:16-18). Amọ sa o, bi mo ṣe ti sọ siwaju, a gbọdọ mọ awọn ilana ti a la kalẹ sinu bibeli lori ọna ti a gbọdọ tẹle lati ma ran ara wa lọwọ ninu ijọ. Aijẹbẹ ifẹ Ọlọrun le ma wa si imuṣẹ nipasẹ iranwọ ti a ba n fun ara wa.

Ki wa ni awọn ilana ti a gbọdọ tẹle? Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, iwọnyi ni pataki julọ lara awọn ilana naa:

– A gbọdọ ri daju pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni ti a fẹ ran lọwọ: Ṣe awọn ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki awọn Kirisitẹni ma ran lọwọ? Rara o! Bibeli sọ wipe, “Njẹ bi a ti n ri akoko, ẹ jẹ ki a maa ṣoore fun gbogbo eniyan, ati paapaa fun awọn ti i ṣe ara wa ninu igbagbọ.” (Galatia 6:10) Yatọ si eyi, o tun sọ wipe, “ Ṣugbọn bi ẹnikẹni ko ba pese fun awọn ibatan rẹ, paapaa fun idile rẹ, o ti ṣẹ ohun naa ti a gbagbọ, o si buru ju alaigbagbọ lọ.” (1Timoti 5:8) Nitori naa, ko ki i ṣe awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun nikan ni o yẹ ki a ma ran lọwọ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Gbogbo awọn ti Ọlọrun ba fun wa ni aye ati anfaani lati ran lọwọ ni a gbọdọ ma ran lọwọ. Ṣugbọn, a gbọdọ ri daju pe a kọkọ mojuto ile wa tabi idile wa ki a to a ṣe eleyi. Aijẹbẹ, a o jẹbi niwaju Ọlọrun. Yatọ si eyi, a tun gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni ayika wa lọwọ, paapaa julọ awọn ọmọ ijọ wa. A si ri pe bibeli fi idi rẹ mulẹ pe a gbọdọ mu riran awọn ọmọ Ọlọrun ti a jọ n ṣepọ ni pataki ju riran awọn ti ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun lọwọ lọ. Idi si ni pe ẹya ara kan naa ni wa ninu Kirisiti Jesu (1Kọrinnti 12). Ko bojumu to lati pa awọn ọmọ ijọ wa ti o ṣe alaini ti, ki a si wa ma lo owo ti awọn ọmọ ijọ miran kojọ lati ma ṣe iranwọ fun awọn alaigbagbọ. Bi awọn aṣaaju wa ninu igbagbọ ti ṣe ṣe kọ ni yẹn. Nitorina, ki a to fun ẹnikẹni ni iranwọ ti o tọ si ọmọ Ọlọrun, paapaa julọ gẹgẹ bi ijọ Ọlọrun, a gbọdọ ri daju ṣaka pe ọmọ Ọlọrun ni ẹni bẹẹ ni tootọ. O si tunmọ si pe o gbọdọ kọja ọrọ ẹnu; a gbọdọ ri ninu iwa ati iṣe ẹni naa pe ọmọ Ọlọrun ti aye rẹ kun fun eso ẹmi ni. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki ẹni naa ṣi oore-ọfẹ naa lo, ki o si tun mu ipalara ba ijọ Ọlọrun. Apẹẹrẹ eyi si kunlẹ jantirẹrẹ.

– Iṣedari ijọ ni lati mọ nipa iranwọ ṣiṣe laarin ọmọ ijọ kan si omiran: Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ni igba ti ijọ Jesu bẹrẹ si ni pade, ti wọn si n ran ara wọn lọwọ, awọn apọsiteli ati awọn diakoni ni o n ṣe iṣakoso iṣẹ iranwọ yi. Awọn ni awọn ti o n ta nkan ini wọn n ko owo fun lati pin fun awọn ọmọ ijọ gẹgẹ bi aini ẹnikọọkan wọn ṣe ri. Idi si ni pe awọn ni o wa ni ipo lati tọpinpin, nipa ọgbọn Ẹmi mimọ ati oye ọrọ Ọlọrun, igbe aye ọmọ ijọ kọọkan ati lati mọ irufẹ iranwọ ti wọn nilo. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe pe awọn eniyan kan dede n mu ẹni ti o ba wu wọn lati ran lọwọ. Ka sọ wipe bẹẹ lo ṣe ri ni, ọpọ ni ko ba kabamọ lori riran awọn ọmọ ijọ kan lọwọ. Bẹẹ si ni ọpọ ko ba tun ṣe kabamọ pe wọn gba iranwọ awọn kan. Yatọ si eyi, ikunsinnu ko ba wa laarin awọn ti wọn ro pe a ko ran awọn lọwọ to. A si ri lotitọ pe akoko kan wa ti awọn opo kan bẹrẹ si ni kun pe wọn awọn ti o n pin ounjẹ ojoojumọ fun wọn ti ti ẹlẹyamẹya ati ojuṣaaju bọ ọrọ naa. Eyi ni o si fa a ti awọn apọsiteli ṣe ni ki wọn yan awọn ti wọn kun fun Ẹmi mimọ, ti wọn si tun ni ọgbọn Ọlọrun ninu wọn lati ma mojutọ ọrọ naa. Nitori naa, ti a ko ba fẹ ṣe aṣiṣe ni riran awọn eniyan lọwọ ninu ijọ tabi ki a mu ki o fa ikunsinu tabi ipalara, a gbọdọ ṣe nipasẹ awọn adari wa ni. Awọn adari wa naa si gbọdọ ṣe ni ọna ti ojuṣaaju ko fi ni wọ ọ nipa fifi aye gba awọn ti o kun fun Ẹmi mimọ ati ọgbọn Ọlọrun lati ṣe amojuto ọrọ naa. (Wo: Iṣe Apọsiteli 4:34-37 & 6:1-7; 1Timoti 5:21)

– Ẹni naa gbọdọ fi ara rẹ jin fun igbe aye iwa mimọ ati isin ninu ijọ: Yatọ si pe ki eniyan jẹ ọmọ Ọlọrun, bi mo ṣe sọ siwaju, o tun gbọdọ fi ara rẹ han ninu ijọ gẹgẹ bi ẹni ti o fi aye rẹ jin fun iwa mimọ ati sisin Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu, nigba ti o n fun Timoti ni alakalẹ lori awọn nkan ti o yẹ ki o wo ki o to ma ran opo kankan lọwọ pẹlu owo ijọ Ọlọrun, sọ fun pe, “Ma ṣe kọ orukọ opo ti o ba din ni ọgọta ọdun silẹ bi opo ti o yẹ fun iranlọwọ, oun si gbọdọ ti jẹ obinrin oloootọ si ọkọ rẹ, Ẹni ti a lee jẹrii rẹ fun iṣẹ rere, ti o ti tọ ọmọ rẹ bi o ti yẹ, ẹni ti o maa n gba alejo, ti o ti ṣe iranṣẹ fun awọn eniyan mimọ ninu irẹlẹ, ti o si maa n ran awọn ti a n pọn loju lọwọ, ẹni ti n lepa lati ṣe rere” (1Timoti 5:9-10) Pẹlu nkan ti Pọọlu sọ nibiyi, a ri pe ẹni yowu ti ijọ yoo ba ran lọwọ gbọdọ jẹ ẹni ti igbe aye ti o n gbe fi ogo fun Ọlọrun, ti oun naa si tun kun fun iṣẹ rere. Nitori naa, ẹni ti a ko ba le gbẹri rẹ jẹ pe igbe aye rẹ wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ati pe o tun kun fi iṣe rere ni sisin ijọ Ọlọrun ko lẹtọ si iranwọ ijọ. Aijẹbẹ, ọpọ ni yoo ma lo iranwọ ti wọn gba ninu ijọ lati ṣe iranu tabi lati gbe igbe aye ti ko fi ogo fun Ọlọrun.

– Awọn ti o n gba iranwọ ko gbọdọ jẹ ọlẹ tabi alaifẹkanṣe: Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika kilọ fun wọn lati ma ṣe ran ẹnikẹni laarin wọn lọwọ lati jẹ ọlẹ tabi alainikanṣe. O tilẹ tun sọ siwaju si fun wọn pe ilana ti awọn fun wọn ni pe ẹnikẹni ti ko ba ṣiṣẹ ko lẹtọ si ounjẹ. Eyi tunmọ si pe ọlẹ, boya ninu ijọ ni o tabi ni ibomiran, ko lẹtọ si ounjẹ tabi iranlọwọ. Awọn ti wọn ṣetan lati ṣiṣẹ tọkantara ni iranwọ wulo fun. Idi si ni pe afojusun iranwọ ninu ijọ ki i ṣe lati pọn awọn kan loju ki a ba le tu awọn kan lara bikoṣe lati mu wa de ibi ti ko ti ni si alaini ni aarin wa. Eyi tunmọ si pe ti a ba ran ọ lọwọ loni, ki iwọ naa ba le ran ẹlomiran lọwọ lọla ni. Ti o ba wa ya ọlẹ, njẹ eyi yoo ṣeeṣe bi? Ko ni i ṣeeṣe. Abi ṣe o wa dara ki awọn kan ma fi tọkantara sin Ọlọrun ati fẹ awọn ara wọn pẹlu nkan ini wọn, ki awọn kan si ma fi imẹlẹ ati iwa ọlẹ jẹ igbadun laala wọn? Ko dara rara. Nitori naa, ijọ Ọlọrun ko lẹtọ lati fun ọmọ ijọ alapamaṣiṣẹ kankan ni owo iranwọ. (Wo: 2Kọrinnti 8:13-14; 2Tẹsalonika 3:6-15; 1Timoti 5:9-15)

– Iranwọ ti o tọ si awọn arugbo ko gbọdọ lọ sọdọ awọn ọdọ: Nkan miran ti a tun fi lọlẹ fun wa ninu bibeli ni pe ko ki i ṣe gbogbo ọmọ ijọ naa ni o nilo iranwọ owo lati ọdọ ijọ. Yatọ si pe eniyan jẹ Kiristiẹni ti a le gba ẹri rẹ jẹ, niwọn igba ti o ba si jẹ ọdọ, ti o ṣi le ṣiṣẹ, ko yẹ ki a tun ma ran lọwọ bi arugbo. Eyi ko sọ wipe ki a ma ran lọwọ rara o, paapaa julọ ti ba wa ninu iṣoro. Amọ a gbọdọ ran lọwọ gẹgẹ bi ọdọ ni, ki i ṣe gẹgẹ bi arugbo ti ko ni ẹnikankan ti o le ran an lọwọ. Eyi si lo fa a ti Pọọlu ṣe sọ fun Timoti pe awọn opo ti ko ba i ti pe ọgọta ọdun ko yẹ ki o wa lori iwe awọn ti ijọ yoo ma fi owo ran lọwọ. Idi si nipe awọn wọnyi si le tun ọkọ ni, ki wọn si tun ma ṣiṣẹ lẹgbẹkan. Aijẹbẹ, a o kan ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lati ya ọlẹ, atojubọle ati alainikannṣe ni. (Wo: 1Timoti 5:9-15)

– Awọn ti o n gba iranwọ gbọdọ jẹ ẹni ko ni ẹbi ti o le ran wọn lọwọ: Yatọ si awọn ilana ti a ti mẹnuba nipa riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ ninu ijọ, a tun gbọdo ri daju pe awọn ti a ba fẹ ran lọwọ jẹ awọn ti ko ni ẹbi tabi ara ti o gbagbọ tabi ti o ṣetan lati ran wọn lọwọ. Bi a ṣe fi ye wa ninu bibeli, awọn ti wọn ba ni ọmọ tabi ara ti o le ran wọn lọwọ ko nilo lati tun ma gba iranwọ ijọ Ọlọrun. O yẹ ki a jẹ ki awọn ọmọ wọn tabi ara wọn mọ ojuṣe wọn si wọn ni, ki wọn si maa ṣe e. Eyi tunmọ si pe awa ti a ba ni obi ninu ijọ ko yẹ ki a tun jẹ ki wọn di bukata ijọ. Nṣe ni o yẹ ki a ma mojuto wọn. Aijẹbẹ, asan ni igbagbọ wa ja si, a ko si san ju awọn alaigbagbọ lọ. Nitori naa, a gbọdọ kọ awọn ọmọ Ọlọrun lati ma ṣe jẹ ki awọn ara wọn ti o yẹ ki wọn maa tọju di bukata ijọ Ọlọrun. Idi si nipe eyi yoo fi aye silẹ fun ijọ lati ran awọn miran ti ko ni oluranlọwọ lọwọ. Amọ ti a ko ba jẹ ki eyi ye awọn ọmọ Ọlọrun, a o kan ri pe ijọ Ọlọrun bẹrẹ si ni ru ajaga ti ko yẹ ki o ru ni. Eyi yoo si ran ọpọ lọwọ lati ma gbe igbe aye ojukokoro ati ọkanjua. (Wo: 1Timoti 5:4-8&16)

– Odiwọn iranwọ si ẹnikẹni gbọdọ wa lori oun ti ijọ ni dipo nkan ti ijọ ko ni: Ko si ẹnikẹni ti o le fun eniyan ni nkan ti ko ba ni. Idi si ni yi ti Ọlọrun fi jẹ ki o ye wa pe gbogbo fififunni wa gbọdọ da lori nkan ti a ni dipo nkan ti a ko ni (2Kọrinnti 8:12). Eyi wa jasi pe ti ijọ Ọlọrun ba fẹ ran ẹnikẹni lọwọ, iranwọ naa gbọdọ wa lori gbedeke nkan ti ijọ ni ni dipo eyi ti ko ni. Idi ni yi ti awọn ọmọ Ọlọrun ti o ba ni lọwọ daradara ṣe gbọdọ ma fi gbogbo igba fi owo tabi nkan iranwọ silẹ fun awọn ara wọn ninu ijọ. Ko ki i ṣe nkan ti o dara ni ki ijọ Ọlọrun ma jẹ gbese nitori pe wọn fẹ ran ọmọ ijọ kan lọwọ tabi nitori pe wọn ni awọn akanṣe iṣẹ kan. Ti a ba fẹ ki a ma ran awọn ọmọ ijọ wa lọwọ lọna ti o peye, nṣe ni ki awa naa bẹrẹ si ni ṣe awọn nkan ti yo jẹ ki o ṣeeṣe.

ỌRỌ IPARI
Riran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ nipa ti ara lati le da duro, ki wọn ma si ṣe wa ni ipo alaini ṣe pataki pupọ. Amọ ti a ko ba tẹle ilana bibeli lati ma ṣe eyi, ko si ni ki a ma kabamọ lori rẹ tabi ki a da rugudu silẹ ninu ijọ.

IBEERE
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe ṣe pataki to fun awọn ọmọ Ọlọrun?
– Awọn nkan miran wo ni o le sọ pe a tun fi ẹsẹ wọn mulẹ ninu bibeli gẹgẹ bi ilana ti o yẹ ki a tẹle lati ran awọn ọmọ Ọlọrun lọwọ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ỌJỌRU 27, ỌWARA 2021

AKỌRI: IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN ỌMỌ ỌLỌRUN AYỌKA: ISIKIẸLI 36:25-27

AKỌSORI: “Emi o si fi ẹmi mi sinu yin, emi o si mu ki ẹ maa rin ninu aṣẹ mi, ẹyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si maa ṣe wọn.” (Iṣikiẹli 36:27)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ pari, a ṣe agbẹyẹwo awọn nkan ti bibeli sọ nipa iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun si awọn ti aye yi. A si ṣe agbeyẹwo awọn nkan wọnyi ki a ba le mọ iha ti o tọ fun wa lati kọ si igbala awọn alailagbọ, ki a ma ba pa iṣẹ ti Ọlọrun n ṣe lori aye wọn lara tabi di lọwọ. Wayi o, bi a tun ṣe ri ninu bibeli, iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Mimọ ko pin si aarin awọn alaigbagbọ ninu Jesu Kirisiti; iṣẹ iranṣẹ rẹ naa kan awọn ti o gbagbọ ninu rẹ. Nitorina o tun ṣe ṣe pataki fun wa lati mọ nipa iṣẹ iranṣẹ rẹ si wa, iyẹn awa ti a gbagbọ ninu Jesu Kirisiti, ti a si ti di atunbi ati ọmọ Ọlọrun nipasẹ rẹ. Eyi yoo ran wa lọwọ lati mọ iha ti o yẹ ki a kọ si i, ki O ba le mu ifẹ Ọlọrun ṣẹ ninu aye wa ati lori aye wa lẹkunrẹrẹ.

IṢẸ IRANṢẸ ẸMI MIMỌ SI AWỌN ỌMỌ ỌLỌRUN
Ki wa ni koko iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun si awa ti a jẹ ọmọ rẹ? Pataki lara awọn nkan ti bibeli fi ye wa nipa rẹ ni iwọnyi:

– Ṣiṣe awọn ọmọ Ọlọrun yẹ ni ọkan wọn gẹgẹ bi ọmọ rẹ: Gẹgẹ bi a ti ṣe ri ninu bibeli, ko si ẹni ti o le jẹri Jesu ni Oluwa ati Olugbala rẹ ti Ẹmi Mimọ ko ba dari rẹ lati ṣe bẹ. Ẹnikẹni ti o ko ba si jẹri Jesu gẹgẹ bi Oluwa rẹ ati ọmọ Ọlọrun ko le di atunbi tabi ọmọ Ọlọrun. Amọ ṣa o, ọtọ ni ki Ẹmi Ọlọrun sọ eniyan di ọmọ Ọlọrun, ọtọ si tun ni ki ẹni naa ri ara rẹ bi ọmọ rẹ. Ko wa si ẹni ti yoo ri ara rẹ bi ọmọ Ọlọrun, ti ọkan rẹ yoo si balẹ lati pe ara rẹ ni ọmọ rẹ, ti ko ba ṣe wipe Ẹmi Mimọ ṣiṣẹ ninu rẹ lati mu ẹru kuro nibẹ, ki O si fi igboya bi ti Jesu lati pe Ọlọrun ni Baba rọpo rẹ. Idi ni yi ti bibeli ṣe sọ fun wa pe, “Nitori ti Ọlọrun ko fun yin ni ẹmi ẹru eyi ti ẹyin o fi maa bẹru: ṣugbọn ẹyin ti gba Ẹmi isọdọmọ eyi ti o sọ yin di ọmọ, nipa eyi ti awa fi n wi pe, Aba, baba. Ẹmi tikararẹ ni o n ba ẹmi wa jẹrii pe, ọmọ Ọlọrun ni awa n ṣẹ…” (Roomu 8:15-16) Nitori naa, ti a ba ri ẹni ti o pe ara rẹ ni atunbi ninu Jesu, ti o si tun wa ni i lara lati pe Ọlọrun ni Baba rẹ tabi ti ko mọ daju pe ọmọ Ọlọrun ni oun, a jẹ pe ko ni Ẹmi Ọlọrun ninu niyẹn. Ẹni ti o ba ni Ẹmi rẹ yi ninu ko ni bẹru tabi jaya lati pe e ni Baba ati lati ba lopọ gẹgẹ bi Baba rẹ. Irufẹ ẹni yi nikan ni o si le ṣe amulo ati jẹgbadun gbogbo ipese Ọlọrun fun un lati jẹ iru eniyan ti o yẹ ki o jẹ laye yi ati ninu ijọba ayeraye rẹ.

– Titu awọn ọmọ Ọlọrun ninu: Aye ti a wa ninu rẹ yi jẹ aye idarudapọ ati eyi ti o kun fun oniruuru iwa ika ati iṣẹlẹ ibi. Awọn nkan ti a n foju ri tabi fi eti gbọ lojoojumọ si n fi gbogbo igba fi idi eyi mulẹ. Nitorina, ti ko ba si ẹnikankan ti o le tu wa ninu, tu wa lara ati fun wa ni igboya ati iwuri lati gbe aye wa lọna ti o tọ ati ti o yẹ, ko si ni ki a ma ṣi iwa wu, ki a gbẹmi ara wa tabi ṣe ara wa ni ijamba. Ṣe ẹni naa wa wa ti o koju osuwọn lati ṣiṣẹ yi? Ko si! Jesu nikan ni o koju oṣuwọn lati tu awọn ọmọ ẹyin rẹ ninu ati lara nigba ti o wa ni aye yi. Oun nikan ni O ba wọn lo ni ọna ti aye ko fi su wọn lati gbe ati ni ọna ti ọkan wọn fi n fi gbogbo igba pongbẹ lati gbe igbe aye to ni itumọ. Amọ ko ki i ṣe ipinnu Ọlọrun ni fun un lati wa ninu aye yi titi lailai. Ipinnu rẹ ni pe ki O goke wa si ọdọ rẹ ti O ba ti ṣe iṣẹ irapada araye tan. Bawo wa ni yoo ṣe tẹsiwaju lati ma tu awọn tirẹ ninu? Nipa riran Ẹmi Ọlọrun si wọn lati ma a ba wọn gbe ni eyi yoo ṣe ṣeeṣe. Idi si niyi ti Jesu fi tẹnumọ ki O to kuro laye pe Ẹmi Ọlọrun ni yoo rọpọ Oun gẹgẹ bi Olutunnu fun awọn ti o ba jẹ tirẹ. Nitorina, ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun, Olutunnu ti wa ninu aye rẹ. Ti o ba si fi aye gba a, ko si iru idojukọ ti o le ba pade, yoo ri daju pe a tu ọkan rẹ ninu, a si tun ṣe e yẹ lati ma sọ ireti nu ṣugbọn lati rin irin iṣẹgun. (Wo: Johanu 14:16-18&26; Johanu 15:26; Johanu 16:7; Roomu 8:11-28)

– Titọ awọn ọmọ Ọlọrun sinu gbogbo otitọ ati ifẹ rẹ: Ọna kan soso fun eniyan lati gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lẹkunrẹrẹ ni ki o mọ Ọlọrun ati ifẹ rẹ ni ọna ti o peye ati ti o ye kooro. Oniruuru imọ ẹni ti Ọlọrun jẹ ati ifẹ rẹ ni o si kun aye. Ṣugbọn ko ki i ṣe gbogbo rẹ naa ni o jẹ otitọ. Imọkimọ ti a ba si ni nipa rẹ tabi nipa ifẹ rẹ ti ko ba fi idi le ori otitọ ko le ṣe wa ni anfaani kankan. Eyi lo fa ti a fi ri ọpọ kaakiri aye ti wọn n sọ pe awọn mọ Ọlọrun tabi pe awọn n sin in ti aye wọn ko si so eso ifẹ rẹ. Ọpọ gan ni o n ṣe oniruuru aṣemaṣe lorukọ Ọlọrun (Johanu 16:1-2). Awọn wọnyi ko ni Ẹmi Ọlọrun ninu. Nitorina, ọpọ lara nkan ti wọn ro pe wọn mọ nipa rẹ ni ko duro lori otitọ. Ti imọ wa nipa Ọlọrun ati ifẹ rẹ yoo ba duro lori otitọ, a gbọdọ ni Ẹmi rẹ ninu wa. Nitoripe Ẹmi rẹ ni yoo fi awọn nkan ti Ọlọrun fẹ ki a mọ nipa rẹ, nipa ifẹ rẹ, nipa agbara rẹ ati nipa ipese rẹ han wa lẹsẹẹsẹ. Idi si niyi ti Jesu fi sọ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ wipe, “Mo ni ohun pupọ lati sọ fun yin pẹlu, ṣugbọn ẹ ko le gba wọn nisinsinyi. Ṣugbọn nigba ti oun, ani Ẹmi otitọ naa ba de, yoo tọ ọ yin si ọna otitọ gbogbo nitori ki yoo sọ ti ara rẹ; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ ni yoo maa sọ: yoo si sọ ohun ti n bọ fun yin. Oun yoo ma yin mi logo: nitori ti yoo gba lati ọdọ mi, yoo si maa sọ ọ fun yi. Ohun gbogbo ti Baba ni, temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wi pe, oun o gba ninu temi, yoo si sọ ọ fun yin.” (Johanu 16:12-15) Njẹ o ri bayi? Iṣẹ Ẹmi Mimọ ni lati fi ohun gbogbo ti o jẹ otitọ nipa Ọlọrun ati iru ibaṣepọ ti O fẹ ki a ni pẹlu rẹ han wa ati lati tọ wa sọna ninu awọn nkan wọnyi. Eyi ko wa jasi pe gbogbo igba naa ni a o ma gbọ ohun Ẹmi Mimọ ninu ọkan tabi eti wa. Ọpọ igba lo jẹ wipe nipasẹ fifi ọrọ inu iwe mimọ ye wa ni yoo ṣe ṣe iṣẹ yi ninu aye wa. Awọn igba miran si wa ti o jẹ wipe nipasẹ iran, ala, ifihan fun awọn wolii tabi ifarahan angẹli, eyi ti yoo wa ni ibamu pẹlu ọrọ inu iwe mimọ, ni yoo ṣe fi gbogbo otitọ ti o yẹ ki a mọ ye wa. Ṣugbọn a gbọdọ mọ daju lọkan wa pe ti Ẹmi Mimọ ko ba fi otitọ Ọlọrun han wa tabi ye wa, ko si irufẹ nkan ti a ṣe ti yoo yọri si eyi. (Wo: Johanu 14:26; Roomu 8:14; 1Kọrinnti 2:9-13; Efesu 1:15-22; Kolose 1:9-14)

– Ṣiṣe awọn ọmọ Ọlọrun yẹ lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun: Igbe aye ti o buyi kun Ọlọrun, ti o si tẹ lọrun ko ki i ṣe nkan ti ọgbọn ori, itara tabi agbara eniyan ka. Idi niyi ti ọpọ ṣe n tiraka ati ṣe laala lasan lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ti ko si ṣeeṣe fun wọn. Ẹmi Ọlọrun nikan ni o le jẹ ki eyi ṣeeṣe. Oun nikan ni O le fun wa ni iwuri, itara, ifẹ, igboya ati okun lati ṣe nkan ti Ọlọrun fẹ ati lati gbe igbe aye ti o tẹ ẹ lọrun ni ọna gbogbo. Iwọ naa wo nkan ti Ọlọrun funrarẹ sọ lori ọrọ yi: “Emi o fi ọkan tuntun fun yin pẹlu, ẹmi titun ni emi o fi ṣaanu yin, emi o si mu ọkan okuta kuro lara yin, emi o si fi ọkan ẹran fun yin. Emi o si fi ẹmi mi sinu yin, emi o si mu ki ẹ maa rin ninu aṣẹ mi, ẹyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si maa ṣe wọn.” (Isikiẹli 36:26-27) Tun wo eyi naa: “Nigba naa ni o si dahun o si wi fun mi pe, Eyi ni ọrọ Oluwa si Serubabeli wi pe, Kii ṣe nipa ipa, kii ṣe nipa agbara, bi ko ṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ ogun wi.” (Sẹkaraya 4:6) Njẹ o ri bayi? Ẹmi Ọlọrun nikan ni O le mu wa rin ninu aṣẹ Ọlọrun, ki a si tun pa idajọ rẹ mọ. Nitori naa, ti a ba ri ọmọ Ọlọrun kankan ti o n tiraka lasan lati ṣe ifẹ rẹ, a jẹ wipe iru ẹni bẹẹ ko i ti mọ pe a ko le ṣe ifẹ Ọlọrun ti ko ba ṣe pe Ẹmi rẹ ṣe wa yẹ lati ṣe e. Idi ni yi ti a ko fi gbọdọ gbọkan le ohun yowu ti a ni lati ṣe ifẹ Ọlọrun bikoṣe Ẹmi rẹ. Aijẹbẹ, ikunna nla ni a o ma fi gbogbo igba pabade. (Wo: Roomu 8:1-13; Efesu 3:14-19)

– Mimu eso iwa-bi-Ọlọrun jade ninu aye awọn ọmọ rẹ: Niwọn igba ti o jẹ wipe Ẹmi Ọlọrun nikan ni O le jẹ ki a gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun, o wa jasi pe Oun nikan naa ni O le jẹ ki aye wa so eso iwa-bi-Ọlọrun. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, pataki idi ti Ọlọrun ṣe yan wa ki a tilẹ to wa si aye, ti O si tun wa tun wa bi ni ki a ba le dabi ọmọ rẹ Jesu Kirisiti ni gbogbo ọna (Roomu 8:29). Eyi naa si tun ni idi ti O fi n fi oniruuru ẹbun ta awọn eniyan lọrẹ lati ṣe wa yẹ lati da bi Jesu ọmọ rẹ ni gbogbo ọna (Efesu 4:11-16). Ti a ba wa fẹ dabi Jesu ni gbogbo ọna, ninu iwa, iṣe, ọrọ, ero ati ifẹ, Ẹmi mimọ gbọdọ gbakoso aye wa patapata. Idi ni yi ti Pọọlu fi sọ fun awọn ara Galatia wipe ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iṣoore, inu rere, jijẹ oloootọ, iwa pẹlẹ ati ikora-ẹni-nijaanu jẹ eso Ẹmi mimọ. Eyi ko tunmọ si pe Ẹmi Ọlọrun ni o n so eso yi. Dipo eyi, o tunmọ si wipe ifarahan awọn nkan yi ninu aye eniyan n fihan pe Ẹmi Ọlọrun n ṣiṣẹ ninu aye rẹ. Nikukuru, Ẹmi Ọlọrun ni o ma n yi aye eniyan pada lati inu, ki o ba le so eso iwa-bi-Ọlọrun. (Wo: Galatia 5:23-24; 2Kọrinnti 3:18)

– Fifi ẹbun lati ba Ọlọrun ṣiṣẹ funni: Yatọ si pe Ọlọrun fẹ ki aye wa ma so eso ti yoo fi han pe ọmọ rẹ ni a jẹ, O tun fẹ ki a darapọ mọ Oun lati mu ifẹ rẹ ṣẹ ninu aye yi, paapaa julọ ninu aye awọn ọmọ eniyan. Ṣugbọn a ko le ba Ọlọrun ṣiṣẹ ti ko ba ṣe wa yẹ. Ọna ti O si n gba ṣe wa yẹ ni nipa fi fun wa ni awọn amuyẹ ti bibeli pe ni ẹbun Ẹmi Mimọ. Eyi jasi pe nipasẹ Ẹmi Ọlọrun ni O ṣe n fun wa ni awọn ẹbun ọfẹ ti o n ṣe wa yẹ lati ṣiṣẹ pẹlu rẹ ninu ọgba ajara rẹ. Idi ni yi ti Pọọlu ṣe sọ eyi fun wa: “Njẹ oniruuru ẹbun ni o wa, ṣugbọn Ẹmi kan naa ni. Oniruuru iṣẹ-iranṣẹ ni o si wa, Oluwa kan naa si ni. Oniruuru iṣẹ-iranṣẹ ni o si wa, ṣugbọn Ọlọrun kan naa ni ẹni ti n ṣiṣẹ gbogbo wọn ninu gbogbo wọn. Ṣugbọn a n fi ẹbun Ẹmi fun olukuluku eniyan lati fi jere. Nitori ti a fi ọrọ ọgbọn fun ẹnikan nipa Ẹmi, ati fun ẹlomiran ọrọ-imọ nipa Ẹmi kan naa; Ati fun ẹlomiran igbagbọ nipa Ẹmi kan naa; ati fun ẹlomiran ẹbun imularada nipa Ẹmi kan naa; Ati fun ẹlomiran lati ṣe iṣẹ iyanu; ati fun ẹlomiran isọtẹlẹ; ati fun ẹlomiran imọ ẹmi yatọ; ati fun ẹlomiran oniruuru ede; ati fun ẹlomiran itumọ ede. Ṣugbọn ẹnikan naa, ani Ẹmi Mimọ kan ṣoṣo naa ni i ṣe gbogbo nnkan wọnyi, o n pin fun olukuluku gẹgẹ bi o ti wu u.” (1Kọrinnti 12:4-11) Yatọ si eyi, Ẹmi Mimọ yi kan naa ni O n kọ eniyan, ti O si tun n funni ni ọgbọn, agbara ati igboya lati lo ẹbun yowu ti O ba fun ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Nitorina, ẹnikẹni ti ko ba ni Ẹmi Mimọ ko le ni awọn amuyẹ ti o yẹ ki o ni lati le ba Ọlọrun ṣiṣẹ ni ọna ti o nitunmọ, ti yoo si tun fi gba oriyin tabi ere. Ẹni ti o ba si ni oun n ṣiṣẹ fun Ọlọrun lalai ni Ẹmi rẹ ṣeeṣe ki o padanu gbogbo nkan ti o ṣe lọjọ kan. (Wo: 2Kọrinnti 3:5-6; Heberu 2:4; 1Peteru 4:11)

– Fifun awọn ọmọ Ọlọrun ni iriri ominira: Bi a ti ṣe sọ siwaju, ara iṣẹ Ẹmi Ọlọrun ni lati fi gbogbo otitọ Ọlọrun han wa. Ki wa ni imọ otitọ Ọlọrun yoo ṣe fun wa? Jesu sọ wipe imọ otitọ rẹ yoo sọ wa di ominira, ominira nitootọ (Johanu 8:32&36). Eyi tunmọ si pe a wa ni ipo ẹru niyẹn. Ẹni ti ko ba wa nipo ẹru lọna kan tabi omiran ko nilo ominira. Ṣugbọn bi ọrọ Ọlọrun ṣe fi ye wa, lati igba ti ọmọ eniyan ti ṣẹ ninu ọgba Edẹni ni a ti di ẹru ẹṣẹ, Eṣu ati awọn ofin ati ilana ti aye yi. Eyi ko si ki i ṣe ifẹ Ọlọrun fun wa. Nitori naa, O ran Jesu wa saye lati ku fun ominira wa. Ẹnikẹni ti o ba si gbaagbọ di ominira kuro lọwọ Eṣu, ẹṣẹ ati ohunkohun ti o ba n lepa lati fi si ipo ẹru. Amọ, ọpọ ọmọ Ọlọrun ni ko i ti ma ni iriri ominira yi ninu aye wọn. Idi si ni pe wọn ko mọ pe iṣẹ Ẹmi mimọ ni lati sọ imọ ominira wọn di iriri ominira. Ni kese ti wọn ba mọ eyi, ti wọn si bẹrẹ si ni tẹwọgba iṣẹ iranṣẹ rẹ ninu aye wọn nipasẹ adura ati ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun, wọn yoo bẹrẹ si ni ni iriri ominira kuro lọwọ gbogbo ẹṣẹ ti o ti jẹ gaba le aye wọn lori ati kuro lọwọ oniruuru iṣẹ esu ati pẹlu kuro lọwọ imulẹru aṣa, iṣẹṣe ati ẹṣin awọn eniyan. Idi si niyi ti Pọọlu ṣe sọ fun wa pe, “Njẹ Oluwa ni Ẹmi naa: nibi ti Ẹmi Oluwa ba si wa, nibẹ ni ominira gbe wa.” (2Kọrinnti 3:17)

– Edidi lati pa awọn ọmọ Ọlọrun mọ de ọjọ irapada: Yatọ si awọn nkan ti a ti sọ siwaju nipa iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Mimọ, a tun fi ye wa ninu bibeli pe Oun naa tun ni edidi tabi ountẹ ti a jan awọn ọmọ Ọlọrun fun ipamọ wọn di ọjọ irapada. Aye ati ọrun ti a mọ yi ko ni wa titi. Ọjọ n bọ ti a o fi opin si ohun gbogbo ti o n lọ lori aye yi ati ninu ọrun ti a mọ yi, ki ọrun ati aye tuntun ti Ọlọrun ti pese ba le rọpọ wọn. Ki o to wa di akoko yi, Ẹmi Mimọ ni Ọlọrun fun awọn eniyan rẹ lati ṣe edidi wọn. Eyi jasi pe Oun ni ountẹ ti o n fi han gbogbo ẹda Ọlọrun pe tirẹ ni a jẹ. Eyi si tun ja si pe Oun ni a le pe ni bi owo asansilẹ ti o n fi han pe dajudaju Jesu n pada bọ wa ni tootọ lati ra agọ ara wa pada, ki ba le gbe ara tuntun wọ fun ijọba ayeraye rẹ. Lafikun, O tun jasi pe Oun ni Ọlọfun fa kalẹ gẹgẹ bi alamojuto ati olupamọ aye wa fun ijọba ayeraye rẹ. Abalajọ, ti bibeli ṣe fidi rẹ mulẹ pe O n ran ailera wa ni aye yi lọwọ, O si tun n ṣipẹ si Ọlọrun fun wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ni akoko ti a ba n gbadura. Idi ni yi ti a fi kilọ fun wa ninu bibeli lati ma ṣe ohunkohun ti o le ba a ninu jẹ. Nitori naa, a ko nilo lati bẹru boya a o de ijọba ọrun lalafia ati ni pipe tabi bẹẹkọ nitori pe a ti fun wa ni Ẹmi Ọlọrun lati ri daju pe a mu wa debẹ. (Wo: Roomu 8:22-27; 2Kọrinnti 1:22; 2Kọrinnti 5:1-5; Efesu 1:13-14 & 4:30)

ỌRỌ IPARI
Iṣẹ iranṣẹ Ẹmi Ọlọrun si awọn ọmọ rẹ ati ninu aye wọn kọja afẹnusọ. Ṣugbọn o ṣe pataki ki a kọbiara si awọn nkan ti a fihan ninu bibeli nipa iṣẹ iranṣẹ rẹ si wa. Eyi yoo ran wa lọwọ lati mọ pe ko si nkankan ti a le da ṣe lati gbe igbe aye ti o tẹ Ọlọrun lọrun lalai si Ẹmi rẹ ninu wa tabi lalai fi ti Ẹmi rẹ ṣe. Mo si gbadura pe okun lati ma fi gbogbo igba ranti eyi ati lati ṣe amulo rẹ yoo kun ọkan wa, ni orukọ Jesu. Amin.

IBEERE
– Awọn ọna wo ni ẹkọ yi gba wulo fun ọ tabi ṣe ọ ni anfaani?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 14, AGẸMỌ 2021

 

AKỌRI: WOLII (2)                                                  AYỌKA: MATIU 16:1-4

 

AKỌSORI: AKỌSORI: “Awọn eniyan pupọ si wa sọdọ rẹ, wọn si wi pe, Johanu ko ṣe iṣẹ, ami kan: ṣugbọn otitọ ni ohun gbogbo ti Johanu sọ nipa ti ọkunrin yii.” (Johanu 10:41)

 

ỌRỌ AKỌSỌ

Ninu ẹkọ ti a n kọ lori wolii ati iṣẹ iranṣẹ rẹ, a ri daju lati inu bibeli pe wolii jẹ ẹnikan ti Ọlọrun n fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han ki O ba a le lo o lati fi ifẹ rẹ tabi ara rẹ han awọn eniyan. Eyi si kọja ki a sọ asọtẹlẹ; dipo bẹẹ, o ni i ṣe pẹlu fifi ifẹ, ete, ero tabi eto Ọlọrun han si awọn eniyan. A si tun ri pe Ọlọrun le fi ara rẹ ati ifẹ rẹ han wolii nipasẹ ala tabi iran tabi nipasẹ biba sọrọ ni ẹnukoẹnu. Amọ ṣa o, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni wolii, ti ko wa fi ara rẹ jin fun ọrọ Ọlọrun ko ni le ṣe iyatọ ti o peye laarin ala, iran tabi ohun ti o wa lati ọdọ Ọlọrun ati eyi ti o wa lati ọdọ Eṣu. Yatọ si eyi, ko tun ni mọ igba ti o yẹ ki o gbe ẹnu dakẹ ati igba ti o yẹ ki o sọrọ. Eyi ni o si fa a ti a fi ni ọpọlọpọ wolii eke kaakiri agbaye loni.

 

WOLII ATI IṢẸ IYANU

Wayi o, ara nkan ti a tun nilo mọ nipa wolii ni pe iṣẹ iranṣẹ rẹ ko ki i fi gbogbo igba ni i ṣe pẹlu ki a ṣe iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu. Lotitọ, bi a ṣe ri ninu bibeli, awọn wolii kan wa ti o jẹ pe Ọlọrun lo wọn fun oniruuru iṣẹ ami ati iyanu. O ṣi ṣe eyi ni ọpọ igba lati jẹ ki awọn eniyan gba a gbọ. Jesu tilẹ fi igba kan sọ eyi fun awọn ara Juu: “Bi ko ṣe pe ẹyin ba ri ami ati iṣẹ iyanu, ẹyin ki yoo gbagbọ lae.” (Johanu 4:48) Nitorina, awọn kan wa ti o jẹ pe ti ko ba ṣe pe wọn ba ri ami tabi iyanu Ọlọrun, wo ko ni gba a gbọ. O le jẹ nitori ipọnju ti o pọ fun wọn tabi nitori itanjẹ orisirisi awọn eke ojiṣẹ Ọlọrun ti wọn ti ba pade tabi nitori ibaṣepọ wọn pẹlu agbara okunkun ni wọn ko ṣe fẹ ni nkankan ṣe pẹlu Jesu tabi Ọlọrun. Ṣugbọn ti awọn wọnyi ba ri iṣẹ ami ati iyanu otitọ, wọn le tipasẹ rẹ gbagbọ, ki wọn si kọ ẹṣẹ, ibọriṣa ati awọn iwa eeri wọn silẹ.

 

Fun apẹẹrẹ, a ri wipe nigba ti Ọlọrun ran Mose pada lọ si Ijibiti lati mu awọn eniyan rẹ jade, O fun ni aṣẹ lati ṣe oniruuru iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu. Ki si ni idi? Ni akọkọ, O ṣe eyi ki awọn ọmọ Isiraẹli, ti iya ti jẹ fun ọpọlọpọ ọdun, ti wọn si ti bẹrẹ si ni ro wipe Ọlọrun awọn baba wọn ti kọ wọn silẹ tabi pe ko ni agbara lati gba wọn, ba le gbagbọ ninu rẹ ati ninu ẹni ti o ran an niṣẹ. Nitorina, bibeli sọ eyi fun wa: “Mose ati Aarọni lọ, wọn ko gbogbo agba awọn ọmọ Isiraẹli jọ: Aaroni sọ gbogbo ọrọ ti Oluwa ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ ami naa ni oju awọn eniyan naa. Awọn eniyan naa si gbagbọ: nigba ti wọn gbọ pe, Oluwa ti bẹ awọn ọmọ Isiraẹli wo, ati pe o ti ri ipọnju wọn, nigba naa ni wọn tẹ ori wọn ba, wọn si sin in.” (Ẹkisodu 4:29-31)

 

Idi keji ti Ọlọrun fi fun Mose ni aṣẹ ati agbara lati ṣe iṣẹ ami ati iyanu ni lati le fi dandan mu Farao lati tu awọn eniyan rẹ silẹ. Iwọ na wo nkan ti Ọlọrun sọ fun Mose lori eyi: “Emi si mọ pe ọba Ijibiti ki yoo jẹ ki ẹyin ki o lọ, bi ko ṣe nipa ọwọ agbara. Emi o si na ọwọ mi, emi o si fi iṣẹ-iyanu mi gbogbo kọlu Ijibiti ti emi o ṣe laarin rẹ: lẹyin eyi ni oun o too jẹ ki ẹ lọ.” (Ẹkisodu 3:19-20) A si ri pe bẹẹ gẹgẹ ni Ọlọrun ṣe si ọba Ijibiti ati awọn eniyan rẹ, ki o to di pe wọn gbagbọ pe Ọlọrun ni agbara lori wọn, ti wọn si tu awọn ọmọ Isiraẹli silẹ.

 

Siwaju si, ni igba aye ọba Ahabu, a ri wipe ibọriṣa ati iṣẹ oṣo gbilẹ to bẹẹ gẹẹ ti awọn eniyan Isiraẹli fi gbagbe Ọlọrun patapata, ti wọn ko si mọ bi o ṣe yẹ ki wọn sin in mọ. Nitorina, nigba ti Ọlọrun ṣetan lati mu wọn padabọsipo, O kọkọ fi iyan ọdun mẹta ati abọ bẹ wọn wo nipasẹ ọrọ ẹnu wolii rẹ, Elija. Lẹyin eyi, O tun wa lo wolii yi lati mu ki ina sọkalẹ lati ọrun sori ẹbọ sisun rẹ, ki o ba le fi awọn oriṣa ti wọn n bọ ati awọn wolii awọn oriṣa yi han gẹgẹ bi eke. (Wo: 1Awọn Ọba 17&18)

 

Nitorina, ọkan pataki lara idi ti Ọlọrun fi ma n tipasẹ awọn wolii rẹ ṣe iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu ni lati jẹ ki awọn eniyan le gba a gbọ ki wọn si ronupiwada, kọ ibọriṣa silẹ tabi ri gẹgẹ bi alagbara lori ohun gbogbo. A si tun fi idi eyi mulẹ nipasẹ iṣẹ iranṣẹ awọn apositeli, ẹfanjẹlisiti ati wolii Jesu ti wọn lọ kaakiri agbaye lati polongo ọrọ rẹ fun araye. A ri wipe pupọ ninu ibi ti wọn lọ ni wọn ti ṣe ọpọlọpọ isẹ ara ati iṣẹ iyanu ti o pe akiyesi awọn eniyan si ihinrere Jesu, ti o si tun jẹ ki wọn gbagbọ. (Wo: Iṣe Awọn Apositeli 5:12, 8:4-8 & 14:3)

 

Amọ ṣa o, ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni Ọlọrun ma n lo awọn wolii tabi awọn iranṣẹ rẹ miran fun iṣẹ ami tabi iṣẹ iyanu. Ailoye eyi si n jẹ ki ọpọ padanu awọn ibukun tabi aabo ti wọn ko ba ma ri gba lati ara awọn wolii Ọlọrun ti O n ran si wọn. Nkan ti mo n sọ ni wipe ọpọ ni o ro pe ẹni ti ko ba ti ma ṣe iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu ko ki i ṣe wolii otitọ. Ṣugbọn pataki julọ ninu iṣẹ iranṣẹ wolii ni lati fi ifẹ, ete ati ero Ọlọrun han awọn eniyan, ki i ṣe lati ṣe iṣẹ iyanu. Iṣẹ iyanu melo ni awọn wolii bi Aisaya, Jeremaya, Emọọsi, Miika, Daniẹli ati bẹẹbẹẹ lọ ṣe? A ko ni akọsilẹ wọn. Ṣugbọn wọn fi tọkantọkan fi ifẹ ati eto Ọlọrun han gbogbo awọn ti O ran wọn si.

 

Bi a tilẹ tun ṣe ri ninu akọsori wa, Johanu onitẹbọmi ti o fi Jesu han fun awọn Juu gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun gan ko ṣe iṣẹ iyanu kankan (Johanu 10:41). Sibẹsibẹ, Jesu sọ wipe ko si wolii naa tabi eniyan naa ti a bi ninu obinrin ti o ga ju Johanu yi lọ niwaju Ọlọrun, ayafi awọn ọmọ ijọba ọrun (Matiu 11:11). Eyi si n jẹ ki o ye wa wipe Ọlọrun ko ki i gbe odiwọn pataki iṣẹ wolii kan tabi omiran le ori iye iṣẹ iyanu ti wọn ṣe ṣugbọn lori bi wọn ṣe fi tọkantọkan jẹ iṣẹ yowu ti o ba gbe le wọn lọwọ si.

 

Ti a o ba i ti gbagbe, a ti ri idi ti Ọlọrun fi ma n lo awọn wolii rẹ lati ṣe iṣẹ iyanu. Amọ ko ki i ṣe gbogbo igba ni O ma n ṣe eyi tabi ni o nilo lati ṣe eyi. Ibikibi ti Ọlọrun ba ti mọ pe awọn eniyan ri iṣẹ iyanu rẹ to lati gbagbọ, O le ma ṣe iṣẹ iyanu miran fun wọn nibẹ mọ. Fun apẹẹrẹ, ninu iwe Matiu ti a n gbe yẹwo fun ẹkọ yi, a ri eyi ka:

 

“Awọn Farisi pẹlu awọn Sadusi si wa, wọn n dan an wo, wọ si n fẹ ki o fi ami han fun wọn lati ọrun wa. Ṣugbọn o dahun o si wi fun wọn pe, Nigba ti o ba di aṣalẹ, ẹyin a wi pe, ọjọ yoo dara: nitori ti oju ọrun pọn. Ati ni owurọ ẹyin a wi pe, ọjọ ki yoo dara lonii, nitori ti oju ọrun pọn, o si ṣu dẹdẹ. A! Ẹyin agabagebe, ẹyin lee mọ ami oju ọrun; ṣugbọn ẹyin ko le mọ ami akoko wọnyi? Iran buburu ati pansaga n fẹ ami: a ki yoo si fi ami fun un, bi ko ṣe ami ti Jona wolii. O si fi wọn silẹ, oo kuro nibẹ.” (Matiu 16:1-4)

 

Njẹ o ri bayi? Jesu kọ jalẹ lati ṣe iṣẹ ami kan tabi omiran fun awọn Farisi ati Sadusi ti o tọ ọ wa. Ki si ni idi? Idi ni wipe wọn ti ni aafani lati ri ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ati iṣẹ ami ti Ọlọrun jẹ ki O ṣe. Sibẹsibẹ, wọn ko gbagbọ. Akoko kan wa ti O tilẹ sọ wipe egbe ni fun awọn ilu bi Korasini, Kapanaumu ati Bẹtisaida nitoripe bi o tilẹ jẹ pe O ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu ninu wọn, wọn ko ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn (Matiu 11:20-24). Nitorina, fun ẹni ti ko ba ni i gbagbọ rara, bi o tilẹ ri ẹgbẹgbẹrun iṣẹ ara ati iṣẹ iyanu wolii, bi Farao na ni ọkan rẹ yoo ṣe yigbe, ti ko si ni ronupiwada. Ti Ọlọrun ba wa kọ lati fi iṣẹ ami han iru ẹni bẹ, njẹ o buru bi? Ko buru rara.

 

Yatọ si eyi, ara awọn idanwo ti Eṣu fun Jesu, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli, ni pe ki o sọ okuta di akara (Matiu 4:1-4; Luuku 4:1-4). O si fẹ ki o ṣe eyi ki o ba le fi ara rẹ han gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Njẹ Jesu wa ṣe gẹgẹ bi o ti wi bi?  Rara o! Ki si ni idi ti ko fi ṣe bẹ? Idi ni wipe Jesu ko kan le dede ṣe iṣẹ iyanu ti ko ba ṣe wipe Ọlọrun lo ni ko ṣe e (Johanu 5:19 & 14:10). Eyi tunmọ si pe ifẹ Ọlọrun ni O n fi gbogbo igba tẹle; ko ki i ṣe ifẹ ti ara rẹ (John 8:29). Nitorina, niwọn igba ti o jẹ pe ifẹ Eṣu ni pe ki O sọ okuta di akara, ko le da lohun rara. A si gbọdọ jẹ ki eyi yewa yekeyeke, ki a ma ba titori pe a fẹ jẹ ki o ye awọn eniyan pe ti Ọlọrun ni a nṣe nitootọ jẹ iṣẹ ti ko ran wa.

 

Ni afikun, ko ki i ṣe gbogbo iṣẹ iyanu naa ni o ma n ti ọwọ Ọlọrun wa. Adamọdi iṣẹ iyanu wa. Awọn wolii eke naa a ma ṣe iyanu nipaṣẹ agbara awọn ẹmi Eṣu. Idi niyi ti Jesu Oluwa wa fi sọ eyi fun wa: “Nitori awọn eke Kirisiti, ati eke wolii yoo dide, wọn o si fi ami ati ohun iyanu nla han: tobẹẹ bi o le ṣe e ṣe, wọn o tan awọn ayanfẹ paapaa.  Wo o, mo wi fun yin tẹlẹ.” (Matiu 24:24-25) Njẹ o ri bayi? Ti a ko ba ṣọra, a le tipaṣẹ iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu kọsẹ tabi ṣọnu.

 

Ni kukuru, a ko le sọ pe eniyan ko ki i ṣe wolii Ọlọrun tabi wolii otitọ nitoripe ko ṣe iṣẹ ara tabi iṣẹ iyanu ni ibamu pẹlu erongba wa. A ko si le gbe odiwọn pataki iṣẹ wolii kankan le bi o ṣe ṣe iṣẹ iyanu to. Ọlọrun ti O n gbe iṣẹ le awọn wolii rẹ lọwọ naa ni o le sọ bi iṣẹ wolii kan ṣe ṣe pataki si ati irufẹ iṣẹ iyanu tabi iṣẹ ara ti yoo ṣe tabi ti ko ni i ṣe.

 

ỌRỌ IPARI

A gbọdọ yago fun fifi iṣẹ iyanu ṣe ami tabi odiwọn boya enikan jẹ wolii Ọlọrun tootọ tabi wolii eke. Boya wolii kan yoo ṣe iṣẹ iyanu tabi ko ni i ṣe ku si ọwọ Ọlọrun; ko si ni i ṣe pẹlu eniyan rara. Nitorina, pataki iṣẹ wolii ni ki o fi ifẹ Ọlọrun ati ete rẹ han si awọn eniyan bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, ki oun na si gbe igbe aye ti o wa ni ibamu pẹlu otitọ Ọlọrun ti o mọ. Ti o ba ti ṣe eyi, iṣẹ iranṣẹ rẹ yoo jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun, bi ko tilẹ wa pẹlu iṣẹ ami ati iṣẹ iyanu.

 

IBEERE

–     Ọna wo ni ẹkọ yi gba ran imọ ati oye rẹ lọwọ lori iṣẹ iranṣẹ wolii?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 02, OKUDU 2021

 

AKỌRI: ṢIṢE AMULO TO PEYE IṢEDARI IJỌ ỌLỌRUN (2)                        AYỌKA: EFESU 4:11-16

 

AKỌSORI: AKỌSORI: “Awọn agba Juda si kọle, wọn si ṣe aṣeyọri nipa iyanju Hagai wolii ati Sakaria ọmọ Iddo…” (Ẹsira 6:14)

 

ỌRỌ AKỌSỌ

Bi a ti ṣe ri ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin, ara awọn idi ti Ọlọrun fi ṣe agbekalẹ iṣedari ninu ijọ rẹ ni ki a ba le tọju awọn ọmọ rẹ lati dagbasoke ninu ẹmi, eyi ti o ni i ṣe pẹlu ki iwa ati iṣe wọn jọ ti Kirisiti ni gbogbo ọna. Idi miran ni o tun ni i ṣe pẹlu pipese wọn fun iṣẹ iranṣẹ. Ọmọ Ọlọrun kọọkan ni o ni ojuṣe ninu idile rẹ. Ṣugbọn ti a ko ba ṣe e yẹ lati mọ ojuṣe naa ati lati maa ṣe ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko si ni ki o ma ba nkan jẹ. Nitorina, ara ojuṣe awọn adari ijọ ti Ọlọrun pese fun wa ni lati pese wa lati jẹ yiyẹ fun iṣẹ iranṣẹ yowu ti Ọlọrun ba ni fun wa. Yatọ si eyi, bi a tun ṣe ri ninu ẹkọ ti a kọ sẹyin, idi miran ti Ọlọrun ṣe gbe awọn adari kalẹ fun wa ninu ijọ ni lati tọ wa sọna lati di ọkan ninu igbagbọ ati imọ wa ninu Kirisiti. Lotitọ, ọkan ni wa ninu Ẹmi ati ninu ara Kirisiti. Amọ ti a ko ba dagbasoke ninu igbagbọ wa ati ninu imọ ẹni ti Kirisiti jẹ, a ko ni ri ara wa gẹgẹ bi ọkan, ki a si ma ṣiṣẹ papọ ninu aye yi bi ọkan.

 

Ki awọn erongba ati ete wọnyi ti o n jẹ ki Ọlọrun pese awọn adari fun wa ninu ijọ wa ba le wa si imuṣẹ, a gbọdọ kọ iha ti o tọ ati ti o yẹ si awọn adari yowu ti Ọlọrun ba fun wa. Ti a ko ba i ti gbagbe, nkan ti o jẹ ki awọn ijọ ti Joṣua dari fi ilẹ-ileri ṣe erejẹ, bi o tilẹ jẹ pe wọn ba ọpọlọpọ idojukọ pade, ni pe wọn kọ iha ti o tọ ati ti o yẹ si iṣedari rẹ. Amọ awọn obi awọn wọnyi, ti Mose ko jade lati Ijibiti, ko ma wọ ile ileri pẹlu wọn. Idi si ni pe wọn ko kọ iha ti o tọ si iṣedari Mose. Wọn ko fi gbogbo ara gba Mose gẹgẹ bi ojiṣẹ Ọlọrun si wọn. Bẹẹ si ni wọn ko fi gbogbo ọkan wọn gba gbogbo ọrọ Ọlọrun ti o mu tọ wọn wa gbọ. Oun funrarẹ gan ṣe apejuwe wọn gẹgẹ bi aṣọtẹ si Ọlọrun. Nitorina, bi o tilẹ jẹ pe a mu wọn jade lati wọ ilẹ ileri ni, wọn kuna lati wọ ibẹ nitori aigbagbọ ati iṣorikunkun wọn si Ọlọrun ati iṣedari ti o yan fun wọn.

 

ṢIṢE AMULO TO PEYE IṢEDARI IJỌ ỌLỌRUN (2)

Ti awa na ko ba fẹ padanu ete ati ipese Ọlọrun fun aye wa gẹgẹ bi ijọ rẹ, ijọ ti O fi ẹjẹ ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti, ra, ani ti a ba fẹ jẹ irufẹ eniyan ti o fẹ ki a jẹ ni aye yi, ki a si ṣe gbogbo ojuṣe ti o yan fun wa ni ọna ti o tẹ ẹ lọrun, awa na gbọdọ kọ iha ti o tọ si iṣedari yowu ti O ba gbe kalẹ si aarin wa. Amọ ti a ko ba mọ iru iha ti o tọ ati ti o yẹ fun wa lati kọ si awọn adari ti Ọlọrun yan fun wa, ko si bi a ko ṣe ni ma kọ iha ti ko yẹ si wọn, eyi ti o le mu ipalara ti o ko ṣe e fẹnu sọ wa fun wa. Ki wa ni iha tabi awọn iha ti o yẹ ki a kọ si awọn adari ti Ọlọrun gbe kalẹ fun wa? Pataki lara wọn ni iwọnyi:

 

–     Ri wọn bi ẹlẹran ara: Lakọkọ, a ko gbọdọ fi igba kankan gbagbe pe eniyan bi tiwa naa ni awọn adari yowu ti Ọlọrun ba fun wa; wọn ọn ki i ṣe Ọlọrun. Nitorina ailera tabi aleebu oriṣiriṣi ni o le yi wọn ka, yala nipa ti ara tabi ti ẹmi tabi yala nipa igbe aye wọn ki wọn to mọ Jesu tabi lẹyin ti wọn ti mọ ọn. Eyi tunmọ si pe a le ni orisirisi idi lati gan wọn tabi lati ma kọbiara si wọn tabi lati ma mu wọn ni pataki. Ṣugbọn niwọn igba ti o ba jẹ pe Ọlọrun ni o fi wọn ṣe adari wa, ti a ba gba ohunkohun laye lati jẹ ki a gan wọn tabi mu wọn ṣere, ko si bi ete Ọlọrun lori aye wa ṣe le wa si imuṣẹ bi o ṣe yẹ. A tilẹ tun le fa jọgọdi si ori ara wa nipa eyi, paapaa julọ ti o ba jẹ pe irufẹ awọn adari bẹẹ n rin ninu ifẹ Ọlọrun. (Wo: Numeri 12; 2Awọn Ọba 2:23-25; Matiu 23:1-3; 1Timoti 4:12; Jemisi 3:1-2; Heberu 5:1-2). Yatọ si eyi, nitoripe ẹlẹran ara ni awọn adari yowu ti a le ni ninu ijọ, wọn le ṣe aṣiṣe, ṣina, ṣubu tabi sọ igbagbọ wọn nu. Nitorina, a gbọdọ kọ lati tẹle wọn ni iwọn bi awọn naa ba ṣe tẹle Jesu ni. Lakọkọ, eyi si tunmọ si pe awa gan an gbọdọ mọ Jesu funra wa. Aijẹbẹ, a ko ni mọ ti adari kan ti a n tẹle ba pada lẹyin ra, eyi si le pa imuṣe ete ati erongba Ọlọrun lori aye wa run. Ekeji, o tunmọ si pe a ko gbọdọ lo iṣubu, iṣina tabi ikuna adari kankan gẹgẹ bi awawi fun sisọ igbagbọ wa nu. (Wo: 1Kọrinnti 11:1)

 

–     Ba wọn lo pẹlu ọwọ: Ti a ba fẹ ki iṣedari awọn adari ti Ọlọrun yan fun wa ninu ijọ mu ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye wa, a gbọdọ ba wọn lo pẹlu ọwọ. Fun apẹẹrẹ, bibeli sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn awa n bẹ yin, ara, lati maa mọ awọn ti n ṣe laalaa laarin yin, ti wọn si n ṣe olori yin ninu Oluwa: ti wọn si n kilọ fun yin; Ki ẹ si ma bu ọla fun wọn gidigidi ninu ifẹ, nitori iṣẹ wọn. Ẹ si maa wa ni alaafia laarin ara yin.” (1Tẹsalonika 5:12-13) Eyi ko wa tunmọ si pe ki a sọ wọn di oriṣa ti a n bọ ni aarin wa tabi ki a jẹ ki wọn gba aaye Ọlọrun ninu aye wa. Ṣugbọn a gbọdọ bọwọ fun wọn gidigidi ninu ifẹ. Nitori kini? Ṣe nitoripe wọn gbayi niwaju Ọlọrun ju wa lọ ni tabi nitoripe ami ororo rẹ pọ lori aye wọn ju ti wa lọ? Rara o! Aye kan na ni Ọlọrun to wa si gẹgẹ bi ọmọ niwaju rẹ. Ifaminororo yan kan naa si ni o fi fun gbogbo wa. Amọ nitori iṣẹ iṣedari ti Ọlọrun gbe fun wọn, O fẹ ki a fi tifẹtifẹ (lalai fi ti oju aye ṣe) bọwọ fun wọn. Aijẹbẹ, ete ti O fi yan wọn sori wa ko ni wa si imuṣẹ.

 

–     Tẹriba lati tẹle itọni wọn: Yatọ si ki a bọwọ fun awọn adari wa ninu ijọ, a gbọdọ farabalẹ ma tẹle itọni wọn. Ki ni itunmọ ki a sọ pe a bọwọ fun eniyan, ki a ma wa gbọran si lẹnu? Ko ni itunmọ. O si tun lewu fun wa. Idi ni yi ti bibeli ṣe sọ pe, “Ẹ maa gbọ ti awọn ti n ṣe olori yin, ki ẹ si maa tẹriba fun wọn: nitori awọn ni n ṣọ ẹṣọ nitori ọkan yin laisinmi, bi awọn ti yoo ṣe iṣiro, ki wọn ki o le fi ayọ ṣe eyi, ni aisi ibanujẹ, nitori eyi ki yoo ja si ere fun yin.” (Heberu 13:17) Njẹ o ri bayi? Ọlọrun yan awọn adari fun wa ninu ijọ ki wọn ba le tọ wa sọna ninu irin igbagbọ wa ati ki wọn si tun ba le pa wa mọ kuro lọwọ awọn ọta ọkan wa. Wọn a si ma ṣe eyi nipa bibọ wa pẹlu ọrọ rẹ, nipa gbigba adura fun wa ati nipa ṣiṣe iṣẹ ẹṣọ lori aye wa. Ti a ko ba wa tẹriba lati gbọ nkan ti wọn n sọ fun wa, niwọn igba ti o si wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko si bi ete Ọlọrun ṣe fẹ wa si imuṣẹ lori aye wa. Yatọ si eyi, a ko le mu inu wọn dun. Niwọn igba ti inu awọn ti o n dari wa ninu ijọ ko ba si dun si wa, yala nitori aiṣedeede wa tabi nitori aigbọran wa, iṣẹ iranṣẹ wọn ko le yọri si ere fun wa. Idi ni yi ti adari ijọ ṣe le ma gbadura fun itẹsiwaju tabi aabo awọn ọmọ ijọ rẹ, ki adura rẹ lori wọn si ma gba.

 

–     Ran iṣẹ wọn lọwọ: O tun ṣe pataki ki a kọ bi a ṣe le ran iṣẹ awọn adari ti Ọlọrun yan fun wa lọwọ, ki a si ma da wọn da ohunkohun ti wọn ba n ṣe lati jẹ ki ete Ọlọrun wa si imuṣẹ lori aye wa ati lori aye awọn onigbagbọ bi tiwa miran. Iṣẹ Ọlọrun kọja nkan ti ẹnikan le da ṣe. Ara idi ti Ọlọrun si ṣe fun wa ni awọn adari ninu ijọ ni yi: ki wọn ba le pese wa lati ṣe iṣẹ rẹ. Ti a ba wa jẹ ọmọ ti o n gbẹkọ, yoo han ninu iha ti a ba kọ si iṣẹ iranṣẹ awọn adari wa. Ki ni idi ti Ọlọrun fi yan idile Aaroni fun iṣẹ alufa lori awọn eniyan rẹ? Idi ni pe o jẹ ọkan gboogi lara awọn ti o n ran Mose lọwọ (Ẹkisodu 17:10-13). Ki si ni idi ti O fi yan Joṣua gẹgẹ bi adari ti yoo rọpo Mose? Idi ni pe oun na jẹ ara awọn ti o n ran Mose lọwọ. Oun tilẹ ti n ran an lọwọ lati igba ewe rẹ (Ẹkisodu 24:13). Bawo ni ti Timoti ati Titu ṣe jẹ ti Pọọlu fi yan wọn lati ṣe idari ara wọn ijọ ti Ọlọrun lo o lati fi lọlẹ? O lo wọn nitoripe wọn wa lara awọn ti o n ran iṣẹ iranṣẹ rẹ lọwọ (Iṣe Apositeli 16:1-5). Ti awa na ba fẹ pọ si ni iwulo lọwọ Ọlọrun, a gbọdọ kọ bi a ṣe n fi tọkantara ran iṣẹ iranṣẹ awọn adari wa lọwọ. O le jẹ nipa gbigba adura fun wọn tabi nipa fififunni tabi nipa biba wọn mojuto awọn ojuṣe wọn kọọkan ki wọn ba le ri aye si lati ṣe awọn iṣẹ ti Ọlọrun fun wọn ti ẹlomiran ko le ba wọn ṣe. A ṣa gbọdọ wa ọna lati ri pe a n ran iṣẹ iranṣẹ wọn lọwọ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun.

 

ỌRỌ IPARI

Ọlọrun ṣe agbekalẹ iṣedari fun wa ninu ijọ lati jẹ ki a le di ohun gbogbo ti O fẹ ki a da, ki a si le ṣe ohun gbogbo ti O fẹ ki a ṣe. Amọ iha ti a ba kọ si awọn adari ti O yan fun wa ni yoo sọ boya ifẹ, ete ati erongba rẹ lori wa yoo wa si imuṣẹ tabi bẹẹkọ.

 

IBEERE

–     Darukọ awọn aleebu nipa ti ara ti o le wa ninu aye adari ijọ Ọlọrun.

–     Awọn ọna wo ni o ro pe o le gba ran iṣẹ iranṣẹ awọn adari ijọ rẹ lọwọ? Njẹ o tilẹ mọ wọn?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 26, EBIBI 2021

 

AKỌRI: ṢIṢE AMULO TO PEYE IṢEDARI IJỌ ỌLỌRUN (1)                        AYỌKA: EFESU 4:11-16

 

AKỌSORI: AKỌSORI: “Awọn agba Juda si kọle, wọn si ṣe aṣeyọri nipa iyanju Hagai wolii ati Sakaria ọmọ Iddo…” (Ẹsira 6:14)

 

ỌRỌ AKỌSỌ

Ki ni iyatọ ti o wa laarin awọn ọmọ Isiraẹli ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti ati awọn ọmọ wọn ti Joṣua ko wọ ilẹ Kenani? Ki lo fa ti awọn ti Mose ko jade kuro ni Ijibiti ko ṣe wọ ile ileri, ti wọn kan ranmu ninu aginju fun ogoji ọdun titi gbogbo wọn fi ṣegbe sibẹ, ṣugbọn ti awọn ọmọ wọn fi wọ ile ileri, ti wọn si ja ajaṣẹgun lori gbogbo awọn ọta wọn lati gba ilẹ na? Ṣe Ọlọrun fẹran awọn ọmọ wọn ju wọn lọ ni? Rara o! Ọlọrun ko fẹran awọn ọmọ wọn ju wọn lọ. Abi ṣe iṣedari Mose ni ko munadoko to lati ṣe itọni awọn eniyan wọnyi de ilẹ ti Ọlọrun ṣe ileri fun wọn ni? Rara o! Iṣedari Mose munadoko gigididi. Bi a tilẹ ṣe ri gan ninu bibeli, nitori pe iṣedari rẹ munadoko ni Ọlọrun ko ṣe pa gbogbo wọn run tọmọtọmọ. (Ẹkisodu 32)

 

Ki wa ni iṣoro gan an? Iṣoro na ni pe iha ti awọn wọnyi ko si iṣedari Mose ko bojumu to. Awọn wọnyi ko rẹ ara wọn silẹ lati ṣe amulo to peye iṣedari ati iwaasu ojiṣẹ Ọlọrun yi lati di irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki wọn da ati lati jogun ini ti O ti ṣeleri fun awọn baba nla wọn. Dipo eyi, nṣe ni wọn fi aye gba ọtẹ, orikunkun, ikunsinu, iṣekuṣe ati bẹẹbẹẹlẹ lọ ni aye wọn ati ni aarin wọn. A tilẹ ri igba ti wọn fi ara wọn jin fun ibọriṣa, nitoripe Mose kan fi wọn silẹ fun ogoji ọjọ ati ogoji oru. Bẹẹ si ni a ri igba ti wọn pinu lati yan adari miran fun ara wọn, eyi ti yo mu wọn pada lọ si ijibiti. Ki si ni idi? Idi ni pe wọn ko fẹ nkan ti Ọlọrun fẹ fun wọn. Nigbati Mose funrarẹ yoo sọrọ nipa wọn, o sọ wipe, “Ẹyin ti n ṣọtẹ si Oluwa lati ọjọ ti mo ti mọ yin.” (Ditaronomi 9:24) Eyi fi ye wa pe Mose kọ ni iṣoro wọn. Aigbagbọ ninu Ọlọrun gan ni iṣoro wọn. Aigbagbọ wọn ni ko jẹ ki wọn gbọran si Mose lẹnu bi o ṣe yẹ. Aigbagbọ wọn ni ko jẹ ki wọn fi ilẹ ileri ṣe ifajẹ. (Wo: 1Korinnti 10:1-11; Heberu 3:19)

 

Ṣugbọn awọn ọmọ awọn ara Isiraẹli yi ti Joṣua ṣe idari yatọ gedegede si wọn. Awọn ko fi igba kankan ba jiyan tabi ba lagidi. Ohunkohun ti o ba si ni ki wọn ṣe, ni ibamu pẹlu aṣẹ Ọlọrun, ni wọn n ṣe. Nitorina, wọrọwọ bayi ni wọn wọ ilẹ ileri ti wọn si gba, bi o tilẹ jẹ pe wọn ba ọpọlọpọ idojukọ pade, ti wọn si tun ja ọpọlọpọ ogun. Eyi si jẹ ki o ye wa pe iha ti a ba kọ si iṣedari ti Ọlọrun ba yan fun wa ni ipa to ga lati ko ninu boya a o di irufẹ ẹni ti Ọlọrun fẹ ka da, ki a si fi ijọba rẹ ṣe erejẹ, tabi bẹẹkọ. O wa yẹ ki a ma a bere lọwọ ara wa lati mọ boya irufẹ ijọ ti Mose ko jade ni Ijibiti ni wa ni tabi irufẹ ijọ ti Joṣua ko wọ ilẹ ileri.

 

ṢIṢE AMULO TO PEYE IṢEDARI IJỌ ỌLỌRUN

Ki a ma deena pẹnu, ti awa na ko ba fẹ dabi ijọ ti Mose ko jade ni Ijibiti ti o kuna lati da irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki wọn jẹ ati lati wọ ilẹ ileri, awa na gbọdọ kọ iha ti o tọ, ti o si nitunmọ si iṣedari ti O gbe kalẹ si aarin wa. Ki a si to le kọ iha ti o tọ si iṣedari ti O ṣe agbekalẹ rẹ, a kọkọ gbọdọ mọ idi ti O fi gbe e kalẹ. Ki lo de ti Ọlọrun, nigbati ti O ti sọ wa di atunbi ninu Jesu Kirisiti, ko kan jẹ ki ẹnikọọkan wa ma da ṣe nkan tirẹ, ki o si ma da rin irin igbagbọ rẹ? Idi ni pe O fẹ ki o ye wa pe ẹnikankan wa ko da wa; ara idile rẹ ni a jẹ. Ninu idile rẹ si ni yi, eto ati ọna ti o tọ lati ṣe ohun gbogbo wa fun ẹnikọọkan. Yatọ si eyi, ojuṣe wa fun ẹnikọọkan ti o jẹ ẹya ara idile yi lati ma a ṣe. Idi si ni yi ti O fi gbe iṣedari ti yoo mu ifẹ ati ete rẹ wọnyi wa si imuṣẹ laye wa. Iwọ na wo diẹ lara nkan ti apositeli Pọọlu sọ fun wa lori eyi:

 

“O si ti fi awọn kan fun ni bii apọsiteli; ati awọn miiran bii woliii ati awọn miiran bii ẹfanjẹlisiti ati awọn miiran bii oluṣọ-agutan ati olukọni; Lati pese awọn eniyan mimọ silẹ fun iṣẹ iranṣẹ, fun imudagba ijọ, ti i ṣe ara Kirisiti: Titi gbogbo wa yoo fi de iṣọkan igbagbọ ati imọ Ọmọ Ọlọrun, titi a o fi di ẹni pipe, titi a o fi de iwọn ẹkunrẹrẹ Kirisiti: Ki awa ki o ma ṣe jẹ ewe mọ, ti a n fi gbogbo afẹfẹ ẹkọ ti siwa ti sẹyin, ti a si n gba kiri nipa itanjẹ eniyan, nipa arekereke fun ọgbọnkọgbọn ati mu ni ṣina. Ṣugbọn ki a ma sọ otitọ ni ifẹ, ki a le maa dagbasoke ninu Kirisiti, ni ohun gbogbo, ẹni ti i ṣe ori ijọ: Lati ọdọ ẹni ti a ti n ṣe gbogbo ara ni ọkan pọ, ti o si n fi ara mọra, nipa gbogbo orikee ti n pese, (gẹgẹ bi olukuluku ẹya-ara ni iwọn tirẹ) o n mu ki ara naa bi si i, fun idagbasoke oun tikararẹ ninu ifẹ.” (Efesu 4:11-16)

Pẹlu akọsilẹ Pọọlu yi, ki ni a ri dimu gẹgẹ bi idi ti Ọlọrun ṣe pese awọn kan silẹ fun wa ninu ijọ rẹ gẹgẹ bi adari wa? Pataki ninu awọn nkan ti a ri dimu niyi:

 

–     Ipese awọn ọmọ Ọlọrun fun iṣẹ iranṣẹ: Akọkọ, Ọlọrun pese wọn fun wa lati pese wa fun iṣẹ iranṣẹ. Eyi tunmọ si pe gbogbo ọmọ Ọlọrun ninu Kirisiti ni o ni iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki o ma ṣe. Ọlọrun nikan ni O fẹ ma fi gbogbo igba lo wa; ko fẹ ki Eṣu tun ma a ri wa yalo. Ṣugbọn ti a ko ba pese wa fun awọn iṣẹ ti O fẹ ki a ṣe, a ko le ṣe wọn. Ti a ba si gbiyanju lati ṣe wọn lalai jẹ pe a ti ṣe wa yẹ, ko si ni ki a ma ba iṣẹ rẹ jẹ, bi awọn kan loni ṣe n ba iṣẹ rẹ jẹ, ti wọn si n tabuku orukọ rẹ. Ki a ba wa le ṣe wa yẹ lati ṣe awọn iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ma ṣe naa ni o ṣe fun wa ni awọn adari ijọ bi apọsiteli, wolii, oluṣọaguntan ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn ti a ko ba kọ iha ti o tọ si awọn wọnyi, iṣedari wọn ati iṣẹ iranṣẹ wọn laarin wa tabi lori wa ko si so eso ti Ọlọrun fẹ ki o so.

 

–     Idari awọn ọmọ Ọlọrun sinu iṣọkan: Idi miran ti Ọlọrun tun ṣe pese awọn adari wọnyi fun wa ninu ijọ ni ki wọn ba le kọ wa, ki wọn si tun mojutowa titi gbogbo wa yoo fi wa ni isọkan ninu igbagbọ ati imọ wa ninu Kirisiti. Eyi tunmọ si pe iṣe awọn adari ijọ wa ni lati ri pe gbogbo wa ri ara wa bi ọkan ninu Jesu Kirisiti dipo ti a o fi ri ara wa bi ọta ara wa. Ikunna ọpọ wọn ni o si fa ti iyapa ati ipinya oniruuru fi wa laarin awa ọmọ Ọlọrun kaakiri agbaye loni. Ti wọn ba n ṣiṣe wọn bi iṣẹ, nṣe ni gbogbo gba yoo tẹwọgba ara wa bi ara kan ninu Jesu Kirisiti pẹlu ifẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn ara ọtọọtọ ni a n ba darapọ.

 

–     Idari awọn ọmọ Ọlọrun fun idagbasoke ninu ẹmi: Lafikun, bi a ṣe ri ninu akọsilẹ Pọọlu, idi miran ti Ọlọrun fi ṣe agbekalẹ awọn adari fun wa ninu ijọ ni lati kọ wa ninu ọrọ Ọlọrun ati pẹlu iwa mimọ, daabo bo wa ati gbawa ni iyanju, ki a ba le dagba soke ninu ẹmi, ki a dabi Jesu ni gbogbo ọna, ki a si ye jẹ ope ti awọn alarekereke yoo ma ti kaakiri pẹlu oniruuru ẹkọ odi ati ẹkọ ailojutu. (Wo: Iṣe Apọsitẹli 20:28-31; 1Peteru 5:1-4) Nitorina, ti awọn adari wa ba n ṣe iṣẹ ti a fi ran wọn bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, nṣe ni o yẹ ki gbogbo wa ma dagba soke si ni rinrin ati ni wiwu iwa bi i Jesu Kirisiti Oluwa wa.

 

Amọ ṣa o, bi mo ti ṣe sọ siwaju tẹlẹ, imuṣẹ ete Ọlọrun ninu aye wa ko ni i ṣe pẹlu iṣẹ ti awọn adara wa n ṣe nikan; o tun ni i ṣe pẹlu iha ti awa naa ba kọ si iṣedari wọn. Idi si ni yi ti a ṣe ni lati kọ lati inu bibeli iha ti o tọna fun wa lati kọ si iṣedari awọn adari ti Ọlọrun yan fun wa.

 

ỌRỌ IPARI

Ọlọrun ni ete daradara fun gbogbo awọn ọmọ rẹ, bi a ṣe ri ninu bibeli. Idi si ni yi ti O fi ma n fi wọn si abẹ itọni ati idari ti yoo jẹ ki ete naa le wa si imuṣẹ. Amọ, yatọ si ki wọn wa labẹ iṣedari ti o munadoko, iha ti awọn naa ba kọ si iṣedari ti a fi wọn si abẹ rẹ naa ni ipa ti o ga lati ko ninu boya ete Ọlọrun yoo wa si imuṣẹ lori aye wọn tabi ko ni wa si imuṣẹ.  

 

IBEERE

–     Ki ni o ri dimu ninu ẹkọ yi?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 19, EBIBI 2021

AKỌRI: KI YOO RI BẸẸ LAARIN YIN AYỌKA: MATIU 20:20-28

AKỌSORI: AKỌSORI: “Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ laarin yi: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ di nla ninu yin, jẹ ki o ṣe iranṣẹ yin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu yin, ẹ jẹ ki o maa ṣe ọmọ-ọdọ yin.” (Matiu 20:26-27)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ipo jẹ ọkan pataki lara awọn nkan ti a ma n wo mọ awọn eniyan lara lati mọ iru iha ti a o kọ si wọn tabi si ibaṣepọ wa pẹlu wọn. Fun apẹẹrẹ, ti eniyan ba wa ni ipo ọla tabi ipo atata ninu aye yi, awọn eniyan a ma bọwọ fun tabi wa ojurere rẹ, bi wọn ko tilẹ fẹran rẹ tabi bi o tilẹ n ṣiwawu. Idi si ni pe wọn ko ni fẹ ki o lo ipo rẹ lati pọn wọn loju tabi jẹ wọn niya. Yatọ si eyi, ti eniyan ba wa ni ipo giga, awọn araye a tete ma kọbiara si i. Wọn le ma kiyesi awọn ti ko si ni ipo ọla tabi ṣe bi igba ti wọn ri wọn nijoko. Ṣugbọn ni kese ti wọn ba ti foju gaani ẹni ti o wa ni ipo giga bayi naa ni wọn yoo ti ma sare kaakiri lati ri pe wọn mu ni inu dun. Idi si ni yi ti ọpọ fi ma n lakaka lati de ipo nla, ipo ọla tabi ipo iyi ninu aye yi. Awọn miran ko tilẹ kọ nkan ti wọn ṣe tabi irufẹ ara ti wọn da lati de ipo ọla, ipo giga tabi ipo atata laye. Bi a ṣe mọ, ko si ẹni ti o fẹ ki awọn eniyan kọ iyan oun kere nibi ti o ba wa tabi ki wọn fi ọwọ yẹnpẹrẹ mu un. Gbogbo eniyan ni wọn ma fẹ ki wọn ri awọn bi eniyan pataki, ẹni ti aye n waari tabi bọwọ fun. Nitorina, ti ẹnikan ba mọ pe ti oun ba gbe awọn igbesẹ kan, o didan ki oun naa de ipọ nla, yoo fẹ gbe igbesẹ naa lalai fi ti atunbọtan rẹ ṣe, paapaa julọ ti ko ba mọ Ọlọrun. Ọpọ ni o si ti tipasẹ eyi ṣe ara wọn ati awọn miran ni ijamba, ti wọn si ti padanu ẹmi ati ọkan wọn.

KI YOO RI BẸẸ LAARIN YIN
O tun wa ṣe ni laanu pe ni arin awọn ọmọ Ọlọrun naa, iyẹn ninu ijọ Kirisiti, a tun ri pe iha ti awọn ti aye yi kọ si wiwa ni ipo ati lilo ipo ko fẹrẹ yatọ rara. Idi si ni pe oye nkan ti Ọlọrun ka si ipo giga ati bi a ṣe n de ibẹ ko ye ọpọ ninu wa paapaa. Nitorina, awa naa a ma ja si ipo ninu ijọ. Bẹẹni, a n ditẹ ara wa, sa ogun si ara wa, jin ara wa lẹṣẹ, ran agbenipa si ara wa ati bẹẹbẹẹ lọ nitori ipo. Ṣugbọn Ọlọrun fẹ ki a mọ pe eyi ko yẹ ki o ribẹ rara laarin wa. Ti a ba si wa kọ lati mọ ifẹ rẹ lori iha ti o yẹ ki a kọ si ipo ninu ijọba rẹ, ko si ni bi a ko se ni ba nkan jẹ ninu ijọ rẹ. Ti a ba si ba nkan jẹ ninu ijọ rẹ, o di didan ki a ba idajọ rẹ pade, ki a si tun padanu oriyin rẹ nigbati opin ohun gbogbo ba de.

Idi gan wa niyi ti Jesu fi farabalẹ kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ nigba ti o wa ni aye lẹkọ lori iha ti o yẹ ki wọn kọ si ipo gẹgẹ bi ọmọ ijọba Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, a ri akọsilẹ yi ninu bibeli nipa iṣẹlẹ ti o mu ki O ṣe alaye lẹkunrẹrẹ fun wọn lori ifẹ Ọlọrun nipa ipo giga ninu ijoba rẹ ati ọna ti a le gba de ibẹ. Akọsilẹ naa ni eyi:

“Nigba naa ni iya awọn ọmọ Sebede ba awọ ọmọ rẹ tọ ọ wa, o sin in, o si n fẹ ohun kan ni ọwọ rẹ. O si bi i pe, kin ni iwọ n fẹ? O wi fun un pe, Jẹ ki awọn ọmọ mi mejeeji ki o maa jokoo, ọkan ni ọwọ ọtun rẹ, ọkan ni ọwọ osi ni ijọba rẹ. Ṣugbọn Jesu dahun, o si wi pe, Ẹyin ko mọ ohun ti ẹyin n beere. Ẹyin ha le mu ninu ago ti emi o mu, ati ki a fi ibatisi ti a o fi batisi mi batisi yin? Wọn wi fun un pe, Awa le ṣe e. O si wi fun wọn pe, Loootọ ni ẹyin oo mu ninu ago mi, ati ninu ibatisi ti a o fi batisi mi i a o si fi batisi yin: ṣugbọn niti ọwọ ọtun ati ni ọwọ osi mi, kii ṣe ti emi lati fifunni bi ko ṣe pe fun kiki awọn ẹni ti a pese rẹ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wa. Nigba ti awọn mẹwaa yooku gbọ, wọn binu si awọn arakunrin wọn mejeeji. Ṣugbọn Jesu pe wọn sọdọ rẹ, o si wi pe, Ẹyin mọ pe awọn ọba Keferi a maa lo agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a maa lo aṣẹ lori wọn. Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ laarin yin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ di nla ninu yin, jẹ ki o ṣe iranṣẹ yin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu yin, ẹ jẹ ki o maa ṣe ọmọ-ọdọ yin: Ani gẹgẹ bi ọmọ-eniyan ko ti wa ki a ṣe iranṣẹ fun un, bi ko ṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi emi rẹ ṣe irapada ọpọlọpọ eniyan.” (Matiu 20:20-28)

Ki ni ẹbẹ iya awọn ọmọ Sebede da le lori? Ipo ni o da le lori. Iya yi fẹ ki awọn ọmọ rẹ mejeji ti o jẹ ọmọlẹyin Jesu, iyẹn Jemisi ati Johanu, di ipo ti o ga julọ mu ninu ijọba rẹ. Bi o si ṣe yẹ ki o ri, eyi bi awọn ọmọlẹyin yoku ninu gidigidi. Ṣugbọn a ko ri ka pe o bi Jesu ninu rara. Ko tilẹ titori ẹbẹ wọn yi barajẹ tabi le wọn danu kuro lọdọ rẹ. Ki ni idi? Idi ni pe Ọlọrun ko lodi si ki eniyan lero tabi nifẹ lati de ipo giga tabi lati di ẹni giga. A tilẹ tun ri ninu bibeli pe O ṣe ileri fun awọn eniyan rẹ lati fi wọn ṣe ori ati ẹni iwaju ninu aye yi, ti O si fi idi eyi mulẹ ni ọpọlọpọ igba (Ditaronomi 28:13).

Amọ ṣa o, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọfun ko lodi si ki a wa ni ipo ọla tabi ipo giga ninu aye yi, ọna ti a gba de ibẹ ati nkan ti a n lo ipo naa fun ṣe pataki si pupọ. Nibakaana, Ọlọrun ko lodi si ki a wa ni ipo tabi aaye ti o ga ninu ijọba rẹ. Amọ ọna lati de irufẹ ipo yi yatọ gedegbe si ọna lati de ipo giga tabi ipo atata ninu aye yi.

Lotitọ, ẹni ti Ọlọrun ko ba gba laaye lati de ipo kan tabi ekeji ninu aye yi ko le debẹ, bi o ti wu ki o tiraka to. Amọ, ọpọ wa naa ni o mọ pe oniruuru ọna ni awọn ti aye yi n gba lati de ipo ọla tabi ipo atata. A si tun mọ pe oniruuru nkan ti o wu wọn ni wọn si n fi awọn ipo wọn ṣe. Fun apẹẹrẹ, Jesu ninu ọrọ rẹ si awọn ọmọlẹyin rẹ sọ pe awọn ti o wa ni ipo nla ninu aye yi maa n lo agbara ati aṣẹ lori awọn ti o wa ni abẹ isakoso wọn (Matiu 20:25). Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni awọn nkan ti wọn n lo ipo wọn fun dara tabi bojumu. Ṣugbọn nigba ti o je pe aṣe ati agbara wa lọwọ wọn, ara ti o ba wu wọn ni wọn le fi awọn ti o wa ni abẹ wọn da.

Amọ bi Jesu ṣe fi ye awọn ọmọ ẹyin rẹ ninu akọsilẹ yi, ijọba Ọlọrun ko ki i ṣe ibi ti eniyan ti n lo ipo rẹ bi o ṣe wu. Ko tilẹ ki i ṣe ibi ti eniyan ti le de ipo giga, ti ifẹ Ọlọrun lori bi a ṣe n de ipo giga tabi lo ipo wa ko ba ye. Lakọkọ, Jesu jẹ ki o ye awọn ọmọ ẹyin rẹ pe bi eniyan tilẹ fi aye rẹ silẹ fun iku tabi ijiya nitori rẹ, ko tunmọ si pe yoo di ipo nla tabi ipo atata mu ninu ijọba rẹ (Matiu 20:22-23). Lẹkeji, O tun jẹ ki o ye wọn pe bi eniyan tilẹ di ipo pataki bi ti apositeli mu ninu ijọ tabi boya o n tilẹ n tẹẹle kaakiri ko tunmọ si pe yoo di ipo nla tabi ipo pataki mu ninu ijọba baba rẹ. Idi si ni pe Ọlọrun gan funrarẹ ni yoo sọ ipo ti ẹnikọọkan wa yo dimu ninu ijọba rẹ (1Korinnti 12:18).

Nitorina ko ni si ojusaaju rara. Aye ti Ọlọrun ba to ẹnikọọkan wa si ni yoo ti ba ara rẹ. Nkan ti ẹnikọọkan wa ba si ṣe ni yoo gba. Lotitọ, eniyan le lo oriṣiriṣi ọna alumọkọrọyin ninu ijọ Ọlọrun ninu aye yi lati fi awọn ọmọ Ọlọrun si abẹ isakoso rẹ. Bẹẹ si ni eniyan le lo ipo rẹ gẹgẹ bi olori ninu ijọ lati jẹ awọn ọmọ Ọlọrun niya, lati pọn wọn loju, lati ja wọn lole tabi lati fi idibajẹ sinu aye wọn. Eyi ko wa jasi pe nigbati Ọlọrun ba fi idi ijọba ayeraye rẹ mulẹ ninu aye yi, irufẹ ẹni bẹ yoo tun wa ni ipo pataki nibẹ, ti o ba ti ẹ ni oore-ọfẹ lati wa nibẹ. Ki a tilẹ ṣọ otitọ, ọpọ awọn adari ijọ ti awọn eniyan n sare tẹle kaakiri loni, ti wọn n to ki wọn to ri wọn tabi ti wọn ti sọ di ọlọrun kekeke ninu aye wọn loni lo jẹ pe ipo ti a o ti ba wọn ni ijọba ọrun yoo ya wa lẹnu gidigidi.

Ọna wo wa ni a le gba di ipo nla tabi ipo atata mu ni ijọba Ọlọrun. Laiṣe aroye pupọ, Jesu sọ fun wa pe ọna sinsin awọn eniyan, paapaa julọ, awọn ọmọ Ọlọrun ni. Iwọ na gbe ọrọ rẹ wo lẹkansi: Ẹyin mọ pe awọn ọba Keferi a maa lo agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a maa lo aṣẹ lori wọn. Ṣugbọn ki yoo ri bẹẹ laarin yin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ di nla ninu yin, jẹ ki o ṣe iranṣẹ yin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣẹ olori ninu yin, ẹ jẹ ki o maa ṣe ọmọ-ọdọ yin: Ani gẹgẹ bi ọmọ-eniyan ko ti wa ki a ṣe iranṣẹ fun un, bi ko ṣe lati ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi emi rẹ ṣe irapada ọpọlọpọ eniyan.” (Matiu 20:25-28) Ṣe o ri bayi? Laarin awa ọmọ Ọlọrun, awọn nkan ti awọn ti aye yi n ṣe pẹlu ipo wọn ko gbọdọ waye rara. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ ri ẹni ti yoo sọra rẹ di abaṣẹwa laarin wa. A ko si tun gbọdọ ri ẹni ti yoo ma lo ipokipo ti o ba wa ninu ijọ lati lo agbara lori awọn ọmọ Ọlọrun nipa jijẹ wọn niya, pipọn wọ loju, fifi idibajẹ sinu aye wọn, jija wọn lole tabi sisọ ọrọ odi si wọn.

Dipo eyi, a gbọdọ fi ara wa jin lati ma sin ara wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ni. Bẹẹni, a gbọdọ ma fi ipokipo ti a ba wa sin ara wa lati di gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ki a da, ki a si tun ṣe gbogbo nkan ti O fẹ ki a ṣe. Ki si ni idi? Idi akọkọ ni pe Jesu funrarẹ, ti o jẹ Oluwa wa, gan fi ipo rẹ ninu aye yi sin gbogbo eniyan ni, ti o si ku fun ẹṣẹ wọn. Idi keji ni pe aparo kan ko ga ju aparo miran lọ laarin ara wa nitoripe ara kanna ni gbogbo wa (Matiu 23:9). Lotitọ, a fi ye wa ninu ọrọ Ọlọrun ki a bu ọla fun awọn adari ijọ wa. Ṣugbọn ko ki i ṣe nitoripe wọn tobi ju wa lọ niwaju Ọlọrun ni a ṣe sọ eyi fun wa bikoṣe nitori iṣẹ ti wọn n ṣe laarin wa (1Tẹsalonika 5:12-13). Nitorina, bi a ba ṣe n bu ọla fun awọn adari wa ni awọn naa gbọdọ ma fi ara wọn jin lati sin wa. Gẹgẹ bi Jesu si ṣe fi ye wa, nipa ṣiṣe eyi ni Ọlọrun ṣe le fiwa si ipo giga ninu ijọba rẹ. Njẹ olusin fun awọn ọmọ Ọlọrun ni a wa ri ara si bi abi ọga ati apaṣẹ lori wọn? Ipo wọn gan ni a o ti ba ara wa ninu ijọba Ọlọrun nigba ti Jesus ba de?

ỌRỌ IPARI
Ko si ẹni ti Ọlọrun ko fẹ fun ipo nla ninu ijọba rẹ. Amọ, eyi kọja ọrọ ẹnu tabi pe a di ipo nla mu ninu aye yi. Ti a ko ba fi ara wa jin, bi Jesu ṣe ṣe nigbati O wa ni aye yi, lati lo ipokipo ti a ba wa lati sin awọn ọmọ Ọlọrun ati awọn eniyan bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ, aifamọ ki a ma ba ijakulẹ pade nigba ti a ba de ijọba ayeraye rẹ, bi o ti wu ki a lọla to loju awọn eniyan ninu aye yi.

IBEERE
– Ki ni idi ti awọn eniyan fi ma n gba ọnakọna ti o wu wọn lati de ipo nla?
– Ọna wo ni a le gba lati ran awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn n ṣi ipo wọn lo lọwọ lati ṣe atunṣe?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal


Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ỌJỌRU 12, EBIBI 2021  AKỌRI: JONA – FI ỌRỌ RO ARA RẸ WO              AYỌKA: JONA 4:1-11

AKỌSORI: AKỌSORI: “Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ kẹdun itakun naa nitori eyi ti iwọ ko ṣiṣẹ bẹẹ ni iwọ ko mu un dagba; ti o hu jade ni oru kan ti o si ku ni alẹ kan.” (Jona 4:10)

ỌRỌ AKỌSỌ

Ninu awọn ẹkọ ti a n kọ ninu iwe Jona, a ti ri bi Jona ati awọn ara Ninefe ṣe ṣe amulo aanu Ọlọrun, ti o si yọri si igbala fun wọn. Eyi si n fi idi rẹ mulẹ fun wa pe alaanu ni Ọlọrun nitootọ, Ọlọrun ti O ma n lọra lati binu, ti O si tun ma n dariji ẹlẹṣẹ ti o ba ronupiwada. Yatọ si eyi, o tun fi idi rẹ mulẹ pe Ọlọrun ko ki i ṣe ojusaaju. Iha ti O kọ si ironupiwada Jona, ti o jẹ olusin ati wolii rẹ, naa ni O kọ si ironupiwada awọn ara Ninefe ti wọn jẹ abọrisa ati alaigbọran. Nitorina, boya ẹṣẹ tobi niwaju wa ni o tabi o kere, ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun, niwọn igba ti a ba ti ronupiwada. Nibakanna pẹlu, boya ẹṣẹ tobi ni o tabi o kere, Ọlọrun le jẹwa niya lori rẹ, niwọn igba ti a ba kọ lati ronupiwada.

FI ỌRỌ RO ARA RẸ WO

Wayi o, abala ti o kasẹ iwe yi nilẹ ti a fẹ wo ninu ẹkọ yi ni i ṣe pẹlu iha ti Jona kọ si bi Ọlọrun ṣe dariji awọn ara Ninefe ninu aanu rẹ, ti ko si pa wọn run mọ, bi O ti ṣeleri tẹlẹ. Wo diẹ lara nkan ti a kọ silẹ nipa eyi:

“Ṣugbọn o ba Jona ninu jẹ gidigidi, o si binu pupọ. O si gbadura si Oluwa, o si wi pe, Emi bẹ ọ, Oluwa, njẹ ohun ti mo wa wi kọ yii nigba ti mo wa ni ilẹ mi? Nitori naa ni mo ṣe salọ si Taṣiṣi ni iṣaaju: nitori emi mọ pe, Ọlọrun oloore-ọfẹ ni iwọ, ati alaaanu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi naa. Njẹ nitori naa, Oluwa, emi bẹ ọ, gba ẹmi mi kuro lọwọ mi nitori o san fun mi lati ku ju ati wa laaye. Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ ha ṣe rere lati binu?” (Jona 4:1-5)

Iha wo ni Jona kọ si bi Ọlọrun ṣe fi aanu gba awọn ara Ninefe? Iha ẹni ti ko ki i fi ọrọ ro ara rẹ wo ni. Lakọkọ, a ri wipe inu wolii yi ko dun rara si bi Ọlọrun ṣe dariji awọn ara Ninefe, ti ko si pa wọn run. Akọsilẹ yi tilẹ fi ye wa pe inu bi i pupọ debi pe o tilẹ fẹ ki Ọlọrun gba ẹmi oun. Ki gan wa ni o n bi ninu, ti ko si jẹ ki inu rẹ dun? Nkan ti o n bi ninu ni pe bi o ṣe woye nibẹrẹ pẹpẹ pe Ọlọrun yoo ṣe ṣe naa ni Ọlọrun papa ṣe. O ti woye pe ti oun ba waasu si awọn ara Ninefe, ti wọn ba si ronupiwada, Ọlọrun naa le ronupiwada, ki O si ma pa wọn run mọ. Oun si fẹ ki Ọlọrun pa wọn run nitori ẹṣẹ wọn ati awọn iwa ika ti wọn ti wu si awọn ọmọ Israẹli, iyẹn awọn eniyan rẹ. Idi niyi ti o fi gbiyanju lati salọ lakọkọ.

Yatọ si eyi, Jona fihan wa pe oun naa wa lara awọn wolii ti wọn ma n fẹ ki asọtẹlẹ wọn, boya si rere ni o tabi si buburu, wa si imuṣẹ ni dandan. Ṣugbọn bi a ṣe ri ka ninu bibeli, ko ki i ṣe dandan ni ki asọtẹlẹ wolii kankan wa si imuṣẹ, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ni o fi ọrọ si lẹnu nitootọ. Iha ti awọn ti a sọtẹlẹ nipa wọn naa ba kọ si nkan ti a sọ nipa wọn ni ipa pupọ lati ko lori boya asọtẹlẹ naa yoo wa si imuṣẹ tabi ko ni wa si imuṣẹ.

Fun apẹẹrẹ, wolii Aisaya sọtẹlẹ ni akoko kan si ọba Hesekaya pe yoo ku sinu aisan rẹ. Ṣugbọn nigba ti ọba yi gbadura si Ọlọrun lori ọrọ naa, Ọlọrun tun ran Aisaya pada lati sọ fun un pe ko ni i ku mọ ati pe Oun tun fun ni ọdun mẹẹdogun si lati gbayegbadun. Nitorina, igbesẹ ti Hesekaya gbe lori isọtẹlẹ ti o gba naa wa lara idi ti Ọlọrun fi yi ọkan rẹ pada. (Wo: Aisaya 38) Amọ ti a ba wo iha ti ọba Jeroboamu kọ si isọtẹlẹ ti o gba lati ọwọ wolii Ahija lori jijọba rẹ ati ifidimulẹ ijọba naa, a o ri pe ko bojumu rara. Nitorina, Ọlọrun yi ọkan rẹ pada lori fifi idi ijọba rẹ mulẹ, O si ke e kuru. (Wo: 1Awọn Ọba 11:26-39 & 14:1-20)

Ki wa gan ni a n sọ? Nkan ti a n sọ nipe ko pọn dandan ki isọtẹlẹ wolii kankan wa si imuṣẹ. Wolii ti isọtẹlẹ rẹ ko ba wa wa si imuṣẹ ko yẹ ko fi ṣe ibinu tabi ija. Nitoripe wiwa si imusẹ isọtẹlẹ nikan kọ ni yo sọ boya wolii eke ni eniyan tabi wolii otitọ ni. Irufẹ eso ti aye eni naa ba n so naa wa lara nkan ti yo jẹ ki a mọ boya wolii otitọ ni tabi wolii eke. A ri awọn wolii eke ati awọn ẹlẹmikẹmi ti isọtẹlẹ wọn ma n jẹ otitọ tabi wa si imuṣẹ. Ṣe eyi wa tunmọ si pe Ọlọrun gba ti wọn bi? Rara o. (Wo: Matiu 7:15-20; Iṣe Apositeli 16:16-18)

Wolii ti Ọlọrun gba tirẹ ni eyi ti o n fi ojoojumọ lepa lati ṣe ifẹ rẹ, yatọ si pe ki o kan sọ asọtẹlẹ nikan. Irufẹ wolii yii, lotitọ, yoo fẹ ki asọtẹlẹ rẹ ni rere ki o wa si imuṣẹ lori awọn eniyan. Bakanna, irufẹ wolii yi yoo fẹ ki awọn eniyan ronupiwada, ki wọn ma ba a ṣegbe, ti o ba sọ asọtẹlẹ ibi si wọn. Apẹẹrẹ iru awọn wolii yi ni Samuẹli, ẹni ti ko dẹkun lati ma kaanu fun Ọba Ṣọọlu, bi o tilẹ jẹ pe oun naa ni o sọtẹlẹ si pe a ti fa ijọba rẹ ya, a si ti yan ẹlomiran dipo rẹ. (Wo: 1Samuẹli 15:35; Isikẹli 11:13)

Ni kukuru, a ri wipe Ọlọrun bere lọwọ Jona boya o tilẹ lẹtọ rara lati binu si i nitoripe ko pa awọn ara Ninefe run. Ki O si ba le jẹ ki o ye pe ko lẹtọ lati binu rara ati wipe aifi ọrọ ro ara rẹ wo ni o n yọ ọ lẹnu, Ọlọrun jẹ ki o ni iriri manigbagbe kan. Wo akọsilẹ iriri naa:

“Jona si jade kuro ni ilu naa, o si jokoo niha ila-oorun ilu naa, o si pa agọ kan nibẹ fun ara rẹ, o si joko ni ibooji labẹ rẹ, titi yoo fi ri ohun ti yoo ṣe ilu naa. Oluwa Ọlọrun si pese itakun kan, o si ṣe e ki o goke wa sori i Jona, ki o le siji bo o lori; lati gba a kuro ninu ibanujẹ rẹ. Jona si yọ ayọ nla nitori itakun naa. Ṣugbọn Ọlọrun pese kokoro kan nigba ti ilẹ mọ ni ijọ keji, o si jẹ itakun naa, o si rọ. Nigba ti oorun la, Ọlọrun si pese ẹfuufu gbigbona ti ila-oorun; oorun si pa Jona lori, to bẹẹ ti o rẹ ẹ, o si fẹ ninu ara rẹ lati ku, o si wi pe, O san fun mi lati ku ju lati wa laaye lọ. Ọlọrun si wi fun Jona pe, o ha tọ fun ọ lati binu nitori itakun naa? Oun si wi pe, O tọ un mi lati binu tite de iku. Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ kẹdun itakun naa nitori eyi ti iwọ ko ṣiṣẹ bẹẹ ni iwọ ko mu un dagba; ti o hu jade ni oru kan ti o si ku ni alẹ kan. Ṣe ki emi ki o ma si da Ninefe si, ilu nla ni, ninu eyi ti iye wọn ju ọkẹ-mẹfa eniyan, ti ko mọ ọtun yatọ si osi wọn wa, ati ọpọlọpọ awọn ohun ọsin?” (Jona 4:5-11)

Bi a ṣe ri ninu akọsilẹ yi, Jona bikita fun itakun lasanlasan, itakun ti ko gbin tabi mojuto, nitoripe itakun naa wulo fun. Ṣugbọn ẹmi awọn ara Ninefe, ti o ṣe iyebiye si Ọlọrun, ẹmi awọn eniyan wọnyi ti o ṣeeṣe ki o ṣegbe titi ayeraye sinu ina ọrun apadi, ko jamọ nkankan loju wolii yi. Idi si ni pe ko fi ọrọ ro ara rẹ wo. Ti a ko ba gbagbe, oun na ri aanu gba ni o ṣe ni oore-ọfẹ ati wa laye lati wo ki ni yoo ṣẹlẹ si awọn ara Ninefe. Ka sọ wipe Ọlọrun ko da lohun nigba ti o bẹbẹ fun aanu ninu ẹja nla ti o wa, ṣe yoo ni anfaani lati pe Ọlọrun lẹjọ bi o ṣe ṣe yi? Ko le ni i rara. Ṣugbọn o ti gbagbe ni kiakia pe bi oun ṣe ri aanu gba naa ni awọn ara Ninefe ṣe ri aanu gba. Nitorina, ko lẹtọ, labẹ bi o ṣe wu ki o ri, lati binu si Ọlọrun tabi lati banujẹ pe Ọlọrun ṣaanu fun awọn ara Ninefe. Idi si ni yi ti Ọlọrun fi lo iriri ti o ni pẹlu itakun ti a ṣọrọ nipa rẹ ninu iwe yi kọ ọ lẹkọ ati lati fi agabagebe rẹ han.

Wayi o, njẹ awa na ko nilo iru ẹkọ ti Ọlọrun kọ Jona yi bi? Njẹ Ọlọrun ko nilo lati fi agabagebe ọkan wa han lori ero ọkan wa si awọn ẹlẹṣẹ ayika wa tabi awọn ti o ṣẹ wa? Njẹ awa na ko fẹran awọn nkan ini wa ti o di dandan ki wọn ṣegbe ju ọkan awọn eniyan lọ bi? Eleyi kọja ọrọ ẹnu lasan o. Niwọn gba ti inu wa ba ti n dun ṣi iku tabi ijiya ẹlẹṣẹ ṣugbọn ti ko dun si ipadanu awọn nkan ini wa, a jẹ wipe alagabagebe bi Jona ni awọn na jẹ pẹlu.

Ko wa yẹ ki o ṣi mi gbọ o. Nkan ti mo n sọ kọ ni pe o dara ki inu wa dun ti nkan ini wa kan ba bajẹ. Dipo eyi, nkan ti mo n sọ ni pe ti a ba le daro nkan ini wa ti o bajẹ, o yẹ ki a le daro ju bẹẹ lọ ti ẹlẹṣẹ ba n jiya tabi ti wọn ba ba iparun pade. Idi ni pe ti nkan ini wa ba bajẹ, a le ra omiran rọpo rẹ. Ṣugbọn ti ẹlẹṣẹ kan ba ṣegbe, ko si nkankan ti a le fi ṣe pasiparọ fun ọkan rẹ. (Wo: Matiu 16:26)

Yatọ si eyi, aanu ni awa naa rigba. Ti o ba jẹ pe bi okun ẹṣẹ ti wa naa ṣe gun to ni Ọlọrun ṣe dana sun un ni, awa na ko ba ti di ẹni egbe. Ṣugbọn O ṣaanu fun wa nipasẹ Ọmọ rẹ Jesu, O si fi ifẹ gba wa la. Siwaju si, ti o ba jẹ pe gbogbo igba ti a n ṣẹ si Ọlọrun naa ni O n ṣe idajọ ẹṣẹ wa ni kiakia, lalai fi aye ironupiwada silẹ fun wa, ṣe a ko ti ni ku tipẹtipẹ tabi ki a ti da idakuda. Ti a ba wa fi ọrọ ro ara wa wo, a ko ni fẹ ki Ọlọrun pa ẹlẹṣẹ run tabi jẹ wọn niya dandan, paapaa julọ niwọn igba ti wọn ba ti fi ami ironupiwada han. Eyi si jẹ pataki lara awọn koko ẹkọ ti iwe Jona kọ wa.

 

ỌRỌ IPARI

Niwọn igba to jẹ pe ọla aanu Ọlọrun ni gbogbo eniyan n jẹ, ko yẹ ki a ri ẹni ti yoo mura kankan pe ki Ọlọrun pa ẹnikẹni run tabi jẹ wọn niya dandan lalai kọkọ fi ọrọ ro ara rẹ wo. Ti o ba jẹ emi ni nkọ, ṣe ma a fẹ ki Ọlọrun ṣe iru idajọ bayi fun mi? Tabi ti Ọlọrun ba ni ki Oun ṣe idajọ temi na bayi, bi mo ṣe n fẹ ki O ṣe idajọ awọn ti o ṣẹ mi tabi idajọ awọn eniyan ika ayika mi ni dandan, njẹ emi naa yoo bọ bi? Awọn ibere ti o yẹ ki a ma bere lọwọ ara wa niyi nigbakugba ti a ba n lepa pe ki idajọ Ọlọrun wa sori awọn elomiran.

IBEERE

–     Ki ni pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Gba ẹda ti ẹ

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 05, EBIBI 2021
 
AKỌRI: JONA – ṢIṢE AMULO AANU ỌLỌRUN (2)                AYỌKA: JONA 3:1-10
 
AKỌSORI: AKỌSORI: “Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ kẹdun itakun naa nitori eyi ti iwọ ko ṣiṣẹ bẹẹ ni iwọ ko mu un dagba; ti o hu jade ni oru kan ti o si ku ni alẹ kan.” (Jona 4:10)
 
ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ kẹyin ninu iwe Jona, a fi ye we pe Ọlọrun ko ki i ṣe Ọlọrun onidajọ nikan; Ọlọrun alaanu ni o jẹ pẹlu. Idi si ni yi ti O fi jẹ pe ọpọ igba ni O ma n fi aaye silẹ fun ironupiwada awọn ẹlẹṣẹ, ki wọn ma ba ṣegbe. Amọ iha ti ẹlẹṣẹ ba kọ si aanu ti Ọlọrun ba fi han an ni yo sọ boya aanu yi yoo yọri si igbala, itusilẹ tabi igbesoke fun tabi boya yoo ja si asan. Ni ti Jona, ko jẹ ki aanu ti Ọlọrun fi han an jasi ofo. Lotitọ Ọlọrun ṣe idajọ aigbọran rẹ ni kiakia, nipa jijẹ ki a ju sinu okun, ki ẹja nla kan si gbe e mi. Ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ ki ẹja na fi ṣe ounjẹ jẹ ni gbogbo ọsan mẹta ati oru mẹta ti o ṣe ninu rẹ. Bi o tilẹ wa jẹ pe o nira pupọ fun ọkunrin yi lati wa ninu ẹja yi, ninu okunkun birimubirimu, o ri wiwa laye rẹ bi ami aanu Ọlọrun. Nitorina, o gba ẹbi rẹ ni ẹbi, o si ke pe Ọlọrun fun aanu ati fun igbala. Oun si da lohun. Eyi tunmọ si pe Jona ṣe amulo aanu Ọlọrun lati ri idariji ati igbala gba. Ti a ba si tun wa ri ẹnikẹni ti oun na ba ṣe bẹẹ gẹgẹ, ti o rẹ ara rẹ silẹ niwaju Ọlọrun fun idariji ẹṣẹ rẹ ati fun itusilẹ, bi o ti wu ki ipo ti ẹni naa wa buru to, Ọlọrun yoo ṣaanu fun, yoo dariji, yoo si tun tu silẹ. Yatọ si eyi, bi eniyan ko tilẹ ṣẹ si Ọlọrun, ṣugbọn ti o ba ara rẹ ninu iyọnu, niwọn igba ti ẹmi ba si wa lẹnu rẹ, ti o ba ke pe fun aanu ati itusilẹ, Ọlọrun yoo gbohun rẹ, yoo si saanu fun.
 
ṢIṢE AMULO AANU ỌLỌRUN (2)
Bi a tun ṣe wa ri ninu iwe Jona, ko ki i ṣe wolii yi nikan ni o ṣe amulo aanu Ọlọrun lati ri idariji ati igbala gba. Awọn ara Ninife naa ṣe amulo aanu rẹ lati ri idariji ati igbala gba. Eyi si ni abala iwe yi ti a fẹ gbe yẹwo ninu ẹkọ yi da le lori. Wayi o, ti a ko ba i ti gbagbe, nkan akọkọ ti a kọkọ ri ninu iwe yi ni pe Ọlọrun ran Jona lati lọ kigbe rara si awọn ara Ninife nitori iwa buburu wọn, ki wọn ki o ba le mọ pe idajọ rẹ n bọ lori wọn. Ki wa ni idi ti Ọlọrun fi kọkọ ranyan si wọn lati jẹ ki wọn mọ pe idajọ rẹ n bọ lori wọn? Ṣe o pọn dandan fun lati ṣe eyi bi? Ko pọn dandan fun Ọlọrun lati ṣe eyi rara. Ti Ọlọrun ba fẹ jẹ eniyan niya, ko nilo lati sọ fun ẹnikẹni nkan ti Oun fẹ ṣe, nitori pe ko si labẹ akoso ẹnikẹni. A si ri awọn apẹẹrẹ ninu bibeli bi O ṣe jẹ awọn eniyan niya ni kiakia, lai kilọ fun wọn rara tabi fi ibawi kan tabi omiran fa wọn leti. Ti a ba wa ri ẹni ti Ọlọrun kọkọ kilọ fun, ki O to ṣe idajọ rẹ, a jẹ wipe ẹni naa ri aanu gba niyẹn. Nitorina, nitori pe Ọlọfun fẹ saanu fun awọn ara Ninefe ni O ṣe kọkọ ran Jona si wọn lati ṣọ fun wọn nipa idajọ rẹ ti o n bọ lori wọn. (Wo: Lẹfitiku 10:1-2; 2Samuẹli 6:1-8; Iṣe awọn apositeli 5:1-11)
 
Wayi o, lẹyin igba ti Jona ti ri ijiya ẹṣẹ aigbọran rẹ si aṣe Ọlọrun, ti O si tun ti ri idariji ati igbala gba, Ọlọrun kọ si lẹkan si pe ki o lọ jẹ iṣẹ ti O ti kọkọ ran an tẹlẹ. Diẹ lara akọsilẹ rẹ ni yi: 
 
“Ọrọ Oluwa si tọ Jona wa lẹẹkeji, wi pe, Dide lọ si Ninefe, ilu nla a ni, ki o si kede si i, ikede ti mo sọ fun ọ. Jona si dide, o si lọ si Ninefe, gẹgẹ bi ọrọ Oluwa. Ninefe si jẹ ilu nla gidigidi, o to irin ijọ mẹta. Jona si bẹrẹ si wọ inu ilu naa lọ ni irin ijọ kan, o si kede, o si wi pe, Niwọn ogoji ọjọ si i, a o bi Ninefe wo. Awọn eniyan Ninefe si gba Ọlọrun gbọ, wọn si kede aawẹ, wọn si wọ aṣọ ọfọ, lati ori agba wọn titi de kekere wọn.” (Jona 3:1-6)
 
Gẹgẹ bi a ṣe rinu awọn ẹṣẹ bibeli yi, ọtọ ni ki a ri aanu ati idariji gba lọwọ Ọlọrun; ọtọ si tun ni ki a ronupiwada lati ṣe ifẹ rẹ. Pe Ọlọrun dariji wa ko tunmọ si pe O fẹ ki a tẹṣiwaju lati ma ṣe nkan ti o wu wa. Rara o. O dariji wa ki a ba le pada lati ṣe ifẹ rẹ ni. Jona ko ṣe ifẹ Ọlọrun ni akọkọ. Nitorina o ri ijiya. Nigba ti Ọlọrun wa dariji tan, ki ni nkan akọkọ ti O ba a sọ? O ni ki o pada lati lọ ṣe ifẹ rẹ. Ṣe o wa ṣe tabi ko ṣe e? O ṣe e! Njẹ Ọlọrun mu ni ọranyan lati ṣe ifẹ rẹ yi bi? Rara o! Ọpọ lo ma n ro pe Ọlọrun mu Jona ni tipatipa lati ṣe ifẹ rẹ ni. Ko ri bẹ rara. Jona funrarẹ lo ronupiwada, ti o si pinu lọkan ara rẹ lati lọ ṣe ifẹ Ọlọrun. Ki si ni idi ti o fi ṣe eyi? O ṣe nitoripe oun naa ti ri pe ko si bi ẹnikẹni ṣe le kọ ifẹ Ọlọrun silẹ ti ko ni ri ijiya, boya ni kiakia tabi ti o ba ya.
 
Laifọrọgun, Jona jẹ iṣẹ ti Ọlọrun ran si awọn ara Ninefe. Iha wo wa ni awọn ara ilu yi kọ si iṣẹ iranṣẹ wolii yi? Akọkọ, bibeli sọ wipe, “Wọn gba Ọlọrun gbọ.” Eyi jasi pe wọn gba iwaasu Jona gbọ. Ki lo fa ti wọn fi gba iwaasu rẹ gbọ? A ko sọ fun wa rara. Ṣugbọn o ṣeeṣe ki o jẹ pe wolii yi sọ iriri ijiya Ọlọrun ti o ri nitori aigbọran rẹ fun wọn ati bi Ọlọrun ṣe saanu fun un, ti O dariji i, ti O si tun gba a la. O tilẹ tun ṣeeṣe ki wọn gbọ iroyin nipa iriri awọn awakọ oju omi ti wolii yi ba rin irinajo, awọn awakọ ti wọn gbe ju sinu omi okun. Nkan yowu ti wọn gbọ, a ri pe awọn wọnyi gba Ọlọrun gbọ. Ki si ni wọn gbagbọ nipa rẹ? Wọn gbagbọ pe ẹlẹda ati onidajọ ohun gbogbo ni ati wipe O ni agbara lotitọ lati ṣe idajọ wọn bi O ṣe ti ẹnu Jona sọ.
 
Bawo wa ni a ṣe mọ pe wọn gbagbọ? A mọ nipasẹ igbese ti wọn gbe lori nkan ti Jona ba wọn sọ. Bi a ṣe ri ninu akọsilẹ iwe yi, nigba ti wọn gbọ iwaasu Jona, wọn barajẹ. Wọn ko si barajẹ nikan, wọn kede aawẹ ati irẹraẹnisilẹ kaakiri gbogbo ilu na. Ọba funrarẹ gan kuro lori itẹ rẹ, o bọ aṣọ igunwa rẹ silẹ, o si paṣẹ pe ki gbogbo eniyan, lọmọde ati lagba, ati gbogbo ẹranko gba aawẹ lati wa oju rere ati aanu Ọlọrun. Yatọ si eyi, o pasẹ pe ki olukuluku ara ilu yi kọ ẹṣẹ ati awọn iwa ika ọwọ wọn silẹ, ni ireti pe ki Ọlọrun saanu fun wọn, ki O si ma jẹ ki wọn ṣegbe.
 
Pẹlu eyi, o wa ye wa pe ti a ba n sọrọ nipa igbagbọ, iṣe wa gbọdọ wa ni ibamu pẹlu nkan ti a ba sọ pe a gbagbọ. Idi gan ni yi ti bibeli ṣe sọ pe igbagbọ lai si iṣẹ, oku ni (Jemisi 2:14-26). Nkan ti a n sọ ni pe ti a ba gba Ọlọrun ati ọrọ rẹ gbọ nitootọ, a o gbe igbesẹ ti o wa ni ibamu pẹlu igbagbọ wa. Fun apẹẹrẹ, ti a ba sọ pe a gba Ọlọrun gbọ gẹgẹ bi oludajọ wa, a o ma gbe igbe aye ti ko fi ni da wa labi. Ṣugbọn ti a ba n gbe igbe aye tani yoo mu mi, ti a si tun wa n sọ pe a gba Ọlọrun gbọ, nṣe ni a n tan ara wa jẹ – oku ni igbagbọ wa.
 
Awọn ara Ninefe gba Ọlọrun gbọ, wọn si fi igbagbọ wọn ninu rẹ han nipa ṣiṣe afẹri aanu rẹ ati nipa rironupiwada kuro ninu awọn iwa ika wọn. Nitori eyi, bibeli sọ pe, “Ọlọrun si ri iṣe wọn pe, wọn yi pada kuro ni ọna ibi wọn: Ọlọrun si ronupiwada ibi ti oun ti wi pe oun yoo ṣe si wọn; oun ko si ṣe e mọ.” (Jona 3:10) Ki ni Ọlọrun ri ti ko fi jẹ awọn ara Ninefe ni iya mọ? O ri iṣe wọn. Igbagbọ ahọn kọ ni Ọlọrun wo mọ wọn lara. Bẹẹ si ni ko ki i ṣe aawẹ wọn ni O wo mọ wọn lara, bi o tilẹ jẹ pe aawẹ gbigba dara pupọ. Ironupiwada wọn ni O wo mọ wọn lara ti O fi dariji wọn, ti ko si pa wọn run mọ. Eyi tun n fi idi rẹ mulẹ fun wa pe ti ẹnikẹni ba ṣe amulo aanu Ọlọrun, yoo yọri si igbala fun.
 
Ki wa lo jẹ ki o ṣeeṣe fun awọn ara Ninefe lati ṣe amulo aanu Ọlọrun? Nkan ti o jẹ ki o ṣeeṣe ni iwaasu Jona. Lotitọ ni pe Ọlọrun fẹ saanu fun awọn eniyan yi. Idi si niyi ti O fi sọ fun Jona lati lọ kede idajọ rẹ ti o n bọ fun wọn. Ti Jona ko ba wa kede idajọ Ọlọrun ti o n bọ sori awọn eniyan wọnyi si wọn nkọ? Njẹ wọn o le ṣe amulo anfaani lati ri aanu gba ti O fi ṣilẹ fun wọn? Wọn ko ni le ṣe amulo rẹ. Eyi si le yọri si iparun fun wọn. Idi gan si ni yi ti Ọlọrun fi kọkọ fi iya jẹ Jona nitoripe o kọ lati fi anfaani aanu ati ore-ọfẹ rẹ han si awọn eniyan yi. Eyi ti o tunmọ si pe o sọ ara rẹ di nkan idiwọ fun awọn ti Ọlọrun fẹ gbala. 
 
Njẹ awa na ko i ti sọ ara wa di nkan idiwọ fun awọn ti Ọlọrun fẹ gbala bi? Niwọn igba ti a ba kọ lati tiraka lati jẹ ki awọn ti ko mọ Ọlọrun ri pe alaanu ni ati wipe anfaani si wa fun wọn bayi lati ṣe amulo aanu rẹ fun igbala wọn, nṣe ni awa na n gbe ara wa kalẹ gẹgẹ bi nkan idiwọ fun awọn ti O fẹ gbala. Eyi si le yọri si ijiya fun wa, gẹgẹ bi o ṣe yọri si ijiya fun Jona. Nkan ti a n sọ ni pe ikede ihinrere Jesu ati ikede ewu ti o sọrọ mọ ki a ma tẹwọgba ṣe pataki pupọ. Ti a ko ba wa jẹ ki awọn eniyan mọ pe Ọlọrun fẹ saanu fun wọn nipasẹ Jesu Kirisiti, Ọmọ rẹ, ki O si gba wọn la kuro ninu egbe ayeraye, ko si bi wọn ṣe fẹ ṣe amulo aanu rẹ lọna ti o peye.
 
ỌRỌ IPARI
Alaanu ni Ọlọrun. Nitorina ọpọ igba ni O ma n fi aye silẹ fun awọn ẹlẹṣẹ lati ṣe amulo aanu rẹ fun igbala. Amọ ti a ko gbiyanju tabi tiraka lati jẹ ki awọn ẹlẹṣẹ mọ pe aanu Ọlọrun fun igbala wọn wa ni arọwọto wọn, ko si bi wọn ṣe fẹ ṣe amulo aanu yi. Eyi si le yọri si iparun fun wọn ati ijiya fun awa gan alara. 
 
IBEERE
– Iyatọ wo lo wa laarin awọn ara Ninefe ti Jona kede idajọ Ọlọrun si ati Wolii Eli ti Samuẹli kede idajọ Ọlọrun si?
– Kini pataki julọ si ọ ninu ẹkọ bibeli yi?
 
 
Lati ọwọ Johnson O. Lawal
 
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 28, IGBE 2021

AKỌRI: JONA – ṢIṢE AMULO AANU ỌLỌRUN (1) AYỌKA: JONA 2:1-10

AKỌSORI: AKỌSORI: “Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ kẹdun itakun naa nitori eyi ti iwọ ko ṣiṣẹ bẹẹ ni iwọ ko mu un dagba; ti o hu jade ni oru kan ti o si ku ni alẹ kan.” (Jona 4:10)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ ti a kọ sẹyin ninu iwe Jona, nkan akọkọ ti a ri dimu ni pe Ọlọrun ko ki i ṣe ẹlẹda ohun gbogbo nikan; onidajọ ohun gbogbo ni pẹlu. Nitorina, a nilo lati ma gbe aye wa pẹlu afiyesi pe Onidajọ ohun gbogbo n wo wa lati ṣe idajọ wa bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ ni akoko ti O ba yan. A tun ripe ko si bi a ṣe le kọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun ti a ko ni ba ijiya rẹ pade. Yatọ si eyi, a ripe ti Ọlọrun ba ṣetan lati jẹ eniyan niya, ko si ẹni ti o ni agbara to lati gba iru ẹni bẹ silẹ. Ko si tun si nkan ti ẹni na le fi tu u loju, ki O ba le ma jẹ ẹ niya, ayafi ti ẹni na ba ronupiwada. Ọlọrun ran Jona ni iṣẹ si awọn ara Ninefe. Ṣugbọn o kọ lati jẹ isẹ na. Eyi si jẹ ki idajọ Ọlọrun wa sori rẹ to bẹẹ gẹ ti o fi di ero inu ibu omi. Amọ nitoripe Ọlọrun jẹ alaanu, ẹni ti ko fẹ iku ẹlẹṣẹ ṣugbọn ironupiwada rẹ, O ṣaanu fun Jona nipa fifi aye silẹ fun lati ronupiwada. Ẹkọ ti a si wa fẹ bẹrẹ si ni kọ ninu iwe rẹ bayi da lori bi a ṣe le ṣe amulo aanu Ọlọrun lati bọ lọwọ idajọ rẹ.

ṢIṢE AMULO AANU ỌLỌRUN (1)
Pẹlu iha ti Jona kọ si iṣẹ ti Ọlọrun fun, gẹgẹ bi a ṣe rika ninu iwe rẹ, kedere ni a ri pe oun na gan ko fi taratara yatọ si awọn ara Ninefe. Lotitọ, oun ko ki i ṣe apaniyan, abọriṣa, alọnilọwọgba ati bẹẹbẹẹlọ, bi awọn ara Ninefe. Amọ niwọn igba ti oun naa ti kọ lati ṣe ifẹ Ọlọrun, ẹlẹṣẹ ni oun naa jẹ. Ọpọ igba ni oye ko ki i ye awọn eniyan pe ẹṣẹ ni ẹṣẹ n jẹ niwaju Ọlọrun, yala ẹṣẹ ti o kere loju wa ni tabi eyi ti o tobi. Nitorina, ijiya kan ṣoṣo ni Ọlọrun ni fun gbogbo ẹṣẹ — iku (Roomu 6:23). Nkan ti mo n sọ ni pe bi Ọlọrun ṣe le titori agbere pa eniyan bẹẹ naa lo ṣe le titori ibinu, ọtẹ ṣiṣe, iyanjẹ tabi odi yiyan pa eniyan (Jẹnẹṣiṣi 38:6-10). Aigbọran lasan ni Jona ṣe o, ti Ọlọrun si titori rẹ jẹ ki a gbe ju sinu omi okun. Eyi si n jẹ ki o ye wa pe ko si ẹṣẹ ti o kere niwaju Ọlọrun tabi ti ko lẹtọ lati ṣe idajọ rẹ.

Ki wa lo de ti Ọlọrun ko ki i fi fi gbogbo igba ṣe idajọ ẹṣẹ, o kere ni tabi o tobi, ni kiakia? Idi ni pe alaanu ni, alaanu ti ko fẹ ki ẹlẹṣẹ parun ṣugbọn ki o ronupiwada. Fun apẹẹrẹ, bibeli sọ eyi fun wa nipa Ọlọrun: “Emi ha ninu inu dundun rara pe ki eniyan buburu ki o ku? Ni Oluwa Ọlọrun wi: bi ko ṣe pe ki o yi pada kuro ninu ọna rẹ, ki o si ye.” (Isikiẹli 18:23) Ni afikun, o tun sọ eyi naa fun wa nipa rẹ: “Oluwa ko lọra lati mu ileri rẹ ṣẹ bi awọn ẹlomiran ti n roo si: ṣugbọn o n mu suuru fun yin nitori ko fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣegbe, bi ko ṣe ki gbogbo eniyan ki o ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ rẹ.” (2Peteru 3:9)

Njẹ o ri bayi? Nitoripe alaanu ni Ọlọrun, O ma n mu suuru fun awọn ẹlẹṣẹ ni ọpọ igba, ki wọn ba le ni anfaani lati ronupiwada, ki wọn si bọ lọwọ idajọ rẹ. Bi o tilẹ wa jẹ pe Jona na mọ eyi, bi a ṣe ri ninu iwe yi, oun gangan ni a ri pe o kọkọ ri aanu Ọlọrun gba. Ti ko ba ri aanu gba ni, ni kete ti wọn gbe ju sinu omi okun ni iba ba omi lọ, ti awọn ẹja tabi ẹran inu omi ko ba fi ṣe ifa jẹ. Ṣugbọn nitoripe Ọlọrun fẹ ṣaanu fun un, O jẹ ki ẹja nla kan gbe e mi. O si wa ninu ẹja naa fun ọsan mẹta ati oru mẹta gbako. (Wo: Jona 1:17)

Ki wa lo fa ti Ọlọrun kan fi jẹ ki ẹja yi gbe Jona mi, ti ko si jẹ ki o jẹ ẹ? Idi ni pe O fẹ fi aye ironupiwada silẹ fun. Ọpọ igba ni Ọlọrun ma n ṣe eleyi fun awọn ẹlẹṣẹ. Ni akoko ti o n ṣe idajọ wọn lọwọ, a si tun fi aye silẹ fun wọn lati ronupiwada. Nkan ti wọn ba wa ṣe pẹlu aaye ti o fi silẹ yi ni yoo sọ boya aanu rẹ yoo yọri si igbala wọn tabi boya yoo ja si ofo lori aye wọn. O wa ṣeni laanu pe ọpọ igba ni o jẹ pe awọn ẹlẹṣẹ ko ki i kọ ododo, bi Ọlọrun tilẹ saanu fun wọn, ki wọn si ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn (Aisaya 26:10; Ifihan 2:20-23).

Njẹ ni ti Jona, ko fi aanu Ọlọrun ṣofo rara. Ko lo awọn ọjọ mẹta ti o fi wa ninu ẹja naa, ninu okunkun biribiri, pẹlu gbogbo bi ifun ẹja ati gbogbo rẹ ṣe lọ mọ lọrun, ma ba Ọlọrun binu tabi yan odi. Dipo bẹẹ, o gba aṣiṣe rẹ ni aṣiṣe o si gbadura si Ọlọrun fun aanu lati inu ẹja ti o wa. Iwọ naa wo diẹ lara nkan ti Bibeli sọ nipa eyi pe: “Nigba naa ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ lati inu ẹja naa wa, O si wi pe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, oun si gbohun mi, mo kigbe lati inu ipo-oku, iwọ si ti gbohun mi. Nitori ti iwọ ti sọ mi sinu ibu, laarin okun, isan mi si yi mi kaakiri; gbogbo bibi omi ati riru omi rẹ kọja lori mi. Nigba naa ni mo wi pe, A ta mi nu kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun maa wo iha tẹmpili mimọ rẹ.” (Jona 2:1-4)

Njẹ o ri bayi? Jona, niwọn igba ti o ti kiyesi pe nitori pe Ọlọrun fẹ ṣaanu fun oun ni O ṣe jẹ ki oun si wa laaye ninu ẹja nla ti o gbemi, bẹrẹ si ni wa ojurere rẹ nipa gbigba adura si. Ki wa lo de ti o fi gbadura si Ọlọrun? Bi mo ti ṣe sọ siwaju, akọkọ ni pe o gba pe ohun ti ṣe aṣiṣe ati wipe iya aṣiṣe oun ni oun n jẹ. Nitorina, ko ṣe orikunkun rara, ki o si jọwọ ara rẹ fun iku. Ti ko ba ṣe eyi ni, a ko ba ti ma gbọ nkankan rara nipa iṣẹlẹ yi.

Idi keji ti Jona fi gbadura si Ọlọrun ni pe o mọ daju pe Oun nikan ni o lagbara lati ṣaanu fun oun, ki O si tun gba oun la. O tilẹ sọ ninu adura rẹ pe awọn ti wọn n kiyesi awọn ọlọrun eke n kọ aanu ara wọn silẹ (Jona 2:8). Nigba ti o si ba Ọlọrun sọrọ, ti o tọrọ fun idariji ati igbala, O gbohun rẹ, O si paṣẹ fun ẹja naa lati pọ ọ sori ilẹ gbigbẹ. Kabiyesi rẹ, Ọlọrun alaaye! (Wo: Jona 2:10)

Nitorina, bi a ṣe ri kọ ni ara Jona, igbesẹ akọkọ ti ẹnikẹni ti o ba fẹ ki aanu Ọlọrun yọri si igbala fun oun gbọdọ gbe ni ki o ri ara rẹ bi Ọlọrun ṣe ri. Eyi jasi pe o gbọdọ gba pe Olotitọ ni Ọlọrun ati pe nkan ti O sọ nipa oun otitọ ati ododo ni. Amọ niwọn igba ti o ba n ṣe orikunkun, ti o si n pe Ọlọrun ni opurọ, ko si bi aanu ati ifarada Ọlọrun fun ṣe le yọri si igbala rẹ. Ọpọ lo si ti ṣegbe nipasẹ eyi. Wọn ṣegbe nitoripe wọn kọ jalẹ lati gba pe idajọ Ọlọrun lori wọn jẹ otitọ. Nitorina, ninu igberaga, wọn ko tọrọ fun aanu rẹ, ki wọn si gba idariji.

A tilẹ ri apẹẹrẹ eyi ninu bibeli nipa ọba Asa. Ọba yi ṣẹ si Ọlọrun ni akoko kan. O si bawi. Ṣugbọn eyi ti yo fi gba ẹbi rẹ ni ẹbi, nṣe ni o bẹrẹ si ni ba Ọlọrun yan odi. Eyi si jẹ ki Eṣu raaye fi aisan jẹ ẹ niya. Sibẹsibẹ, ko ba Ọlọrun laja, ki o si tọrọ fun aanu ati aforiji, ki o ba le ri igbala. Awọn oniṣeegun aafin rẹ nikan naa ni o gbajumọ, ti o si gbọkanle fun iwosan ati igbala rẹ. Nitorina, o ku ṣaaju asiko rẹ, lalai ri igbala Ọlọrun (2Kironika 16). Ti awa na ba kọ lati rẹ ara wa silẹ niwaju Ọlọrun nigba ipọnju, ipọnju ti a fi ọwọ ara wa fa sori ara wa, ki a si wa oju rẹ fun aanu ati idariji, o ṣeeṣe ki awa na ba ipọnju lọ.

Siwaju si, gẹgẹ bi a ṣe ri kọ lati ara Jona, igbese ekeji ti ẹnikẹni ti o ba fẹ jẹ ki aanu Ọlọrun yọri si igbala fun un ni lati gbe ni ki o ke pe e, gẹgẹ bi ẹnikan ṣoṣo ti O le gba a la. Ọtọ ni ki eniyan gba pe oun ti ṣẹ si Ọlọrun ati pe ijiya tọ si oun; ọtọ si tun ni ki o kepe Ọlọrun fun aanu. Judasi Isikariọti, ti o fi Jesu han, gba lotitọ pe oun jẹbi nkan ti o ṣẹlẹ si Jesu. Ṣugbọn ṣe o tọ Ọlọrun wa bi fun aanu, idariji ati irapada? Rara o. Nṣe ni o pa ara rẹ. A si awọn miran bi tirẹ naa, ti awọn na pa ara wọn nitori ẹṣẹ tabi aiṣedeede wọn tabi ti wọn sa tọ awọn eniyan tabi awọn ọlọrun miran lọ fun irapada. (Wo: Matiu 27:3-5)

Irufẹ iwa bayi ko le yọri si igbala fun ẹlẹṣẹ rara, boya ninu aye yi tabi ni ayeraye ti a n wo niwaju wa. Ẹlẹṣẹ kọ ni yo ṣe idajọ ara rẹ tabi jẹ ara rẹ niya. Ọlọrun nikan ni O wa ni ipo ti o tọ lati ṣe idajọ ẹlẹṣẹ ati lati jẹ ẹ niya. Bẹẹ si ni, ko si ẹnikẹni tabi ọlọrunkọlọrun ti o le gba ẹlẹṣẹ lọwọ ijiya ẹṣẹ rẹ yatọ si Ọlọrun ẹlẹda ati onidajọ ohun gbogbo. Nitorina, oore-ọfẹ kan ṣoṣo ti o wa fun ẹlẹṣẹ naa ni ki o tọ Ọlọrun wa fun idariji, igbala ati irapada. Eyi ni Peteru ṣe ti ko fi ṣegbe bi Judasi, bi o tilẹ jẹ pe oun naa ṣẹ Jesu.

Wayi o, ko ki i wa ṣe awọn ti o ṣẹ nikan ni ọrọ yi bawi. Gbogbo eniyan pata ni o bawi, pẹlupẹlu awọn ọmọ Ọlọrun. Ranti pe ko digba ti eniyan ba ṣẹ si Ọlọrun ki o to bọ sinu wahala tabi idamu ninu aye yi. Nitorina, igbakigba ti a ba ba ara wa ninu iṣoro, nṣe ni o yẹ ki a kepe Ọlọrun fun aanu ati igbala, dipo ti a o fi ma ṣe aroye tabi sọrọ odi bi Joobu, ti o ro pe Ọlọrun ko ṣe daradara rara nipa fifi aye gba ipọnju lati wọnu aye rẹ. A gbọdọ mọ pe a ko ni ododo kankan ti a fi le ṣogo niwaju rẹ (Aisaya 64:6). Ododo Kirisiti, ti a fi igbagbọ gba, nikan ni a gbọdọ dirọmọ niwaju Ọlọrun lati ri aanu, aabo ati igbala gba lọwọ rẹ (1Korinnti 1:30-31).

Nitorina, irufẹ ipọnju tabi wahala yowu ti o le ba wa, bi o tilẹ jẹ pe eyi ti o fiwa sinu okunkun birimubirimu bi ti Jona ni, nṣe ni ki a duro lori ododo Jesu, ki a si kepe Ọlọrun fun aanu ati igbala. Oun yoo si da wa lohun, yoo si yọ wa ninu ọfin Eṣu, bi O ṣe yọ Jona. Amọ ṣe a o kepe bi? Njẹ ipọnju wa tilẹ to ti Jona ti a fi sọ igbagbọ wa nu, ti a si bẹrẹ si ni wa ọna abayọ si ibi ti ko ti si ọna rara?

ỌRỌ IPARI
Alaanu ni Ọlọrun. Nitorina, ọpọ igba ni O ma n mu suuru fun awọn ẹlẹṣẹ, ki wọn ba le ronupiwada. Ṣugbọn suuru rẹ ko ni wa titi lailai. Nitorina, ẹlẹṣe ni lati ṣe amulo rẹ ni kiakia, ki ipese aanu rẹ fun wọn ma ba ja si asan.

IBEERE
– Ki ni o ṣe pataki si ọ ju ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 21, IGBE 2021

AKỌRI: JONA – ỌLỌRUN KO ṢE E SA FUN                                          AYỌKA: JONA 1:1-17

AKỌSORI: “Nigba naa ni Oluwa wi pe, Iwọ kẹdun itakun naa nitori eyi ti iwọ ko ṣiṣẹ bẹẹ ni iwọ ko mu un dagba; ti o hu jade ni oru kan ti o si ku ni alẹ kan.” (Jona 4:10)

ỌRỌ AKỌSỌ

Iwe wolii Jona jẹ iwe bibeli kan ti a kọ lati fi ọkan Ọlọrun lori ẹlẹṣẹ han si wa. Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Ọlọrun korira ẹṣẹ patapata. Idi ni yi to ṣe jẹ pe idajọ kan ṣoṣo ni O ni fun ẹlẹṣẹ, eyi si ni iku (Roomu 6:23). Ṣe dandan wa ni ki ẹlẹṣẹ ku, abi ọna abayọ wa? Ti ko ba ki i ṣe dandan ni fun ẹlẹṣẹ lati ku, ọna wo ni o le gba lati bọ lọwọ idajọ iku Ọlọrun? Ki gan ni ero ati ipinnu Ọlọrun lori awọn ẹlẹṣẹ ati ẹṣẹ ti wọn n da? Njẹ ipinnu rẹ lori wọn ṣe e yipada bi? Ti o ba ṣe e yi pada, ọna wo ni wọn le e gba yi pada? Ibeere wọnyi ati awọn miran ti o tun fi ara pẹ wọn ni a dahun fun wa ninu iwe Jona, eyi ti a fẹ bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo rẹ ninu ẹkọ bibeli yi. Mo wa gbadura pe ki Ọlọrun ṣi wa ni iye lati le ri gbogbo nkan ti o fẹ ki a tipasẹ ẹkọ yi ri, ki O si tun fun wa ni okun inu lati ma ṣe amulo wọn ninu aye wa ati ninu gbogbo ibaṣepoọ wa pẹlu awọn ti o wa ni awujọ wa. Amin.

ỌLỌRUN KO ṢE E SA FUN

Tani Jona? Nkan ti ọpọ ti o dagbọ sinu ijọ Ọlọrun mọ nipa Jona ko ju pe o jẹ oloorun lọ. Nitorina wọn a ma pe ni ‘Jona oloorun’. Lotitọ ni ẹnikan pe Jona ni oloorun ninu akọsilẹ iwe rẹ. Amọ eyi ko wa tunmọ si pe oorun na ni o ma n fi gbogbo igba sun tabi pe ọrọ lori oorun sisun ni iwe rẹ da le lori. Jona, bi a ti ṣe ri ninu bibeli, jẹ ọkan lara awọn woli Ọlọrun igbaani ti o n ba awọn eniyan sọrọ lorukọ Oluwa. A tilẹ sọrọ lori imuṣẹ asọtẹlẹ rẹ kan ninu bibeli, eyi ti o waye ni akoko Jeroboamu keji ti o jọba lori Isiraẹli (2Awọn Ọba 14:23-25). Nitorina, wolii pataki ni Jona jẹ ni ilẹ Isiraẹli.

Amọ ṣa o, iwe wolii Jona ko da lori iṣẹ iranṣẹ rẹ ni ilẹ Isiraẹli rara, o kere ni tabi o pọ. Dipo eyi, o da lori iṣẹ iranṣẹ kan pato ti Ọlọrun fi ran an si awọn ara ilu kan ti a n pe ni Ninefe ni igbaani. Eyi jasi pe iwe yi ko sọ ohun gbogbo to ni i ṣe pẹlu igbe aye wolii yii tabi iṣẹ iranṣẹ rẹ fun wa. Ṣugbọn o n ba wa sọrọ lori iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun un si awọn ara Ninefe ati awọn ẹkọ ti a le ti ara eyi kọ nipa iru ẹni ti Ọlọrun n ṣe, iha ti O kọ si ẹṣẹ ati aigbọran si aṣẹ rẹ ati iha ti O kọ si ironupiwada.

Wayi o, nkan akọkọ ti a kọkọ ba pade ninu iwe Jona ni pe Ọlọrun fun ni iṣẹ lati lọ ṣe ni ilu Ninefe, ṣugbọn dipo ki o lọ jẹ iṣẹ na, nṣe ni o gbiyanju lati sa lọ kuro niwaju Ọlọrun. Wo diẹ lara awọn ẹsẹ iwe na ti a ti fi idi eyi mulẹ: “Ọrọ Ọluwa si tọ Jona ọmọ Amitai wa, wi pe, Dide, lọ si Ninefe, ilu-nla ni, ki o si kigbe si i, nitori iwa buburu wọn goke wa iwaju mi. Ṣugbọn Jona dide lati sa lọ si Taṣiṣi kuro niwaju Oluwa, o si sọkalẹ lọ si Jopa; o si ri ọkọ kan ti n lọ si Taṣiṣi: Bẹẹ ni o sanwo ọkọ, o si sọkalẹ ninu rẹ, lati ba wọn lọ si Taṣiṣi kuro niwaju Oluwa.” (Jona 1:1-3)

Ki gan wa ni iṣoro Jona? Bi mo ṣe sọ siwaju, wolii Ọlọrun pataki ti awọn eniyan mọ daadaa ni Jona jẹ. Iṣẹ ti Ọlọrun si n ran an lọ jẹ ni Ninefe ko ki i ṣe akọkọ iru rẹ. Ki wa lo fa ti ko fi fẹ lọ jẹ iṣẹ yi? Lotitọ, a ko sọ fun wa pọnbele ninu iwe naa idi kan pato ti ko fi fẹ jẹ iṣẹ yi. Ṣugbọn pẹlu awọn nkan ti a sọ ninu iwe yi ati awọn iwe bibeli miran, a le mẹnuba pataki idi ti ọkunrun yi ko fi fẹ jẹ iṣẹ ti Ọlọrun ran. Fun apẹẹrẹ, a jẹ ki o ye wa ninu bibeli pe ilu Ninefe jẹ ibujoko Ọba awọn ara Asiria ti o ko awọn ara Isiraẹli ni igbekun kuro ni ilẹ wọn (2Awọn Ọba 17). Nitorina ọta nlanla ni awọn ara ilu yi jẹ si awọn eniyan Jona, iyẹn awọn ara Isiraẹli. Eyi tunmọ si pe o nilati dun mọ Jona ninu ti Ọlọrun ba ṣe idajọ awọn eniyan yi, ti O si pa wọn run.

Niwọn igba ti o si jẹ pe bi ọrọ ṣe ri niyi, ṣe o wa yẹ ki o ni Jona lara lati lọ sọ fun awọn ara ilu yi pe iwa ika wọn ti goke tọ Ọlọrun lọ ati pe iparun ni ere gbogbo ẹṣẹ wọn? Ti a ba fi oju ti ara wo o, a o sọ pe ko yẹ ki o ni i lara. Ṣugbọn o ni i lara nitoripe o mọ iru ẹni ti Ọlọrun jẹ. Ki wa ni nkan na ti o mọ nipa Ọlọrun ti ko fi fẹ jẹ iṣẹ ti O ran an? Ohun ni a ri ninu awọn ẹsẹ wọnyi: “Ṣugbọn o ba Jona ninu jẹ gidigidi, o si binu pupọ, O si gbadura si Oluwa, o si wi pe, Emi bẹ ọ, Oluwa, njẹ ohun ti mo wa wi kọ yii nigba ti mo wa ni ilẹ mi? Nitori naa ni mo ṣe salọ si Taṣiṣi ni isaaju: nitori emi mọ pe, Ọlọrun oloore-ọfẹ ni iwọ, ati alaaanu, o lọra lati binu, o si ṣeun pupọ, o si ronupiwada ibi naa.” (Jona 4:1-2)

Pẹlu nkan ti Jona sọ ninu awọn ẹsẹ iwe rẹ yi, o farahan pe wolii yi mọ Ọlọrun daadaa. O mọ pe Oun ko ki i ṣe Ọlọrun ti o fẹ iku ẹlẹṣẹ bi ko ṣe pe ki o ronupiwada (Isikiẹli 18:23). Ẹlẹṣẹ ni awọn ara Ninefe, ti iparun tọ si. Sibẹsibẹ, Jona mọ pe ti oun ba ni oore-ọfẹ lati mu ọrọ Ọlọrun tọ wọn lọ, o ṣeeṣe ki wọn ronupiwada. Ti wọn ba si ronupiwada, Ọlọrun naa le ronupiwada, ki O si ma pa wọn run mọ, gẹgẹ bi O ti pinnu tẹlẹ. Niwọn igba ti awọn wọnyi si jẹ ọta fun Jona, ọta ti o fẹ ki Ọlọrun fi iya jẹ, ko fẹ ki wọn ni aafani ironupiwada rara. Idi si ni yi ti o fi pinnu lati ma jẹ iṣẹ ti Ọlọrun fi ran, ṣugbọn lati sa lọ kuro niwaju rẹ. Njẹ awa na ko ma titori idi kan tabi omiran gbiyanju lati sa fun iṣẹ ti Ọlọrun fẹ ki a ṣe bi?

Ni kukuru, bi Jona ṣe mọ Ọlọrun to, ko tun wa ni oye pe Ọlọrun ko ki i ṣe ẹni ti eniyan le sa fun tabi ti eniyan le kọ lati ṣe ifẹ rẹ laiba ijiya tabi idaamu pade. Ko si tun ye pe, ti ẹnikan ba kọ lati jẹ iṣẹ ti Ọlọrun ran, O ni agbara lati gbe elomiran dide ti yoo ṣe ifẹ rẹ. Lotitọ, Jona gbiyanju lati sa lọ kuro niwaju Ọlọrun si ilu miran. Ṣe o wa ro pe Ọlọrun ko ni mọ nkan ti oun n ṣe ni tabi ibi ti o n lọ? Ko jẹ jẹ bẹ! Gẹgẹ bi ọrọ oun tikararẹ, Ọlọrun ni ẹni ti o da aye, okun, iyangbẹ ilẹ, eniyan ati ohun gbogbo (Jona 1:9). Nitorina, o mọ lọkan rẹ pe oun ko le fi ara pamọ fun Ọlọrun. Sibẹsibẹ, o salọ pẹlu ero wipe boya ti oun ba jina rere si ilẹ Ninefe, idajọ Ọlọrun yoo le pada wa si ori wọn.

Ṣugbọn aṣiṣe nla gba ni eyi jẹ fun wolii yi. Nitoripe Ọlọrun jẹ ki idaamu de ba oun ati awọn atukọ ti wọn gba a sinu ọkọ oju omi wọn lati gbe lọ si Taṣiṣi, to bẹẹ gẹ ti wọn fi ju u sinu omi okun nigbẹyingbẹyin, ti ẹja nla kan ti Ọlọrun ti pese si gbe mi (Jona 1:4-17). Eyi si jẹ ki awọn ti wọn wa pẹlu Jona ninu ọkọ oju omi yi ti ara rẹ mọ pe Ọlọrun tirẹ gan an ni Ọlọrun otitọ ati ododo. Ọlọrun ti eniyan ba le sapamọ fun ko ki i ṣe Ọlọrun otitọ. Ọlọrun ti aaye ko ba gba a ni ibi gbogbo ko ki i ṣe Ọlọrun ododo. Ṣugbọn Ọlọrun ti Jona n sin, ti awa na si n sin, jẹ Ọlọrun ti ko ṣe sa pamọ fun ati Ọlọrun ti aaye gba nibi gbogbo. Nitoripe Oun ni o da aye ati ọrun ati ẹda gbogbo (Saamu 24:1). Nitorina, a gbọdọ mọ pe ko si ọrọ tabi aṣiri aye wa kankan ti o pamọ si. Kedere ba yi ni ohun gbogbo han si. Ti a ba wa n ṣeke, ti a n huwa ti o wu wa, ti a n jale tabi pa awọn eniyan lẹkun jaye, ki a mọ pẹ oju Ọlọrun to ohun gbogbo ti a n ṣe. Ti akoko ba si to, o di dandan ki o fun wa ni ere iṣẹ ọwọ wa. (Wo: Saamu 139:7-12)

Yatọ si eyi, nkan ti o ṣẹlẹ si Jona jẹ ki awọn ti wọn jọ n rin irinajo mọ pe Ọlọrun rẹ jẹ Ọlọrun ti o lagbara lati ṣe idajọ awọn alaigbọran, ti ko si si nkankan ti wọn le ṣe lati bọ lọwọ idajọ rẹ, ti ko ba ṣaanu fun wọn. Owo wa, ile wa tabi awọn nkan ini wa ko le gba wa ni ọwọ idajọ rẹ, bi a ti lẹ jọwọ gbogbo wọn silẹ. Ironupiwada nikan ni o le jẹ ki a bọ lọwọ idajọ rẹ. Nitorina, a nilo lati kiyesara gidigidi nipa iha ti a o ma kọ si ọrọ rẹ ati ifẹ rẹ fun aye wa. Aijẹbẹ, wahala ni a n kọ lẹta si. Ko si wa digba ti Ọlọrun gbe iṣẹ iranṣẹ kan lewa lọwọ ti a si kọ lati ṣe ki O to mura lati ṣe idajọ wa. Igbakugba ti a ba ti kọ lati ṣe ifẹ rẹ, nṣe ni a n ṣilẹkun ṣilẹ fun idajọ rẹ. Ọna ti yo wa gba lati ṣe idajọ wa nikan naa ni a ko le sọ. Ṣe o wa dara ki o jẹ nipasẹ idajọ rẹ lori wa ni awọn eniyan yoo ṣe mọ ọn ni Ọlọrun otitọ, nigba ti wọn le mọ ọn bẹẹ gẹgẹ nipasẹ igbọran ati iwa ododo wa?

Lafikun, a nilo lati ma rin pẹlu imisi ati itọni Ẹmi-mimọ lẹnu iṣẹ wa ati ninu gbogbo ibaṣepọ wa pẹlu awọn eniyan. Idi si ni pe a le tipaṣẹ awọn ọna wọnyi ni ajọṣepọ pẹlu awọn ti o wa labẹ idajọ Ọlọrun tabi labẹ awọn egun buruku kan ti o le pa awọn ati awọn ti o ba ba wọn ni ajọṣepọ lara. Ọlọrun nikan lo wa mọye awọn alaiṣẹ ti o tipaṣẹ awọn ti o wa labẹ idajọ rẹ tabi awọn egun kan padanu ẹmi wọn tabi padanu iṣẹ tabi awọn nkan ini wọn.

ỌRỌ IPARI

Ọlọrun jẹ Ọlọrun ti O da ohun gbogbo, ti ohun gbogbo wa ni ikawọ rẹ, ti O ri ohun gbogbo, ti O si lagbara lori ohun gbogbo. Nitorina, ko ki i ṣe ẹni ti a le sa fun, yẹra fun tabi ko ọrọ rẹ ku laikabamọ. Idi si ni yi ti a fi gbọdọ mu ṣiṣe ifẹ rẹ ni igba gbogbo lọkunkundun. Aijẹbẹ, ko si ọna abayọ fun wa kuro labẹ idajọ rẹ.

IBEERE

–     Ki ni pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 14, IGBE 2021

AKỌRI: FIFI JESU HAN AYỌKA: JOHANU 1:29-39

AKỌSORI: “Ni ọjọ keji, Johanu ri Jesu n bọ wa sọdọ rẹ; o wi pe, Wo o, ọdọ-aguntan Ọlọrun, eni ti o ko ẹṣẹ aye lọ.” (Johanu 1:29)

ỌRỌ AKỌSỌ
Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, pataki lara awọn ojuṣe wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ni lati fi Jesu han fun araye. Ṣugbọn ki ni koko fifi Jesu han? Ki ni idi ti a ṣe n fi i han fun awọn eniyan? Ki ni a n fi han nipa rẹ fun araye? Idi ti a ṣe n fi Jesu han ati awọn nkan ti a ba n fihan nipa rẹ ni yo sọ irufẹ igbesẹ ti awọn eniyan yoo gbe lori rẹ. Nkan ti a o si fihan nipa Jesu ati idi ti a o fi fi awọn nkan wọnyi han nipa rẹ yo ni i ṣe pẹlu imọ ati oye ti a ni nipa ẹni ti o jẹ. A ko wa le mọ iru eniyan ti Jesu jẹ ti ko ba ṣe pe Ọlọrun Baba rẹ ba fi iṣipaya ati ifihan nipa rẹ kun ọkan wa. Jesu funrarẹ sọ eyi fun wa: “Ohun gbogbo ni a fifun mi lati ọdọ Baba mi wa: ko si ẹni ti o mọ Ọmọ, bi ko ṣe Baba; bẹẹ ni ko si ẹni ti o mọ Baba bi ko ṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i han fun.” (Matiu 11:27) Idi niyi ti awọn eniyan mimọ igbaani fi ma n fi gbogbo igba gbadura pe ki Ọlọrun fun awọn ni ẹmi ọgbọn ati ifihan ninu imọ rẹ, ki wọn ki o ba le mọ ọn si i (Efesu 1:15-19). Awọn wọnyi woye pe ti eniyan ko ba mọ Jesu daradara, ko ni le ṣe afihan ti o peye, ti o si tọ nipa rẹ. Nitorina, awa na ti a jẹ ọmọ Ọlọrun loni ni lati mọ Jesu daradara, ki a ni imọ ati oye ti o tọ, ti o si jinlẹ nipa rẹ. Aijẹbẹ, a ko ni le ṣe ifihan rẹ fun awọn eniyan bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ. Yatọ si eyi, irufẹ ifihan yowu ti a ba fun awọn eniyan nipa rẹ, niwọn igba ti ko ba ti duro lori otitọ ti o peye, di dandan ki o ṣi wọn lọna, ki o si jẹ ki wọn gbe igbesẹ ti o tako ifẹ Ọlọrun lori rẹ.

FIFI JESU HAN
Wayi o, ọpọlọpọ apẹẹrẹ awọn ti wọn fi Jesu han fun awọn eniyan ni a ri ninu bibeli. Ṣugbọn ninu ẹkọ bibeli yi, a fẹ ṣe agbeyo mẹta pere lara wọn. Akọkọ ni ifihan Jesu ti Johanu onitẹbọmi ṣe. Bi a ṣe ri ninu bibeli, Johanu onitẹbọmi ni ẹni akọkọ ti o kọkọ fi Jesu han ni gbangba. Ki si ni o fi han nipa rẹ? O fi i han gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun, nitoripe o sọ pe, “Emi si ti ri i, emi si jẹrii pe, Eyi ni ọmọ Ọlọrun.” (Johanu 1:34) Yatọ si eyi o fi i han gẹgẹ ọdọ-aguntan ti o ko ẹṣẹ araye lọ (Johanu 1:29).

Ki wa lo fa ti Johanu, ti a tọ dagba gẹgẹ bi Juu ati ninu ẹsin awọn Juu, ṣe gba pe ọmọ Ọlọrun ni Jesu n ṣe, ti o si tun n polongo rẹ fun araye lati jẹ ki wọn mọ? Idi ni pe Ọlọrun funrarẹ lo fun ni ifihan yi pe ọmọ Oun ni Jesu i ṣe. O sọ ninu ọrọ rẹ si awọn Juu pe awọn nkankan wa ti Ọlọrun ti sọ pe ki oun kiyesi lara awọn ti oun n batisi ati pe ẹni ti oun ba ti ri awọn nkan na lara rẹ ni ọmọ Oun, ti yo batisi awọn eniyan pẹlu Ẹmi Mimọ, ti yoo si tun ru ẹru ẹṣẹ wọn lọ (Maaku 1:1-11; Johanu 1:25-34). Ki si ni idi ti Johanu ṣe ṣe afihan Jesu ni ọna wọnyi? Idi ni ki awọn eniyan ba le tọ Jesu wa fun igbala ati irapada ọkan wọn. A si ri ọpọ ti o tipaṣe ọkunrin yi ri igbala ati irapada gba lọdọ Jesu.

Apẹẹrẹ keji ti a tun ri ninu bibeli nipa awọn ti o fi Jesu han ni ti obinrin ara Samaria kan ti Jesu pade ni ilu Sikari, lẹba kanga omi kan. Obinrin yi, gẹgẹ bi a ṣe ri i ka, ti ni ọkọ maarun sẹyin. O si tun wa ba ti ọkunrin kan ti ko fẹ rara ni akoko ti o pade Jesu yi. Ti awa na ba fi oju inu wo, irufẹ obinrin yi ṣeeṣe ki o jẹ onijagidijagan kan tabi oniṣekuṣe. Ṣugbọn ni ọwọ akoko perete ti oun ati Jesu fi jomitoro ọrọ, o ri pe ireti irapada ati itusilẹ kuro ninu aye ainitunmọ wa fun oun. Nigba ti Jesu si sọ fun pe Oun ni Mesaya ti wọn n reti, nṣe ni obinrin yi fi ladugbo rẹ silẹ, ti o si pada lọ si inu ilu rẹ lati pe awọn ara ilu na lati wa wo boya Jesu ni Mesaya ti wọn reti ni tootọ tabi Oun kọ. Ti a ba si wo daada, ko le jẹ pe obinrin yi kan sọra nipa Jesu lọna yẹnperẹ kan ni, ki awọn ara ilu rẹ si tẹle wa wo o. O ni lati jẹ pe o sọrọ nipa rẹ fun wọn pẹlu itara ni, to bẹẹ gẹ ti wọn fi rọ jade lati wa wo iru eniyan ti o jẹ. Eyi si yọri si bi ọpọ ninu wọn ṣe gbagbọ fun irapada ati igbala ọkan wọn. (Wo: Johanu 4:1-45)

Ki wa lo fa ti obirin Samaria yi ṣe fi Jesu han fun awọn ara ilu rẹ? Idi ni pe Ọlọrun ba ọkan rẹ pade lọwọ akoko ti o lo pẹlu Jesu. Eyi si jẹ ki o ri pe ẹni ti o n ba oun sọrọ kọja eniyan lasan; O jẹ ẹni ti o wa ni ipo lati tan oungbẹ aye oun, ki O si fun oun ni ifọkanbalẹ ti o n lọ lati ile ọkọ de ile ọkọ wa, ti ko si ri. Ki si ni o fi han nipa Jesu? O fi i han gẹgẹ bi Mesaya Ọlọrun, Olugbala araye ti wọn ti n reti lati ọjọ pipẹ. O fi i han ki awọn ara ilu rẹ na ba le tọ ọ wa fun igbala. O tunmọ si pe obirin yi mọ pe, bi o tilẹ jẹ pe aye oun ko ni itunmọ, aye ọpọ na ni ilu ti o wa ni ko ni itunmọ, ti o si nilo iwosan lati ọwọ Jesu.

Apẹẹrẹ miran ti a si tun ri ninu bibeli nipa awọn ti o fi Jesu han ni ti Judasi ọmọ Isikarioti. Bi a ti ṣe ri ninu bibeli, Judasi jẹ ọkan lara awọn apositeli mejila akọkọ ti Jesu Oluwa yan lati wa pẹlu rẹ ati lati jẹ ajẹẹri ti yo ma fi irufẹ ẹni ti o jẹ han fun araye (Matiu 10:1-4; Maaku 3:13-19). Eyi tunmọ si pe ọkunrin yi ni oore-ọfẹ ti ko wọpọ lati ni imọ ati oye iru eniyan ti Jesu jẹ (1Johanu 1:1-3). Gẹgẹ bi ọkan lara awọn apositeli ti o ma n fi gbogbo igba wa pẹlu rẹ, o gbọ iwaasu rẹ ju ọpọ eniyan lọ, o ri iṣẹ iyanu rẹ ju ọpọ lọ, o si tun ri irufẹ aye ifẹ ati igbagbọ ti Oun n gbe ni ọna ti ọpọ ko ni oore-ọfẹ lati ri. Oun papa wa lara awọn ti Jesu ran jade lọ lati waasu ati lati sọ pe ijọba ọrun ti de tan, lati le ẹmi eṣu jade ati lati wo oniruuru aisan san. Nitorina, Judasi ko ipa tirẹ ninu fifi Jesu han fun araye gẹgẹ bi Mesaya ati Olugbala.

Amọ ṣa o, bi a tun ṣe ri ka ninu bibeli, nigba ti o to akoko kan, Judasi yi kanna, ti o ti ko ipa ribiribi ni fifi Jesu han gẹgẹ bi Olugbara araye, ni o tun wa fi i han fun awọn ti o n lepa ẹmi rẹ lati pa a. Bibeli sọ nipa rẹ pe, “Ẹni ti yoo si fi i han ti fi ami fun wọn, wi pe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko ni ẹnu, oun naa ni; ẹ mu un, ki ẹ si maa lọ ni alaafia.” (Maaku 14:44) Ki wa ni ọkunrin yi fi han nipa Jesu? O fi i han gẹgẹ bi ẹni ti o yẹ ki araye fi ṣe ẹlẹya, ki wọn si tun lu u pa. Ki si ni idi ti o fi Jesu han ni ọna yi? Idi ni pe o ti sọ igbagbọ rẹ pe Olugbala ati Mesaya araye ni Jesu nitootọ nu. Eyi jasi pe ni akoko ti o fi Jesu han yi fun awọn Juu lati pa, ko ni igbagbọ ninu rẹ mọ gẹgẹ bi Ọmọ Ọlọrun ati Olugbala araye. O kan ri bi ẹnikan ti eniyan le ti ara rẹ pa owo ni. O si pa owo lati ara rẹ nitootọ. Ṣugbọn ikoro, ibanujẹ ati iku ayeraraye ni o fi ṣe ere jẹ. (Wo: Matiu 27:3-5)

Wayi o, njẹ awa na wa lara awọn ti o n fi Jesu han bi? Ti a ba jẹ ọmọ Ọlọrun lotitọ, a gbọdọ ko ipa takuntakun lori ṣiṣe afihan Jesu fun araye. Ti a ba si wa n fi i han, ki ni a n fi han nipa rẹ? Bi mo ṣe sọ tẹlẹ, nkan ti a ba mọ nipa rẹ ni yo sọ irufẹ nkan ti a o fi han nipa rẹ. Ki wa gan ni a mọ nipa rẹ? Ṣe otitọ si ni awọn nkan ti a mọ nipa rẹ? Yatọ si eyi, ṣe otitọ ti a mọ nipa rẹ peye to? Tani Jesu jẹ si wa gan? O ti fi igba kan ri bere lọwọ awọn ọmọ ẹyin rẹ pe, “Ta ni ẹyin n fi mi pe gan?” Ta ni awa na n fi Jesu pe? Eyi ni yo sọ irufẹ ifihan rẹ ti a o ṣe.

Ọrọ yi wa koja ọrọ ẹnu lasan. O kọja ki a kan fi ẹnu sọ pe Ọmọ Ọlọrun, Oluwa ati Olugbala ni Jesu n ṣe fun wa. Ihuwa si wa gan ni yoo sọ boya bi a ṣe wi pẹlu ẹnu wa na ni o ṣe ri. Ranti pe, Judasi fi ẹnu ko Jesu lẹnu nigba ti o n fi i han, ti o si pe ni ‘Olukọni’. Ṣugbọn o fi i han, ki a ba le mu, ki a si pa a ni. Awa na le ma fi ẹni ko Jesu lẹnu ninu ile isin wa, ki a si ma bọwọ fun ninu orin wa ati nigba ti a ba n gbadura. Ṣugbọn ni ile wa, ni ibi iṣẹ wa, ni adugbo wa tabi ni ile-iwe wa, njẹ a n fi i han bi ẹni ti o yẹ ki awọn eniyan bọwọ fun? Njẹ a n fi i han nibi gbogbo ti a n lọ bi ẹni ti o le gba awọn eniyan la nitootọ, ki O si fun aye wọn ni itunmọ?

O wa ṣeni laanu pe ọpọ wa loni ti a pe ara wa ni Kirisitiẹni tabi ojiṣẹ Ọlọrun ni o jẹ pe nṣe ni a n fi Jesu han bi ole, ọlẹ, alọnilọwọgba, opurọ, ẹlẹtan, oniṣekuṣe ati ẹnikan ti ko yẹ ki awọn eniyan kọbiarasi lọ titi. Idi si ni yi ti ọpọ ko fi fẹ ni nkankan an ba a ṣe pọ. Amọ ki awa na wa ranti pe, ti a ba fi Jesu han fun awọn eniyan ni ọna aitọ, ti a si fun awọn eniyan ni idi lati tabuku rẹ ati lati kọ ọ silẹ, iru ijiya ti o tọ si Judasi na n duro de wa. Ayafi ti a ba si ronupiwada nikan naa ni a o fi bọ lọwọ ijiya na.

ỌRỌ IPARI
Awa ti a ba sọ pe a ni ibaṣepọ pẹlu Jesu ni a le fi iru eniyan ti o jẹ han. Amọ ti ibaṣepọ wa pẹlu rẹ ko ba dan mọran tabi ti ko ni itunmọ si wa, nkan ti ko tọ ni a o ma fi han awọn eniyan nipa rẹ. Eyi si lewu lọpọlọpọ fun wa. Nitorina, niwọn igba ti a ba pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun, o ṣe pataki ki a lepa lati mọ Jesu ni otitọ ati ni ododo, ki a ba le fi nkan ti o tọ nipa rẹ han araye. Aijẹbẹ, yoo san fun wa lati yẹra fun, ki a si ma fun ẹnikẹni ni idi lati ro pe boya a ni nkankan ba a ṣe pọ. Eyi ko ni jẹ ki wọn ti ara wa kọsẹ, ki a si fa idajọ ti o ga ju ti wọn gan lọ le ara wa lori.

IBEERE
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministryng.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 24, ẸRẸNA 2021

AKỌRI: IKỌSẸ LATI ARA ENIYAN AYỌKA: MAAKU 6:1-6

AKỌSORI: “Gbẹnagbẹna naa kọ yii, ọmọ Maria, arakunrin Jemiisi, ati Josisi, Eati ti Juda, ati Simoni? Awọn arabinrin rẹ ko ha si wa nihin-in yii lọdọ wa? Wọn si kọsẹ lara rẹ” (Maaku 6:4)

ỌRỌ ISAAJU
Ninu ẹkọ bibeli ti a ṣe kọja lọ, a ṣe agbẹyo awọn nkan ti o le fa ti eniyan fi le ti ara Ọlọrun kọsẹ. Lotitọ ko yẹ ki ẹnikẹni ri ohun ikọsẹ ninu Ọlọrun. Idi si ni pe ko si ohun ikọsẹ ninu rẹ. Amọ ti a ko ba ni oye iwa ati iṣeṣi Ọlọrun tabi ti a jẹ alamọju, o ṣeeṣe ki a kọsẹ lara rẹ nigba ipọnju tabi iṣoro. Wayi o, ninu ẹkọ bibeli eleyi, a fẹ ṣe agbeyẹwo awọn nkan ti o le fa ki a ti ara eniyan kọsẹ. Gẹgẹ bi ọrọ Jesu, ko le ṣe ki ohun ikọsẹ ma wa, niwọn igba ti a ba wa ninu aye yi. Ṣugbọn egbe ni fun ẹni na ti a ba ti ara rẹ kọsẹ. Njẹ eyi wa jasi pe ẹni ti o ba kọsẹ lati ara eniyan ko ni ẹbi rara tabi pe ko ni gba idajọ ti o peye lati ọwọ Ọlọrun? Rara o. Nkan ti eyi tunmọ si ni pe idajọ ti ẹni ti a ti ara rẹ kọsẹ yoo buru ju ti ẹni ti o kọsẹ lọ. Ṣugbọn ẹni ti o kọsẹ na yoo gba idajọ lori ipa ti oun na ko lori ikọṣẹ ara rẹ. Yatọ si eyi, njẹ gbogbo igba ti a ba ti ara eniyan kọsẹ na ni o jẹ pe ẹni ti a ti ara rẹ kọsẹ jẹbi? Rara o. Ko ki i ṣe gbogbo igba ti eniyan ba ti ara ẹnikan kọsẹ na lo jẹ pe ẹni na lẹbi, bi a ti ṣe ri ninu bibeli. Idi si niyi ti awa naa ṣe gbọdọ kiyesara ki a ma ba ti ara ẹnikẹni kọsẹ. (Wo: Luuku 17:1-2)

IKỌSẸ LATI ARA ENIYAN
Amọ o, ti a ko ba ni imọ awọn ọna ti a le gba ti ara awọn eniyan kọsẹ, ko si ki a ma ti ara wọn kọsẹ. Awọn ọna wo wa ni a le gba ti ara awọn elomiran kọsẹ? Ti a ba fẹ sọ otitọ, ọna ti a le ti ara awọn eniyan kọsẹ, ki a si ṣẹ si Ọlọrun pọ. Ṣugbọn diẹ lara wọn ni iwọnyi:

– Aikaniyansi: Ara awọn nkan ti a kọ ninu bibeli ni pe Ọlọrun ko fẹ ki a ma fi oju tẹnbẹlu awọn ẹlomiran fun idi kankan rara. Lotitọ, o ṣeeṣe ki a ni awọn amuyẹ kan ti awọn ko ni. Eyi ko wa jasi pe wọn ko le wulo lọpọlọpọ fun iṣẹ Ọlọrun tabi fun igbesoke ti awa funrawa. Amọ ti a ba fi oju tẹnbẹlu wọn, afaimọ ki a ma kọsẹ lara wọn, ki a si padanu ipese tabi igbala Ọlọrun fun wa. Fun apẹẹrẹ, a ri ka ninu bibeli pe igba kan wa ti Jesu lọ si ilu rẹ, nibi ti a ti tọ ọ dagba, ti awọn ara ilu yi si fi oju kere rẹ. Ki si ni idi? Idi ni pe o jọ wọn loju lọpọlọpọ pe Jesu ti wọn mọ latilẹ gẹgẹ bi gbẹnagbẹna lo wa di wooli ati olukọ ọrọ Ọlọrun ti gbogbo eniyan n wari fun. Nitorina, bibeli sọ pe wọn kọsẹ lara rẹ, wọn si padanu igbala ati iwosan ti Ọlọrun ko ba ti ipasẹ rẹ fun wọn. Kẹ si wa wo o, a ko le ka irufẹ ikọsẹ yi si ikọsẹ lati ara Ọlọrun bi ko ṣe ikọsẹ latii ara eniyan, nitoripe ọmọ eniyan ni Jesu n ṣe, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun naa ni pẹlu. (Wo: Maaku 6:1-6)

– Ailoye ọrọ Ọlọrun: nkan miran ti o tun le fa ki a ti ara eniyan kọsẹ ni aini oye to ninu ọrọ Ọlọrun lori nkan ti o tọ tabi nkan ti ko tọ. Fun apẹẹrẹ, ọpọ igba ni awọn adari ẹsin awọn Juu ti ara Jesu ati awọn ọmọ ẹyin rẹ dẹṣẹ nitori pe oye ifẹ Ọlọrun lori awọn nkankan ko ye wọn. Awọn n fi gbogbo igba ṣe akitiyan lati ri pe wọn pa gbogbo ofin Mose mọ. Ṣugbọn nitori itunmọ ọpọ ninu awọn ofin yi ati ete Ọlọrun fun wọn ko ye wọn, ọpọ igba ni awọn akitiyan wọn lati pa awọn ofin yi mọ ma n jẹ ki wọn da awọn ailẹṣẹ lẹbi tabi da awọn ẹlẹsẹ lare, ki wọn si ṣẹ si Ọlọrun (Matiu 12:1-8; Maaku 7:1-15). Fun apẹẹrẹ, a ri ka ninu bibeli pe nitori ailoye awọn adari Juu wọnyi, wọn a ma binu ti Jesu ba n ṣe iṣẹ iyanu ti o mu imularada tabi iwosan ba aye ẹnikẹni ni ọjọ isinmi. Loju ti wọn, iṣẹ ni iṣẹ njẹ. Iba jẹ aṣọ fifa, ina dida tabi imuniladara, iṣẹ ni iṣẹ n jẹ. Niwọn igba ti Ọlọrun si ti pasẹ pe ki wọn ma ṣe iṣẹ kankan ni ọjọ isinmi, Jesu ko lẹtọ lati wo ẹnikẹni san ni ọjọ na. Eyi si wa lara idi ti wọn fi gbimọ lati pa a, ti wọn si ṣẹ si Ọlọrun. (Wo: Matiu 12:9-14) Ti awa na ko ba fi ara wa jin lati ni oye kun oye ati imọ kun imọ ninu ifẹ Ọlọrun, o ṣeeṣe ki a ma ti ara awọn ọmọ Ọlọrun miran gan gbẹṣẹ, nigba ti a ba n da wọn lẹbi lori nkan ti Ọlọrun ko ti da wọn lẹbi. Loni, ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ni o ma n da awọn ọmọ rẹ miran lẹbi lori pe wọn lo ẹṣọ ara tabi pe wọn wọ ṣokoto tabi pe wọn n lo ilu ni akoko ijọsin wọn ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn ailoye ifẹ Ọlọrun ni o n fa awọn nkan wọnyi, ti o si n jẹ ki wọn ṣẹ si Ọlọrun.

– Owu jijẹ tabi ilara: Ti owu jijẹ nkọ? Owu jijẹ naa le fa ki a ti ara awọn alaiṣẹ kọsẹ. Niwọn igba ti inu wa ko ba ti dun si oriire awọn miran tabi ti inu n bi wa nitoripe ẹnikan n ṣe awọn nkan ti a ko le e ṣe, owu jijẹ ti bẹrẹ niyẹn. Bi a ṣe ri ninu bibeli, awọn adari awọn Juu jowu Jesu lọpọlọpọ nitori awọn iṣẹ iyanu ti o n ṣe. Nitorina wọn mọọmọ bẹrẹ si ni sọ awọn ọrọ alufansa si, debi pe wọn tilẹ sọ pe nṣe ni o n fi ẹmi Eṣu le ẹmi Eṣu jade, ti wọn ṣi tipasẹ eyi ṣẹ si Ẹmi Mimọ. Yatọ si eyi, owu jijẹ yii naa tun wa lara nkan ti o jẹ ki wọn fa le Pilatu lọwọ lati pa a, ti wọn si di apaniyan. (Wo: Matiu 12:22-32 &27:17-18). Keeni nkọ? Ki ni idi ti o fi kọsẹ lati ara aburo rẹ, Abẹli? Ṣebi ilara lo fa. O ṣe ilara arakunrin rẹ nitoripe Ọlọrun gba ẹbọ rẹ nigbati ti ko si gba oun tabi ẹbọ ti o mu wa. (Wo: Jẹnẹsisi 4:1-16) Lafikun, awọn Juu ti awọn Pọọlu ba pade ni ọpọ ibi ti wọn lọ lati waasu si awọn Keferi titori owu jijẹ ṣiṣẹ lodi si ihinrere Jesu, eyi ti o si jasi ikọsẹ fun wọn (Iṣe Awọn Apositeli 13:44-52). Nitorina, a gbọdọ sọrọ fun owu jijẹ tabi ilara, ki a ma ba ti ara awọn ti a n ṣe ilara si kọsẹ, ki a si padanu ipese, igbala tabi igbega Ọlọrun fun wa tabi ki a di ẹni itanu.

– Afarawe omugọ: Lotitọ, a kọ wa ninu bibeli lati ma ṣe awokọse awọn ti o n ṣe rere (Filipi 3:17; Heberu 13:7). Amọ a gbọdọ ni imọ ati oye ti o peye ninu ọrọ Ọlọrun lati mọ iru afarawe ti o tọ fun wa lati ṣe. Aijẹbẹ, a le tipasẹ afarawe awọn ọmọ Ọlọrun kan kọsẹ lara wọn, ki a si ṣubu ninu igbagbọ wa. Idi ni yi ti Pọọlu ṣe sọ eyi fun wa: “Ẹ maa ṣe afarawe mi, ani gẹgẹ bi emi ti n ṣe afarawe Kirisiti.” (1Korinnti 11:1). Eyi tunmọ si pe Pọọlu ko fẹ ki ẹnikẹni gbe oun ga ju Jesu lọ ninu aye wọn tabi ki wọn fi Pọọlu si aye ti o tọ si Jesu ninu aye wọn. Nitorina, niwọn bi o ba ṣe tẹle Jesu mọ naa ni o yẹ ki awọn ti o n ṣe afarawe rẹ tẹle. Amọ bawo ni wọn ṣe fẹ mọ boya o n tẹle Jesu tabi ko tẹle, ti awọn gan ko ba mọ Jesu funrawọn? Ko si bi wọn ṣe fẹ mọ. Idi si ni yi ti ọpọlọpọ ọmọ Ọlọrun ṣe n ṣe radarada loni. Wọn n ṣe afarawe omugọ. Wọn n ṣe afarawe awọn adari wọn ti o ti pada lẹyin Jesu tabi ti o ti rekọja sinu ẹṣẹ. Eyi si le jasi iparun fun wọn, ti wọn ko ba ri aanu gba. Nitorina, bi o ṣe wu ki a fẹran eniyan to tabi ki Ọlọrun ti lo fun aye wa to, niwọn igba ti iṣe tabi iwuwasi rẹ ba ti tako ifẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi a ṣe la a kalẹ fun wa ninu bibeli, a ko gbọdọ se afarawe rẹ, ki a ma ba kọsẹ lati ara rẹ. (Wo: Matiu 23:1-3)

– Gbibgbe eniyan ga ju Ọlọrun lọ: Ọpọ loni lo jẹ pe ti wọn ba ti gbọ pe wooli, alufa tabi ajinhinrere ni ẹnikan, nṣe ni wọn yo o bẹrẹ si ni bọ ọ. Eyi si ti jẹ ki wọn kọsẹ, ki wọn si ṣubu ninu irinajo igbagbọ wọn. Lotitọ, a fi ye wa ninu bibeli pe ki a ma gba awọn iranṣẹ Ọlọrun gbọ, ki a si tun ma bu iyi ati ọla fun wọn (2Kironika 20:20; Matiu 10:40-42; 1Tẹsalonika 5:12-13). Amọ a ko gbọdọ wa titori eyi sọ wọn di ọlọrun kekere ninu aye wa. Ọlọrun le ma lo wọn tabi ti lo wọn lati ba aini wa pade tabi lati ṣe awọn akanṣe iṣẹ kan ninu aye wa. Ṣugbọn niwọn igba ti iwa ati iṣe tabi ọrọ wọn ba ti bẹrẹ si ni tako aṣẹ Ọlọrun, bi a ṣe la a kalẹ ninu bibeli, a ko gbọdọ tẹle wọn tabi ṣe amulo nkan ti wọn n sọ. Aijẹbẹ, a o ti ara wọn ṣẹ si Ọlọrun. Ranti itan wooli agba ati wooli ọdọmọde ti o wa ninu bibeli. Kini idi ti ọdọmọde wooli yi fi kọsẹ, ti o si ri ijiya iku? Idi ni pe wooli agba ṣi i lọna nipa pipa irọ fun. Nitorina, gẹgẹ bi ọrọ bibeli, wooli eke ati wooli jẹunjẹun ati opurọ pọ nigboro. Awọn ojiṣẹ Ọlọrun ti o si ti ṣina naa pọ ni igboro pẹlu. Awa ni a wa gbọdọ ṣọ ara wa, ki a ri pe eso ẹmi n jẹyọ ninu aye awọn adari ijọ ti a n ba lopọ, ki a si tun ri pe a ko jẹ ki ẹnikẹni ṣo ara rẹ di ọlọrun mọ wa lọwọ, ki wọn ma ba ṣi wa ni ọna. (Wo: 1Awọn Ọba 13; Matiu 7:15-20)

– Ifẹ lati gbẹsan: A ri ka ninu bibeli pe Dafidi, ni akoko kan, binu to bẹẹ gẹ ti o fi fẹ pa idile ọkunrin kan ti a n pe ni Nabali run. Idi si ni pe ọkunrin na wuwa aida si oun ati awọn eniyan rẹ. Nitorina, wọn woye pe o yẹ ki awọn gbẹsan. Ti ko ba wa ṣe pe Ọlọrun lo Abigẹli, aya Nabali, lati tu wọn loju, ki o si jẹ ki wọn ri pe wọn ti fẹ kọsẹ lati ara Nabali, gbigbẹsan yi ko ba sọ wọn di apaniyan niwaju Ọlọrun. (Wo: 2Samuẹli 25) Nitori eyi, a gbọdọ sọra fun gbigbẹsan ara wa lara awọn ti o n ṣeka fun wa tabi ni wa lara. Idi si ni pe a ko ni imọ tabi oye idajọ ti o peye rara. Ọlọrun nikan ni o ni. Idi si ni yi ti o fi ni ki a fi igbẹsan gbogbo silẹ fun Oun, ki a si ma ṣe rere si awọn ti o ba n lepa wa tabi ti o n ṣe ika fun wa. Aijẹbẹ, ko si ki awa naa ma ṣe aṣeju, ki a ṣi di ika niwaju rẹ nibi ti a ba ti n gbiyanju lati gbẹsan. (Wo: Roomu 12:19-21)

– Ainifẹ si otitọ: Ki ni idi ti ọpọ loni ṣe n ti ara awọn kan ti wọn pe ara wọn ni ojiṣẹ Ọlọrun tabi ọmọ Ọlọrun ṣe awọn nkan kan ti ko ṣe gbọ si eti? Ainifẹ si otitọ ọrọ ati ẹkọ ti o ye kooro jẹ ọkan gboogi lara rẹ. A ri awọn wooli loni ti o n fa irun abẹ awọn obinrin ijọ wọn lojutaye ati awọn ti wọn n ṣe awọn nkan kayefi miran. Ṣibẹsibẹ, awọn wọnyi ni ọpọ ọmọ ijọ, ti wọn n tẹle wọn, ti wọn si tun n ko owo fun wọn lati polongo ẹsin ara wọn. Ki lo fa ti wọn fi ri awọn wọnyi tanjẹ ati ti wọn se ri ori wọn fi gba paarọ? Ainifẹ si otitọ awọn alatẹle awọn wọnyi wa lara nkan to fa. Bibeli jẹ ki o ye wa pe ti eniyan ko ba ti ni ifẹ si otitọ, ti eniyan ba ti kọ lati ni imọ Ọlọrun, o di dandan ki Ọlọrun fi ṣilẹ fun itanjẹ ati iye rira. Irufẹ awọn bẹ ni o ma n tẹle awọn wooli eke, ti wọn si n ti ara wọn kọsẹ ninu igbagbọ. (Wo: Roomu 1:21-32; 2Tẹsalonika 2:9-12; 2Timoti 4:3-4)

– Aikiyesara: Bi a ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe ẹbi Josẹfu ni pe o jẹ arẹwa ọkunrin ati ẹnikan ti o dun un wo. Ṣugbọn, nitori eyi, iyawo oluwa rẹ bẹrẹ si ni lepa rẹ lati fa sinu ẹṣẹ agbere. Ti ko ba wa jẹ ẹnikan ti o kiyesara ni, nṣe ni ko ba ti ipasẹ arabinrin yi kọsẹ, ki o si padanu ete ati ipinnu Ọlọrun lori aye rẹ. (Wo: Jẹnẹsisi 39:6-13) Nitori eyi ni bibeli ṣe sọ fun wa pe ẹni ti o ba ro pe oun duro ṣinṣin ki o kiyesara, ki o ma baa ṣubu (1Korinnti 10:12). Ọpọlọpọ pakute ni Eṣu ma n lo awọn eniyan lati dẹ fun awọn ọmọ Ọlọrun, ki wọn ba le kọsẹ. Amọ ti a ba kiyesara, ti a ko si jẹ ki igberaga tabi amọju jẹ ki a kọ eti ọgbọnhin si ikilọ ati ibawi Ọlọrun tabi ti awọn ọmọ rẹ, a ko ni i bọ sinu wọn.

ỌRỌ IPARI
Lotitọ ni bibeli fi ye wa pe ohun ikọsẹ ko le ṣe alai ma wa ninu aye yi. Amọ ko ki i ṣe dandan ni fun wa lati tipasẹ ẹnikẹni kọsẹ. Ti a ko ba wa fẹ ti ipasẹ ẹnikẹni kọsẹ, a gbọdọ rẹ ara wa silẹ, ki a si fi ara wa jin fun ọrọ Ọlọrun.

IBEERE
– Darukọ awọn ọna miran ti a le tipasẹ awọn eniyan kọsẹ, yatọ si awọn eyi ti a mẹnuba ninu ẹkọ yi.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 17, ẸRẸNA 2021

AKỌRI: IKỌSẸ LATI ARA ỌLỌRUN AYỌKA: MATIU 11:1-6

AKỌSORI: “Alabukun-fun si ni ẹnikẹni ti ki yoo ri ohun ikọsẹ ninu mi.” (Matiu 11:6)

ỌRỌ ISAAJU
Bi a ṣe ri ka ninu bibeli, awọn nkan ti o le mu ki eniyan kọsẹ ko le ṣe alai ma wa, niwọn igba ti a ba wa ninu aye yi. Amọ egbe ni fun ẹni na ti a ba tipasẹ rẹ jẹ ki awọn eniyan kọsẹ. Nitorina a nilo lati kiyesara gidigidi, ki a ma ba jẹ irinṣẹ ti Eṣu yo ma lo lati bi awọn eniyan ṣubu ninu igbagbọ wọn tabi lati jẹ ki wọn gbe igbesẹ ti yoo jẹ ki wọn ṣegbe. (Wo: Luuku17:1-3; Roomu 14:13) Ṣugbọn ṣa o, nkankan ti o tun wa ṣe ni laanu ni pe ọpọ igba ni awọn eniyan tun ma n ba ikọsẹ pade ninu ibaṣepọ wọn pẹlu Ọlọrun. Njẹ eyi tilẹ ṣeeṣe? Ani ṣe o ṣeeṣe ki eniyan ti ara Ọlọrun kọsẹ? Ti o ba ṣeeṣe, ki ni o le fa ati pe ewu wo ni o wa nibẹ? Awọn nkan wọnyi ni a fẹ gbeyẹwo ninu ẹkọ bibeli yi. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun lo ẹkọ na lati ran wa lọwọ lati ma ṣe ri ohun ikọsẹ kankan ninu Ọlọrun, ki a si padanu ipese ati oriyin rẹ.

IKỌSẸ LATI ARA ỌLỌRUN
Wayi o, bi mo ti ṣe beere tẹlẹ, njẹ o ṣeeṣe ki a ti ara Ọlọrun kọsẹ? O ṣeeṣe. Yatọ si pe a ri eyi dimu ninu bibeli, a tun ri ninu iṣesi awọn kan ninu aye yi si Ọlọrun pe eniyan le ti ara Ọlọrun kọsẹ. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn kan ti o jẹ pe gbogbo igba ti wọn ba fẹ wa awawi fun bi aye wọn ṣe polukumusu tabi kun fun idibajẹ, Ọlọrun ni wọn ma n di gbogbo rẹ le lori. A si tun ri awọn ti o jẹ pe ti wọn ba wo idarudapọ inu aye yi lọ siwaju ati sẹyin, wọn a ma sọ pe ti Ọlọrun ba wa nitooto, ti o si jẹ Oun ni ẹlẹda ati alakoso aye, a jẹ pe Oun ni o yẹ ki a ri bu fun gbogbo laasigbo ọmọ ẹda. Awọn wọnyi ti ri ohun ikọsẹ ninu Ọlọrun bi o tilẹ jẹ pe ko si ohun ikọsẹ kankan ninu rẹ rara (1Johanu 1:5). Ki wa ni awọn nkan ti o le fa ki eniyan ba ikọsẹ pade lati ara Ọlọrun? Pataki lara wọn ni iwọnyi:

– Ailoye: Lakọkọ, ti awọn eniyan ko ba ni oye pe rere ni Ọlọrun, ẹni ti ko le ṣe ibi tabi aiṣododo kankan rara, o ṣeeṣe ki wọn ri ohun ikọsẹ lara ra ni igba ipọnju tabi nitori rukerudo aye yi (Saamu 92:15). Eyi jasi pe Ọlọrun kọ ni o wa nidi gbogbo rugudu ti n ri ninu aye yi. Eṣu ati ẹṣẹ wa ni o fa wọn. Ekeji, ti awọn eniyan ko ba ni oye pe Ọlọrun ko le ṣe ohunkohun tabi fi aye gba ohunkohun ti o lodi si imuṣẹ ete rẹ ni rere fun aye wọn, o ṣeeṣe ki Eṣu ti wọn ni igba ipọnju tabi idanwo lati ti ara Ọlọrun kọsẹ (Joobu 2:7-10; Jemisi 1:12-17). Ekẹta, ti awọn eniyan ko ba ni oye pe ko si irufẹ iṣoro tabi idojukọ ti wọn le ba pade ti o ṣajoji tabi ti Ọlọrun ko ni ọna abayọ silẹ fun wọn ninu rẹ, o ṣeeṣe ki wọn ti ara rẹ kọsẹ dipo ki wọn nawọ gan iranwọ rẹ ti O ti pese silẹ fun wọn (Iṣe Apositeli 17:24-27; 1Korinnti 10:13). Ẹkẹrin, ti a ba ro pe ọranyan ni fun Ọlọrun lati pa wa mọ tabi tu wa silẹ ninu iṣoro wa nitori ododo wa, ko si ni ki a ma ti ara rẹ kọsẹ nigba ti a ba ba awọn idojukọ kan pade, ti Ọlọrun ko si ṣe bi a lero pe o yẹ ki o ṣe. Ti a ba si wo akọsilẹ bible lori awọn laaṣigbo Joobu ati bi o ṣe kọsẹ gigigidi nipa ọrọ ẹnu lati ara Ọlọrun, a o ri pe ailoye awọn nkan ti mo ti sọ siwaju yi gan ni o fa ikọsẹ rẹ. Joobu ko ni oye pe ko si ibi kankan ninu Ọlọrun ati pe iha tirẹ ni Ọlọrun fi gbogbo igba wa. Nitorina nkan ti o nilo lati ṣe ni pe ki o ke pee ninu iṣoro rẹ dipo ki o ma fi ẹsun aiṣododo kan an ati ki o ma duro lori ododo ara rẹ, ododo ti ko ja mọ nkankan niwaju Ọlọrun. Ti ko ba si ṣe pe Ọlọrun fi aanu gba a, nṣe ni ko ba parun sinu ikọsẹ rẹ.

– Amọju: Ailoye didara, ifẹ, eto ati ipese Ọlọrun fun wa lati bori idojukọ yowu ti a le ba pade ni aye yi nikan kọ ni o le jẹ ki a kọsẹ lati ara rẹ. Nkan miran ti o tun le jẹ ki a kọsẹ lara rẹ ni amọju tabi ka pe ni ṣiṣe bi Ọlọrun. Nkan ti mo n sọ ni pe niwọn igba ti a ba ni lọkan pe ọna kan pato ni o yẹ ki Ọlọrun gba lati yanju iṣoro wa tabi pe igbesẹ kan bayi ni o yẹ ki o gbe lati yọ wa ninu ọfin yowu ti a jin si. Fun apẹẹrẹ, nigbati Naamani, olori-ogun Siria, ti o dẹtẹ tọ wooli Eliṣa wa, iwoye tirẹ ni pe o yẹ ki Eliṣa jade tọ oun wa, ki o si kepe Ọlọrun rẹ, ki o si fi ọwọ ba ara oun, ki oun si ri iwosan gba (2Awọn Ọba 5:11). Eyi tunmọ si pe ọkunrin yi ti ni lọkan ọna ti o yẹ ki Ọlọrun gba lati wo oun san. Nigba ti ọrọ ko si ri bi o ṣe fẹ ki o ri, o binu, o si kọsẹ. Ti ko ba si ṣe pe Ọlọrun lo ọkan lara awọn iranṣẹ rẹ lati ba sọ otitọ ọrọ, nṣe ni ko ba padanu iwosan rẹ ni ọjọ yi, ti ko ba si fi iyoku ọjọ aye rẹ dẹtẹ. (Wo: 2Awọn Ọba 5)

A tun ri apẹẹrẹ eleyi miran ninu ọrọ kan ti o waye laarin Jesu Kirisiti Oluwa wa ati Johanu onitẹbọmi. Gẹgẹ bi a ṣe fi ye wa ninu bibeli, Johanu yi ni Ọlọrun ran lati pese ọkan awọn Juu silẹ fun Jesu ati lati tọka rẹ si wọn gẹgẹ bi Mesaya ti wọn n reti (Luuku 1:8-16; Johanu 1:19-34). O si ṣe bẹẹ gẹgẹ. Ṣugbọn nigba ti o to akoko kan, ọba Hẹrọdu mu Johanu, o si ti i mọlẹ nitori pe oun ba wi pe ko ni ẹtọ lati fi aya arakunrin, Filipi, ṣe aya. (Wo: Maaku 6:17-18) Nigba ti o si ṣe diẹ ti o ti n woye pe ki a tu oun silẹ, ti a ko si tu silẹ, ọkan rẹ bẹrẹ si ni rẹwẹsi. Boya o wa ba Ọlọrun sọrọ lori eyi tabi ko ba sọrọ, a ko le sọ. Ṣugbọn a ri akọsilẹ yi ninu bibeli ti o jẹ ki o ye wa pe wooli Ọlọrun nla yi kọsẹ lati ara Jesu nitoripe o ṣe iyemeji: “O si ṣe, nigba ti Jesu pari aṣẹ rẹ tan fun awọn ọmọ-ẹyin rẹ mejeejila, o ti ibẹ rekọja lati maa kọni, ati lati maa waasu ni ilu wọn gbogbo. Nigba ti Johanu gburoo iṣẹ Kirisiti ninu tubu, o ran awọn ọmọ-ẹyin rẹ meji, O si wi pe, Iwọ ni ẹni ti n bọ tabi ki a maa reti elomiran? Jesu si dahun o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹyin gbọ, ti ẹ si ri fun Johanu: Awọn afoju n riran, awọn arọ si n rin, a n wẹ awọn adẹtẹ mọ, awọn aditi n gbọran, a n ji awọn oku dide, a si n waasu ihinrere fun awọn otoṣi. Alabakun-fun ni ẹnikẹni ti ki yoo ri ohun ikọsẹ ninu mi.” (Matiu 11:1-6)

Ki wa ni o fa ti Johanu, ti o jẹ pe oun ni o fi Jesu han gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ati Mesaya ti awọn ara Isiraẹli n reti, fi bẹrẹ si ni ṣe iyemeji lori rẹ? Nkan ti o fa ni pe o woye pe o yẹ ki Jesu ṣe nkankan nipa atimọle oun, niwọn igba ti o jẹ pe O n ṣe oriṣiriṣi iṣẹ akanṣe ati iyanu ni aarin awọn eniyan yoku. Nigba ti ko si ri ki Oun ṣe nkankan, o bẹrẹ si ni ro lọkan rẹ pe boya Jesu tilẹ kọ ni ẹni ti awọn n reti. Ṣugbọn ṣe ete Ọlọrun ni lati lo Jesu lati yọ ọ kuro ninu tubu? Bawo ni o tilẹ ṣe mọ pe Jesu ni Ọlọrun fẹ lo lati yọ kuro ninu tubu yi tabi pe yiyọ awọn eniyan kuro ninu tubu afojuri wa lara nkan ti a ran Jesu wa si aye ni igba akọkọ lati ṣe? Ni kukuru, Johanu ri ohun ikọsẹ ninu Jesu nitoripe o ro pe oun mọ ọna ti o yẹ ki Ọlọrun gba lati tu oun silẹ.

Bẹẹ gẹgẹ, awa na le ti ara Ọlọrun kọsẹ niwọn igba ti a ko ba ni oye pe rere ni Ọlọrun ni gbogbo igba, pe iha ti wa ni O wa ati pe ko si irufẹ idojukọ ti a le ni ti ko ni ọna abayọ fun ati tun pe igbala wa lati ọdọ Ọlọrun ko da lori ododo wa bi ki i ṣe ododo tirẹ. A tun le ti ara rẹ kọsẹ ti a ba ro pe a gbọn to lati mọ ọna ti o yẹ ki O gba lati ran wa lọwọ tabi lati ṣe wa ni rere. Ọna Ọlọrun ati ero rẹ yatọ si ọna ati ero eniyan. Idi si ni yi ti o fi jẹ Ọlọrun. Ko ni jẹ Ọlọrun tabi ki a ma nilo rẹ niwọn igba ti a ba ti mọ nkan ti o yẹ ki O ṣe lati fun wa ni iṣẹgun lori idojukọ wa. Nitorina, a gbọdọ ṣọra fun amọju ninu ibaṣepọ wa pẹlu rẹ. Aijẹbẹ, nigba ti O ba kọ ti ko dasi ọrọ aye wa ni ọna ti a ro pe yoo gba da si, iyemeji le wọle sinu ọkan wa, ki o si jẹ ki a kọsẹ, ki a si tun padanu igbala tabi ipese rẹ fun wa.

ỌRỌ IPARI
Jesu Oluwa wa sọ pe alabukunfun ni awọn ti ko ri ohun ikọsẹ ninu Oun. Eyi tunmọ si pe ibukun ni fun ẹni na ti ko lo iṣesi Ọlọrun gẹgẹ bi awawi fun ikọsẹ rẹ. Idi si ni pe imọlẹ ni Ọlọrun, ko si ki i fi igba kankan gbe igbesẹ kankan ti o le fa ikọsẹ tabi iṣubu fun awọn eniyan rẹ. Niwọn igba ti a ba si ti rẹ ara wa silẹ, ti a si mu suuru lati ri igbala tabi ipese rẹ, ko si nkankan ti yo mu wa ti ara rẹ kọsẹ. Dipo eyi, nṣe ni ibukurn rẹ yoo ṣan bo gbogbo aye wa.

IBEERE
– Awọn nkan miran wo ni o tun gbagbọ pe o le jẹ ki eniyan ti ara Ọlọrun kọsẹ, yatọ si awọn eyi ti a mẹnuba ninu ẹkọ yọ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 10, ẸRẸNA 2021

 

AKỌRI: O N KOJỌPỌ NI TABI O N TUKA                              AYỌKA: MATIU 12:30

 

AKỌSORI: “Ẹni ti ko ba wa pẹlu mi, o n ṣe odi si mi; ẹni ti ko ba si ba mi kopọ, o n fọnka.” (Matiu 12:30)

 

ỌRỌ ISAAJU

Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, gbogbo awọn ti o jẹ ọmọ Ọlọrun ninu Kirisiti Jesu ni a ti ṣe yẹ pẹlu ẹbun ẹmi kan tabi omiran lati wulo fun un. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun awọn ara Kọrinnti: “Ṣugbọn a n fi ẹbun ẹmi fun olukuluku eniyan lati jere.” (1Korinnti 12:7) O tun sọ eyi fun awọn ara Efesu: “Ṣugbọn olukuluku wa ni a fi oore-ọfẹ fun gẹgẹ bi oṣuwọn ẹbun Kirisiti.” (Efesu 4:7) Peteru naa tun wa ṣe afikun awọn ọrọ wọnyi nigba ti o sọ pe, “Bi olukuluku ti n ri ẹbun gba, bẹẹ ni ki ẹ maa ṣe ipinfunni rẹ laarin ara yin, bi iriju rere ti oniruuru oore-ọfẹ Ọlọrun.” (1Peteru 4:10). Nitorina, ko si ọmọ Ọlọrun kankan ti ko ni ẹbun Ẹmi Mimọ. A si fun un ni ẹbun yi ki oun na ba le jẹ irinṣẹ ti Ọlọrun le e lo lati tun aye awọn miran ṣe. Ti a ba wa ri ẹnikẹni ti o pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun ti o tun wa n sọ pe oun ko ni ẹbun ẹmi kankan, a jẹ pe onitọun n tan ara rẹ jẹ ni – boya ko ki i ṣe Ọmọ Ọlọrun rara. Ti a ba si tun wa ri ẹnikẹni ti o pe ara rẹ ni ọmọ rẹ ti ko si kọbiara si lilo awọn ẹbun ti a fun, a tun gbọdọ fura si ẹni na. Idi si ni pe ko si ọmọ Ọlọrun tootọ ti ko ni ni itara lati ṣiṣẹ fun ilọsiwaju ijọba baba rẹ, bi ko tilẹ ni imọ to lori ọna ti o le gba ṣe bẹ.

 

O N KOJỌPỌ NI TABI O N TUKA

O wa ṣe ni laanu pe ọpọ ti a n pe ni ọmọ Ọlọrun ni ko ki i kọbiara si ṣiṣe awari ati lilo ẹbun ẹmi wọn. Ọpọ naa lo si tun jẹ pe ọna ti wọn n gba lo awọn ẹbun ẹmi wọn lodi si ifẹ Ọlọrun. Nitorina Ọlọrun ko le lo nkan ti wọn n ṣe lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Nitori irufẹ awọn eniyan wọnyi ni Jesu Oluwa wa ṣe wa sọ ọrọ ti o wa ninu ẹsẹ bibeli ti a n gbe yẹwo fun ẹkọ bibeli yi, eyi ti o ka bayi: “Ẹni ti ko ba wa pẹlu mi, o n ṣe odi si mi; ẹni ti ko ba si ba mi kopọ, o n fọnka.” (Matiu 12:30)

 

Ki wa ni koko nkan ti Jesu sọ silẹ yi? Koko mẹrin ọtọọtọ ni a le mẹnuba lori ọrọ yi. Awọn si ni yi:

 

–     Ko si agbedemeji ni ọrọ sisin Ọlọrun: A ko le sọ pe a ki i ṣe ti Ọlọrun ati pe a ki i si ṣe ti Eṣu. Ẹnikẹni ti ko ba ti jẹ ti Ọlọrun, ti Eṣu ni onitọun. Eni na le ma jale, parọ, ṣekẹ, ṣagbere, ṣojukokoro ati bẹẹbẹẹ lọ. Amọ, niwọn igba ti o ba kọ lati gba Jesu ni Oluwa ati Olugbala rẹ, ki o si tipasẹ rẹ fi ara rẹ jin fun Ọlọrun, ti Eṣu ni i ṣe. Idi ni yi ti Jesu ṣe sọ ninu lẹta rẹ si awọn ara Laodikia pe, “Ẹmi mọ iṣẹẹ rẹ, pe iwọ ko gbona bẹẹ ni iwọ ko tutu; emi iba fẹ pe ki iwọ kuku tutu, tabi ki iwọ kuku gbona. Njẹ, nitori ti iwọ ṣe ilọwọwọ, ti o ko si gbona, bẹẹ ni o ko tutu, emi o pọ ọ jade kuro ni ẹnu u mi.” (Ifihan 3:15-16) Ṣe o ri bayi? Ti Jesu ba le sọ pe Oun yo tu awọn kogbọnakotutu ọmọlẹyin rẹ danu kuro lẹnu rẹ, melomelo wa ni awọn ti o duro si agbedemeji ninu sisin Ọlọrun ati sisin Eṣu. O daju pe ko tilẹ ka awọn wọnyi mọ awọn tirẹ rara.

 

–     Ti o ko ba ti ba a ṣiṣẹ, nṣe ni o n ba iṣẹ rẹ jẹ: Koko miran ti a tun gbọdọ fi ọkan si ninu ọrọ Jesu ni pe ẹnikẹni ti ko ba ti ba ṣiṣẹ lati kojọpọ n fọnka ni. Eyi tunmọ si pe ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni onigbagbọ ninu Kirisiti ti kọ wa fi ara rẹ jin lati ṣe iṣẹ yowu ti Ọlọrun le yan fun lati ṣe, fun idagbasokọ ijọ rẹ tabi fun igbeeru si ihinrere, n ṣiṣẹ lodi si iṣẹ Jesu. Lafikun, ẹnikẹni ti o ba pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun ti o tun wa kọ lati ṣe amulo ẹbun ẹmi rẹ, nṣe ni iru ẹni bẹ n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ. Idi si ni pe Ọlọrun ko ki i dede fun eniyan ni ẹbun ẹmi tabi ki O sọ pe ki eniyan ṣe nkan ti ko ba ni nkan ti o fẹ fayọ pẹlu rẹ. Ti a ba wa kọ, ti a ko lo ẹbun ẹmi wa tabi ṣe nkan ti o fẹ ki a ṣe, a jẹ pe a ti n pa ifẹ ati ete rẹ lori aye wa ati lori awọn eniyan miran lara niyẹn. A ko si le ṣe iru nkan bayi ki a ma fa idajọ rẹ sori wa tabi ki a ro pe a o ri oriyin gba lọdọ rẹ. Nitorina, o ye ki o bere lọwọ ara rẹ irufẹ iha ti o kọ si awọn iṣẹ ti Ọlọrun ti ba ọ sọrọ le lori ati awọn iṣẹ ti O n tipasẹ awọn adari ijọ rẹ gbe fun ọ. O tun ye ki o bere lọwọ ara rẹ boya o n lo ẹbun ẹmi rẹ lọna ti o peye to. Idahun rẹ si awọn ibeere yi yoo sọ fun ọ boya nṣe ni o n pa iṣẹ Jesu lara tabi mu tẹsiwaju. (Wo: Kolose 4:17; 2Timoti 1:7&4:5)

 

–     Iṣẹkiṣẹ ti a ba ṣe lodi si fẹ rẹ n pa iṣẹ rẹ lara: Nkan miran ti o tun gbọdọ ye wa yekeyeke ni pe iṣẹkiṣẹ ti a ba ṣe lodi si ifẹ Ọlọrun ko le mu itẹsiwaju ba iṣẹ rẹ rara. Dipo bẹ, nṣe ni yo koba nkan ti O n ṣe. Nitorina, ọtọ ni ki a lo ẹbun ẹmi wa; ọtọ tun si ni ki a lo awọn ẹbun ẹmi yi ni ọna ti o ba ifẹ Ọlọrun mu. Bẹẹ si ni, ọtọ ni ki a tẹramọ iṣẹ iranṣẹ ti Ọlọrun fun wa; ọtọ tun si ni ki a ṣe iṣẹ iranṣẹ yi ni ọna ti o ba ifẹ rẹ mu. Ọpọ ni o n ṣi ẹbun ẹmi wọn lo loni, ti wọn si n tabuku ọrukọ Jesu, bi a tun ṣe ri pe ọpọ miran na ti o si n ṣi oore-ọfẹ iṣẹ iranṣẹ ti a fun wọn lo loni, ti wọn ti sọ iṣẹ iranṣẹ wọn di karakata tabi ọna fun jibiti lilu tabi agbere ṣiṣe. Awọn wọnyi ko ṣiṣẹ lati gba oriyin Ọlọrun amọ fun oriyin awọn eniyan ati ifẹkufẹ ti ara wọn. (Wo: Matiu 6:1-4&23:14; Johanu 7:18; 2Korinnti 2:17; Filipi 3:18-19; 2Timoti 4:2-4; 2Peteru 2; Juudu 1). Lafikun, ọpọ ni o n jẹ pe ẹran ara ati ọgbọn ori wọn ni wọn gbọkan le lati ṣe iṣẹ Ọlọrun, ti wọn ti gbagbe pe ohunkohun ti a ko ba tipasẹ Ẹmi Ọlọrun ṣe, oku, asan ati ofo ni (Johannu 6:63; Roomu 15:17-18; 2Cor 3:17). Gbogbo awọn ti n ṣiṣẹ lọna aitọ yi ni o n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ ni ọpọ ọna dipo ki wọn ma mu itẹsiwaju ba. Awọn wọnyi si ni awọn Apositeli Oluwa igbaani pe ni eke, ti wọn si wa ni abẹ ewu didi ẹni itanu. Njẹ awa na ko ha wa ni abẹ ewu yi bi? Njẹ iṣẹ iranṣẹ wa peye niwaju Ọlọrun to bẹẹ gẹ ti yo fi fun wa ni oriyin? (Ifihan 3:2)

 

–     Iwakiwa ti a ba n wu lodi si ifẹ rẹ n pa iṣẹ rẹ lara: Yatọ si awọn nkan ti a ti mẹnu ba ṣiwaju, a tun gbọdọ mọ pe iha ti a kọ si igbe aye ti a n gbe ati iwa ti a n wu ṣe pataki pupọ ni mimu itẹsiwaju ba iṣẹ Ọlọrun ati ni biba iṣẹ rẹ jẹ. Ka tilẹ sọ otitọ, awọn ọna ti a n gba lo ominira wa gan tun le mu itẹsiwaju tabi ipalara ba iṣẹ Ọlọrun. A le ma sọtẹlẹ, ki a ma riran, ki a ma wo awọn alaisan san tabi ki a ma ṣe iwaasu ti o ye kooro. Ṣugbọn ti igbe aye ti a n gbe ba lodi si ifẹ Ọlọrun, ko si ni bi a ko ṣe ni pa iṣẹ yowu ti a ba ṣe fun un lara, ki o si fi idibajẹ si. Njẹ o tilẹ mọ pe Jesu sọ pe o ṣeeṣe ki eniyan ti ilẹkun mọ awọn ti o fẹ wọ ijọba ọrun, ki wọn ma ba raye wọle? Yatọ si eyi, O tun sọ pe o ṣeeṣe ki eniyan sọ awọn ti o sọ pe oun jere ọkan wọn di ọmọ Eṣu pọnbele, ti aye wọn yo tun wa buru ju bi o ṣe wa tẹlẹ lọ? Lafikun, Pọọlu naa sọ pe o ṣeeṣe ki eniyan bi iṣẹ Ọlọrun lulẹ ninu aye awọn eniyan nitori ounjẹ tabi nitori nkan mimu. Nitorina, bi o ṣe ṣe pataki ki a ṣiṣẹ Ọlọrun ni aṣepe ati aṣeyẹ naa ni o ṣe ṣe pataki ki a gbe igbe aye ti ko ni tako iṣẹ yowu ti a n ṣe fun. Aijẹbẹ, nṣe ni a o ma ba iṣẹ rẹ jẹ ti a o si ro pe nṣe ni a n mu itẹṣiwaju ba. (Wo: Matiu 23:13&15; Roomu 14:15-21; 1Korinnti 8:9-13)

 

ỌRỌ IPARI

Ṣiṣiṣẹ pẹlu Ọlọrun ṣe pataki pupọ fun gbogbo ọmọ rẹ. Idi si ni yi ti O fi fun ẹnikọọkan wa ni ẹbun ẹmi, ki a ba le ma lo wọn lati mu itẹsiwaju ba iṣẹ rẹ. Amọ ti a ba kọ ti a ko lo awọn ẹbun yi tabi ti a n lo wọn gẹgẹ bi ifẹ ti ọkan wa, nṣe ni a n ba iṣẹ rẹ jẹ. Ẹni ti o ba si ba iṣẹ Ọlọrun jẹ di dandan ki o ri idajọ rẹ. Nitorina, a nilo lati kiyesara ki a ma ba di ẹni itanu niwaju Ọlọrun nitori iha omugọ ti a kọ si iṣẹ rẹ.

 

IBEERE

–     Awọn ti ko ṣe nkankan ninu ijọ Ọlọrun n ba iṣẹ Ọlọrun jẹ ni. Ṣẹ bẹ ẹ lo ri nitootọ?

–     Njẹ o le ṣe apẹẹrẹ awọn ọna ti iwa wa ṣe le di iṣẹ Ọlọrun lọwọ tabi ran iṣẹ rẹ lọwọ?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

 

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 24, ERELE 2021

 

AKỌRI: IWE JUUDU-IṢỌRA FUN IPALARA INU IJỌ                                  AYỌKA: JUUDU 1-25

 

AKỌSORI: “Ṣugbọn ẹyin, olufẹ, ẹ ma gbe ara yin ro lori igbagbọ yin ti o mọ julọ, ẹ maa gbadura ninu Ẹmi-Mimọ.” (Matiu 13:30)

 

ỌRỌ ISAAJU

Iwe Juudu jẹ ọkan pataki lara lẹta ti awọn apositeli Oluwa igbaani kọ lati pe akiyesi awọn ọmọ Ọlọrun si pataki ki wọn ja fitafita lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn, ki wọn ma ba kuna. Ta gan wa ni Juudu? Juudu, gẹgẹ bi o ti fi ye wa ninu lẹta yi jẹ iranṣẹ Jesu Kirisiti ati arakunrin Jemisi (Juudu 1). Jemisi ewo wa ni a sọrọ nipa ninu lẹta yi, nitori awọn meji ni a mọ si Jemisi laarin awọn apositeli Oluwa? Ṣe Jemisi arakunrin Johanu ni tabi Jemisi arakunrin Jesu Oluwa wa, ti oun na pada di atunbi ati apositeli Jesu? Jemisi ti o jẹ ọkan lara awọn aburo Jesu ni Juudu n sọrọ nipa nibiyi (Maaku 6:3; 1Korinnti 15:7; Galatia 1:19). Eyi wa tunmọ si pe aburo Jesu ni Juudu na jẹ ati pe apositeli ni oun naa pẹlu. Niwọn igba ti ọkunrin yi, ti o jẹ aburo Jesu Oluwa, ti o si tun wa lara awọn ti ko kọkọ fi igba kan gba a gbọ, ba le pada gba pe ọmọ Ọlọrun ati Oluwa ni o jẹ, ko ni si awawi kankan fun ẹnikẹni lati kọ Jesu silẹ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun ati Oluwa gbogbo nkan ti a da (Johanu 7:5).

 

IṢỌRA FUN IPALARA INU IJỌ    

Awọn wo wa ni Juudu kọ iwe rẹ ti a n ṣe agbeyẹwọ rẹ yi si? O sọ wi pe awọn ti a pe, olufẹ ninu Ọlọrun Baba, ti a si pamọ fun Jesu Kirisiti, ni oun kọ iwe na si (Juudu 1). O tunmọ si pe awọn ọmọ Ọlọrun, awọn onigbagbọ ninu Jesu Kirisiti ni a kọ iwe yi si. Ki gan wa ni idi ti o fi kọ iwe na? Bi mo ṣe sọ tẹlẹ, o kọ iwe yi lati pe akiyesi wa si pataki ki a ja gidigidi lati duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa, ki a ma ba gba wa danu, ki a si di ẹni itanu. Ki si idi ti Juudu fi n pe akiyesi wa si eyi? Idi yi ni a ri ni ẹsẹ ikẹrin iwe rẹ, ti o ka bayi: “Nitori awọn eniyan kan n bẹ ti wọn n yọ wọle, awọn ẹni ti a ti yan lati igba atijọ si idalẹbi yii, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti n yi oore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti wọn si n ṣẹ Oluwa wa kan ṣoṣo naa, ani Jesu Kirisiti Oluwa.” (Juudu 4)

 

Pẹlu nkan ti Juudu sọ ninu iwe yi, a ri di mu pe ipalara ti o le wa fun igbagbọ wa ninu ijọ gan ni o fẹ ki a kiyesara fun. Eyi ko wa ja si pe igbagbọ wa ko le ba ipalara pade ni aarin awọn ti ko ki i ṣe onigbagbọ bi ti wa. O le ba pade. Ṣugbọn ọpọ igba ni o jẹ pe ipalara igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun ma n waye lati ọwọ awọn eke tabi agabage ọmọ Ọlọrun ti wọn n darapọ mọ. Nitorina, koko kan pataki ti Juudu fẹ ki a di mu ninu iwe yi ni pe awọn adamọdi ọmọ Ọlọrun wa. Awọn wọnyi ni wọn yọ kẹlẹ wọ inu ijọ Ọlọrun lati ṣi awọn ọmọ rẹ lọna ati lati tabuku orukọ rere rẹ. Oun si fi idi eyi mulẹ nipa fi fun wa ni apẹẹrẹ awọn iṣẹlẹ kan ti o ti waye sẹyin, ti a si kọ silẹ fun wa ninu iwe mimọ. Awọn iṣẹlẹ yi n fi idi rẹ  mulẹ fun wa pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti Ọlọrun ba pe lati jogun iye, ti o si dahun, na ni o ma n pada jogun rẹ. Awọn ti ko ba duro ṣinṣin ninu igbagbọ wọn ninu rẹ ko ni jogun iye tabi ipese rẹ fun wọn. Yatọ si eyi, Juudu tun n fi idi rẹ mulẹ fun wa nipa awọn iṣẹlẹ yi pe dandan ni ki idajọ Ọlọrun wa si ori awọn alaiwa-bi-rẹ, bi o ti wu ki wọn ni ọla tabi ipo to tabi bi o ti wu ki wọn pẹ ninu iwa ibajẹ to. (Wo Juudu 5-7)

 

Ọna wo wa ni a le gba lati mọ awọn wọnyi ti wọn n yọ kẹlẹ wọ inu ijọ lati doju igbagbọ wa delẹ? Gẹgẹ bi ọrọ Juudu, a le mọ wọn nipa irufẹ eso ti wọn n so. Iru eso wo wa ni wọn so? Juudu pin eso yi si isọri melokan. Akọkọ, o ni wọn a ma so eso ipaniyan, bi ti Keeni, ti o pa aburo rẹ Abẹli, ẹni ti o yẹ ki o daabobo (Jẹnẹsisi 4:1-16). Nitorina, ti a ba ti ri ẹni na ti o n ṣe awọn nkan ti o le mu ijamba ba aye tabi igbagbọ awọn ọmọ Ọlọrun ninu ijọ, ti ko si ṣetan lati gba ibawi, ara awọn ti a n sọrọ wọn niyẹn. Ekeji, o sọ pe wọn a ma so eso ojukokoro, bi ti Balaamu (Numeri 22-24). A si wa ri pe ọpọ ijọ Ọlọrun ni o kun fun Balaamu loni, awọn ti o jẹ pe owo ati awọn nkan ti aye yi nikan ni wọn mọ. Awọn wọnyi le ṣe ohunkohun lati ni anikun owo, bi o ti wu ki nkan na lodi si ifẹ Ọlọrun to. Wọn a ma parọ. Wọn a ma jale. Wọn a ma sọ asọtẹlẹ eke. Wọn a si ma da iye le ẹbun Ọlọrun. Bi o ti wa wu ki awọn eniyan yi mọ bibeli tabi lọla to ni aarin ijọ, eke ni wọn, eke ni a si gbọdọ ka wọn si. (Woo: Juudu 11)

 

Isọri eso kẹta ti awọn eke onigbagbọ ti Juudu n ba wa sọrọ le lori ma n so ni iṣọtẹ, bi ti Kọra ti o ko awọn eniyan jọ lati ṣọtẹ si Mose ati Aarọni (Numeri 16). Eyi wa ja si pe ti a ba ti ri ẹnikẹni ti o pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun, ṣugbọn ti a n fi gbogbo igba ba nidi ọtẹ, aigbọran ati ihalẹ si iṣedari nibikibi, a ti ri ọkan lara awọn ti o le ṣe igbagbọ wa ni ijamba niyẹn. Njẹ eyi wa tunmọ si pe ti iṣedari ibi ti a ba wa ko ba wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, nṣe ni ki a dakẹ, ki a si ma woran? Rara o. Ọlọrun ko fẹ ki a lọwọ si idibajẹ kankan. Amọ ọna ti a la kalẹ fun wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun lati gbogun ti idibajẹ yatọ patapata si ti awọn ti aye yi. Adura gbigba, iwaasu ọrọ Ọlọrun ati diduro ṣinṣin ninu iwa ododo jẹ pataki lara awọn ọna ti a la kalẹ fun wa. Awọn igbesẹ miran ẹwẹ ti a ba wa gbe lati tako idibajẹ ninu aye yi gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ofin ilẹ wa, gẹgẹ bi Ọlọrun ti kọ wa lati bọwọ fun ofin ilẹ ti a ba wa (Roomu 13:1-7). Ṣugbọn a ko gbọdọ ba wa nibi iṣọtẹ rara. A ko si gbọdọ ba wa nibi isọrọ igberaga tabi ihalẹ si awọn ijoye ẹmi ti aye yi, bi ọpọlọpọ awọn kan ti wọn pera wọn ni iranṣẹ Ọlọrun ṣe ma n ṣe, ti wọn a si ma pe Eṣu ati awọn ẹmi aimọ rẹ ni orisirisi ọrukọ ti awọn angẹli Ọlọrun ti o lagbara pupọ gan ko le e pe wọn. (Wo: Juudu 8-16)

 

Yatọ si eyi, Juudu sọ pe awọn wọnyi jẹ oniṣekuṣe, ẹlẹgan ati alai-ni-Ẹmi mimọ (Juudu 17-18). Eyi tunmọ si pe wọn ko le ṣe nkankan ti yo jẹ ki awọn ọmọ Ọlọrun ti wọn ba ṣe pọ dagba soke si, tabi duro ṣinṣin si ninu ifẹ rẹ afi ki wọn ba aye wọn jẹ. Nitorina, ti a ba ti ri ẹnikẹni ti o pe ara rẹ ni ọmọ Ọlọrun ti o n wu irufẹ iwa yi, ara wa awọn ti Juudu n sọrọ nipa ni yẹn.

 

Ki wa ni a nilo lati ṣe lati ma fi ori lugbadi ẹtan, arekereke ati iṣẹ ibi awọn adamọdi ọmọ-Ọlọrun yi? Akọkọ, Juudu ni a gbọdọ ma ṣe awọn nkan ti you gbe wa ro ninu igbagbọ wa. Ki si ni awọn nkan wọnyi? Adura gbigba lati inu imisi Ẹmi mimọ jẹ ọkan lara wọn, gẹgẹ bi Juudu ṣe sọ (Juudu 20). Gbigbọ, kika ati ṣiṣe aṣaro ninu ọrọ Ọlọrun jẹ omiran (Jọṣua 1:8; Iṣe Apositeli 20:32). Ibadapọ to loorin pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun otitọ na si tun jẹ omiran lara awọn ti ohun ti a gbọdọ fi ara wa jin fun ki a ma ba gba wa danu kuro ninu igbagbọ wa (Iṣe Apositeli 20:28-31; Heberu 3:12-13&10:25).

 

Nkan ekeji ti Juudu mẹnuba ni ki a ma pa ara wa mọ ninu ifẹ Ọlọrun. Eyi tunmọ si ki a ma kiyesara, ki a si ma rin gberegbere kọja ala ifẹ Ọlọrun si wa (Juudu 21). Nkan ẹkẹta ti Juudu sọ pe ki a ma ṣe ni riran ara wa lọwọ ninu irin ajo igbagbọ wa pẹlu iṣọra. Idi si ni pe a ko le ṣe alairi awọn ọmọ Ọlọrun ti yo bọ sinu panpẹ Eṣu ati awọn ọmọ rẹ lati ṣi wọn lọna ati lati pa aye wọn run. Ko wa wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun lati fi awọn wọnyi silẹ fun iparun; dipo bẹ a gbọdọ gbe igbeṣe ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun lati mu wọn pada bọ sipo. Amọ o, a tun gbọdọ kiyesara bi a ṣe n ṣe eleyi, ki awa na ma ba ṣubu. (Wo: Galatia 6:1; Juudu 22-23)

 

Juudu wa para iwe yi nipa fifi ye wa pe Ọlọrun ni agbara lati pa wa mọ kuro ninu ohunkohun ti o le fẹ fa ikọsẹ fun wa. Nitorina, a nilo lati gbe ọkan wa le patapata, ki a si ma ro pe ọgbọn tabi ipinnu wa le mu wa duro ṣinṣin ninu igbagbọ wa ninu Jesus Kirisiti. (Wo: Juudu 24-25)

 

ỌRỌ IPARI

Ko ki i ṣe aarin awọn eniyan ti aye yi nikan ni ọmọ Ọlọrun ti le ba ipalara igbagbọ pade. O le ba pade ninu ijọ Ọlọrun na ati laarin awọn ti o pe ara wọn ni ti Kirisiti Jesu. Eyi ni idi ti Juudu ati awọn apositeli Oluwa igbaani ṣe kilọ fun wa lati ma fi gbogbo igba wa ni iṣọra fun awọn adamọdi ọmọ Ọlọrun ati ojiṣẹ rẹ. Ti a ba wa kọ lati gba pe awọn adamọdi ọmọ Ọlọrun wa ninu ijọ tabi lati gba pe a le tipaṣe awọn kan ti wọn n pe ara wọn ni ọmọ Ọlọrun ṣi wa lọna tabi mu wa ṣubu, aifamọ ki a ma padanu ninu irin ajo igbagbọ wa nigbẹyingbẹyin.

 

IBEERE

–     Ki ni o ṣe pataki si ọ julọ ninu Ẹkọ yi?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 17, ERELE 2021

 

AKỌRI: Ẹ JẸ KI WỌN DAGBA PỌ                               AYỌKA: MATIU 13:24-30&36-43

 

AKỌSORI: “Ẹ jẹ ki awọn mejeeji ki o dagba pọ titi di igba ikore…” (Matiu 13:30)

 

ỌRỌ ISAAJU

Ni iwọn oṣu melokan sẹyin, mo ṣe alabapade lori ẹrọ ayẹlukara fọnran kan nipa paitọ kan ti o n fa irun abẹ awọn obinrin ijọ rẹ lojutaye. Bi o si ṣe n ṣe eyi na ni o n pe orukọ Jesu, ti awọn ọmọ ijọ rẹ si n ṣe amin. O ya ọ lẹnu, abi? Yatọ si eyi, mo tun ti ri fọnran paitọ miran ti o n wẹ ninu gorodomu kan ninu ile ijọsin rẹ ati ni oju awọn ọmọ ijọ rẹ, ti o si wa bẹrẹ si ni bu lara omi ti o fi wẹ yi lati inu gorodomu ti o lo fun awọn ọmọ ijọ rẹ lati mu. Bi o si ṣe n ṣe eyi na ni awọn kan n kọrin, ti gbogbo awọn ọmọ ijọ ọkunrin yi si n to jade wa lẹyọkọọkan lati wa gba omi mu. Melomelo gan ni a fẹ sọ? Ṣe ti awọn adari ijọ, alagba ijọ, ọga akọrin ati bẹẹbẹẹlọ ti wọn n fi gbogbo igba ba awọn ọmọ ijọ wọn lopọ ni ki a sọ ni tabi ti awọn ti wọn pe ara wọn ni burọda tabi sisita ti o n fi ọgbọn alumọkọrọyin ja awọn ọmọ ijọ miran lole? Orisirisi iwa ibajẹ, iwa ika ati iwa ibọriṣa ti a ko le fẹnusọ tabi ka tan ni o wa laarin ijọ Ọlọrun kaakiri agbaye loni. Eyi si ma n jẹ ki ọpọ ro pe ko si ijọ Ọlọrun otitọ mọ ati pe irọ ni gbogbo wa n pa tan ara wa jẹ.

 

Ẹ JẸ KI WỌN DAGBA PỌ

Amọ ti a ba farabalẹ ṣe agbeyewọ ọrọ Ọlọrun daradara, a o ri pe ko si nkankan ti o ṣe ijọ Ọlọrun; ijọ rẹ si wa digbi. O kan wa jẹ pe ko ki i ṣe gbogbo awọn ti a mọ gẹgẹ bi ọmọ ijọ rẹ tabi ti o n darapọ mọ awọn ọmọ ijọ rẹ na ni Oun naa ri gẹgẹ bi tirẹ. Ọpọ ti o wa laarin awọn ọmọ rẹ, ti a si n fi orukọ rẹ pe lo jẹ pe wọn ko ki i ṣe tirẹ rara. Ki wa ni idi ti ko fi ya wọn sọtọ kuro laarin awọn ọmọ rẹ, ki wọn ba ye tabuku orukọ rẹ? Idi yi ni o sokunfa owe kan ti Jesu sọ fun awọn ọmọ ẹyin rẹ nigba ti O ṣi wa laye pẹlu wọn. Imọ ati oye owe yi si jẹ eyi ti yo ran wa lọwọ pupọ lati mọ iru iha ti o yẹ ki a kọ si awọn iwa aiwabiọlọrun ti o n jẹyọ ninu ijọ loni ati iroyin nipa wọn. Ki wa ni owe na da le lori? Ẹ jẹ ki a gbe yewo ninu akọsilẹ Matiu, ti o ka bayi: 

 

“Owe miiran ni o pa fun wọn, wi pe; ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fun irugbin rere is oko rẹ: Ṣugbọn nigba ti eniyan sun, ọta rẹ wa, o fun epo sinu alikama, o si ba tirẹ lọ. Ṣugbọn nigba ti o hu jade, ti o si so eso, nigba naa ni epo buburu fi ara han pẹlu. Bẹẹ ni awọn ọmọ-ọdọ baalẹ naa tọ ọ wa, wọn wi fun un pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fun sinu oko rẹ? nibo ni o ha ti ri epo buburu? O si wi fun wọn pe, Ọta ni o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ si bi i leere pe, iwọ ha fẹ ki a fa wọn tu kuro? O si wi pe, Bẹẹkọ, nigba ti ẹyin ba n tu epo kuro, ki ẹyin ki o ma baa tu alikama pẹlu wọn. Ẹ jẹ ki awọn mejeeji ki o dagba pọ titi di igba ikore: ni akoko ikore emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tete kọ ko epo jọ, ki ẹ di wọn ni iti lati fi ina sun wọn, ṣugbọn e ko alikama sinu aba mi.” (Matiu 13:24-30)

 

Owe yi, laiṣe aniani, jẹ eyi ti o n tọka si nkan ti awọn ọta le ṣe lati ba iṣe ọwọ eniyan jẹ. A si ri ọpọ oniwaasu ti wọn ma n lo owe na lati yan adura orisirisi fun awọn ọmọ Ọlọrun lati gba. A tilẹ tun ri awọn ti o nlo gẹgẹ bi awawi wọn fun aisun adura alaalẹ. A wa dupẹ lọwọ Jesu Oluwa wa pe O sọ itumọ owe yi ati ọna ti o gba kan wa gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun. Aijẹbẹ, awọn itumọ jakujaku ti ọpọ n fun owe naa ni a ba rọju faramọ.

 

Wayi o, nkan akọkọ ti Jesu fi ye wa bi O ṣe n sọ owe yi ni pe o ni i ṣe pẹlu ijọba ọrun. Eyi jasi pe O n fi owe yi ṣe apejuwe nkan ti o n ṣẹlẹ ninu ijọba ọrun ni. Gbogbo awọn ti O si darukọ ninu owe naa ni wọn duro fun nkankan tabi omiran ninu ijọba yi, gẹgẹ bi O ṣe salaye. O wa ṣe ni laanu pe ọpọ ninu wa lo ma n ro pe ti a ba ti n sọrọ ijọba ọrun, ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu rẹ gbọdọ dara. Ṣugbọn ọrọ bibeli tako eyi patapata. Ọrọ rẹ jẹ ki o ye wa pe ko ki i ṣe gbogbo nkan ti o sorọ wiwọ ijọba ọrun tabi mimura silẹ de e na ni o dara. Idi si ni pe ijọba ọrun kọja nkan ti a n reti; ijọba ọrun wa ni aarin wa, nitoripe Ọlọrun ni o da ohun gbogbo, ti o si tun ni ohun gbogbo. O kan jẹ pe ọpọ wa ko  ki i kọbiara si ni. A ko si kọbiara si nitoripe ijọba Eṣu naa wa ni aarin wa. Amọ ọjọ nbọ ti ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ijọba Eṣu yoo wa si opin, ti o si wa jẹ pe ijọba Ọlọrun nikan ni yo ma fi gbogbo igba farahan si awọn eniyan.

 

Ọna wo wa ni owe yi ṣe ni i ṣe pẹlu ijọba ọrun? Matiu fi eyi han wa ninu akọsilẹ rẹ ti o ka bayi:

 

“Nigba naa ni Jesu ran ijọ eniyan lọ, o si wọ inu ile; awọn ọmọ-ẹyin rọ si tọ ọ wa, wọn wi pe, Sọ idi owe epo ti oko fun wa. O dahun o si wi fun wọn pe ọmọ-eniyan ni ẹni ti n funrugbin rere; Oko ni aye; irugbin rere ni awọn ọmọ ijọba; ṣugbọn epo ni awọn ọmọ ẹni buburu u ni; Ọta ti o fun wọn ni Eṣu; igbẹyin aye ni ikore; awọn angẹli si ni awọn olukore. Nitori naa, gẹgẹ bi a ti ṣe ko epo jọ, ti a si fi ina sun wọn; bẹẹ ni yoo ri ni igbẹyin aye. Ọmọ-eniyan yoo ran awọn angẹli rẹ, wọn o si ko gbogbo ohun ti o mu-ni-kọsẹ ni ijọba rẹ kuro, ati awọn ti o n dẹṣẹ. Yoo si sọ wọn sinu ina ileru: nibẹ ni ẹkun oun ipayinkeke yoo gbe wa. Nigba naa ni awọn olododo yoo ma ran bi oorun ni ijọba Baba wọn. Ẹni ti o ba ni eti ko o gbọ.” (Matiu 13:36-43)

 

Ẹni ti o ba ti ka owe ti Jesu kọkọ sọ ninu ori kẹtala iwe Matiu yi kan na ti o da lori afunrugbin kan ti o funrugbin, yo kiyesi pe itunmọ irugbin ninu owe ti a n gbe yẹwo yi yatọ si itunmọ rẹ ninu owe ti afunrugbin. Irugbin ninu owe afunrugbin tunmọ si ọrọ Ọlọrun. Ṣugbọn itunmọ rẹ yatọ ninu owe eyi. Idi ti mo si fi pe akiyesi wa si eyi ni pe ki a ba le ṣọra lati ma fun awọn afiwe ti o wa ninu ọrọ Ọlọrun ni itunmọ ti ara wa. Ohunkohun ti o ba ni i ṣe pẹlu afiwe, ala tabi iran ninu ọrọ Ọlọrun jẹ eyi ti a gbọdọ fi ara balẹ gbe yẹwo, ki a ma ba fun ni itunmọ ti ara wa, ki a si tipasẹ rẹ kuna.

 

Laifọrọgun, awọn nkan ti Jesu jẹ ki o ye wa ninu owe yi ni iwọnyi: akọkọ, oko ti a funrugbin si ni aye ti a wa ninu rẹ yi. Ekeji, irugbin rere ninu owe na duro fun awọn ọmọ ijọba Ọlọrun, awọn ti a ti tun bi, ti a si ti rapada. Gẹgẹ bi a si ti mọ, inu aye yi na ni wọn si wa; Ọlọrun ko i ti ko wọn kuro ninu rẹ. Eyi ni o wa fun Eṣu laaye lati ma lo arekereke lati gbin awọn ọmọ tirẹ si aarin wọn. Awọn wọnyi ni Jesu sọ pe wọn duro fun epo ninu owe yi, ti Eṣu ti o jẹ baba wọn si duro fun Ọta.

 

Nitorina, a ko gbọdọ jẹ ki o ya wa lẹnu idi ti a fi n ri awọn ika, ọdaran, oniṣekuṣe, wọbia, oṣo, ajẹ ati bẹẹbẹẹlọ ninu ọpọ ijọ Ọlọrun loni. Eṣu ni o ma n fi ọgbọn alumọkọrọyin gbin wọn sinu ijọ. Wọn le jẹ alagba, wooli, alufa, akọrin ati bẹẹbẹẹ lọ. Ṣugbọn awọn wọnyi ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun rara bikoṣe ọmọ Eṣu, ti o gbin si arin wa lati ṣi wa lọna ati lati di awọn ti Ọlọrun fẹ gbala lọwọ lati wọle sinu ijọba rẹ. A si ri awọn ẹsẹ bibeli miran ti o tun fi idi eyi mulẹ fun wa (2Peteru 2; Juudu).

 

Ki wa ni idi ti Ọlọrun ko fi fa awọn wọnyi tu kuro ninu ijọ rẹ ni kiakia, ti O wa fi aye gba wọn lati ma jọsinpọ pẹlu awọn ọmọ rẹ, ki wọn si ma tabuku orukọ rẹ? Gẹgẹ bi a ti ri ninu owe yi, idi ti Ọlọrun ko fi ṣe eyi ni pe ko fẹ ki awọn ọmọ rẹ jiya ẹṣẹ awọn ika eniyan yi. Ọlọrun mọ pe o ṣe e ṣe ti Oun ba n ṣe idajọ awọn eniyan yi, ki awọn ọmọ rẹ kọkan na fi ara gba ninu rẹ, paapaajulọ awọn ti oye ko ye. Nitorina, ninu ọgbọn rẹ, Oun a fi wọn silẹ titi di akoko ikore.

 

Igba wo wa ni akoko ikore? Igbẹyin aye ni akoko ikore, gẹgẹ bi alaye Jesu Oluwa wa. Awọn wo si ni olukore? Awọn angẹli mimọ Ọlọrun ni olukore. Awọn wọnyi ni yo la aye yi kọja lati ya awọn ọmọ Eṣu sọtọ kuro laarin awọn ọmọ Ọlọrun, ki wọn ba le gba ijiya ti o tọ, lalai koba ẹnikẹni. Ki wa ni idi ti Ọlọrun ṣe ṣetan lati mu suuru, ki O si fi ara da iwọsi ati ẹgbin orisirisi ninu ijọ awọn eniyan rẹ di akoko ikore? Idi ni pe ni akoko ikore, ko si ẹni ti yoo ṣi epo mu si irugbin rere tabi irugbin rere si epo, nitoripe eso ti wọn yo so yo yatọ si ara wọn. Eyi wa ja si pe akoko na n bọ ti o jẹ pe gbogbo awọn oniṣẹ ẹṣẹ ti o wa ninu ijọ Ọlọrun ni yoo farahan gẹgẹ bi oniṣẹ ẹṣẹ nipaṣẹ eso wọn, gẹgg bi ọrọ Jesu (Matiu 7:15-20). Awọn wọnyi ko ni fi ara pamọ wuwa ika tabi ṣe iṣekuṣe mọ. Gbangbagbangba bayi ni wọn yo ma fi ara wọn han gẹgẹ bi Kirisitiẹni eke.

 

Njẹ a ko wa ma ri eyi ninu aye loni bi? A n ri i! A ti n ri awọn ijọ ti o n ṣe igbeyawo fun ọkunrin ati ọkunrin ati fun awọn obinrin ati obinrin. A si tun ri awọn ijọ ti o fi aye gba orisirisi iṣẹ ẹṣẹ. Yatọ si eyi, a ti n ri ọpọ ti o gbagbọ tẹlẹ ti wọn ti n kọ ẹyin si Jesu, ti wọn si n darapọ mọ awọn ti aye yi ti ko gba Ọlọrun gbọ tabi ti wọn n darapọ mọ awọn ẹlẹsin miran ni gbangba. Eyi si fi n ye wa pe, igbẹyin aye ti n kan ilẹkun, awọn angẹli Ọlọrun si ti n ṣiṣẹ lati gba gbogbo awọn epo inu ijọ Ọlọrun pọ si ọna kanna. A wa ni a wa nilo lati duro ṣinṣin ninu otitọ Jesu Kirisiti ti a ti gba gbọ, ki a ma ba gba wa ṣubu (Roomu 16:17-18). Si ranti pe, Pọọlu apostile sọ eyi fun wa: “Ṣugbọn ipilẹ Ọlọrun ti o daju duro ṣinṣin, o ni edidi yii wi pe, Oluwa mọ awọn ti i ṣe tirẹ. Ati pẹlu, ki olukuluku ẹni ti n ṣe ti Oluwa ki o kuro ninu aisododo.” (2Timoti 2:19)

 

ỌRỌ IPARI

A ko le ṣe alai ma ri awọn oniṣẹ ẹṣẹ ninu ijọ Ọlọrun, nitoripe Eṣu ni o n gbin wọn si aarin wa. Ko wa si ninu ipinu Ọlọrun lati fa wọn tu siwaju akoko ti O ti da fun ikore aye. Nitorina, a ni lo lati kiyesara, ki a si ma gba ọmọ Eṣu kankan laye (iba a jẹ wooli, alufa, ajinhirere ati bẹẹbẹẹlọ) lati fi idibajẹ sinu aye wa, di iṣẹ iranṣẹ wa lọwọ tabi sọ wa di ẹni ikuna. Adura mi ni pe aanu Jesu Kirisiti Oluwa wa ko ni fi wa silẹ. Amin.

 

IBEERE

–     Njẹ ẹkọ yi wa ni ibamu pẹlu iriri rẹ gẹgẹ bi ọmọ Ọlọrun bi?

–     Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ na?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

 

 

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 10, ERELE 2021

 

AKỌRI: KI NI BIBELI SỌ — ỌṢỌ ARA ṢIṢE FUN OBINRIN?                     AYỌKA: 1TIMOTI 2:9-10

 

AKỌSORI: “O si dahun, o wi fun wọn pe, Igikigi ti Baba mi ti n bẹ ni ọrun ko ba gbin, a o fa tu kuro.” (Matiu 15:13)

 

ỌRỌ ISAAJU

Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe kayefi rara ni ki awọn eniyan ṣi ọrọ Ọlọrun tunmọ tabi ki wọn ṣi i lo. Ṣugbọn niwọn igba ti a ba ti ṣi ọrọ rẹ tunmọ tabi ṣi i lo, ko si bi ọrọ na ṣe le mu ifẹ rẹ ṣe ninu tabi lori aye wa. Idi si ni yi ti o fi jẹ pe ẹnikẹni ti o ba n gbọ ọrọ Ọlọrun tabi ka ọrọ rẹ gbọdọ lepa lati ri pe itunmọ ti o peye, ti o si ye kooro ni o fun. Aijẹbẹ, Eṣu, ẹlẹtan ni, yoo ṣi ni ọna, yoo si ri pe ọrọ Ọlọrun ti o gbọ tabi ti o ka ko ṣe ni anfaani kankan tabi ki o tilẹ ko sinu iyọnu. Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi akọsilẹ bibeli lori ọkan lara awọn idanwo ti Eṣu fun Jesu Oluwa wa, a ri pe o yan ẹṣẹ bibeli kan fun lati ti i lati bẹ silẹ lati ibi sonso tẹmpili. Ti ko ba wa jẹ pe itunmọ ọrọ Ọlọrun ye Jesu daradara ni, nṣe ni ko ba tẹle imọran Esu lati bẹ silẹ, ko ba si ṣẹ si Ọlọrun, ki o si gba ibẹ ku. (Wo: Matiu 4:5-7; Luuku 4:9-12)

 

Nitorina, ewu pupọ lo sorọ mọ ṣiṣi ọrọ Ọlọrun tunmọ tabi ṣiṣi ọrọ rẹ lo. Eyi si ni idi ti ẹnikọọkan lara awa ti a pe ara wa ni ọmọ rẹ gbọdọ ma fi gbogbo igba lepa lati mọ ọrọ rẹ lori ohun gbogbo daju, nipaṣẹ iranlọwọ Ẹmi Mimọ ati nipa fifi ara balẹ ṣe agbeyẹwo ọrọ rẹ funra wa. Aijẹbẹ, ko si igba ti Eṣu ko ni i ṣi wa lọna, ja wa lole ibukun Ọlọrun tabi ko wa sinu wahala ti ko yẹ ki o jẹ tiwa rara.

 

ỌṢỌ ARA ṢIṢE FUN OBINRIN?

A wa fẹ bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo nkan ti bibeli ṣọ lori awọn nkankan ti o ṣaba ma n fa ariyanjiyan laarin awọn ọmọ Ọlọrun, ti o si ma n jẹ ki a rin lodi si ifẹ Ọlọrun ninu ibaṣepọ wa. Ọkan lara wọn si ni ọsọ ara ṣiṣe, paapaa julọ laarin awọn obinrin. Ṣe o tilẹ tọna ki obirin onigbagbọ ma ṣe ọṣọ ara rẹ, yala pẹlu awọn nkan bi yẹti eti, yẹti imu, ẹgba ọrun, ẹgba ẹṣẹ, irun didi ati bẹẹbẹẹlọ, tabi ko tọna? A ti ri oriṣiṣi ẹkọ ti a mu ninu bibeli lori eyi. Eyi ti o si da bi ẹni pe o wọpọ julọ ni ti awọn ti o sọ pe ko tọna rara ati pe irufẹ awọn ti o ba n ṣe eleyi yo lọ si ọrun apadi. Idi si ni yi ti a fi ri awọn Kirisitiẹni ti o ma n fi oju buruku wo obinrinkobirin ti wọn ba ri ti o ṣe ọṣọ ara rẹ, ti wọn a si ma da wọn lẹbi gẹgẹ bi ẹni ti Ọlọrun ti kọ silẹ.

 

Ṣugbọn ṣe nkan ti ọrọ Ọlọrun kọ wa ni eyi? Ti o ba jẹ nkan ti o kọ wa ni, o di dandan fun wa lati ma fi gbogbo igba fi idi rẹ mulẹ ninu aye wa ati laarin wa, ki a si ma pe akiyesi awọn ti ko ba rin ni ibamu pẹlu rẹ si loorekoore. Amọ ti ko ba si wa n ṣe nkan ti ọrọ rẹ kọ wa ni eyi, nṣe ni a gbọdọ fa irufẹ aṣitunmọ ọrọ rẹ yi tu kuro ni aye wa ati ni aarin wa. Bi a ṣe ri ninu ẹṣẹ bibeli ti a lo fun akọsori wa, Jesu Oluwa wa sọ pe igikigi ti Ọlọrun Baba wa ko ba ti gbin, a gbọdọ faa tu ti gbongbo ti gbongbo ni. Nkan ti O si n sọrọ le lori ninu ẹṣẹ bibeli yi ni awọn ẹkọ adabọwọ awọn eniyan, ti o lodi si ifẹ Ọlọrun, ti a si ti gbe ga ju ọrọ Ọlọrun lọ.

 

Njẹ ki wa ni bibeli sọ lori ẹṣọ ara ṣiṣe, paapaa julọ si awọn obinrin onigbagbọ? Awọn ẹṣẹ yi tọka si nkan ti o sọ:

 

“Bẹẹ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o maa fi aṣọ iwọntunwọnsi ṣe ara wọn ni ọṣọ, pẹlu itiju ati iwa airekọja; kii ṣe pẹlu irun didi ati wura, tabi Piali, tabi aṣọ olowo iyebiye, Bi ko ṣe nipa iṣẹ rere (eyi ti o yẹ fun awọn obinrin ti o jẹ olufọkansin Ọlọrun). (1Timoti 2:8-10)

 

“Ki ọsọ yin ma ṣe je ti ode, ti irun didi, ati ti wura lilo tabi ti aṣọ wiwọ, Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹda naa ti o farasin, ni ọkan yin, pẹlu ọṣọ aidibajẹ ti ẹmi irẹlẹ ati ẹmi tutu, eyi ti o ṣe iyebiye ju niwaju Ọlọrun.” (1Peteru 3:1-4)

 

Ki ni awọn aridimu inu awọn ẹsẹ bibeli yi? Akọkọ ni pe ọsọ ṣise wa gbọdọ jẹ IWỌNTUNWỌNSI. Eyi tunmọ si pe a ko gbọdọ ṣe ọsọ ti yo jẹ ki awọn eniyan ma so pe, “Ha ha ha, eyi o wa pọju?” A si ri pe eyi wọpọ pupọ laarin awọn obinrin wa loni, ati awọn ti o wa ninu ijọ ati awọn ti ko ki i ṣe Kirisitiẹni. Ọpọ igba ni wọn ma n fi aṣeju bọ imura wọn. Ti wọn ba kun oju, wọn o kun lakunju. Ti wọn ba si lo nkan ọṣọ na, o di dandan ki wọn lo wọn ni aloju debi pe eniyan o fẹ le ṣi elomiran mu si egun. A tun ri pe awọn miran le lo gbogbo akoko ti o yẹ ki wọn fi ṣe ojuṣe wọn ninu ile tabi ni ẹnu iṣẹ lati ṣe ọṣọ ara wọn. Aṣeju ni eyi. Ọrọ Ọlọrun si lodi si.

 

Nkan ekeji ti awọn ẹsẹ bibeli yi fi ye wa ni pe ỌṢỌ WA GBỌDỌ KỌJA TI ARA. Eyi tunmọ si pe a gbọdọ kọbiara si ẹwa ọkan wa ju ẹwa ti ara lọ. Idi si ni pe ẹwa ti ọkan ni o ṣe iyebiye si Ọlọrun julọ. Nitorina ni awọn apositeli Pọọlu ati Peteru ṣe sọ fun wa pe ki a ma jẹ ki ọṣọ wa jẹ ti irun didi tabi ti wura lilo tabi ti aṣọ olowo iyebiye wiwọ, ṣugbọn ki o jẹ ọṣọ ẹmi irẹlẹ, iwa tutu ati iṣẹ rere. Nkan ti eyi n ṣọ fun wa ni pe a ko gbọdọ tọka si wa bi arẹwa nitori bi oju wa ṣe gun rege si tabi nitori ẹṣọ ara wa. Dipo eyi, nṣe ni ki a tọka si wa gẹgẹ bi arẹwa nitori pe a kun fun irẹlẹ, iwa pẹlẹ, iwa tutu ati iṣẹ rere.

 

Njẹ eyi wa jasi pe awọn obinrin wa ko gbọdọ dirun rara, lo ẹṣọ wura tabi fadaka tabi wọ aṣọ olowo nla? Rara o! O wa bani ninujẹ pe bi ọpọ awọn oniwaasu wa ṣe tunmọ awọn ọrọ awọn apositeli yi ni eyi. Idi si ni yi ti wọn fi ma n gbogun ti awọn ti o ba n lo ẹṣọ wura tabi fadaka si eti, ọwọ, imu tabi ẹsẹ wọn. Ọpọ igba ni wọn si tun ma n fi ojusaaju tabi agabagebe bọ, ti wọn a ma da awọn ti o lo yẹti eti lẹbi, ti wọn ko si ni da awọn ti o di irun tabi lo aṣọ olowo iyebiye lẹbi. Amọ, gẹgẹ bi nkan ti a ri ninu awọn ẹṣẹ bibeli yi, ti o ba jẹ pe Ọlọrun lodi si lilo ẹsọ wura tabi fadaka tabi ṣiṣe irun wa lọsọ, o tunmọ si pe o lodi si didi irun tabi wiwọ aṣọ tabi bata olowo nla na niyẹn. Ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun ti ko si lo yẹti eti tabi ẹgba ọrun ni o ma n di irun, ko irun tabi wọ bata tabi aṣọ olowo nla.

 

Lai ṣe aroye asan, Ọlọrun ko fi igba kankan sọ ninu ọrọ rẹ pe ki awọn eniyan rẹ ma ṣe ọṣọ ara wọn tabi lo ẹṣọ tabi pe awọn ti o ba ṣe bẹ yoo lọ si ọrun apadi. Adabọwọ awọn eniyan ni eyi. Bawo wa ni ti igba ti Ọlọrun sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli pe ki wọn ki o bọ awọn nkan ọṣọ ara wọn kuro, ki Oun ma ba pa wọn run? Njẹ eyi ko ha tunmọ si pe ko fẹ ki a ma lo ẹṣọ ara bi? Rara, ko ri bẹ. (Wo: Ekisodu 33:4-6)

 

Lakọkọ, Ọlọrun funrarẹ ni o pa a laṣẹ fun awọn ọmọ Isiraẹli yi lati gba awọn nkan ẹṣọ yi lọwọ awọn ara Ijibiti nigba ti O n mu wa jade kuro nibẹ. (Wo: Ekisodu 3:22 & 12:35-36) Ti o ba wa jẹ pe ko fẹ ki wọn lo awọn ẹṣọ yi, ki ni idi ti o ṣe ni ki wọn gba wọn? Lafikun, bi a ṣe ri ka ninu bibeli, akoko kan wa ti Ọlọrun funrarẹ ni ki awọn ọmọ Isiraẹli yi mu ọrẹ wura, fadaka, idẹ ati bẹẹbẹẹ lọ wa fun Oun (Ekisodu 25:1-8). Ti Ọlọrun ba tako nini tabi lilo awọn nkan yi, ṣe yo tọna fun un lati sọ fun awọn eniyan yi lati mu wa fun gẹgẹ bi ọrẹ? 

 

Yatọ si eyi, ninu iwe Isikiẹli, nigbati ti Ọlọrun n ṣe afiwe bi O ṣe ṣe awọn ọmọ Isiraẹli lọṣọ, O sọ wipe Oun lo ohun ẹṣọ wura ati fadaka, aṣọ olowo iyebiye ati ororo oloorun didun ṣe wọn lọsọ (Isikiẹli 16:8-13). Niwọn igba ti eyi si ribẹ, yeke ni o yẹ ki o ye wa pe Ọlọrun ko lodi si lilo ohun ẹṣọ lati fi ẹwa wa han. Idi ti O si fi ni ki awọn ọmọ Iṣiraẹli yi bọ awọn nkan ẹṣọ wọn nigba ti wọn wa ninu aginju ni pe awọn nkan ẹṣọ yi ni wọn lo lati fi mọ ere wura fun ara wọn lati bọ. O tunmọ si pe bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun ko lodi si ki a ni tabi lo awọn nkan wura, fadaka tabi idẹ fun ọṣọ ara wa, ko fẹ ki a sọ awọn nkan wọnyi di oriṣa ti a o ma bọ. Ko ki i wa ṣe nkan ọṣọ nikan ni o le di oriṣa fun wa lati bọ. Nkankinkan ti a ba ni, ti a ba si gba laaye lati gba aye Ọlọrun ninu aye wa ti di oriṣa fun wa. Eyi si le jẹ tẹlifiṣọn, ẹrọ ibanisọrọ, iṣẹ wa, aya wa, ọkọ wa, awọn ọmọ wa, awọn obi wa ati bẹẹbẹẹ lọ.

 

ỌRỌ IPARI

Ni akotan, a gbọdọ jẹ ki o ye wa yekeyeke pe Ọlọrun ko lodi si ọṣọ ara ṣiṣe. Ṣugbọn O fẹ ki a ma ṣe ohun gbogbo ni iwọntunwọnsi, ki a si ma fi aye silẹ fun ẹnikẹni lati tabuku imura wa, boya nitori pe a ko bo ihoho wa daradara tabi nitoripe a lo ohun ti o le ti awọn miran wọ inu ifẹkufẹ tabi iṣekuṣe tabi nitoripe a lo awọn nkan ti o le jẹ ki awọn eniyan ṣi wa mu si awọn oniranu awujọ tabi nitoripe a n fi aye gba ọṣọ ara wa ṣiṣe lati di ojuṣe wa si Ọlọrun tabi si eniyan lọwọ. Yatọ si eyi, Ọlọrun ko fẹ ki a mu ọṣọ ara wa ṣiṣe ni pataki ju ọṣọ ọkan wa lọ. Nitoripe ko si bi a ṣe le rewa loju to, ti iwa wa ko ba wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ẹwa ofo, ọṣọ ofo ni a n ṣe. 

 

IBEERE

–     Ki ni iwọ ro pe o fa ti ọpọ awọn ọmọ Ọlọrun fi ma n da awọn ti o n lo ọṣọ ara lẹbi?

–     Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

 

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

 

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 06, SẸRẸ 2020

AKỌRI: ADURA – AWỌN NKAN TI ADURA KO LE RỌPO AYỌKA: AISAYA 1:15-17

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Bi a ti ṣe fi idi rẹ mulẹ latẹyinwa, adura gbigba ṣe pataki pupọ ninu aye ọmọ eniyan. Nitorina, a ko gbọdọ fi ọwọ yẹnpẹrẹ mu. Dipo eyi, nṣe ni o yẹ ki a ma gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ, gẹgẹ bi ọrọ iwe mimọ. Amọ ṣa o, o tun wa yẹ ki o ye wa na pe awọn nkankan wa ti a ko le fi adura gbigba rọpo ninu aye wa. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki a ma fi ọpọ igba gbadura asan tabi adura agbadanu. Idi si ni yi ti ẹkọ ti a n kọ lori adura gbigba ti ọtẹ yi yo da lori awọn nkan na ti a ko gbọdọ gbiyanju ati fi adura gbigba rọpo niwaju Ọlọrun, ti a ko ba fẹ ki adura wa ni idena.

AWỌN NKAN TI ADURA KO LE RỌPO
Ki wa ni awọn nkan na ti adura gbigba ko le rọpo ninu aye wa? Akọkọ, adura gbigba ko le rọpo gbigbe igbe aye ododo. Jemisi, ninu lẹta rẹ si ijọ, sọ eyi: “…Iṣẹ ti adura olododo n ṣe ni agbara pupọ.” (Jemisi 5:16) Adura ta ni Jemisi sọ pe o n ṣiṣẹ agbara pupọ? Adura olododo! Eyi tunmọ si pe irufẹ eniyan ti o n gbadura si Ọlọrun ṣe pataki pupọ si. Lotitọ, bibeli fi ye wa pe ko si ẹnikẹni ti o ba ke pe e, ti a ko ni dalohun, ki a si gba a la (Roomu 10:12-13). Ṣugbọn bibeli kan na tun fi ye wa pe awọn asiko kan wa to jẹ pe Ọlọrun le ma da eniyan lohun adura rẹ, niwọn igba ti oun na ko ka ọrọ tabi ifẹ rẹ si.

Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun sọ eleyi fun awọn eniyan rẹ lati ẹnu woli Aisaya: “Nigba ti ẹyin si na ọwọ yin jade, emi oo pa oju mi mọ fun yin: nitootọ, nigba ti ẹyin ba gba adura pupọ, emi ki yoo gbọ: ọwọ yin kun fun ẹjẹ. Ẹ wẹ, ki ẹ mọ; mu iṣẹ buburu yin kuro niwaju oju mi: dawọ duro lati ṣe buburu; Kọ lati ṣe rere; wa idajọ, ran awọn ẹni ti a nilara lọwọ, ṣe idajọ alainibaba, gba ẹjọ opo wi.” (Aisaya 1:15-17) Ki ni idi ti Ọlọrun fi sọ ninu ẹsẹ bibeli yi pe Oun yoo pa oju Oun mọ fun awọn eniyan rẹ ti o n gbadura si? Titori aiṣododo wọn ni. O tilẹ tun sọ pe bi o ti wu ki adura wọn pọ jọjọ to, Oun ko ni da wọn lohun.

Nitorina, ọpọ ọrọ ko kun agbọn ni ọrọ ẹni ti o ba n gbe ninu aiṣododo, ti o si tun n gbadura pupọ si Ọlọrun. Ọlọrun ko ni da lohun. O wa ṣeni laanu pe a ri ọpọ awa ti a pe ara wa ni ọmọ Ọlọrun ti o jẹ pe igbe aye wa ko wa ni ibamu pẹlu ododo rẹ ni ọna pupọ. A n parọ. A n ṣe agbere. A n gba riba. A n lọnilọwọgba. A n yi iwe. A n rẹ ọmọnikeji wa jẹ. A si tun n lo oriṣiriṣi osuwọn ti ko peye lati ta ọja wa. Ṣibẹsibẹ, a ko ki i ṣe alaiwa ni ọpọlọpọ ipejọpọ adura fun itẹsiwaju, igbega tabi igbooro si aye wa. Bawo ni Ọlọrun ṣe fẹ gbọ ti wa?

Njẹ o tilẹ mọ pe awọn igara ọlọṣa, awọn ajinigbe, awọn agbenipa, ati awọn ti o fi eniyan ṣe ogun owo miran gan ma n lọ si ipade adura ati awọn ori oke adura kan tabi omiran lati gbadura? Ṣe adura wa jẹ ọna lati tu Ọlọrun loju ni tabi ọna lati jẹ ki O fi oju fo awọn aiṣedeede wa? Eyi ko ribẹ rara. Ti o ba ni awọn iwa tabi iṣe wa ti ko ba ifẹ rẹ mu, a nilo lati kọ wọn silẹ, ki a ṣi ṣe atunṣe lori wọn, ti a ba fẹ ki O ma tẹti si adura wa. Iwọ na wo ohun ti O sọ fun awọn eniyan rẹ ninu ẹṣẹ bibeli ti o wa loke yẹn lẹẹkansi. O sọ fun wọn pe ki wọn wẹ ara wọn mọ kuro ninu eeri wọn, ki wọn si bẹrẹ si ni wu iwa ododo. Aijẹbẹ, ko ni dahun adura wọn bi o ti wu ki o pọ to.

Wayi o, nkan kanna ni O si n ba awa na sọ loni. O fẹ ki a wẹ ara wa mọ kuro ninu awọn iwa ika ati iwa eri wa, ki O ba le ma fi gbogbo igba gbọ adura wa. Ki a ma wa ri ẹni ti yo sọ pe, “Mo mọ tẹlẹ pe ẹlẹṣẹ ni mi. Ṣugbọn bi o ti wu ki n dẹṣẹ to, Ọlọrun ko ki i fi igba kankan ma dahun adura mi.” Iru ẹni ti o ba n sọ eleyi ko ni oye iwuwasi Ọlọrun rara. Ọlọrun ko ki i tọju wa nitori bi a ṣe gbadura to; dipo eyi, O ma n tọju ni ibamu pẹlu ifẹ, aanu ati oju rere rẹ si wa ni. Nitorina, ọpọ awọn nkan ti a n jẹgbadun lati ọwọ rẹ ko fi taratara ni i ṣẹ pẹlu bi adura wa ṣe muna doko si tabi bi a ṣe n rin ninu ododo si. Amọ ti a ba wa bẹrẹ si ni gan aanu ati ifẹ rẹ si wa, ti a si n ṣe ohun ti o wu wa nitoripe a woye pe a si n gbadun didara Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ pe inu ẹṣẹ ni a ngbe, ti o ba di akoko kan, Ọlọrun yo jẹ ki o ye wa pe a ko le ma gbe ninu ẹṣẹ, ki a si ma ri pipọsi oore-ọfẹ rẹ (Roomu 6:1).

Fun apẹẹrẹ, nigbati Akani dẹṣẹ si Ọlọrun, ti o ji awọn nkan iparun fun lilo ara rẹ, orilẹ-ede Isiraẹli ṣubu niwaju awọn ọta wọn. Eyi si mu ki Joṣua ṣọkun, barajẹ ati gbadura si Ọlọrun. Ṣugbọn nibi ti o dubulẹ si na ni Ọlọrun ti sọ fun pe ki o dide, ko si ṣe atunṣe, nitoripe Oun ko ni wa pẹlu wọn tabi gbọ adura wọn titi wọn yo fi ṣe idajọ ẹṣẹ ti o wa ni arin wọn. (Wo: Joṣua 7) Nitorina, wipe Ọlọrun ko i ti bẹrẹ si ni kọ eti ikun si adura wa ni akoko yi ko tunmọ si pe bẹ ni yo ṣe ri titi lailai. Ti a ba kọ jalẹ lati duro sinu ododo rẹ, akoko n bọ ti adura wa ko ni ja mọ nkankan loju rẹ mọ. Boya a tilẹ ti wa ni akoko yi, ti a ko si mọ.

Nkan keji ti adura gbigba ko le rọpo ni ṣiṣẹ pẹlu ijafafa. Ọpọ loni ni o n gbadura fun itẹsiwaju, igbega, igbooro si ati bẹẹbẹẹlọ. Ṣugbọn agbeyẹwo iṣẹ wọn fi han pe wọn ko koju oṣuwọn fun igbega tabi ilọsiwaju ti wọn n bere fun. Mo n sọrọ nipa awọn ti o n ṣe imẹlẹ lẹnu iṣẹ, awọn isansa lẹnu iṣẹ, awọn ti ko jẹ olotitọ pẹlu iṣẹ wọn ati awọn ti ko ki i fi ọpọlọ pipe ati ifarabalẹ ṣe iṣẹ ti wọn ba gbe fun wọn. Ko si bi awọn wọnyi ṣe le gbadura fun igbega to, ti Ọlọrun le gbọ. Ti Ọlọrun ba wa tilẹ gbe wọn ga, ko ni i jẹ nitori adura wọn rara; o wa le jẹ nitori pe o fẹ lo wọn lati ṣe aanu fun awọn miran ni.

Bibeli salaye yekeyeke iha ti o yẹ ki a kọ si iṣẹ wa, yala iṣẹ ti a n ṣe labẹ ile isẹ kan ni tabi iṣe adani. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ eyi fun wa: “Ẹyin ọmọ-ọdọ, ẹ maa gbọ ti awọn ọga yin nipa ti ara ni ohun gbogbo; ki I ṣe ni arojuṣe, bi awọn alaṣewu eniyan; ṣugbọn ni otitọ inu, ni ibẹru Ọlọrun: ohunkohun ti ẹyin ba n ṣe, ẹ maa fi tọkantọkan ṣe e, gẹgẹ bi fun Oluwa, kii si i ṣe fun eniyan. Ki ẹ mọ pe, Oluwa ni yoo san ẹsan fun yin: nitori ẹyin n sin Kirisiti Oluwa. Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ṣe aiṣododo, yoo gba ere aiṣododo rẹ pada: nitori kii ṣe ojuṣaaju.” (Kolose 3:22-25) Ṣe iwọ na ri bayi? Jesu Oluwa wa n wo ẹnikọọkan wa lati wo bi a ṣe n ṣe iṣẹ wa pẹlu ijafaafa, otitọ ati ori pipe si, ki O ba le pin wa lere ninu aye yi ati ni ọjọ idajọ. Eyi tunmọ si pe ko ki i ṣe awọn ti o gba wa ṣiṣẹ tabi ti o gbe isẹ fun wa tabi ti o n ra nkan lọwọ wa nikan ni yoo pin wa lere iṣẹ wa; Ọlọrun funrarẹ na yoo pin wa lere. Ko si wa si ojusaaju pẹlu rẹ, bi Pọọlu ṣe sọ fun wa.

Nitori eyi, ti a ba n ṣe imẹlẹ lẹnu iṣẹ tabi ti a ṣiṣẹ aparutu, ti a wa n gbadura pe ki Ọlọrun gbe wa ga tabi sọ iṣẹ wa di gbooro, a kan n tan ara wa jẹ ni. Ko si ojusaaju pẹlu rẹ. Idi si ni yi ti ko fi ni titori pe a jẹ ọmọ rẹ tabi tori pe a n fi gbogbo igba gbadura ati aawẹ lori oke ati ni pẹtẹlẹ fun wa ni nkan tabi ipo ti ko tọ si wa tabi ipo ti o tọ si awọn ti o ja fafa lẹnu iṣẹ wọn. Nitorina, bi o ba ṣe n gbadura fun igbega tabi isọdigbooro, ri pe oun ṣiṣẹ tọ ọ pẹlu; ri pe ti Ọlọrun ba bẹ iṣẹ rẹ wo, yi o le gboriyin fun ọ, ki O si tun fa ọ lọwọ soke.

Nkan kẹta ti a ko le fi adura gbigba rọpo ni iṣọra. Jesu sọ pe, “Maa ṣọna, ki ẹ si maa gbadura, ki ẹyin ki o ma baa bọ sinu idẹwo…” (Matiu 26:41) Pọọlu na si tun sọ pe, “Ẹ maa duro ṣinṣin ninu adura gbigba, ki ẹ si maa ṣora ninu rẹ pẹlu idupẹ.” (Kolose 4:2) Eyi tunmọ si pe adura gbigba yatọ si iṣona tabi iṣọra, iṣọra naa si yatọ si adura gbigba. Amọ ṣa o, awọn nkan mejeji yi ma n ṣiṣẹ pọ fun rere ẹnikẹni ti o ba n ṣe wọn ni. Ṣugbọn ọpọ ni eyi ko ye. Lotitọ wọn n gbadura, wọn si n ṣe afẹri Ọlọrun. Amọ wọn ko mu iṣọra ni ọkunkundun. Nitorina, wọn ko ki ṣe alaibọsinu panpẹ Eṣu. Ti awa na ko ba si fẹ ma fi gbogbo igba bọ sinu panpẹ Eṣu, a gbọdọ kọ bi a ṣe n ṣọra tabi mọ iwọn ara ẹni.

Wo Joṣẹfu, fun apẹẹrẹ. O mọ nkan ti o tunmọ si pe ki eniyan ma ṣọ ara rẹ. Nigba ti o ti ri bi iyawo Potifa, ọga rẹ ṣe n ṣe si, ni o ti kọ ara rẹ lati jinna si. Ọjọ ti o si wa dabi ẹni pe o fẹ bọ sinu panpẹ obinrin yi, nṣe ni o fere ge. Ko ba ṣe aroye kankan; ko si duro sibẹ ma bẹ Ọlọrun pe ki o ko oun yọ. Nṣe ni o salọ patapata. Eyi si wa ni ibamu pẹlu ọrọ bibeli ti o sọ pe, “Ẹ maa sa fun agbere.” (Wo: Jẹnẹsisi 39:7-12; 1Korinnti 6:18) Nkan ikẹdun ni o wa jẹ pe ọpọ ọmọ Ọlọrun ni o ti bọ sinu ẹṣẹ agbere nitori aikiyesara. Iwọ ti o ko fẹ ko sinu ẹṣẹ agbere, amọ ti o n fi gbogbo igba wa pẹlu awọn obinrin tabi awọn ọkunrin ni akoko ti ko wọ, bawo ni o o ṣe ni bọ sinu rẹ? Tabi iwọ ti o ko fẹ yiwe lẹnu iṣẹ, amọ ti o jẹ pe awọn ọrẹ alaiwabiọlọrun ni o n ko kaakiri, bawọ ni wọn ko ṣe ni ti ọ lati ṣe nkan ti ko tọ lọjọkan? Tabi iwọ ti o ko fẹ bọ sinu ijamba ọkọ, amọ ti o n fi gbogbo igba sare asapajude, bawo ni Eṣu ko ṣe ni lo ere sisa rẹ lodi si o lọjọkan?

Jesu Oluwa wa gan mọn iwọn ara rẹ. O mọ itunmọ ki a ṣọra pẹlu, ki a si ma ma gbadura nikan. Idi niyi ti ko ṣe bẹ silẹ lati ibi ti o ga julọ lori tẹmipili nigbati Eṣu dan wo lati ṣe bẹ. Dipo eyi, O sọ fun pe a ti kọ iwe rẹ pe a ko gbọdọ dan Oluwa Ọlọrun wa wo. (Wo: Matiu 4:5-7) Ṣugbọn ọpọ wa ni a ma n dan Ọlọrun wo nipaṣẹ aikiyesara tabi aimọwọnaraẹni. Niwọn igba ti a ba si kọ lati kiyesara tabi mọn iwọn ara wa, ko si bi a ṣe le gbadura to ti a ko si ni ma ko sinu panpẹ Eṣu.

ỌRỌ IPARI
Ni akotan, nkan ti mo n gbiyanju lati jẹ ki o ye wa na ni pe adura ni aye tirẹ, iwa ododo, ṣiṣiṣẹ pẹlu ijafafa ati ikiyesara naa ni aye ti wọn. A ko gbọdọ fi adura dipo awọn nkan wọnyi, bi a ko ṣe gbọdọ fi awọn nkan yi rọpo adura ninu aye wa. Aijẹbẹ, ọpọ igba ni adura wa ko ni jẹ didahun, eyi ti o si le yọri si pe ki a jẹ iyan wa ni iṣu.

IBEERE
– Bawo ni ẹkọ yi ṣe wulo laarin awọn ọmọ Ọlọrun si?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com

alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

November 2020

ADURA – NJẸ ADURA LE NI IDENA? (AYỌKA: AISAYA 59:1-2)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 18, BELU 2020

AKỌRI: ADURA – NJẸ ADURA LE NI IDENA?

AYỌKA: AISAYA 59:1-2

CLICK HERE TO DOWNLOAD FILE

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ara awọn nkan ti ọpọ fẹ ma n mọ lori adura gbigba ni boya o ṣeeṣe tabi ko ṣeeṣe ki adura wa ni idena? Ti o ba ṣeeṣe, ọna wa ni o gba ṣeeṣe ati pe ki ni a le ṣe lati ri pe adura ti a ba gba si Ọlọrun ko ni idena? Lotitọ, bibeli fi idi rẹ mulẹ pe o ṣeeṣe ki adura ti eniyan ba gba ni idena. Ṣugbọn ọpọ igba ni o jẹ pe awọn nkan ti a ma n ro pe o n dena adura wa gan kọ ni o n dena wọn. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn ti wọn gba pe Eṣu, awọn ẹmi aimọ, awọn ajẹ tabi awọn oṣo lagbara lati ma jẹ ki adura wọn goke tọ Ọlọrun lọ, debi pe yo tilẹ dahun. Irufẹ awọn awọnyi ni wọn ma n sọrọ lori bi awọn ẹyẹ ajẹ ṣe n ṣa adura jẹ. Njẹ ṣe otitọ wa ni pe awọn kan le ṣa adura jẹ? Irọ gba a ni eyi jẹ. Ko si ẹnikẹni ti o le ṣa adura ẹnikẹni jẹ. Ko si si ẹnikẹni ti o le di Ọlọrun lọwọ lati gbọ tabi dahun adura wa. Bi bibeli ṣe fi idi rẹ mulẹ, awa nikan na ni o le dena adura ara wa. Idi si ni yi ti o fi yẹ ki a ma kọ ẹkọ ninu bibeli ki a ba le mọ awọn nkan na ti a le ṣe ti yo si yọri si idena fun adura wa.

NJẸ ADURA LE NI IDENA?
Bi mo ṣe sọ siwaju, ko si ẹnikẹni tabi ẹdakẹda ti o le ṣa adura wa jẹ tabi di adura wa lọwọ lati de eti Ọlọrun. Ki ni a n fi Ọlọrun pe gan? Ọlọrun jẹ Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo, gẹgẹ bi awọn ẹkọ ti a kọ sẹyin lori adura gbigba ṣe fi han. Ko si di igba ti a ba to gbadura si ki o to mọ ero ọkan wa tabi aini wa. Idi si ni yi ti Jesu ṣe kọ wa pe ki a ma ma ṣe atunwi asan ti a ba n gbadura tabi ki a ma ṣe aniyan lori ọrọ aye wa, nitoripe Ọlọrun Baba wa mọ ohun ti a ṣe alaini rẹ ki a to beere lọwọ rẹ (Matiu 6:7-8 & 31-32).

Yatọ si eyi, Ọlọrun funrarẹ gan sọ fun wa ninu awọn ẹsẹ bibeli kan pe ki a to gbadura rara ni Oun yo ti dahun ati pe nigba ti a ba si n gbadura lọwọ ni Oun yoo ti gbọ (Aisaya 65:24). A si fi idi eyi mulẹ ninu akọsilẹ ti o wa ninu bibeli lori iranṣẹ Aburahamu ti o ran lati wa aya fun ọmọ rẹ Isaki. Nigbati iranṣẹ yi de ilu ti o n lọ, o gbadura si Ọlọrun ki o ṣe ọna rẹ ni rere, ki o si jẹ ki o ri aya rere fun Isaki. Gẹgẹ bi a si ti kọwe rẹ, ki o to pari ọrọ adura rẹ, Rebeka jade si lẹba kanga omi ti o wa, oun yi si ni Ọlọrun ti pese gẹgẹ bi idahun si adura iranṣẹ yi. Eyi tunmọ si pe ki ọkunrin yi to gbadura rara ni Ọlọrun ti ri ọkan rẹ ati iru adura ti yo gba. Ki a tilẹ so otitọ, ki ọkunrin yi to rin irinajo yi ni Ọlọrun ti pese Rebeka silẹ fun Isaki. (Wo: Jẹnẹsisi 24:12-21)

Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ọna wo wa ni ẹdakẹda fẹ gba lati di Ọlọrun lọwọ lati gbọ adura wa tabi di adura wa lọwọ lati de eti Ọlọrun. Nkan ti ọpọ ma n ro ni pe adura ma n rin tabi sare lọ si ọrun ti a ba ti n sọrọ. Nitorina, awọn kan le lọ duro de ni oju ọna, ki wọn si ma jẹ ki o de ọdọ Ọlọrun. Kantankantan gba ni eyi, ti ko si ni itunmọ rara.

Bawo wa ni ti awọn angẹli ti o ma n gbe adura awọn eniyan goke tọ Ọlọrun lọ ṣe jẹ? Lotitọ, a rika ninu awọn nkan ti Jesu fi han Johanu pe awọn ẹda ọrun kan ati awọn angẹli kan fi adura awọn eniyan mimọ rubọ bi turari si Ọlọrun. (Wo: Ifihan 5:8 &8:1-4) Eyi ko wa tunmọ si pe ti awọn angẹli kan ko ba gbe ẹbẹ adura wa tọ Ọlọrun lọ, ko ni mọ nkan ti a fẹ, debi pe yoo ṣe. Nkan ti eyi kan fi idi rẹ mulẹ fun wa ni ọrọ bibeli ti o sọ pe gbogbo awọn angẹli ni a ran lati ma ṣiṣẹ fun igbala ati iṣerere awọn ọmọ Ọlọrun. Eyi ti o tunmọ si pe ti a ba n gbadura si Ọlọrun na ni awọn angẹli ti o ran lati ba wa ṣiṣẹ a ma ṣiṣẹ lati ri pe idahun si adura wa tẹ wa lọwọ (Daniẹli 10; Heberu 1:14).

Wayi o, a tun wa le ri ẹni ti yo tọka si akọsilẹ inu iwe Daniẹli ti o fi ye wa bi a ṣe di angẹli ti Ọlọrun ran lati fun ni idahun adura rẹ lọwọ ni akoko kan. Otitọ ni pe angẹli ti Ọlọrun ran si Daniẹli lati fun ni idahun adura rẹ ba idiwọ pade lati ọdọ Eṣu ati awọn ọmọ ogun rẹ fun ọsẹ mẹta gbako. Ṣugbọn adura ti Daniẹli gba kọ ni awọn wọnyi di lọwọ lati de ọdọ Ọlọrun; dipo eyi, ifarahan idahun si adura yi ni wọn di lọwọ fun igba diẹ. Gẹgẹ bi angẹli na gan ṣe sọ, lati ọjọ kinni ti Daniẹli ti ba Ọlọrun sọrọ fun oye awọn iṣipaya kan ti o ri ni Ọlọrun ti gbọ ohun rẹ, ti O si ti ran angẹli yi lati fun ni idahun. Nitorina, ifarahan idahun si adura Daniẹli ni a dena fun ọsẹ mẹta yi, ko ki i ṣe adura rẹ tabi idahun si adura rẹ ni a dena. Eyi si tun fi idi ọrọ Jesu ati ti awọn eniyan mimọ igbaani ti o wa ninu bibeli mulẹ pe ni kese ti a ba ti gbadura si Ọlọrun ni o ma n dahun. Ko ki i lọra rara lati da awọn ti o ba n kepe lohun. (Wo: Danieli 10:20-22; Daniẹli 10; Luuku 18:7-8)

O wa ṣeeṣe o ki Eṣu gbiyanju lati di ifarahan idahun si adura wa lọwọ tabi ki o jẹ pe yo gba akoko diẹ ki awọn igbeṣe ti Ọlọrun n gbe lori ọrọ ti a ba sọ to farahan. Idi si ni yi ti bibeli tun ṣe kọ wa pe ki a ma rẹwẹsi ninu adura gbigba, ki a si ma ṣe kọ Ọlọrun silẹ nitoripe a ko ri ifarahan esi adura wa. Awọn igba miran wa to jẹ pe o le gba Ọlọrun ni iṣẹ iyanu bi melokan, ni ibamu pẹlu ọgbọn ailodiwọn rẹ, bi a ti rika ninu bibeli nipa itusilẹ awọn ọmọ Isiraẹli kuro ni Ijibiti, ki a to ri pe O ti dahun adura wa tipẹtipẹ. Nigba ti a ba si dojukọ iru akoko bi eleyi, ti a n gbadura, ti ko si dabi ẹni pe Ọlọrun n ṣe nkankan lori ọrọ wa, nṣe ni o yẹ ki a bẹrẹ si ni gbadura pe ki O mu ohunkohun ti o ba n dena ifarahan esi adura wa kuro loju ọna, ki a mu suuru, ki a si tun duro ṣinṣin ninu ṣiṣe ifẹ rẹ (1Tesalonka 2:17-18&3:10-11; Heberu 10:35-36). O wa ṣe ni laanu pe ọpọ loti padanu ifarahan esi adura wọn nitoripe wọn ko mu suuru to fun Ọlọrun nipa diduro ṣinṣin ninu ifẹ rẹ ati ninu igbọkanle wọn ninu rẹ.

Ti Ọlọrun ko ba wa ki i lọra rara lati gbọ ati lati dahun ẹbẹ adura awọn ti o n kepe, ti ko si si ẹni na tabi ẹda na ti o le di adura wa lọwọ lati wa si eti rẹ, ki wa ni o le fa idena adura wa? Nkan akọkọ ti o le fa ki Ọlọrun ma gbọ tabi dahun adura wa ni ki a ma gbadura lodi si ifẹ rẹ. Ranti pe Johanu sọ ninu lẹta rẹ akọkọ pe, “Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ, pe bi awa ba beere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, o n gbọ ti wa.” (1Johanu 5:14) Eyi jasi pe ti a ko ba bere nkan ti a fẹ ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun, ko ni gbọ ti wa, de bi pe yo da wa lohun.

Fun apẹẹrẹ, Jesu Oluwa wa ti fi ye wa pe o lodi si ifẹ Ọlọrun fun wa lati ma ṣe atunwi asan ti a ba n gbadura tabi ki a ma gba adura aṣehan tabi ki a ma ṣogo lori ododo wa ti a ba n gbadura (Matiu 6:5-7&23:14; Luuku 18:9-14). Ti a ba wa kọ eti ikun si awọn ikilọ lori adura gbigba yi, ti a si n ṣe ifẹ inu wa, o didan ki Ọlọrun na kọ eti ikun si awọn ẹbẹ adura wa, ki O si ma da wa lohun.

Lafikun, Jemisi ninu lẹta rẹ na sọ pe a le ṣi beere ninu adura gbigba. O si fun ni apẹẹrẹ nkan ti o tunmọ si lati ṣi beere. O sọ pe nigba ti a ba n bere nkan lọwọ Ọlọrun lati le lo fun ifẹkufẹ ara wa, a n ṣi beere ni eyi, a ko si ni ri idahun si adura wa. O wa jasi pe Ọlọrun ko kan ni fun wa ni ohunkohun nitoripe a nilo rẹ; Ọlọrun yo tun wo nkan ti a fẹ fi ohun ti o ba fun wa ṣe ki O to yọnda rẹ fun wa. Ṣe a fẹ lo fun ilọsiwaju wa ati ti awọn elomiran ni abi a fẹ lo lati ni awọn miran lara tabi lati ṣe faari niwaju wọn? Gbogbo nkan wọnyi ni o ṣe pataki si Ọlọrun. (Wo: Jemisi 4:1-3)

Nkan miran ti o tun ma n dena adura ni ẹṣẹ. O kere loju wa ni o tabi o tobi, ẹṣẹ ma n dena adura. Lotitọ, ko ki i ṣe gbogbo igba na ni Ọlọrun ma n wo ẹṣẹ awọn eniyan ki O to dahun adura wọn. A tilẹ mọ lati inu bibeli pe gbogbo awọn ti i ṣe ti Kirisiti ni a ti dalare lọfẹ nipa iku rẹ fun ẹṣẹ wa (Roomu 3:23-24). Nitorina, niwọn igba ti a ba ngbadura si Ọlọrun ninu ododo Jesu, ti adura wa si wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ, ko ni i ṣalai dawa lohun. Nitori Jesu ni yo ma fi gbogbo igba ri ninu wa.

Amọ ṣa o, Ọlọrun ko fẹ ki a titori pe a wa ninu Kirisiti ati pe Oun ni ododo wa, ki a wa ma wu iwa ti ko tọ si ọmọnikeji wa tabi ki a ma ba agọ ara wa jẹ tabi ki a ma rin ni aiteriba fun awọn adari wa tabi ki a ma ni ẹmi idariji. Ti a ba n ṣe eyi, ti a si kọ lati ronupiwa niwọn akoko ti O ba fun wa, o didan ki O bẹrẹ si ni jẹ ki a jere aigbọran wa si aṣẹ rẹ. Ọna kan ti ijiya yi si ti le farahan ni idena si adura wa.

Fun apẹẹrẹ, Peteru sọ eyi fun awọn ọkọ wa: “Bẹẹ gẹgẹ ẹyin ọkọ, ẹ maa fi oye ba awọn aya yin gbe, ki ẹ si maa bu ọla fun wọn gẹgẹ bi ohun elo ti o ko lagbara, ati pẹlu bii ajumọ-jogun oore-ọfẹ iye; ki adura yin ki o ma baa ni idena.” (1Peteru 3:7) Njẹ o ri bayi? Ti iwọ gẹgẹ bi ọkọ ko ba ṣe daradara to si iyawo rẹ, ti o ko bu ọla fun, gẹgẹ bi ọrọ bibeli, o le dena adura rẹ. Ọpọ ọkọ ni o si jẹ pe idi ti wọn ko fi ni itẹsiwaju ni pe wọn ko ṣe ojuṣe wọn si awọn aya wọn. O tunmọ si pe ko digba ti a ba to jale tabi parọ tabi ṣe agbere ki adura wa to ni idena. Ti a ko ba ṣe ojuṣe wa ninu ile wa, si awọn obi wa, si ijọba wa, si awọn oṣiṣẹ wa, si Ọlọrun, si ijọ rẹ, si awọn ti o n kọ wa ni ẹkọ ọrọ Ọlọrun, o ṣeeṣe ki adura wa fun ilọsiwaju tabi fun ilera ati bẹẹbẹẹlọ ma gba.

Idi eyi ni a ṣe gbọdọ mu ọrọ Pọọlu lọkunkundun ti o sọ pe a ko le tẹsiwaju ninu ẹṣẹ dida ki a si tun wa fẹ ki oore-ọfẹ Ọlọrun maa pọ si lori aye wa (Roomu 6:1). Oore-ọfẹ Ọlọrun ni o jẹ ki a ma gbadura, ki a si ma ri idahun gba. Ṣugbọn ti a ba wa kọ lati ṣe ifẹ rẹ, o didan ki Oun naa bẹrẹ si ni kọ lati ṣe ifẹ wa to ba to awọn akoko kan, ki a ba le ronupiwada, ki a si ma ṣe ara wa leṣe.

ỌRỌ IPARI
Ni akotan, a ti ri ninu bibeli pe ko si nkankan ti o le dena adura wa afi awa funra wa. Nkan ti Eṣu ati awọn angẹli rẹ le dena ni ifarahan esi adura wa. Ṣugbọn niwọn igba ti a ko ba ti sọ igbekele wa ninu Ọlọrun nu, ti a si duro ṣinṣin ninu ifẹ rẹ pẹlu suuru, o didan ki a ri ifarahan gbogbo ẹbẹ adura wa.

IBEERE
– Ṣe alaye ni ṣoki iyatọ laarin idena adura ati idena ifarahan esi adura?
– E wo ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu awọn koko ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

October 2020

ADURAADURA – IPO WO NI O TỌ JULỌ FUN ADURA GBIGBA                                       AYỌKA: MAAKU 14:32-35) – KI NI GBEDEKE AKOKO TI O YẸ KI A FI MA GBADURA (AYỌKA: MATIU 6:8)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 11, BELU 2020

AKỌRI: ADURA – IPO WO NI O TỌ JULỌ FUN ADURA GBIGBA                                       AYỌKA: MAAKU 14:32-35

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ

A bẹrẹ awọn isọri ẹkọ lori adura gbigba nipa sisọrọ lori pataki ẹkọ adura gbigba. A si sọ wipe o ṣe pataki ki a kọ bi a ṣe n gbadura gẹgẹ bi alakalẹ ọrọ inu bibeli ki a ma ba ma gba agbadanu adura. Ọpọ loni ni o jẹ wipe adabọwọ ara wọn tabi ti awọn wooli wọn ni wọn n tẹle lori adura gbigba. Ṣugbọn adabọwọ eniyan, bi o ti wu ki o jọni loju tabi wuni lori to, ko le rọpọ alakalẹ Ọlọrun. Nitorina, ohunkohun, ẹkọkẹkọ ti a ba ti ri pe o lodi si awọn nkan ti a lakalẹ fun wa lori adura gbigba ninu bibeli, nṣe ni o yẹ ki a takete si. A ko gbọdọ titori pe wooli agba kan tabi alufa nla kan ni o sọ awọn nkan yi ki a wa tẹle. Niwọn igba ti o ba ti tako nkan ti a fi lọlẹ fun wa ninu bibeli, nṣe ni ki a yẹra fun. (Wo: Ditaronomi 13:1-5)

IPO WO NI O TỌ JULỌ FUN ADURA GBIGBA

Wayi o, ara awọn ibere ti o tun ma n jẹyọ lori adura gbigba ni o ni i ṣe pẹlu ipo ti o tọ fun eniyan lati wa ti o ba fẹ gbadura. Ipo wo gan ni o tọ fun ẹniyan lati mu tabi wa ti o ba n gbadura? Ṣe ori iduro lo tọna julọ ni tabi ki a kunlẹ? Abi ki a dojubolẹ gbadura ni o dara julọ ni tabi ki a gbojusoke si Ọba ọrun tabi ki a joko sibikan? E wo gan ninu awọn ipo yi ni o tọ julọ fun adura gbigba, ti yo jẹ ki adura wa jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun?

Fun awọn kan, adura ori ikunlẹ ni o ṣe iyebiye ju niwaju Oluwa, paapajulọ ti o ba jẹ pe adura fun idariji ẹṣẹ tabi fun ojurere ni a n gba. Fun awọn miran ẹwẹ, adura ti a ba dubulẹ gba, paapajulọ ni ihoho ọmọluabi, ni o ma n jẹ bi idan ju. Awọn kan si wa ti wọn gbagbọ pe ki a duro gbadura ni ọ tọna julọ. Eyi si wa lara idi ti o fi jẹ pe ọpọ igba ni awọn adari adura gbigba ni awọn ile ijọsin wa ma n fẹ ki awọn eniyan dide duro lati gbadura ti wọn ba wa ni ipade adura tabi ni akoko adura. Inu a si ma bi ẹlomiran ti o ba ri pe awọn kan ko dide duro lati gbadura ni akoko ti o n dari rẹ. A tilẹ ri awọn ti wọn gbagbọ pe awọn ti o ba joko gbadura ni akoko adura agbapapọ ti ijọ le gbe ogunologun tabi ki ẹmi buburu ti ara elomiran jade wọ ara ti wọn lọ.

Ṣugbọn ti a ba ṣe agbeyẹwo awọn nkan ti a fi han wa ninu ọrọ Ọlọrun finnifinni, a o ri pe ko si otitọ kankan lara gbogbo awọn adabọwọ awọn eniyan yi. Nkan ti a n sọ ni pe ko si ibi kankan ninu bibeli ti a ti fi idi rẹ mulẹ pe ti eniyan ko ba kunlẹ, dide duro, dubulẹ tabi joko gbadura, Ọlọrun ko ni gbọ adura rẹ. Eyi tunmọ si pe ko si ipo ti eniyan ko le mu tabi wa lati ba Ọlọrun sọrọ.

Fun apẹẹrẹ, Jesu Oluwa ko ni ipo kan pato ti o ma n mu ti o ba fẹ gbadura. Ipo ti o ba mu ma n ni i ṣe pẹlu ibi ti o ba wa ati bi nkan ti o fẹ gbadura nipa ba ṣe dun un ni ọkan to. Nitorina, a ri awọn igba ti o dubulẹ gbadura, gẹgẹ bi a si tun ṣe ri awọn igba ti o jẹ pe o duro gbadura ni. A tilẹ tun wa ri pe ninu asamọ kan ti o pa fun awọn eniyan lori adura gbigba, ọkunrin agbowo ode ti o sọrọ nipa rẹ duro gbadura ni. Ọlọrun si gbọ adura rẹ. Eyi ja si pe ọkan ti a fi n ba Ọlọrun sọrọ lo ṣe pataki ju, ki i ṣe ipo ti a mu.  (Wo: Maaku 14:32-35; Luuku 18:9-14;  Johanu 11:41-42)

Lafikun, a ri pe awọn ẹniyan mimọ igbaani ko ni pato ipo kan tabi omiran ti wọn ma n mu ti wọn ba n gbadura. Ipo ti wọn ba mu ni akoko kan ni i ṣe pẹlu ibi ti wọn wa ati pẹlu itara ọkan wọn ni akoko na. Nitori eyi, a ri igba ti wọn duro gbadura, gẹgẹ bi a si tun ṣe ri awọn igba ti wọn dide tabi dubulẹ gbadura (Ditaronomi 9:18-19; Joṣua 7:6-9; 2Awọn Ọba 18:41-46; 1Kironika 17:16). Ṣugbọn idahun adura wọn ko fi igba kankan ni i ṣe pẹlu ipo ti wọn wa lati gbadura. Dipo eyi, o ni i ṣe pẹlu ọkan ti wọn fi gbadura ati bi adura wọn ṣe wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun si. Dafidi, fun apẹẹrẹ, fi igba kan dojubolẹ gbadura si Ọlọrun ki ọmọ ti o kọkọ tipasẹ Baṣeba aya Uraya bi ma ba a ku. Ṣugbọn Ọlọrun ko da lohun nitori pe adura na ko wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. (Wo 2Samuẹli 12:13-23)

Nitorina, nkan akọkọ ti a gbọdọ mu ni ọkunkundun ti a ba n gbadura ni ki ọkan wa wa pẹlu Ọlọrun ni akoko ti a ba n gbadura si. Ko ki i ṣe pe ki a sọ pe a n gbadura, ki ọkan wa ma rede kiri tabi ki o jina si Ọlọrun (Maaku 7:6). Nkan ikeji ti a gbọdọ mojuto ti a ba n gbadura ni ki adura wa wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Ti a ko ba i ti gbagbe, Johanu sọ eyi fun wa ninu lẹta rẹ akọkọ si ijọ Ọlọrun: “Eyi si ni igboya ti a wa ni niwaju rẹ, pe bi awa ba beere ohunkokun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, o n gbọ ti wa.” (1Johanu 5:14) Ṣe o ri bayi pe ko sọ pe ti a ba beere ohunkohun lọwọ Ọlọrun lori ikunlẹ, yo gbọ ti wa tabi pe ti a ba bere ohunkokun lọwọ rẹ lori inaro, yo gbọ ti wa. Dipo eyi, o sọ pe ti a ba bere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, yo gbọ ti wa. Nitorina, bi a o ṣe mọ ifẹ rẹ ni o yẹ ki o jẹ wa logun julọ, ki a ba le ma gba adura ni ibamu pẹlu rẹ.

Nkan ẹkẹta ti o tun ṣe pataki ki a fi si ọkan ti a ba gbadura ni ki a wa ni ipo ti yo o jẹ ki a fi ọkan si nkan ti a n ṣe, ti ko si ni jẹ ki a sunlọ. Fun apẹẹrẹ, idi kan pataki ti a fi le sọ fun awọn ti a n dari ninu eto adura lati dide duro ni ki a ba le ran wọn lọwọ lati ma sunlọ. Akiyesi si ni pe, ọpọ ni o ti ma n ṣe ọpọlọpọ wahala ki wọn to wa fun eto tabi ipade adura. Ti awọn wọnyi ba si joko tabi dojubolẹ tabi kunlẹ gbadura, o ṣeeṣe ki wọn sunlọ ki wọn to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ. Ṣugbọn ti wọn ba wa ni inaro, a ti sunlọ wọn yo o ṣoro diẹ, bi o tilẹ jẹ pe ẹlomiran ninu wọn yo si papa sun na ni.

Yatọ si eyi, awọn ibi kan wa ti ko le fi aye silẹ fun wa lati mu awọn ipo kan ti a ba fẹ gbadura. Fun apẹẹrẹ, ti eniyan ba fẹ sare fi bi iṣẹju melokan gbadura ninu ọkọ ero tabi ibi iṣẹ rẹ, o ṣeeṣe ki o ma ni ore-ọfẹ a ti kunlẹ, duro tabi dubulẹ gbadura laida wahala silẹ tabi jẹ ki awọn miran foju si lara. Irufẹ ẹni bẹ yo fẹ joko si ibikan ti awọn eniyan ko ti ni le tete fura si nkan ti o n ṣe lati gbadura. Nitorina, ibi ti a ba wa na wa lara awọn nkan ti yo juwe iru ipo ti a o mu lati gbadura.

Ni afikun, o tun ṣe pataki ki a bọwọ fun ẹnikẹni ti o ba n dari wa ninu adura gbigba ti a ba wa pẹlu awọn ọmọ Ọlọrun miran. Ọlọrun ko fẹ rudurudu, ko si ki fi igba kankan lọwọ si (1Korinnti 14:33). Nitorina a gbọdọ wa ni itẹriba fun ara wa ki a ba le fihan pe a bọwọ fun Kirisiti (Efesu 5:21). Idi si ni yi ti a fi gbọdọ tele nkan ti ẹni ti o n dari wa ninu adura ba sọ nipa ipo ti o fẹ ki a wa, niwọn igba ti ko ba ti tako ọrọ bibeli, ti ko si tako ilera wa. Ti o ba fẹ ki a dide gbadura, ki a dide pẹlu ibọwọ fun Ẹmi Kirisiti ti o wa ninu rẹ. Ti o ba si fẹ ki a joko, ki a ṣe bẹẹ pẹlu. Eyi kọ ni yo sọ bi Ọlọrun yo ṣe dahun adura wa si. Ṣugbọn yo fihan pe a n gbọran si aṣẹ Ọlọrun, ko si ni jẹ ki adura wa ni idena. O tun wa ṣe pataki na fun ẹnikẹni ti o ba n dari adura lati ma lo ọpọlọ rẹ. Ko mọgbọn wa lati sọ pe ki gbogbo eniyan dide duro gbadura, lalai ku ẹnikẹni, ni ipejọpọ ti awọn arugbo tabi awọn oloyun wa. Ẹni to ba n ṣe eyi n fihan pe oun ko ni imọ tabi oye ọrọ Ọlọrun to ati pe oun ko mọ bi a ṣe n tẹlẹ itọni Ẹmi mimọ.

ỌRỌ IPARI

Lai denapẹnu, koko nkan ti mo n sọ ni pe ti a ba fẹ gbadura, ki a jẹ ki ifẹ Ọlọrun jẹ wa logun ninu ẹbẹ adura wa, ki a si tun wa ni ipo ti o rọ wa lọrun julọ lati gbadura pẹlu ọkan ti o papọ si ọdọ rẹ, lalai ṣe idiwọ tabi iyọlẹnu fun awọn ti o wa ni ayika wa ati lalai tanrawa jẹ nipa sisun lọ tabi rirede kaakiri ninu ọkan wa nibi ti a ti n gbadura.

IBEERE

–              Ki ni pataki julọ si ọ ninu awọn nkan ti a kọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280

ADURA – KI NI GBEDEKE AKOKO TI O YẸ KI A FI MA GBADURA (AYỌKA: MATIU 6:8)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 04, BELU 2020

AKỌRI: ADURA – KI NI GBEDEKE AKOKO TI O YẸ KI A FI MA GBADURA

AYỌKA: MATIU 6:8

Click here to download the file

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ

Bi a ti ṣe kọ tẹlẹ, o ṣe pataki fun gbogbo eniyan, paapaajulọ awọn ọmọ Ọlọrun, lati fi ara wọn jin lati kẹkọ ninu bibeli lori adura gbigba. Idi si ni pe ki wọn ma ba ma gba agbadanu adura. Ko wa tan si ori ki kọ ẹkọ lori adura gbigba nikan o; o tun ṣe pataki fun wa lati ma ṣe amulo awọn ẹkọ ti a n kọ lori adura gbigba. Aijẹbẹ, a kan n kọ ẹkọ lasan ni – aye wa ko ni jẹ ere adura gbigba bi o ṣe ye ki o jẹ. Nitorina, bi a ṣe n tẹsiwaju ninu awọn ẹkọ ti a n kọ lori adura gbigba, mo rọ ọ lati mu awọn ẹkọ na ni ọkunkundun, ki o si ma fi igba gbogbo ba Ọlọrun sọrọ pe ki O fun ọ ni okun lati ṣe amulo wọn.

KI NI GBEDEKE AKOKO TI O YẸ KI A FI MA GBADURA

Wayi o, nkan miran ti a tun fẹ gbe yẹwo lori adura gbigba ni iye iṣẹju tabi wakati ti o yẹ ki a ma lo lati gbadura. Ki gan ni gbedeke akoko ti o yẹ ki a ma lo lati gbadura lojumọ? Njẹ bibeli ti lẹ sọ wipe iye wakati tabi iṣẹju bayi ni o yẹ ki a ma lo lati ba Ọlọrun sọrọ? O ṣe pataki ki a mọ eleyi ki a ma ba ma da ara wa lẹbi pe a ko gba adura to tabi tan ara wa jẹ pe a n gbadura to tabi ju.

Gẹgẹ bi a ṣe ri ninu bibeli, lotitọ, Ọlọrun fẹ ki a ma gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ. Amọ ko si gbedeke akoko kankan ti O fi lelẹ fun wa lati ma ba a sọrọ tabi lati ma a gbadura si. Nitori eyi, ko tọna fun ẹnikẹni lati ma sọ fun awọn eniyan pe ti wọn ko ba i ti gbadura fun wakati kan tabi meji tabi mẹfa tabi ju bẹẹ lọ, wọn ko ti mọ nkan ti wọn ṣe tabi pe wọn ko ki i ṣe Kirisitiani ti o muna doko.

Lakọkọ na, o gbọdọ ye wa pe ko ki i ṣe iye wakati tabi iṣẹju ti eniyan lo lati gbadura ni yo sọ bi adura rẹ yo ṣe gba si tabi bi Ọlọrun yo ṣe tara da lohun si. Rara o. Dipo eyi, irufẹ ọkan ti eniyan fi ba Ọlọrun sọrọ ni yo sọ iha ti yo kọ si adura rẹ. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ eyi nigba ti O n ba awọn farisi ati awọn akọwe awọn Juu wi: “Egbe ni fun yin, ẹyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitori ti ẹyin jẹ ile opo run, ati nitori aṣehan, ẹ n gbadura gigun: nitori naa ni ẹyin o ṣe jẹbi pupọ.” (Matiu 23:14) Njẹ o ri bayi? Awọn Farisi ati akọwe wọnyi nifẹ si ki wọn ma gbadura gigun nibikibi ti wọn ba ti fun wọn ni anfaani lati gbadura. Ṣugbọn ki ni idi ti wọn fi n gbadura gigun bi eyi? Bi Jesu Oluwa ṣe so, nitori aṣehan ni wọn ṣe n ṣe bẹ. O tunmọ si pe awọn wọnyi ko ma gbadura gigun nitori pe ẹbẹ adura wọn pọ ṣugbọn nitori pe wọn fẹ wu awọn eniyan lori, ki wọn ba le ma kan sara si wọn gẹgẹ bi afadurajagun to le. Njẹ eyi wa ba ifẹ Ọlọrun mu bi? Rara o! Ko ba ifẹ Ọlọrun mu. Idi si ni yi ti Jesu fi gbojuagan si wọn, ti O si jẹ ki o ye wọn pe adura agbadanu ni wọn n gba.

Lafikun, Jesu tun sọ eyi lori adura gbigba: “Ṣugbọn nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma ṣe atunwi asan bi awọn keferi; wọn ṣebi a o titori ọrọ pupo gbọ ti wọn. Nitori naa ki ẹyin ma ṣe dabi wọn. Baba yin saa mọ ohun ti ẹyin ṣe alaini ki ẹ to beere lọwọ rẹ.” (Matiu 6:8) Ki ni idi ti Jesu ṣe sọ wipe ki a ma ṣe atunwi asan ti a ba n gbadura? Idi ni pe Ọlọrun Baba wa ti a ba sọrọ ko ni isoro pẹlu eti rẹ lati gbọran. Nitorina, ko ki i ṣe bi a ba ṣe tẹnu mọ ọrọ to tabi pariwo to ni yo ṣe gbọ to. Yatọ si eyi, Oun jẹ Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo. Nitorina, ki a to la ẹnu wa ba sọ ohunkohun, O ti mọ. Ko wa yẹ ki a ma ba a sọrọ bi ẹni ti ko mọ nkankan nipa ṣiṣe atunwi asan.

Nkan ti mo tilẹ wa fa ki a kiyesi ninu ọrọ Jesu ni pe ko si bi ẹni ti o ba n ṣe atunwi asan lẹnu adura gbigba ko ṣe ni pẹ tabi ki o dabi ẹni pe o n lo akoko to pọ lati gbadura ju ẹni ti ko ṣe atunwin asan lọ. Njẹ eyi wa ja si pe adura rẹ yo gba ju ti ẹni ti ko ṣe atunwi asan lọ ati ti ko si pẹ lẹnu adura gbigba tirẹ to o? Rara o! Oluwa ti fẹkan tẹlẹ sọ fun wa pe ọpọ ọrọ ko kun agbọn; pe a n ṣe atunwi asan ko tunmọ si pe Ọlọrun yo gbọ ti wa. A kan n fi akoko wa ṣofo lori adura gbigba lasan ni, niwọn igba ti a ba n ṣe atunwi asan. Idi si ni pe o lodi si ifẹ Ọlọrun.

Nitori eyi, mo fẹ ki a fi sọkan pe riri idahun si adura wa ko ni i ṣe pẹlu wakati tabi iṣẹju ti a lo lati gbadura. Dibo bẹ, o ni i ṣe pẹlu ọkan ti a fi ba Ọlọrun sọrọ ati bi ẹbẹ adura wa ṣe wa ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ si. Njẹ eyi wa tunmọ si pe a ko nilo lati pẹ lori adura gbigba rara ati pe ti a ba kan ti ba Ọlọrun sọrọ fun bi isẹju kan tabi iṣẹju meji, o ti to. Eyi ko ri bẹ rara. Lotitọ, Ọlọrun yo dahun adurakadura ti a ba gba, yala pẹlu isẹju kan ni tabi iṣẹju meji ni, niwọn igba ti a ba ti gba ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Amọ nkan melo gan ni a le ba Ọlọrun sọrọ lori laarin iṣẹju meji tabi iṣẹju kan? Nkan diẹ naa ni. Ọlọrun si fẹ ki a ma ba Oun sọrọ lori ohun gbogbo to ni i ṣe pẹlu aye wa.

Nitorina, gbedeke akoko ti a o lo lati gbadura ni i ṣe pẹlu awọn nkan ti a fẹ ba Ọlọrun so ni igba ti a fẹ gbadura ati bi aye ṣe ṣi silẹ fun wa to lati gbadura laini idiwọ tabi iyọlẹnu awọn ti o wa ni ayika wa. Fun apẹẹrẹe, a ri wipe Jesu Oluwa wa gan ko ni gbedeke akoko kan ti O fi n gbadura nigba ti O wa lorilẹ aye yi. Awọn igba kan wọn ti O fi gbogbo oru gbadura, ti o tunmọ si pe O lo to bi wakati mẹfa lati gbadura (Luuku 6:12). A si ri awọn igba ti o jẹ pe yo tete sare ji jade lati lọ gbadura ni, ki o to di pe awọn eniyan yoo ji, ti wọn yoo si tọ ọ wa fun ẹkọ ọrọ Ọlọrun ati iwosan (Maaku 1:35-37). Eyi tunmọ si pe O le ma ri ju wakati kan tabi meji lọ lati gbadura ni iru awọn akoko yi. A tilẹ tun wa ri pe nigba ti O wa pẹlu awọn ọmọ ẹyin rẹ ninu Ọgba Gẹsitimani, O beere lọwọ wọn pe ṣe wọn ko le ba Oun sọna ninu adura gbigba fun wakati kan pere ni (Matiu 26:40).

Awọn apẹẹrẹ yi fi idi rẹ mulẹ fun wa pe ko si ko si gbedeke akoko kan ti a le sọ pe ohun ni a gbọdọ ma lo lati gbadura. Sibẹsibẹ, o ṣe pataki ki a ma lo akoko to peye lojoojumọ lati ba Ọlọrun sọrọ. A le ma ni wakati kan tabi meji taara lati gbadura laini idiwọ tabi iyọlẹnu awọn eniyan. Iṣẹ ti a n ṣe, ile ti a n gbe, igbeyawo wa, bi awọn ọmọ wa ṣe dagba si ati awọn nkan miran ti o fara jọ awọn wọnyi ni yoo sọ iye iṣẹju tabi wakati ti a o le lo lẹkanṣoṣo lati gbadura. Nitorina, bi a ko tilẹ le lo wakati kan tabi jubẹẹlọ lati gbadura laidanuduro, yala nitori awọn ọmọ wa tabi nitori akoko ti a n lo lẹnu iṣẹ, a ṣi le pin akoko adura wa si bi ọna mẹta tabi jubẹẹlọ, ninu eyi ti a ti le ma fi boya ogun iṣẹju tabi iṣẹju mẹẹdogun gbadura ni akoko adura kọọkan, laini idiwọ tabi iyọlẹnu ẹnikẹni.

ỌRỌ IPARI

Ko si gbedeke akoko kankan ti a la kalẹ ninu bibeli fun wa lati ma fi gbadura. Ṣugbọn niwọn igba ti a mọ pe o yẹ ki a ma gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ, ti a si tun mọ pe ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni o yẹ ki a ma fa le Ọlọrun lọwọ, o ṣe pataki ki a to aye wa ni ọna ti a o fi ma ri akoko to peye lati ba Ọlọrun sọrọ laini idiwọ tabi iyọlẹnu awọn ti o wa ni ayika wa.

IBEERE

–              Bawo ni o ṣe rọrun fun wa to lati fi akoko to peye silẹ lati ba Ọlọrun sọrọ lojoojumọ?

–              Ki ni pataki julọ ninu nkan ti o kọ ninu ẹkọ yi.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – IBO NI O YẸ KI A TI MA GBADURA?                                                                       (AYỌKA: JOHANU 4:20-24)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)

ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE

ỌJỌRU 14, OWARA 2020

AKỌRI: ADURA – IBO NI O YẸ KI A TI MA GBADURA?

AYỌKA: JOHANU 4:20-24

CLICK HERE TO DOWNLOAD FILE

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ

Lara awọn nkan ti a ti kọ sẹyin lori adura gbigba niwọnyi: ‘pataki ẹkọ adura’, ‘ta ni o yẹ ki a ma gbadura si?’, ‘ki ni idi ti Ọlọrun ṣe fẹ ki a ma gbadura si Oun?’, ‘irufẹ awọn nkan wo ni o yẹ ki a ma gba ni adura?’ ati ‘igba wo ni o yẹ ki a ma gbadura?’ A wa fẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ na nipa wiwo ‘ibi ti o ti yẹ ki a ma gbadura?’ O si ṣe pataki ki a ṣe agbeyẹwo nkan ti bibeli sọ lori ibi ti o ti yẹ ki a ma gbadura, ki awọn adura wa ba le ma jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun ni igba gbogbo. Bi a ṣe mọ, oniruuru ẹkọ odi ni o wa ni igboro loni lori eyi. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn ti wọn sọ pe ti a ba fẹ ki adura wa gba, ki o si ma ni idiwọ rara, a gbọdọ de awọn ori oke ara kan ti Ọlọrun sọkalẹ tabi fi ibujoko rẹ si. A si ri tun ri awọn to jẹ pe ti wọn ko ba i ti de eti omi, wọn ko gbagbọ pe adura wọn le gba. Yatọ si eyi, a ri awọn ti wọn n sọ pe ọrọ Jesu gan ni awọn dirọ mọ ni tawọn. Idi si ni yi ti o fi jẹ pe kọrọ iyara wọn nikan ni wọn gbagbọ pe adura wọn ti le gba. Ewo gan wa ni o yẹ ki a di mu tabi gbagbọ ninu gbogbo awọn ilana adura gbigba wọnyi?

IBO NI O YẸ KI A TI MA GBADURA?

Ti a ba fẹ mọ ibi ti o tọ fun wa lati gbadura, ki Ọlọrun si gbọ, a ni lati gbe ọrọ Jesu Oluwa wa yẹwo lori rẹ. Ki ni Jesu kọ wa lori ibaṣepọ pẹlu Ọlọrun ti o ni itunmọ, ti o si jẹ itẹwọgba? Nkan ti O kọ wa ni pe Ẹmi ni Ọlọrun, ti a ba si fẹ sin in ni otitọ ati ni ododo, a gbọdọ sin in lati inu ẹmi wa. Ọrọ yi jẹyọ nigba ti O n ba obinrin kan sọrọ lori aye rẹ. Bi a si ṣe ri ka, nitoripe obinrin fẹ fi ọgbọn pẹ otitọ ọrọ ti Jesu n ba sọ silẹ, o ṣe ayaba lọ si ori ọrọ ibi ti o tọ lati jọsin Ọlọrun ati ibi ti ko tọ. O sọ wipe, “Awọn baba wa sin lori oke yi, ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sin.” (Johanu 4:20)

Njẹ irọ ni obinrin yi a pa bi? Rara o. Ni otitọ, Ọlọrun tikararẹ ti sọ fun awọn ọmọ Isiraẹli pe Oun yo yan ibikan ti wọn yo ti ma jọsin Oun fun wọn nigba ti wọn ba de ilẹ Ileri. Nigba ti akoko si to fun un lati ṣe imuṣe ọrọ yi, Jerusalẹmu ni ilu ti O yan fun wọn.  (Wo: Ditaronomi 12; 1Kironiku 22-23:2) Ṣugbọn ṣa o, ijọsin awọn ọmọ Isiraẹli ni Jerusalẹmu ni i ṣe pẹlu ẹbọ riru ati fifi ọrẹ fun Ọlọrun, ko ni i ṣe pẹlu adura rara. Eyi tunmọ si pe ko di igba ti wọn ba to de Jerusalẹmu ki wọn to gba adura si Ọlọrun, ki O si gbọ. Ibikibi ti wọn ba wa ni wọn ti le e ba a sọrọ ninu adura, ki O si gbọ, ki O si tun dahun.

A si wa ri ninu bibeli pe nigbati Solomọni Ọba n ṣe iyasimimọ Tẹnpili Ọlọrun ti o kọ ni o bẹ Ọlọrun pe, ninu aanu rẹ, ki O dahun adura ki adura ti ẹnikẹni tabi ijọ eniyan ba gba si lati inu Tẹnpili yi tabi nibikibi ti wọn ba ti dojukọ Tẹnpili yi lati gbadura. (Wo: 1Awọn Ọba 8:22-53) Eyi gan lo wa fa ti ọpọlọpọ fi wa ro wipe ti wọn ko ba i ti de Jerusalẹmu tabi inu Tẹnpili Oluwa ti o wa nibẹ, adura wọn ko le fi taratara gba.

Ṣugbọn nigba ti Jesu Oluwa de, ti O si bẹrẹ si ni kọ awọn eniyan ni ijọsin otitọ si Ọlọrun, O fi ye wọn pe ilana yi ko wa ni ibadọgba pẹlu ifẹ Ọlọrun, bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fi ọpọlọpọ ọdun fi aye gba awọn eniyan rẹ lati tẹle. A si ri ifidumlẹ eyi ninu idahun ti O fun arabinrin ti a n sọrọ rẹ yi lori ibi ti o tọ lati jọsin Ọlọrun. Akọsilẹ idahun na ni eyi:

“Jesu wi fun u pe, Gba mi gbọ, obinrin yi, wakati na mbọ, nigbati ki yio ṣe lori oke yi, tabi Jerusalẹmu, li ẹnyin o ma sin Baba. Ẹnyin nsin ohun ti ẹnyin ko mọ: awa nsin ohun ti awa mọ: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wa. Ṣugbọn wakati na mbọ, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn olusin toto yio ma sin Baba li ẹmi ati li otitọ: nitori iru wọn ni Baba n wa ki o ma sin on. Ẹmi li Ọlọrun: awọn ẹniti nsin i ko le ṣe alaisin i li ẹmi ati li otitọ.” (Johanu 4:21-24)

Ki ni koko ọrọ Jesu Oluwa wa ninu awọn ẹsẹ bibeli yi? Koko rẹ ni pe ijọsin otitọ si Ọlọrun ki i ṣe nkan ti a le de mọ ile kan tabi ilu kan tabi ori-oke kan. Ijọsin otitọ si Ọlọrun fẹ jẹ eyi ti o gbọdọ waye lati inu ẹmi wa wa. Ẹmi ni Ọlọrun funrarẹ. Nitorina, ẹnikẹni ti o ba fẹ sin ni otitọ ati ni ododo gbọdọ sin pẹlu ẹmi rẹ ati pẹlu ọkan otitọ. Bi Jesu si ṣe sọ, awọn ti yoo si Ọlọrun tọkantara ati pẹlu aiṣẹtan gan an ni Oun funrarẹ n wa. Ko ki i ṣe awọn ti wọn yo korajọpọ sinu ile kan tabi si ori oke kan, ti o si jẹ pe ọkan wọn ko ni si pẹlu rẹ.

Eyi wa ja si pe ọkan wa ni Ọlọrun n wo, ki i se ile ijọsin wa. Niwọn igba ti ọkan wa ba si ti mọ niwaju rẹ, ti o si jẹ pe tọkantọkan ni a n juba rẹ, yin in logo, fun un ni ọrẹ ati gbadura si, o di dandan ki O tẹwọgba ijọsin wa, lai fi ti ibi ti a ti n jọsin ṣẹ. Ṣugbọn ti ọkan wa ko ba wa pẹlu rẹ, ti o si jẹ pe boya ọja, ile-iṣẹ wa, ibi okowo wa, oko wa, ọdọ awọn ọrẹ wa tabi ibi inawo kan ti a fẹ lọ ni ọkan wa ba wa, ko si bi ile, yara tabi ori-oke ti a duro si ti le dara to, ijọsin wa si nibẹ ko le jẹ itẹwọgba. Idi si ni pe Ọlọrun ko fẹ awọn ti yoo kan ma fi ẹnu lasan sin in, ti ọkan wọn yo si jina si. (Wo: Maaku 7:6-7)

Ki a tun ma wa gbagbe pe pẹlu iṣẹ irapada ti Jesu ti ṣe fun gbogbo wa, awa gan ni Tẹnpili Ọlọrun lọwọlọwọ bayi. Bẹẹni, gbogbo wa ti a ti tipasẹ Jesu di ọmọ Ọlọrun ni a ti di ilegbe Ọlọrun, ti o tunmọ si pe Ọlọrun n gbe inu wa ni bayibayi. (Wo: 1Korinnti 3:16 & 6:19) Nitorina, ko si ibi ti a duro si lati jọsin tabi gbadura ti Ọlọrun ko ni i gbọ. Boya inu yara wa ni, ile-iwẹ ni, ile igbọnsẹ ni, aarin ọja ni, ibi iṣẹ wa ni, inu ọkọ ni ati bẹẹbẹẹlọ, niwọn igba ti ọkan wa ba ti wa ninu nkan ti a n ṣe, o ti pari — Ọlọrun yoo tẹwọgba ohunkohun ti a ba ṣe ni orukọ ọmọ rẹ Jesu. Ko si yẹ ki a jẹ ki ẹnikẹni tan wa jẹ pe ti a k o ba i ti de awọn ile ijọsin kan tabi awọn ori oke gbankọgbi kan, Ọlọrun ko ni gbọ ti wa.

Ṣugbọn o tun wa yẹ ki a ṣe agbeyẹwo ọrọ Jesu ti awọn kan ma n saba dirọ mọ gẹgẹ bi idi ti wọn ṣe n sọ wipe ko ki i ṣe ibikibi ti a ba ri ni a ti le gbadura. Ki si ni ọrọ naa? Ọrọ naa ni a ri akọsilẹ rẹ ninu iwe Matiu, ori kẹfa, ti o ka bayi:

“Nigbati iwọ ba ngbadura maṣe dabi awọn agabagebe; nitorii nwọn fẹ ati ma duro gbadura ni sinagogu ati ni igun ọna ita, ki enia ki o ba le ri wọn. Lotọ ni mo wi fun nyin, nwọn ti gba ere wọn na. Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbadura, wọ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si se ilẹkun rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti mbẹ ni ikọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ikọkọ yio san a fun ọ ni gbangba.” (Matiu 6:5-6)

Ki ni a ri dimu ninu ọrọ Jesu ninu awọn ẹsẹ bibeli ti o wa loke yi? Nkan akọkọ ni pe nigba ti Jesu gan wa laye, awọn eniyan a ma gbadura ninu sinagọgu ati ni ibikibi ti o ba wu wọn. Njẹ o wa tunmọ si pe Oluwa lodi si eyi? Rara o! Nkan ti O lodi si ni idi ti wọn ṣe n gbadura ni awọn ibi ti wọn ti n gbadura yi. Gẹgẹ bi O ṣe sọ, idi ti awọn kan ṣe n gbadura ni gbangba, boya ninu sinagọgu ni tabi ibomiran, ni ki awọn eniyan ba le ri wọn gẹgẹ bi aladura. Igba kan tilẹ tun wa ti O ba awọn Farisi ati awọn Ọlukọ ofin wi fun bi wọn ṣe fẹran lati ma gba adura gigun ki awọn eniyan ba le ma bọwọ fun wọn bi ọga ninu adura gbigba (Matiu 23:14). O wa tunmọ si pe alaṣehan ni awọn wọnyi ati pe nitori asehan wọn ni Jesu ṣe ba wọn wi lori adura gbigba wọn ni gbangba, ti O si jẹ ki o ye wọn pe adurakadura ti a ba gba lati ṣe aṣehan ko jẹ itẹwọgba niwaju Ọlọrun.

Amọ o, ko wa tunmọ si pe awọn ti o n gbadura ni gbangba tabi ti o n gbadura gigun nikan na ni o le jẹbi asehan. Eniyan le gbadura ninu yara rẹ ki o si tun jẹbi aṣehan. A ri ọpọ to jẹ wipe ti wọn ba n gbadura ninu yara wọn tabi ni ẹyinkunle wọn, gbogbo awọn to wa ni ayika ni yo mọ pe wọn ngbadura. Aṣehan ni eyi na jẹ. Ko si ni ere lati ọdọ Ọlọrun. Idi ti Jesu ṣe kọ wa lati ma gbadura si Ọlọrun ni ikọkọ ni ki a ba le ni oye pe adura gbigba ni i ṣe pẹlu biba Ọlọrun sọrọ, ko ni i ṣe pẹlu biba eniyan sọrọ. Yatọ si eyi, O tun kọ wa ki a ma gbadura ni ikọkọ ki a ba le yẹra fun idilọwọ awọn eniyan ti a ba n gbadura. Nitorina, bi o tilẹ jẹ pe eniyan ni a n  gbadura fun, a ko gbọdọ gbagbe nigba kankan pe Ọlọrun ni a n ba sọrọ. A ko si gbọdọ wa ma gbadura lati wu awọn eniyan lori, ki wọn ba le ma gboriyin fun wa pe a mọ adura gba. Ọlọrun ko ni dahun adura wa nitori pe ẹnu wa dun, tabi nitori pe a mọ ọrọ to lẹsẹẹsẹ tabi nitori pe adura wa gun; Ọlọrun yo dahun adura wa nitori pe alaanu ni, nitori pe a gbadura si pẹlu igbagbọ ati nitori pe a gbadura si tọkantọkan.

Nitori eyi, nkan ti o yẹ ki o jẹ wa logun julọ ti a ba n gbadura si Ọlọrun ni ọkan ti a fi n gbadura si, ki i ṣe ibi ti a duro si lati gbadura si. A le gbadura si ni ikọkọ tabi ni gbangba. Niwọn igba ti ọkan wa ba ti mọ, ti o si wa ni ibadọgba pẹlu ifẹ rẹ, ti a ko si jẹ ki ohunkohun (boya ẹrọ agbelewọ wa ni tabi ero okan wa tabi oorun) di wa lọwọ, o di dandan ki o da wa lohun. Jesu, ti o jẹ awokọṣe wa, na fi awọn igba kan gbadura ni gbangba (Johanu 11:41-42&12:27-28). Ko ki i ṣe gbogbo igba na ni o fi gbadura ni ikọkọ. Ṣugbọn boya ikọkọ ni o ti gbadura ni o tabi ni gbangba, ko fi akoko kankan gbadura aṣehan tabi ki O gba adura ti ọkan rẹ ko si nibẹ. Nitori eyi, ko si igba ti o gbadura ti Ọlọrun ko da lohun. Ti awa naa ba si n fi gbogbo igba tẹle ilana ti O la kalẹ fun wa, o di dandan ki Ọlọrun naa ma fi gbogbo igba da wa lohun.

ỌRỌ IPARI

Riri idahun si adura ti a ba gba ko ni nkankan ṣe pẹlu ibi ti a ti n gbadura; dipo bẹẹ, o ni ohun gbogbo ṣe pẹlu ọkan ti a fi n gbadura. Nitorina, ọkan wa ni o yẹ ki a ṣiṣẹ le lori, ki o ba le ma fi gbogbo igba wa ni ibadọgba pẹlu ifẹ Ọlọrun, ki adura wa si ma ba ni idena.

IBEERE

–              Njẹ a ri awọn ori oke pataki kan tabi ile ijọsin kan ti o jẹ pe ti eniyan ko ba i ti de ibẹ, adura rẹ ko le gba?

–              Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – IGBA WO NI O YẸ KI A MA GBADURA? (AYỌKA: LUUKU 18:1)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 07, OWARA 2020

AKỌRI: ADURA – IGBA WO NI O YẸ KI A MA GBADURA? AYỌKA: LUUKU 18:1

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ wa ti o gbẹyin lori adura gbigba, a ri pe ko si nkankan ti ko yẹ ki a ma fa le Ọlọrun lọwọ lori aye wa nipasẹ adura gbigba. Boya o kere ni tabi o pọ ni, boya o ga lagaju fun wa ni o tabi yẹnpẹrẹ ni loju wa, ko si ohun na ti o jẹ mọ ọrọ aye wa ati igbayegbadun wa ti ko yẹ ki a fa le Ọlọrun lọwọ nipasẹ adura gbigba. Idi si ni pe ko si nkankan ti a le da ṣe tabi da yanju lori ọrọ aye wa ti ko ba ṣe pe Ọlọrun ba lọwọ si. Nitorina, eyi ti a o fi ma ṣe aniyan tabi laala asan, nṣe ni o ye ki a kọ ara wa lati ma fa ohun gbogbo ti o jẹ mọ aye wa le Ọlọrun lọwọ. Niwọn igba ti a ba si n ṣe eyi, gẹgẹ bi Pọọlu ti sọ fun awọn ara Filipi, o di dandan ki Ọlọrun fi alaafia rẹ ti o ju gbogbo imọ eniyan lọ ṣe abo fun ọkan wa, ki O si tun ma fi ọna ara mojuto ohun gbogbo ti a fa le lọwọ (Filipi 4:6-7).

IGBA WO NI O YẸ KI A MA GBADURA?
Wayi o, a fẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ yi nipa ṣiṣe agbeyẹwo igba ti o yẹ ki a ma gbadura. Awọn igba wo gan ni o yẹ ki a ma gbadura? Bi a ṣe ri ka ninu bibeli, gbogbo igba ni o yẹ ki a ma gbadura. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ eyi fun wa: “…o yẹ ki a ma gbadura nigba gbogbo, ki a ma si saarẹ.” (Luuku 18:1) Pọọlu na tun ba wa sọrọ lori eyi ninu lẹta rẹ si awọn ijọ Tẹsalonika. O sọ wipe, “Ẹ maa gbadura ni aisinmi.” (1Tẹsalonika 5:17) Nitorina, ko si igba ti ko yẹ ki a ma gbadura si Ọlọrun. Gbogbo igba ni o yẹ ki a ma gbadura si. A ko si gbọdọ fi igba kankan dẹkun adura gbigba si i.

Gẹgẹ bi a ti ṣe kọ tẹlẹ, adura gbigba jẹ ọna kan pataki ti a fi n fi igbẹkẹle wa ninu Ọlọrun han; o jẹ ọna kan pataki ti a fi n sọ fun Ọlọrun pe a mọ pe a ko le da nkankan ṣe lalai fi tiẹ ṣe. Njẹ a wa ri igba naa ti ko yẹ ki a fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han? Ko si rara. Gbogbo igba ni o yẹ ki a ma fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han nipa gbigba adura si.

Ṣugbọn ṣe o wa ṣeeṣe lati ma gbadura ni gbogbo igba, laisinmi ati laiṣaarẹ? O ṣeeṣe. Ti ko ba ṣeeṣe ni, Jesu ko ni sọ fun wa pe o yẹ ki a ma gbadura ni gbogbo igba, ki a ma si ṣaarẹ. Eyi ko wa jasi pe ki a ma ṣe nkan miran mọ ju pe ki a ṣa ma gbadura lọ. Ti o ba jẹ nkan ti Jesu n sọ ni eyi, a jẹ wipe a ko le wulo fun ara wa, fun Ọlọrun tabi fun ẹlomiran niyẹn. Yatọ si eyi, o tunmọ si pe Jesu gan ti O sọ wipe ki a ma gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ ti kuna ni yẹn. Nitoripe Oun funrarẹ ko pa gbogbo nkan miran ti o ni i ṣe pẹlu gbigbe aye yi ti lati kan ma fi gbogbo igba gbadura.

Gẹgẹ bi a ti ri ninu bibeli, bi o tilẹ jẹ wipe Jesu jẹ aladura eniyan, ẹni ti o n fi igba gbogbo fi igbẹkẹle rẹ ninu Ọlọrun han, O n jẹun nigba ti o yẹ ki o jẹhun, O n wẹ nigba ti o yẹ ki O wẹ, O n sun nigba ti o yẹ ki O sun, O si n waasu nigba ti O yẹ ki O waasu. Eyi tunmọ si pe Jesu ko fi awọn nkan miran ti O tọna fun lati ṣe silẹ nitori pe O fẹ gbadura. Nitori eyi, ko bojumọ fun ẹnikẹni ninu wa lati fi awọn ojuṣe rẹ silẹ nitori pe o fẹ ṣe amuṣẹ tabi amulo ọrọ Jesu ti o sọ wipe, “O yẹ ki a ma gbadura nigba gbogbo, ki a ma si ṣaarẹ,” tabi pe o fẹ ṣe amulo ọrọ Pọọlu ti o ṣo wipe, “Ẹ maa gbadura ni aisinmi.”

Nkan ti mo n gbiyanju lati sọ, fun apẹẹrẹ, nipe ko yẹ ki a ri iya ti yoo pa awọn ọmọ rẹ ti ki wọn ma ṣere gele kaakiri ile tabi adugbo nitoripe o fẹ gbadura tabi lọ si ipade adura. Bi o ṣe ṣe pataki lati gbadura na ni o ṣe ṣe pataki fun wa lati mojuto ile wa tabi lati ri pe a ko kuna ni ṣiṣe ojuṣe wa ni ile wa ni tabi ni ibi iṣe wa.

Ki gan wa ni o tunmọ si pe ki a ma gbadura laiṣinmi tabi pe ki a ma gbadura ni gbogbo igba? Nkan ti o tunmọ si ni pe ki a ma gbadura nigba ti nkan dara ati nigba it nkan ko dara, nigba ti nkan pọ ati nigba ti ko to tabi ko si, nigba ti nkan dẹrun ati nigba ti ko dẹrun, nigba ti o rọrun ati nigba ti ko rọrun, nigba ojo ati nigba ẹrun ati laarọ, lọsan ti lalẹ. Ọpọ ni o ro pe igba ti wahala ba ba aye eniyan tabi awọn ti o sunmọ eniyan nikan ni o ṣe pataki ki a mura si adura gbigba. Nitorina ti wọn ba ri ẹni ti o tẹramọ adura gbigba, wọn a ma ro lọkan wọn pe boya iṣoro aye rẹ pọ ni.

Ṣugbọn Ọlọrun ko fẹ ki a duro di igba ti a ba ni iṣoro ki a to mu adura gbigba si ni ọkunkundun. Ko fẹ ki a duro de igba ti Esu ba ba nkan jẹ mọ wa lọwọ tan tabi de igba ti idibajẹ ba ba awọn nkan ti a ro pe apa wa ka tan ki a to ke pe. Lafikun, Ọlọrun ko fẹ ki a duro de igba ti a ba de opin ọgbọn ati oye wa lori ọrọ aye wa, ki a to mọ pe a ko le da ohun kan ṣe lalai fi tirẹ ṣe. Dipo eyi, O fẹ ki a ma fi gbogbo igba ba Oun sọrọ lori ọrọ aye wa, ti ẹbi wa, ti iṣẹ wa, ti ilu wa, ti orilẹ-ede wa ati bẹẹbẹẹlọ, paapaajulọ nigba ti nkan dara, ti o si tun dẹrun fun wa. Bẹẹni, O fẹ ki a ma fi igba gbogbo fi igbẹkẹle wa ninu rẹ lati mojuto gbogbo ohun ti o ni ṣe pẹlu aye wa ati igbayegbadun wa han. Niwọn igba ti a ba si n ṣe eyi, aye wa ko ni salai ma ni itunmọ, ki o si tun fi gbogbo igba ma ni iriri isinmi, alaafia ati ifọkanbalẹ ti o n ti ọwọ Ọlọrun wa.

O wa ṣeni laanu pe ọpọlọpọ eniyan, laiyọ awọn ọmọ Ọlọrun gan silẹ, ni o jẹ wipe igba ti wọn ba to ni iṣoro ti o ka wọn laya tabi ti o sọ ọgbọn wọn di omugọ ni wọn yoo to ranti pe awọn ma ni Ọlọrun. Igba yi ni wọn yo to ma sare kaakiri, ti wọn yo ma wa awọn ti yo ba wọn ṣe iṣọ oru pajawiri tabi gba awẹ pajawiri. Eyi ko yẹ ki o ri bẹ rara. Nitootọ, gẹgẹ bi bibeli ṣe fi ye wa, niwọn igba ti ẹmi ba si wa lẹnu wa, ko si igba ti a ko le kepe orukọ Oluwa, ki a si reti ki O da wa lohun. Ẹnikẹni ti o ba kepe orukọ Oluwa fun iranlọwọ yo ri igbala ni ọrọ Ọlọrun wi. Amọ o, ti a ba fi ikọkukọ kọ ara wa, ti a ṣi jẹ ki o di aṣa fun wa lati ma duro de igba ti iṣoro tabi idamu ba de si wa ki a to mu adura gbigba ni ọranyan, o ṣeeṣe ki idamu miran ti gba ẹmi kuro lẹnu wa ki o to di pe a o ri nkankan ba Ọlọrun sọ.
(Wo: Saamu 107; Roomu 10:13)

Lotitọ o, pe a ni fi gbogbo igba fi ọrọ aye wa le Ọlọrun lọwọ ko tunmọ si pe ki a ma ni idojukọ rara. Jesu Oluwa wa, fun apẹẹrẹ, jẹ ẹnikan ti o n fi gbogbo igba gbadura si Ọlọrun. Ko ki i duro de igba ti wahala tabi idojukọ ba wa ki O to gbadura. Sibẹsibẹ, O ba oniruuru idojokọ pade lati ọdọ Eṣu ati lati ọdọ awọn eniyan. Amọ, nitoriti O ti kọ bi a ṣe n fi gbogbo nkan le Ọlọrun lọwọ nigba ti o dara ati nigba ti ko dara, ko si idojukọ tabi wahala kankan ti o bori rẹ. Nigba ti yoo si fi aye yi silẹ, O sọ gbangbagbangba pe, “Emi ti ṣẹgun aye.” (Wo: Johanu 16:33)

Nibakanna, ti awa na ba fi ara wa jin lati ma gbadura ni gbogbo igba, laisinmi ati laiṣaarẹ, ko si idojukọ tabi ipenija yowu ti o le tọ wa wa ti a ko ni ni iriri iṣegun ati iṣelogo lori rẹ. Yatọ si eyi, niwọn igba ti a ba ti n fi gbogbo igba fa akoso ọrọ aye wa, iṣe wa, ile wa, awọn ọmọ wa, ilu wa, ijọ Ọlọrun ati ohunkohun ti o jẹ wa logun le Ọlọrun lọwọ, ọpọ ogun tabi idojukọ gan ni yoo ti jẹ ṣiṣẹ ki a to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ; ọpọ ogun ni yoo si jẹ ṣiṣẹ ti a tilẹ ma le mọ nkankan nipa rẹ ti a o fi kuro ni aye yi.

Lafikun, a tun ri awọn ti wọn ro pe awọn akoko kan ni o yẹ ki eniyan ma gbadura tabi pe awọn akoko kan ni eniyan le gbadura ti Ọlọrun yoo si gbọ. Bi a ṣẹ ri ka ninu bibeli, ko si akoko na ti a gbe ohun wa soke si Ọlọrun ninu adura ti ko ni gbọ tabi dawa lohun. Fun apẹẹrẹ, ko si akoko kan gboogi ti Jesu Oluwa wa nlo lati ba Ọlọrun sọrọ. A ri awọn igba ti o ji jade lati gbadura. A si ri awọn igba ti o ṣe iṣọ oru. Ẹwẹ, awọn igba kan si wa to jẹ wipe ojumọmọ ni o ke pe Ọlọrun. O ni ṣe pẹlu irufẹ aini ti o fẹ ki Ọlọrun ba pade ati akoko ti aini na yọju. (Wo: Matiu 14:13; Maaku 1:35; Johanu 12:27)

Nitori eyi, a ko nilo lati duro de ọganjọ oru ki a to ba Ọlọrun sọrọ lori aye wa. Ti nkan ba ti bajẹ ki ilẹ to su nkọ? Niwọn igba ti a ba ti mọ nkan ti a nilo lati ọwọ rẹ, iba a jẹ aarọ ni a wa ni tabi ọsan tabi alẹ, a ni anfaani, gẹgẹ bi bibeli ṣe fi ye wa, lati gbadura si, ki O si da wa lohun (Efesu 3:12; Heberu 4:10). Ma wa kọbiara si awọn ti wọn ma n sọ pe ẹni ti o ba fẹ ki Ọlọrun dahun adura oun ni kiakia oru kanjọ ni o yẹ ki o ma gbadura. Isọkusọ gba a ni eleyi. Ko ki i ṣe ọrọ bibeli rara.

Ju gbogbo rẹ lọ, o yẹ ki a fi sọkan, ki a si di amure wa ṣinṣin lati ma gbadura ni gbogbo igba. Eyi ko si tunmọ si pe a gbọdọ ma fi gbogbo igba wa ibi kan ti a le ti ara wa mọ ki a ba le ma gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ. Ti o ba jẹ nkan ti a n wa ni eyi, o ṣeeṣe ki a ma le mu ọrọ Ọlọrun yi ṣẹ lori aye wa. Idi si ni pe ko ki i ṣe gbogbo igba naa ni aye yoo ma wa ni ṣiṣi ṣilẹ fun wa lati ri ibikan fi ara pamọ si lati ba Ọlọrun sọrọ. Lotitọ, o se pataki, o si dara ki a to aye wa ni ọna ti a o fi ma ri aye lojoojumọ tabi loorekoore lati fi ara pamọ si ibi ti a le gbadura si Ọlọrun laisi idiwọ tabi iyọlẹnu awọn eniyan. Ṣugbọn a ko gbọdọ duro de igba ti a ba to ri aye ṣe eyi ki a to ba Ọlọrun ṣọrọ. Nibikibi ti a ba wa, niwọn igba ti ọkan wa ba ti sipaya lati ba a sọrọ, ki a si fi igbekẹle wa ninu rẹ han, nṣe ni o yẹ ki a gbohun ọkan wa soke si ninu adura gbigba. A tilẹ le ma le ya ẹnu wa nitori ibi ti a wa. Ṣugbọn bi Hana, iya Samuẹli, ṣe fi itara ọkan ba Ọlọrun sọrọ, lai sọrọ sita rara, awọn naa le ma fi gbogbo igba ba Ọlọrun sọro ninu ọkan wa, lai gbohun soke tabi sọrọ sita rara. Ọlọrun ti o si ri ọkan wa, yoo fi idahun ti o peye bẹ wa wo pẹlu agbara nla rẹ.

Ki a si wa ranti pe bibeli gan sọ fun wa pe, “Nitori ti oju Oluwa n lọ siwa, sẹyin ni gbogbo aye, lati fi agbara fun awọn ti ọkan wọn wa ni pipe si ọdọ rẹ…” (2Kironika 16:9) Hun! Ọrọ nla ni eyi. Koko rẹ na si ni pe oju Ọlọrun nsọ awọn ti ọkan wọn n fi gbogbo igba wa ni ọdọ rẹ lati fi amojuto aye wọn ati awọn nkan ti o jẹ wọn logun le lọwọ. Irufẹ awọn wọnyi si ni yo ma fi gbogbo igba ri titobi agbara ati ogo Ọlọrun ninu aye wọn. Njẹ irufẹ eniyan yi ni awa jẹ bi? Njẹ gbogbo igba ni a fi n fi ọkan wa tan Ọlọrun lati mojuto aye wa ati lati jẹ ki wọn ri bi o ṣe yẹ ki wọn ri?

ỌRỌ IPARI
Adura gbigba jẹ nkan ti a gbọdọ ma ṣe laisinmi ati laiṣaarẹ. Aijẹbẹ, o ṣeeṣe ki iṣoro tabi idojukọ aye wa ti gba wa danu ki a tilẹ to ri anfaani a ti ba Ọlọrun sọ nkankan. Nitorina, nṣe ni o yẹ ki a fi bi a ṣe n gbadura laisinmi ati laiṣaarẹ kọra. Ti a ba ṣi ṣetan lati ṣe eyi tọkantọkan, o didan ki Ọlọrun fi agbara fun ọkan wa nipasẹ Ẹmi Mimọ rẹ lati jẹ ki o ṣeeṣe fun wa.

IBEERE
– Kini awọn idi ti ọpọ fi ma n gbagbe pataki adura si Ọlọrun ti ko ba si idojukọ fun aye wọn?
– Njẹ o ṣeeṣe lati ma fi gbogbo igba fi ọkan wa ba Ọlọrun sọrọ?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

September 2020

ADURA – AWỌN NKAN WO NI O YẸ KI A MA GBADURA NIPA? (AYỌKA: FILIPI 4:6-7)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 30, OWEWE 2020

AKỌRI: ADURA – AWỌN NKAN WO NI O YẸ KI A MA GBADURA NIPA?
AYỌKA: FILIPI 4:6-7

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu awọn ẹkọ ti a ti kọ sẹyin lori adura, a ri wipe pataki ni ẹkọ adura jẹ ti a ko ba fẹ ma gba agbadanu adura tabi ki a ma yan ara wa jẹ nitori aigbadura to. A tun ṣe agbeyẹwo ẹni ti o yẹ ki a ma gbadura si ati idi ti o fi yẹ ki a ma gbadura si. A si ri pe Ọlọrun, ti o da ọrun ati aye, nikan naa lo tọ, ti o si yẹ ki a ma gbadura si. Ko tan sibẹ o, a tun wo orukọ ẹni ti o yẹ ki a ma lo lati gbadura si Ọlọrun. Nkan ti a si ri ninu bibeli ni pe Jesu Kirisiti nikan ni ẹni na ti ododo rẹ dangajia to niwaju Ọlọrun, laye, lọrun ati ni isalẹ ilẹ, lati bere ohunkohun lọwọ rẹ, ki O si ṣẹ. Nitori idi eyi, ti a ko ba fẹ ki aiṣododo tabi ẹṣẹkẹṣe pa adura wa si Ọlọrun lara, orukọ Jesu ni a gbọdọ fi ma gbadura.

AWỌN NKAN WO NI O YẸ KI A MA GBADURA NIPA?
Wayi o, a fẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ wa lori adura gbigba nipa ṣiṣe agbeyẹwo awọn nkan ti o yẹ ki a ma bere lọwọ Ọlọrun ninu adura wa. Ki ni awọn nkan na ti o yẹ ki a ma ba Ọlọrun sọ ninu adura wa? Bi a ṣe ri ninu bibeli, gbogbo nkan ti o ni ṣe pẹlu aye wa ni o yẹ ki a ma ba Ọlọrun sọ ninu adura.

Bi mo ti ṣe ṣalaye fun wa ṣeyin, ọkan pataki lara idi ti Ọlọrun ṣe fẹ ki a ma gbadura si Oun ni ki a ba le fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han. O fẹ ki a ma fi gbogbo igba fihan nipasẹ adura gbigba pe ko si ohunkohun ti a le da ṣe lalai fi tiẹ ṣe. Ma gbagbe pe ko di igba ti a ba gbadura si Ọlọrun ki O to mọ aini tabi isoro wa. Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo ni Oun jẹ. Nitorina, ko ki se awọn ọrọ ti a ba sọ si i nigba ti a ba n gbadura ni yo jẹ ki O mọ awọn nkan ti a nilo ni aye wa. O ti mọ awọn nkan wọnyi gan ki a to mọ wọn. Ṣugbọn nipa gbigba adura, a wa naa n fi han pe oye ye wa pe a ko le da ohunkohun ṣe lalai si Ọlọrun.

Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, ko si nkankan, o kere ni tabi o tobi ni, nipa aye wa ti ko yẹ ki a fa le Ọlọrun lọwọ ninu adura. A si wa ri pe Jesu Kirisiti, Oluwa wa ti a n tẹlẹ, gan ti fi aye rẹ ṣe apejuwe pe gbogbo nkan ti o ni i ṣe pẹlu aye wa ni o yẹ ki a ma ko le Ọlọrun lọwọ ninu adura. O sọ eyi ninu ọrọ rẹ si awọn Juu lọjọ kan: “Loootọ, loootọ ni mo wi fun yin, ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun ara rẹ, bi ko ṣe ohun ti o ba ri pe Baba n ṣe, wọnyi ni ọmọ si n ṣe bẹẹ gẹgẹ.” (Johanu 5:19) A ri nibi yi pe Jesu funrarẹ gan gba pe ko si ohun kankan ti Oun le da ṣe lai fi ti Baba rẹ, Ọlọrun, ṣe. Idi si niyi ti O fi n fi gbogbo igba gbadura si i lori ohun gbogbo. A ti lẹ fun wa ni awọn apẹẹrẹ ninu bibeli lori bi O ṣe gbadura ki O to yan awọn ọmọ ẹyin rẹ, bi O ṣe gbadura ki O to ji Lasaru dide, bi O ṣe gba adura ọpẹ ni awọn igba ti O fi ounjẹ kekere bọ ọpọ eniyan, bi O ṣe gbadura fun awọn Ọmọ ẹyin rẹ ki O to tọ iku ori igi agbelebu wo ati bi O ṣe gbadura si Ọlọrun nipa iku rẹ. (Wo: Matiu 14:15-21; Maaku 1:35&6:46-48; Luuku 6:12-16; 22:41-44; Johanu 11:41-42; Johanu 17; Heberu 5:7)

Pọọlu na wa ba awa naa sọrọ lori eyi ninu lẹta rẹ si awọn ara Filipi. O wi pe, “Ẹ ma ṣe ṣe aniyan nipa ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ maa beere ohun wọn-ọn-ni ti ẹ fẹ lọwọ Ọlọrun.” (Filipi 4:6) Ki ni ohun akọkọ ti Pọọlu sọ fun wa ninu ẹṣẹ bibeli yi? Ohun na ni pe ki a ma ṣe ṣe aniyan nipa ohunkohun. Si ri wi pe ko sọ pe ki a ma ṣe ṣe aniyan nipa awọn nkankan. Dipo bẹ, o sọ wipe ki a ma ṣe ṣe aniyan nipa ohunkokun. Jesu gan tilẹ lo koko sọ eyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ. O ni ẹ ma ṣe ṣe aninyan nipa ohun ti ẹ o jẹ, ohun ti ẹ o mu, aṣọ ti ẹ o wọ tabi aye yin (Matiu 6:25&31).

Ki si ni idi ti ko fi yẹ ki a ma ṣe aniyan lori ohunkohun? Idi ni pe aniyan wa ko le yi nkankan pada. Aniyan wa, arokan wa lori ọrọ aye wa ko le sọ oru di ọsan fun wa tabi ki o mu nkan ti ko to ki o to, ki o si tun ṣeku. Dipo bẹ, ọpọ igba ni o jẹ wipe aniyan ṣiṣe a kan tun fa aarẹ si agọ ara wa ni tabi ki o jẹ ki a ṣi iwa wu tabi ṣi ẹṣẹ gbe. Nigba ti eyi si ri bẹ, aṣẹ Ọlọrun fun wa nipasẹ Ọmọ rẹ Jesu ati apositeli rẹ Pọọlu ni pe a ko gbọdọ ṣe aniyan lori ohunkohun. A ko gbọdọ jẹ ki ọrọ aye wa, iṣẹ wa, awọn ọmọ wa tabi ilu wa jẹ ki a dorikodo ma ronu.

Ṣugbọn ṣe ki a wa ma wọ ọrọ aye wa ni ran ni? A bi ki gan an ni Ọlọrun fẹ ki a ṣe lori awọn ipenija, aini tabi idojukọ aye wa, nigba ti O ni ki a ma ṣe aniyan nipa wọn? A ṣa le wa ma wo wọn niran ki wọn ma bajẹ si? Lotitọ, Ọlọrun ko fẹ ki a ṣe aniyan lori ohunkohu, boya o kere ni tabi o pọ. Sibẹsibẹ na, ko fẹ ki a ma wo ọrọ aye wa niran. Dipo bẹ, O fẹ ki a gbadura si Oun lori wọn.

Nitorina, Pọọlu sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli ti o wa loke yi pe, “…ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹbẹ pẹlu idupẹ, ẹ maa beere ohun wọn-ọn-ni ti ẹ fẹ lọwọ Ọlọrun.” Njẹ o ri bayi? Ninu ki ni o ti yẹ ki a ma gbadura si Ọlọrun? Ninu ohun gbogbo! O tun mọ si pe ohunkohun ti o ba ti wa si ọkan wa lori ọrọ aye wa ni o yẹ ki a fi le Ọlọrun lọwọ. A ko gbọdọ ro pe awọn nkankan wa ti ko kan Ọlọrun tabi ti ipa wa ka. Ma jẹ ki n tan ọ, ko si nkan ẹyọkan bayi, bi o ti wulẹ ki o kere tabi rọrun to ni oju wa, ti apa wa ka, ti Ọlọrun ko ba fun wa ṣe. Nitori eyi, yala ọrọ ile rẹ ni, ti ilẹ rẹ ni, ti ẹkọ rẹ tabi ẹkọ awọn ọmọ rẹ ni, ti ẹya ara rẹ ni, ti adugbo rẹ ni, ti awọn obi rẹ ni, ti awọn ọrẹ rẹ ni, ti iyawo rẹ ni, ti ọkọ rẹ ni, ti ile isẹ rẹ ni, ti awọn ọta ti o n yọ ọ lẹnu ni, ti iṣẹ iranṣẹ rẹ ti, ti ounjẹ ti o fẹ jẹ ni, ti awọn olori orilẹ-ede rẹ ni, ti nkan ọgbin rẹ ni, ti ẹṣẹ ti o da ni tabi ti irin ajo rẹ ni, fa le Ọlọrun lọwọ ninu adura, ki o si sọ ohun ti o ba fẹ ki o ṣe lori rẹ fun un. Ma ṣe jẹ ki o ro ọ loju rara lati ṣe. Nitoripe Ọlọrun funrarẹ gan ti ṣetan lati da ọ lohun ki o tilẹ to bere rara.

Lotitọ, ọpọ igba ni o ma n ṣoro fun wa lati mọ nkan ti a fẹ ba Ọlọrun sọ ti a ba n gbadura. Nṣe ni yo kan ti lẹ dabi igba ti ẹnikan ti ra wa niye, ki a ma ba mọ ohun ti o tọ fun wa lati bere. Idi ni yi ti bibeli ṣe so wipe, “Bẹẹ gẹgẹ ni Ẹmi mimọ n ran wa lọwọ pẹlu ninu ailera wa: nitori a ko mo bi a ti n gbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmi mimọ tikararẹ n fi irora ti a ko le fi ẹni sọ bẹbẹ fun wa. Ẹni ti o si mo ohun ti n bẹ ninu eniyan, o mọ ohun wọn-ọn-ni ti Ẹmi n wi, nitori ti o n bẹbẹ fun awọn eniyan gẹgẹ bi ifẹ Ọlorun.” (Roomu 8:26-27) Kaasa! Gbogbo wa ni o ni ailera ailoye to lori awọn nkan ti o yẹ ki a ma gbadura nipa. Ṣugbọn niwọn igba ti Ẹmi Ọlọrun ti n gbe inu wa, O ṣetan lati ma fi igba gbogbo ran wa lọwọ lati gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun. Nitorina, bi o tilẹ jẹ wipe a kan n gbin ninu irora ni, ti ọrọ ta fẹ sọ gan ko ye wa, Ẹmi Ọlọrun to mọ ero ọkan wa delẹ mọ iru nkan ti o yẹ ki a ba Ọlọrun sọ. Oun yoo si ri pe Oun lo gbingbin ati irora ọkan wa lati ba Ọlọrun sọ ọ. O si di dandan ki O dahun adura wa. Yatọ si eyi, ti ba fi ara wa jin lati ka bibeli wa daradara, o di dandan ki a ri ọpọlọpọ ẹkọ kọ lori irufẹ awọn nkan ti o yẹ ki a ma bere lọwọ Ọlọrun ninu adura ati awọn eyi ti ko yẹ ki a ma bere.

ỌRỌ IPARI
Ni kukuru, ko si nkankan ti ko yẹ ki a ma ba Ọlọrun sọ ninu adura. Ohun gbogbo ti o ni ṣe pẹlu aye wa ni o yẹ ki a ma fa le lọwọ nipasẹ adura wa, nitoripe ko si ohun kan ṣoṣo ti a le da yanju funra wa. Ti a ba si wa ri pe ọrọ ko fẹ dun lẹnu wa tabi pe a kan le gbin tabi fi ọkan ṣọrọ nikan ni, ki a ma ṣe foya rara. Dipo eyi, ki a tẹsiwaju ninu adura wa pẹlu gbigbin tabi fi fi ọkan wa ba Ọlọrun sọrọ. Idi si ni pe Ẹmi Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo ti o jẹ aini wa mọ bi yo ṣe jẹ ki ẹbẹ adura wa de iwaju Ọlọrun, ki o si tun jẹ itẹwọgba pẹlu.

IBEERE
– Njẹ a ti lẹ ri awọn nkankan lori aye wa ti ko yẹ ki a filọ Ọlọrun rara ninu adura?
– Ki ni o jẹ pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – NI ORUKỌ TANI O YẸ KI A MA GBADURA? (AYỌKA: JOHANU 16:23-28)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 23, OWEWE 2020

AKỌRI: ADURA – NI ORUKỌ TANI O YẸ KI A MA GBADURA?
AYỌKA: JOHANU 16:23-28

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
A n tẹsiwaju losẹ yi lori ẹkọ ti a n kọ nipa adura gbigba. Ti a ba gbagbe, a bẹrẹ ẹkọ yi latori pataki ẹkọ adura. A sọ wipe o ṣe pataki ki a kọ bi a ṣe n gbadura ki a ma ba ma gba agbadanu adura. A tun tẹsiwaju lati wo tani o tọ ki a ma gbadura si ati idi ti o fi tọ ki a ma gbadura si. A si ri pe Ọlọrun ti o da ọrun ati aye nikan ni o tọ, ti o si yẹ ki a ma gbadura si. Yato si eyi, a tun ṣe agbeyẹwo idi ti Ọlọrun se fẹ ki a ma gbadura si Oun, bi o tilẹ jẹ wipe O mọ aini wa gbogbo, ko si di igba ti a ba gbadura si ko to mọ ojuṣe tabi ẹtọ rẹ lori aye wa. A si ri wipe ki a ba ma ba gbagbe rẹ ṣugbọn ki a ba ma fi igba gbogbo ranti pe a ko le da ohun kankan ṣe lalai fi tiẹ ṣe ni O ṣe fẹ ki a ma gbadura si.

NI ORUKỌ TANI O YẸ KI A MA GBADURA?
Wayi o, a fẹ tẹsiwaju ninu ẹkọ wa lori adura gbigba nipa wiwo orukọ ti o yẹ ki a ma lo lati gbadura. Bi mo ti ṣe sọ ninu awọn ẹkọ ti a kọ sẹyin, awọn eniyan ti n gbadura lati igba ti a ti bi Enọsi, ọmọ Sẹti, ọmọ Adamu. Ṣugbọn ẹṣẹ ko jẹ ki nkan lọ deede mọ laarin awọn ati Ọlọrun. Ki ẹṣẹ to wọle sinu aye Adamu ati Efa, ko digba ti wọn ba to bere nkan lọwọ Ọlọrun ki O to ṣe e fun wọn. Bi a tilẹ ṣe ri ninu bibeli, gbogbo nkan ti wọn nilo lati gbayegbadun ni Ọlọrun ti pese silẹ ki o to da wọn. Wọn kan de ile aye bẹrẹ si ni gbadun ni. Ṣugbọn ni kete ti ẹṣẹ wọle ni ohun gbogbo yipada. O si wa di pe ti awọn eniyan ko ba fi igbẹkẹle wọn ninu Ọlọrun han nipa bibere awọn nkankan lọwọ rẹ, o le ma bọ si wọn lọwọ.

Yatọ si fifi igbẹkẹle wa ninu Ọlọrun nipa gbigba adura si i, a tun ri pe a gbọdọ fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han nipa irufẹ iwa ti a n wu. Eyi tunmọ si pe ti a ba nigbagbọ ninu Ọlọrun nitootọ, a o ma ṣe ifẹ rẹ ni ọna gbogbo. Ti a ba wa kọ jalẹ lati ṣe ifẹ rẹ, ti o si jẹ pe ifẹ ti ara wa ni a n ṣe, o di dandan ki eyi pa adura wa lara. Fun apẹẹrẹ, bibeli sọ eyi fun wa: “Ẹni ti o mu eti rẹ kuro lati gbọ ofin, ani adura rẹ paapaa yoo di irira.” (Iwe owe 28:9) O tun sọ nibomiran pe, “Kiyesi i, ọwọ Oluwa ko kuru lati gbani, bẹẹ ni eti rẹ ko wuwo ti ki yoo fi gbọ. Ṣugbọn aiṣedeede yin ni o ya yin kuro lọdọ Ọlọrun yin, ati ẹṣẹ yin ni o pa oju rẹ mọ kuro lọdọ yin, ti oun ki yo fi gbọ.” (Aisaya 59:1-2)

Njẹ iwọ naa ri bayi? Niwọn igba ti ẹṣẹ ba wa ninu aye eniyan, ko si bi ko ṣe ni pa adura rẹ lara, lọna kan tabi omiran. Iwa ika n pa adura lara. Agbere n pa adura lara. Ojukokoro n pa adura lara. Ipaniyan n pa adura lara. A si wa ri pe ko si ẹnikan laarin gbogbo awa ọmọ eniyan ti ko ni ẹṣẹ kan tabi omiran ninu aye rẹ. O le jẹ ẹṣẹ to farasin ni o tabi ẹṣẹ ti ko ja mọ nkankan loju awa ti a jẹ eniyan. Ṣugbọn niwaju Ọlọrun, ẹṣẹ ni ẹṣẹ n jẹ, ko si eyi to kere tabi ti o tobi. Ọpọ awọn nkan ti a n ṣe ti o dabi eni pe o dara jọjọ loju wa gan lo jẹ pe ko ni itunmọ si Ọlọrun, niwọn igba to jẹ wipe awọn idi ti a fi n ṣe awọn nkan wọnyi gan ko mọ niwaju rẹ.

Idi si niyi ti bibeli fi ṣọ wipe, “Gbogbo wa si dabi ohun aimọ, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bii afẹfẹ.” (Aisaya 64:6) O tun sọ siwaju pe, “Gbogbo eniyan ni o ṣaa ti ṣẹ, ti wọn si kuna ogo Ọlọrun.” (Roomu 3:23) Kiyesi pe bibeli tẹnumọ pe gbogbo eniyan patapata ti o ti ipaṣẹ Adamu baba nla wa wa ni o ti ṣẹ si Ọlọrun, ti o ti di ohun aimọ niwaju rẹ, ti gbogbo ododo wọn ko si jamọ nkankan niwaju rẹ. O tun wa fidẹ rẹ mulẹ pe gbogbo wa pata loti kuna ogo Ọlọrun nitori ẹṣẹ ti o wa ni aye wa. Eyi tunmọ si pe ko si ẹnikankan lara wa ti o duro pe tabi ti o dangajia niwaju rẹ lati bere nkankan lọwọ rẹ ati lati rigba. A ti kuna. Ko si si nkan rere kankan ti o tọ si wa. A ko tilẹ lẹnu ọrọ rara niwaju Ọlọrun. Nkan ẹyọkan ti o tọ si wa naa ni idajọ iku.

Ranti pe bibeli sọ fun wa pe, “Iku ni ere ẹṣẹ…” (Roomu 6:23) Niwọn igba ti o si jẹ pe ẹlẹṣẹ ni gbogbo wa nipaṣẹ ajọbi wa ninu Adamu, iku ohun gbogbo nikan na lo tọ si wa. Ko si nkan rere kan ti a le sọ pe a lẹtọ lati bere ki a si ri gba lọwọ Ọlọrun. O wa jasi pe gbogbo nkan rere ti o n bọ si wa lọwọ, ti a si n jẹ gbadun ko tọ wa wa nitori pe a pe tabi mọ tabi dangajia ninu ododo niwaju Ọlọrun. Aanu ati oju rere lasan ni a ri gba. O si yẹ ki a ma fi gbogbo igba dupẹ gidigidi lọwọ rẹ fun eyi. Ẹni ti eyi ko ba wa ye, ti o ro pe oun ni ododo kan lati ṣogo niwaju Ọlọrun n tan ara rẹ jẹ ni. Ko si adura rẹ kankan ti yo jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun. (Wo, Luuku 18:9-14)

Sibẹsibẹ, nkan ti Ọlọrun fẹ fun wa kọ ni eyi. Ọlọrun ko fẹ ki a jinna si rara tabi ki ẹṣẹ ma jẹ ki a gbadun ibaṣepo wa pẹlu rẹ. Idi eyi ni o fi ran ọmọ rẹ Jesu Kirisiti, ti a ko bi nipaṣẹ Adamu ṣugbọn nipaṣẹ Ẹmi mimọ lati wa si aye lati fi han wa irufẹ eniyan ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ ati lati ku fun ẹṣẹ wa, ki ọna ba le ṣi fun wa lati sunmọ Ọlọrun nigbakugba lai si idiwọ ati lati bere ohunkohun lọwọ rẹ lai ni idena ẹṣẹ. A si ri pe Jesu yi nikan na ni ẹni kan ṣoṣo ti o duro de e de niwaju Ọlọrun ni ọna gbogbo, ti ko ni abawọn tabi eeri ẹṣẹ kankan. Gbogbo igba ni O fi n ṣe nkan ti o tẹ Ọlọrun lọrun (Johanu 8:29). Ọlọrun paapaa sọ eyi nipa rẹ, “Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹni ti inu mi dun si gidigidi.” (Luuku 3:22)

Nitorina, Jesu nikan ni o ni ododo ti o peye niwaju Ọlọrun gẹgẹ bi eniyan. Nitorina, Ọlọrun ti buyi ati ọla ati agbara fun orukọ rẹ, O si ti gbe orukọ naa ga ju gbogbo orukọ lọ. Orukọ rẹ ga ju orukọ gbogbo eniyan, angẹli ati gbogbo nkan ti Ọlọrun da lọ. Ni orukọ yi si ni gbogbo eekun gbọdọ wolẹ, ki wọn si jẹwọ rẹ gẹgẹ bi Oluwa lori ohun gbogbo ti Ọlọrun da, fun iyi ati ogo Ọlọrun. (Wo: Filipi 2:6-11; Heberu 1:4-14)

Niwọn igba ti awọn nkan yi si ribẹ, ti ẹnikẹni ba fẹ tọ Ọlọrun wa, ti ko si fẹ ki ẹṣẹ tabi ohunkohun di ohun lọwọ, ni orukọ Jesu ati nipasẹ ododo rẹ ni o yẹ ki o ṣe eyi. Nkan ti mo n sọ nipe ẹnikẹni ti ko ba fẹ ki ẹṣẹ ohun, kekere ni o tabi nla ni, ki o di oun lọwọ lati ba Ọlọrun rin tabi ki o dena adura oun, nipasẹ Jesu ni o yẹ ki o lọ. Idi si ni yi ti Jesu funrarẹ ṣe sọ awọn nkan wọnyi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ:

“Ati ni ọjọ naa ẹyin ki o bi mi leere ohunkohun. Loootọ, Loootọ ni mo wi fun yin, ohunkohun ti ẹyin ba beere lọwọ Baba ni orukọ mi, oun o fifun yin. Titi di isisinyi ẹ ko ti i beere ohunkohun ni orukọ mi: ẹ beere, ẹ o si ri gba, ki ayọ yin ki o le kun. Nnkan wọnyi ni mo ti fi owe sọ fun un yin: ṣugbọn akoko de, nigba ti emi ki yoo fi owe baa yin sọrọ mọ, ṣugbọn emi o sọ ti Baba fun yin gbangba. Ni ọjọ naa, ẹyin o beere ni orukọ mi: Emi ko wi fun yin pe emi o beere lọwọ Baba fun yin: Nitori ti Baba tikararẹ fẹran yin, nitori ti ẹyin ti fẹran mi, ẹ si ti gba pe lọdọ Ọlọrun ni emi ti jade wa.” (Johanu 16:23-27)

A ri daju ṣaka ninu awọn ọrọ ti Jesu sọ silẹ yi pe O n fi idi rẹ mulẹ fun wa pe orukọ Oun nikan ni o yẹ fun wa lati ma fi gbadura si Ọlọrun Baba. Gẹgẹ bi Oun na se fihan ninu gbolohun rẹ si awọn ọmọ ẹyin wọnyi, wọn ti n gbadura tẹlẹ ki wọn to ba pade. Wọn ko si ṣiwọ adura gbigba lẹyin igba ti wọn ti ba pade. Ṣugbọn ni orukọ ẹnikọọkan wọn ati idile rẹ ni o n gbadura. Ni ori ododo ara wọn si ni adura wọn duro le lori. Amọọ, bi a si ti ṣe sọ tẹlẹ, ko si ẹnikankan lara wa ti o ni orukọ tabi ododo ti o koju osuwọn tabi ti o dangajia lati ri nkankan gba lọdọ Ọlọrun tabi lati tilẹ sun mọ. Nitorina, a ko ni aye lati ba Ọlọrun ṣe pọ lọna ti ko ni odiwọn. A ko si ni ododo kankan ti o le ki wa laya lati sọ pe ki O ṣe nkankan fun wa. Aanu rẹ na ni a gbọdọ ma fi gbogbo igba tọrọ.

Ṣugbọn Jesu ti wa fun wa ni aṣẹ lati sunmọ Ọlọrun nipasẹ orukọ ati ododo tirẹ. Niwọn igba ti a ba si tọ Ọlọrun wa nipaṣẹ orukọ ati ododo rẹ, ko si ki O ma da wa lohun. Ko ni wo ẹṣẹ wa rara, nitori Jesu ti san gbese wọn. Dipo bẹ, ododo ati ọla Jesu, ẹni ti o san gbese gbogbo ẹṣẹ wa, ni yoo ma fi gbogbo igba wo mọ wa lara. Idi niyi ti Pọọlu ṣe wa sọ fun wa pe, “Ninu ẹni ti awa ni igboya ati igbagbọ lati tọ Ọlọrun lọ laibẹru ohun kan.” (Efesu 3:11)

Njẹ iwọ na ri bayi? Ninu Jesu nikan ni a ti igboya ti o peye lati tọ Ọlọrun wa laibẹru nkankan. Ninu ẹṣẹ wa, a ko ni igboya lati tọ Ọlọrun wa tabi lati bere ohunkohun ni ọwọ rẹ. Ṣugbọn ninu Jesu ẹṣẹ wa ti di ohun igbagbe, nitori pe O ti san gbese gbogbo rẹ. Bakanna, ninu awọn eniyan bi ti wa, a ko ni igboya lati tọ Ọlọrun wa. Nitoripe gbogbo eniyan ni o ti ṣẹ, ti wọn si ti kuna ogo Ọlọrun. Idi si ni yi ti ko fi tọna lati ma gbadura ṣi Ọlọrun ni orukọ eniyan kankan, boya o wa laye ni o tabi ko si ni aye. Ko tọna lati ma tọ Ọlọrun wa ni orukọ Maria iya Jesu tabi ni orukọ Peteru aposteli Jesu tabi ni orukọ wooli, ajinhinrere tabi alufa kankan. Gbogbo awọn wọnyi na lo nilo ododo Jesu ki wọn to le ba Ọlọrun rin ni pipe ati yiyẹ. Ko wa yẹ ki a fi ẹni ti o mu wa yẹ silẹ, ki a si ma tele awọn ti O muyẹ.

Lafikun, bi mo si ti ṣe sọ siwaju, bibeli jẹ ki o ye wa pe ko si angẹli tabi ẹda ọrun kankan ti ododo rẹ to ti Jesu niwaju Ọlọrun tabi ti orukọ rẹ ni iyi tabi ọla bi ti Jesu niwaju rẹ. Johanu tilẹ fi idi eyi mulẹ ninu akọsilẹ ifihan ti o ri pe Jesu nikan ni o yẹ niwaju Ọlọrun lati gba iwe edidi kan ni ọwọ rẹ, nibi ti a ko ti ri ẹda kankan ni ọrun, ni aye ati ni isalẹ ilẹ ti o yẹ lati gba. Gbogbo awọn ẹda ọrun ni wọn si n juba rẹ gẹgẹ bi ẹnikan ṣoṣo ti ọla ati ogo ati agbara tọ si. (Wo: Ifihan 5)

Ṣe o wa yẹ ki a fi orukọ ati ododo Jesu silẹ, ki a si ma lo orukọ awọn angẹli kan, bi Geburẹli tabi Maikẹli, lati gbadura si Ọlọrun? Ko yẹ rara. Ko si ni itunmọ. Irufẹ adurakadura ti a ba si gba nipa ṣiṣe eyi jẹ adura asan. O wa ṣe e ṣe o, ki o dabi ẹni pe Ọlọrun n gbọ ti wa, bi o tilẹ je pe a n gbadura lodi si ifẹ rẹ. Jẹ ki o ye ọ pe ko ki i ṣe nitori adura wa ni Ọlọrun ṣe n da wa lohun. Rara o. Nitori ifẹ rẹ si wa ni O ṣe n da wa lohun ninu aimọkanmọkan wa. Ṣugbọn nigba ti O ba ti duro titi de wa lati kẹkọ ọrọ rẹ, ti a ko si kọ lati kẹkọ, yoo wa bẹrẹ si ni jẹ ki o ye wa pe agbadanu adura ni a n gba. Idi si niyi ti awọn kan ko fi ni itẹsiwaju to jamọ nkankan mọ, bi o tilẹ jẹ wipe wọn n gbadura lọpọ. Ọlọrun kan fẹ ki o ye wọn wipe gbigbadura lọpọ nikan ko to lati ri idahun si adura wa gba; a tun gbọdọ gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ. Ara ifẹ rẹ si ni pe ohunkohun ti a ba fẹ bere lọwọ rẹ, ki a bere rẹ ni orukọ ọmọ rẹ Jesu ati ninu ododo rẹ.

ỌRỌ IKẸYIN
Jesu nikan ni ẹni na ti o ni ododo, laye, lọrun, nisalẹ ilẹ, ti o peye niwaju Ọlọrun lati ri ohunkohun gba ni ọwọ rẹ. Oun kan yi naa si tun ni o fi ẹjẹ rẹ ra wa pada ki a ba le duro bi ẹni ti o peye niwaju Ọlọrun. Nitorina, ti a ba fẹ gbadura, ni orukọ rẹ ni o yẹ ki a ma tọ Ọlọrun lọ. Eyi wa lara nkan ti ko ni jẹ ki adura wa jẹ agbadanu.

IBEERE
– Ki ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ J. Oluwatoosin Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – KINNI IDI TI ỌLỌRUN ṢE FẸ KI A GBADURA SI? AYỌKA: LUUKU 11:1-4

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 16, OWEWE 2020

AKỌRI: ADURA – KINNI IDI TI ỌLỌRUN ṢE FẸ KI A GBADURA SI?
AYỌKA: LUUKU 11:1-4

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ninu ẹkọ bibeli ti a kọ kẹyin lori adura gbigba, a ri awọn idi ti o fi jẹ pe Ọlọrun nikan ni o tọ ki a ma gbadura si. Idi akọkọ ni pe Ọlọrun ni ẹlẹda ati ẹni ti o ni ohun gbogbo. Nitorina, ti a ba nilo nkankan, Oun nikan ni o koju osuwọn lati da wa lohun lalai dakun iṣoro wa. Idi ẹkeji ni pe baba ni Ọlọrun jẹ fun wa, bi o tilẹ jẹ wipe ọpọ ni ko mọ eyi. Baba ti o si mọ ojuṣe rẹ pelu ni o jẹ. Nitorina, niwọn igba ti a ba ti fi akoso aye wa ati ohun gbogbo ti a nilo le ni ọwọ gẹgẹ bi baba wa, ko si ni ki aye wa ma dara, ki o si tun nitunmọ, ni ibamu pẹlu eto rẹ fun aye wa.

KINNI IDI TI ỌLỌRUN ṢE FẸ KI A GBADURA SI?
Ṣugbọn o tun wa yẹ ki a mọ idi ti Ọlọrun ṣe fẹ ki a ma gbadura si Oun. Eyi si ṣe pataki nitoripe niwọn igba to jẹ pe Ọlọrun ni ẹlẹda ati ẹni ti o ni ohun gbogbo, ti o si tun jẹ wipe baba ni O jẹ fun wa, ko yẹ ki O ṣẹṣẹ duro de igba ti a ba gbadura si ki O to mọ tabi ṣe ojuṣe rẹ lori aye wa. Jesu Oluwa wa gan tun fi idi eyi mulẹ nigba ti O n kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ lori adura gbigba. O sọ wipe,”Ṣugbọn nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma ṣe atunwi asan bi awọn keferi; wọn sebi a o titori ọrọ pupọ gbọ ti wọn. Nitori naa ki ẹyin ma ṣe dabi wọn. Baba yin saa mọ ohun ti ẹyin ṣe alaini ki ẹ to beere lọwọ rẹ.” (Matiu 6:7-8) O tun tẹsiwaju lati sọ wipe, “Nitori naa, ẹ ma ṣe ṣe aniyan, wi pe, kin ni a o jẹ, tabi kin ni a o mu, tabi aṣọ wo ni a o wọ? Nitori gbogbo nnkan wọnyi ni awọn keferi n wa kiri. Nitori Baba yin ti n bẹ ni ọrun mọ pe ẹyin ko le ṣe alaini gbogbo nnkan wọnyi.” (Matiu 6:31-32)

Njẹ o ri bayi pe ko digba ti a ba gbadura si Ọlọrun, ti a ke, ti a fẹfun too, ki O to mọ nkan ti a fẹ tabi ti a nilo? Ọlọrun ti o mọ ohun gbogbo, ti o si lagbara lori ohun gbogbo ni Oun jẹ. O si le tọju wa, ki O da abo bo wa, ki O si tun mojuto gbogbo aini wa lailai ṣe pe a gbadura si. Fun apẹẹrẹ, a ri eyi ka ninu iwe Jẹnẹsisi, ori ikeji, ẹsẹ ikejidinlogun: “Oluwa Ọlọrun si wi pe, Ko dara ki ọkunrin naa ki o nikan maa gbe; Emi oo se oluranlọwọ ti o dabi rẹ fun.” Iwọ na gbe eyi yẹwo. Ọlọrun funrarẹ ni o kọkọ ṣe afẹri ati afihan aini Adamu, ọkunrin akọkọ. Oun lo kọkọ sọ wipe ko dara ki Adamu nikan ma da gbe – o nilo oluranlọwọ ti o dabi tirẹ. Ko si wa ṣe pe Ọlọrun kan tọka si aini Adamu nikan; O tun gbe igbesẹ lati tan aini na. O pese iyawo rere fun un. (Wo: Jẹnẹsisi 2:21-25)

Nibakanna, ọpọ ohun rere ti a n jẹ gbadun laye yi lo jẹ wipe Ọlọrun n pese rẹ fun wa lai ṣe wipe a gbadura si i. A ko tilẹ le gbadura to gan. Ti o ba si jẹ wipe oṣunwọn ti a fi n gbadura na ni Ọlọrun n lo lati da wa lohun ni, ọpọ wa ni ko ba ti di jatijati tabi ki o ti sọ ẹmi rẹ nu. Titori eyi gan ni Pọọlu ṣe sọ fun wa nipa Ọlọrun pe, “Njẹ, fun ẹni ti o le ṣe lọpọlọpọ ju eyi ti a n beere tabi ti a n ro lọ gẹgẹ bi agbara ti n ṣiṣẹ ninu wa.” (Efesu 3:20) Kiyesi eyi daradara, ki o si fi sọkan lati le ma samulo rẹ: Ọlọrun le se lọpọlọpọ ju ẹbẹ adura wa tabi ero ọkan wa lọ.

Nigbati eyi si ribẹ, ki wa gan lo de ti Ọlọrun ko kuku fi tẹsiwaju lati ma tan aini wa lalai duro de igba ti a ba to gbadura si? Abi ṣe o kan wu u lati da wa laaamu tabi lati fi han wa pe Oun le ṣe ohunkohun ti o ba wu u ni O ṣe fẹ ki a ma gbadura si Oun? Eyi ko ri bẹ rara. Bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun lagbara lati ṣe ohun ti o ba wu, ti ẹnikẹni ko si le e yẹ lọwọ wo, Oun ko ki i se Ọlọrun ti o ma n ṣi agbara lo. Awọn idi pataki wa ti O ṣe fẹ ki a ma gbadura si Oun ki O to ṣe awọn nkankan fun wa tabi laye wa. Awọn idi pataki na si ni yi:

– Ki a ba le mọ pe ko si nkankan ti a le ṣe lai si Ọlọrun: Solomọni ninu orin rẹ kan sọ wipe, “Bi ko ba ṣe pe Ọluwa ba kọ ile naa, awọn ti kọ ọ n ṣiṣẹ lasan; bi ko ba ṣe pe Oluwa ba pa ilu mọ, oluṣọ ji lasan.” (Saamu 127:1) Jesu Oluwa wa naa si sọ wipe, “…ni yiyara yin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kankan.” (Johanu 15:5) Awọn ẹsẹ bibeli yi ati awọn miran bi tiwọn n fi ye wa pe lai si Ọlọrun ko si ohunkohun ti a le da se tabi da ni. Eyi ko si ṣokunkun rara si Adamu, Efa ati awọn ọmọ ti wọn kọkọ bi. Idi si niyi ti o ṣe jẹ pe awọn ni o kọkọ bẹrẹ si ni gbadura si Ọlọrun (Jẹnẹsisi 4:25-26). Ṣugbọn bi ẹṣẹ ṣe n gberu si naa ni oye pe ko si nkankan ti a le da ṣe tabi da ni ṣe n sọnu si laarin awọn ọmọ eniyan. Nitorina ni o se jẹ wipe ọpọ igba ni awọn eniyan a ma fi ogo ati ọla ti o yẹ ki wọn fun Ọlọrun lori aṣeyọri, alaafia tabi ibalẹ ọkan wọn fun ara wọn tabi fun awọn orisa kekeke ti wọn n sin. Idi si niyi ti Ọlọrun fi ma n mọnmọn jẹ ki a dojukọ awọn ipenija kan ti yoo jẹ ki a mọ pe agbara wa, ipa wa, ọgbọn wa, iyi wa, awọn eniyan ti a mọ tabi awọn orisa ti a n bọ ko ni agbara kankan lati gba wa la, fun wa ni ayọ, gbe wa ga tabi fun wa ni alaafia ti Oun Ọlọrun ko ba jẹ ki o ṣe e ṣe. Nkan ti mo n sọ naa ni wipe ti Ọlọrun ko ba fi aye awọn ipenija ti yo jẹ ki a ke pe ninu adura silẹ, ọpọlọpọ wa ni ko ni mọ pe lai fi tiẹ ṣe, aye wa ko le ni tunmọ; lai fi tiẹ se, ohunkohun ti a ba ro pe a ṣe, asan, ofo, naa ni yoo jasi nigbẹyingbẹyin. (Wo: Ise Aposteli 17:24-27) Idi wa niyi ti Jesu Oluwa wa ṣe fi apẹẹrẹ lele fun wa nipa gbigba adura si Ọlọrun. Ko fi adura gbigba si i ṣere rara, bi o tilẹ jẹ wipe ọkan ni awọn mejeeji jẹ. O tilẹ sọ eyi fun wa: “Lootọ, lootọ ni mo wi fun yin, ọmọ ko le ṣe ohunkohun fun ara rẹ, bi ko ṣe ohun ti o ba ri pe Baba n ṣe: nitori ohunkohun ti o ba n ṣe, wọnyi ni ọmọ si n ṣe bẹẹ gẹgẹ.” (Johanu 5:19) Eyi tunmọ si pe Jesu ko gbe ile aye lai fi ti Ọlọrun ṣe ninu ohun gbogbo. Abalajọ ti O fi ṣe aṣeyori lọna gbogbo ninu ifẹ Ọlọrun. Ti awa na ba si fẹ ṣe aṣeyọri lọna gbogbo bi tirẹ, ki a si tun gbe aye ti o nitunmọ, a gbọdọ fi ti Ọlọrun ṣe ni ọna gbogbo, ki a si ma fi igbekele wa ninu rẹ han ninu ohun gbogbo ti ba n ṣe.

– Ki a ma ba gbagbe Ọlọrun: Ọkan lara awọn nkan ti bibeli fi ye wa ni pe o ṣe e ṣe ki awa eniyan gbagbe Ọlọrun nigba ti a ba jẹun yo tan (Ditaronomi 8:10-20). Sebi bi o tilẹ jẹ wipe ẹṣẹ wọ inu aye wa wa nipa aigbọran baba ati iya wa akọkọ, a si ri pe awọn eniyan si n kepe orukọ Oluwa. Oun naa si n da wọn lohun lati fi ayọ kun ọkan wọn. (Wo: Jẹnẹsisi 4:25-26) Ṣugbọn nigba ti o ya, ti wọn bẹrẹ si ni lọla, ti wọn si n ṣawari awọn ẹbun ati nkan amuyẹ oriṣiriṣi ti Ọlọrun fun wọn lati gbe aye gbadun, ti nkan si bẹrẹ si ni lọ ni mẹlọmẹlọ fun wọn, wọn pa Ọlọrun ti, wọn si bẹrẹ si ni ṣe ohun ti o wu wọn. Eyi gan ni o jẹ ki Ọlọrun pinu lati pa aye igbanni rẹ pẹlu ikun omi. (Wo: Jẹnẹsisi 6:1-7) Nitorina, ti Ọlọrun ba n fi gbogbo igba ṣe nkan ti a fẹ tabi nilo lalai ṣe pe a bere lọwọ rẹ, lai si aniani, bopẹ boya, a o gbagbe pe ẹnikan tilẹ n bẹ ti o n jẹ Ọlọrun. Iwọ naa wo nkan ti Ọlọrun sọ pa awọn ọmọ Isiraẹli: “Gẹgẹ bi a ti bọ wọn, bẹẹ ni wọn yo, wọn si gbe ọkan wọn ga; nitori naa ni wọn ṣe gbagbe mi.” (Hosia 13:6) Njẹ iwọ naa o ha ti gbagbe Ọlọrun bi? Njẹ ara o wa ti tu ọ debi pe o ko tilẹ ranti pe Ọlọrun ni o n tọju rẹ, ti o si n jẹ ki ohun gbogbo lo dede fun ọ? Njẹ ko digba ti wahala ba bẹ silẹ ninu aye rẹ tan ki o to ranti pe lalai si Ọlọrun, aye rẹ ko le ja mọ nkankan?

ỌRỌ IPARI
Ọlọrun fẹ ki a ma gbadura si Oun ki a ba le fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han. Niwọn igba ti a ko ba si ma fi gbogbo igba fi igbẹkẹle wa ninu rẹ han, a jẹ wipe a ti gbagbe rẹ niyẹn – a ti gbagbe pe Oun ni o dawa, ti o si ni wa ati pe lai fi tiẹ ṣe, ofo ati asan ni aye wa ati arakara ti o wu ki a fi wọn da yoo jasi nigbẹyingbẹyin.

IBEERE
– Ṣe apẹẹrẹ meji ọna ti itura tabi ọrọ le gba jẹ ki awọn eniyan gbagbe Ọlọrun.
– Nkan wo ni o ṣe pataki julọ si ọ ninu ẹkọ yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com|alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – TANI O YẸ KI A GBADURA SI? (ẸSẸ BIBELI: LUUKU 11:1-4)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH (IJỌ OTITỌ BIBELI)
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
ỌJỌRU 9, OWEWE 2020

AKỌRI: ADURA – TANI O YẸ KI A GBADURA SI?
ẸSẸ BIBELI: LUUKU 11:1-4

CLICK HERE TO DOWNLOAD

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Ni ọsẹ ti o kọja, a bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo pataki ẹkọ adura. Ki ni adura? Adura, fun ọpọlọpọ eniyan, jẹ ọna ti a n gba ba Ọlọrun sọrọ. Otitọ si ni eyi. Sugbọn adura kọja ọna ti a n gba ba Ọlọrun sọrọ. Adura tun jẹ ọna ti a n gba fi igbẹkele wa ninu rẹ han. Lafikun, o tun jẹ ọna ti a n gba ri ipese rẹ gba. Yatọ si eyi, adura a ma fun eniyan ni ore-ọfẹ lati mọ Ọlọrun si. Bi a si ṣe fi han wa ninu bibeli, lati igba aye baba nla wa Adamu ni awọn eniyan ti n gbadura si Ọlọrun. Nitori eyi, gbogbo eniyan ni o yẹ ki o ma gbadura. Amọ, o wa ṣe pataki ki a kọ bi a ṣe n gbadura ki a ma ba ma gba agbadanu adura. Gẹgẹ bi bibeli ṣe fi idi rẹ mulẹ, adurakadura ti ko ba wa ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ko le jẹ itẹwọgba niwaju rẹ (1Johanu 5:14-15). Niwọn igba ti adura ko ba si jẹ itẹwọgba niwaju rẹ, ko si bi a ṣe fẹ gbadun rẹ bi o ṣe tọ ati bi o ṣe yẹ. Nitorina, o ṣe pataki ki ẹnikọọkan wa tiraka lati kẹkọ lati inu iwe mimọ nipa bi a ṣe n gbadura ti o ye koro, adura ti Ọlọrun ko le salai ma dahun.

TANI O YẸ KI A GBADURA SI?
Ibo wa gan ni o yẹ ki a ti bẹrẹ ẹkọ wa lori adura gbigba? Lati ori ẹni ti o yẹ ki a gbadura si ni. Ibẹ gan si ni Jesu Oluwa wa ti bẹrẹ nigba ti o n salaye fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lori bi a se n gbadura. O sọ wipe: “Nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma wi pe, Baba wa ti n bẹ ni ọrun…” (Luuku 11:2) O se ni laanu wipe ọpọ ti o ti fi ẹsẹ bibeli yi ṣe akọsori tabi akọmọna ni ko ki i kiyesi koko ọrọ ti o jẹ jade nibẹ. Wọn sa mọ si adura Oluwa, eyi ti o yẹ ki wọn ka loorekoore ninu isin ijọ wọn tabi ti wọn ti pari adura nibikan. Ṣugbọn, lakọkọ na, adura yi ko ki i ṣe adura Oluwa. Idi si ni pe Jesu ko gbadura ni ibi yi rara. Dipo bẹ, O n kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ ni bi a ṣe n gbadura ni. Ti a ba fẹ apẹẹrẹ adura Jesu, a le ka iwe iyinrere ti Johanu, ori ikẹtadinlogun. Nkan ekeji to tun se pataki nipa awọn ọrọ ti Jesu sọ ni ẹsẹ bibeli yi ati awọn eyi to tẹle ni pe akawe tabi apẹẹrẹ bi a ṣe le gbadura lasan ni wọn. Ete Jesu kọ ni pe ki a sọ wọn di akọmọna ti a o ma fi gbogbo igba ka. O kan sọ wọn ki a ba le mọ bi o ṣe yẹ ki a ma gbadura ni.

Ki a ma dena pa ẹnu, koko akọkọ ti a ri di mu ninu nkan ti Jesu sọ ninu ẹsẹ bibeli yi pe Ọlọrun nikan ni o tọ ki a ma gbadura si. Ki si ni idi ti o fi jẹ pe Ọlọrun nikan ni o tọ ki a ma gbadura si? Idi ni wipe:

– Ọlọrun jẹ Ẹlẹda ati ẹni ti o ni ohun gbogbo: Bibeli sọ wipe: “Ni atetekọṣe ni Ọlọrun da ọrun ati aye.” (Jẹnẹsisi 1:1) O si tun tẹsiwaju lati fi ye wa bi Ọlọrun ṣe da ohun gbogbo ti n bẹ ninu aye (Jẹnẹsisi 1:3-31). O wa kasẹ rẹ nilẹ nipa sisọ pe, “Ti Oluwa ni ilẹ ati ẹkun rẹ, aye, ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ.” (Saamu 24:1)Niwọn igba ti eyi si ri bẹ, o tunmọ si pe ikawọ Ọlọrun ni ohun gbogbo ti eniyan le nilo lati gbe aye gbadun ati lati gbe aye ṣerere wa. Enikẹni ko wa le ri ohun daradara ti ko si labuku kan gba bikoba sepe Ọlọrun fun. Ẹnikẹni ko si le ri nkankan ṣe ti ko ba ṣe pe Ọlọrun ba jẹ ki o se e se. (Wo: Saamu 127:1; Johanu 3:27; Jemisi 1:17) Ti a ba wa ri ẹnikẹni, a si ri ọpọ eniyan, ti o n gbadura si ẹnikẹni, ẹdẹkẹda, angẹli ki angẹli tabi ohunkohun yatọ si Ọlọrun, onitọhun n ṣe nkan ti ko tọ. Ki a si ma parọ, ibọriṣa gbaa ni. Idi si ni pe Ọlọrun ti o da ọrun ohun aye nikan ni Ọlọrun otitọ ati ododo. Ẹda rẹ ni gbogbo wa, gbogbo nkan ati gbogbo ẹda yoku jẹ, yala lọrun ni tabi ni aye. Iwa omugọ gbaa wa ni fun wa lati fi ẹlẹda wa silẹ lati tọ awọn nkan tabi ẹda ti O da lọ lori aini tabi amojuto aye wa. (Wo: 1Korinnti 8:4-6)

Lotitọ, ọpọ ni o n kopa ninu ibọrisa oriṣiriṣi, ti wọn si n rijẹrimu, ti won si tun n ni ilọsiwaju. Ṣe a wa lọ sọ wipe awọn orisa wọn n gbe wọn bi? Rara o. Jẹ ki o ye o wipe, ko ki i ṣe kiki awọn ti o mọ Ọlọrun, ti o si n sin nikan ni O dara si, ti O si n pese fun. Gẹgẹ bi bibeli ṣe fi han wa, Ọlọrun dara si gbogbo eniyan, bi wọn ko ti lẹ mọ. Idi si ni pe O fẹ ki wọn ni anfaani lati mọ ọ ati lati bẹrẹ si ni sin ninu ifẹ rẹ, ki wọn ba le gbadun didara rẹ si lai ni odiwọn. Amọ o, eyi ko tunmọ si pe ọwọ Ọlọrun na ni gbogbo nkan ti awọn abọrisa tabi awọn ti ko mọ Ọlọrun ni ti wa. Awọn nkan miran wa ti wọn ni tabi ti wọn da ti o jẹ nipasẹ agbara ẹmi Esu ni o ti wa. Irufẹ awọn nkan bayi ko si ni se alaimu ewu kan tabi omiran lọwọ nitori Ibukun Ọlọrun nikan ni o ma n pese fun eniyan lai mu ibanujẹ tabi wahala kankan lọwọ. Nitorina ma ṣe ṣe afarawe ẹnikeni ti o ba n bọriṣa lọna kan tabi omiran. Atunbọtan rẹ ko ni dara. (Wo: Iwe Owe 10:22; Ise Aposteli 14:15-17)

– Ọlọrun jẹ Baba fun wa: Jesu Oluwa wa, nigba to n sọrọ lori gbigba adura si Ọlọrun, sọ wipe, “Nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma wi pe, Baba wa ti n bẹ ni ọrun…” Eyi tunmọ si pe Baba ni Ọlọrun jẹ fun gbogbo awọn ẹda rẹ. Ki si ni iṣẹ baba? Iṣẹ baba ni lati pese fun awọn ọmọ rẹ ati lati mojuto wọn ki awọn na ba le dagba de ibi ti wọn o ti to oju bọ. Nitorina, iṣẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi Baba wa, ni lati pese fun gbogbo aini wa ati lati mojuto wa. Awa nikan kọ si ni O n pese fun tabi ti O n mojuto; gbogbo iṣẹ ọwọ rẹ ni O n pese fun, ti O si n mojuto. Fun apẹẹrẹ, Jesu sọ eyi fun wa: “Ẹ ṣaa woo ẹyẹ oju ọrun, wọn kii funrugbin, bẹẹ ni wọn kii kore, wọn ki i si kojọ sinu aba, ṣugbọn Baba yin ti n bẹ ni ọrun n bọ wọn. Ẹyin ko ha san ju wọn lọ…Eeṣe ti ẹyin si fi n se aniyan nitori aṣọ? Kiyesi ẹranko ti n bẹ ni igbẹ, bi wọn ti n dagba, wọn kii ṣiṣẹ, bẹẹ ni wọn kii ranwu: Mo si wi fun yin pe, a ko se Solomọni paapaa ni ọṣọ ninu gbogbo ogo rẹ to bi ọkan ninu awọn wọnyi.” (Matiu 6:25-29) Iwọ na gbe awọn ọrọ wọnyi wo daadaa. Ọlọrun jẹ Baba ti o wulo ni ọna ti ko se fi ẹnu sọ. Nitori eyi lo ṣe jẹ wipe O n pese fun awọn ẹyẹ oju ọrun, awọn ẹranko igbẹ ati awọn koriko ati ododo igbẹ, ti O si n ṣe itọju wọn, bi o tilẹ jẹ wipe awọn nkan wọnyi ko ṣiṣẹ, bẹ ẹ si ni wọn ko ṣabọ. Ṣe Ọlọrun ti O wa n ṣe eyi ni ko wa ni pese, ki O si tun tọju awa eniyan ti a da ni aworan rẹ? O dandan fun lati pese fun wa ati lati ṣe ju bi a ṣe ro tabi fẹ lọ. Ṣugbọn nitori pe ọpọ ko ni imọ ati oye Ọlọrun ati agbara rẹ, wọn ko ri gẹgẹ bi Baba ti O fẹ jẹ si gbogbo wa. Eyi si ni idi ti wọn ki i fi tọ ọ lọ fun ipese fun aini wọn ati fun amojuto aye wọn. Njẹ tani iwọ naa ri bi baba rẹ? Ṣe baba rẹ nipa ti aye yi ni abi ọga rẹ abi ọrẹ rẹ abi ọkọ rẹ abi awọn orisa ti wọn nbọ ni idile yin? Ta gan ni o mu bi alabojuto aye rẹ? Kiyesi, ẹni ti o ba mu bi alabojuto ati olutọju aye rẹ ni yo sọ bi aye rẹ yo ṣe ri ati ibi ti aye rẹ yo yọri si nigbẹyingbẹyin. Amọ ni temi o, Ọlọrun ọrun ni Baba mi ati olutọju mi. (Wo: 1Peteru 5:7)

ỌRỌ IPARI
Ọlọrun nikan ni adura gbigba wa tọ si. Oun nikan ni o koju osuwọn lati tẹwọ gba adura wa ati lati fun wa ni idahun ti o peye. Nitorina nse ni o yẹ ki a fi gbogbo iṣakoso aye wa le lọwọ, ki a si kọ gbogbo awọn orisa kekeke ti a fa aye wa le lọwọ silẹ, ki aye wa ba le nitunmọ, ki ohun gbogbo ba si le yọri si itura ati idunnu fun wa nikẹyinkẹyin.

IBEERE
– Bawo ni o ṣe tọna si to fun wa lati ma gbadura si awọn angẹli kan tabi awọn eniyan mimọ atijọ kan tabi kẹ Maria iya Jesu?
– Ki ni nkan ti o jẹ pataki julọ si ọ ninu ẹkọ bibeli yi?

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

ADURA – PATAKI ẸKỌ ADURA (ẸSẸ BIBELI: LUUKU 11:1-4)

ALAYTHIA BIBLE CHURCH
ALAKALẸ ẸKỌ BIBELI ATI ALAYE
WEDNESDAY 2ND SEPTEMBER 2020

AKỌRI: ADURA – PATAKI ẸKỌ ADURA
ẸSẸ BIBELI: LUUKU 11:1-4

Click here to Download

AKỌSORI: “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dake, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1)

ỌRỌ AKỌSỌ
Adura se pataki, o se koko ninu igbe aye ọmọ eniyan, nitori o jẹ ọna kan pataki lati fi igbẹkele wa ninu Ọlọrun han ati lati ri ipese rẹ gba. Ti a ba n ṣorọ nipa gbigba adura, ọpọ ma n ro wipe awọn Kiristiani nikan ni ọrọ yi kan. Sugbọn bi a ṣe rika ninu bibeli, adura gbigba ko ni i se pẹlu pe eniyan jẹ Kirisitiani tabi ko jẹ Kirisitiani rara; dipo eyi, o ni i se pẹlu pe eniyan jẹ eniyan. Ki Jesu tilẹ to wa si aye rara ni awọn eniyan ti n kepe Ọlọrun ninu adura. Bibeli so wipe, “A bi ọmọkunrin kan fun Ṣeti; ti o si pe orukọ rẹ ni Ẹnọṣi: nigba naa ni awọn eniyan bẹrẹ si i ke pe orukọ Oluwa.” (Jẹnisisi 4:26) Eyi fi han wa pe lati igba aye Adamu baba nla gbogbo eniyan ni a ti n gbadura si Ọlọrun. Sugbọn nigba ti ẹṣẹ gbilẹ si, ti awọn eniyan si bẹrẹ si ni sọ oye Ọlọrun nu, ni ibọrisa wọle, ti awọn eniyan si so oye pataki adura nu. A wa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun riran ti o ran Jesu wa si aye lati gba wa ninu ẹsẹ wa ati lati mu wa bada bọ sinu ibasepọ ti o peye pẹlu rẹ nipasẹ adura gbigba.

PATAKI ẸKỌ ADURA
Ti a ba ni ki a bẹrẹ si ni sọ bi adura ṣe ṣe pataki to, ko si iwe ti yoo to fun wa lati ṣe akọsilẹ rẹ. Amọ gẹgẹ bi mo se ti sọ tẹlẹ, lakọkọ, adura jẹ ọna kan pataki lati fi igbẹkele wa ninu Ọlọrun han. Ekeji, adura jẹ ọkan lara awọn ọna ti a le gba ri ipese Ọlọrun gba. Ẹkẹta, adura tun jẹ ọna kan pataki ti Ọlọrun ma n lo lati ru wa soke lati mọ ifẹ rẹ. Idi si niyi ti o ṣe yẹ ki eniyan kọokan mọ bi a ṣe n gbadura, adura ti yo so eso rere.

Ki o ye ọ daju, ko ki i ṣe gbogbo adura na ni o ma n so eso rere. Adura ti a ba gba ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun nikan ni o le so eso rere. Johannu sọ eyi fun wa ninu lẹta rẹ akọkọ: “Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ, pe bi a awa ba beere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ, o n ti gbọ ti wa. Bi awa ba si mọ pe o ti gbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba beere, awa mọ pe awa ri ibeere ti awa ti beere lọdọ rẹ gba.” (Johannu 5:14-15) Njẹ iwọ na ri bayi? Adura ti a ba gba gẹgẹ bi ifẹ Ọlọrun nikan ni a le ri idahun lati ọdọ rẹ si. Eyi ti a ko ba gba ni ibamu pẹlu ifẹ rẹ ko le ja mọ nkankan fun wa. A kan fi akoko ati okun wa sofo lori rẹ ni.

Eyi ko wa tun mọ si pe ti a ko ba gbadura ni ibamu pẹlu ifẹ Ọlọrun ko ni ṣe nkankan fun wa. Rara o. Ọlọrun ko ki i duro de igba ti a ba to gbadura si ki O to dun wa ninu tabi da wa lare. Ka so otitọ, ọpọlọpọ nkan daradara ni Ọlọrun n se fun wa ni ojoojumọ lailai se pe a gbadura si. A ri ka ninu Saamu kan pe, “Olubukun li Oluwa, eni ti o nba wa gbe ẹru wa lojoojumọ; Ọlọrun igbala wa.” (Orin Dafidi 68:19) Kaasa! Eyi ma ga o! Ọlọrun n ba wa gbe ẹru wa lojoojumọ! Njẹ iwọ tilẹ mọ eyi bi? Ọpọ loni ni ko mọ pe Ọlọrun ni o n ba wọn gbe ẹru aye wọn, awọn ẹru ti ko ba ti ṣe wọn leṣe tabi gba ẹmi wọn. Nitori eyi ni Jesu Oluwa ṣe sọ wipe Ọlọrun dara si gbogbo eniyan, yala awọn eniyan rere ni tabi awọn eniyan buburu. (Wo: Matiu 5:45)

Sibẹsibẹ, o si ṣe pataki ki a kọ bi a ṣe le ma gba adura ti o nitumọ si Ọlọrun, adura ti Oun ko le salai ma dahun. A ri apẹẹrẹ pataki eyi ninu nkan ti Luuku sọ nipa awọn ọmọ ẹyin Jesu akọkọ. O so wipe, “Bi o si ti n gbadura ni ibi kan, nigba ti o ti dakẹ, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ wi fun un pe, Oluwa, kọ wa bi a tii gbadura bi Johannu si ti kọ awọn ọmọ ẹyin rẹ.” (Luuku 11:1) Kini idi ti awọn ọmọ ẹyin yi fi fẹ ki Jesu kọ wọn bi a tii gba adura? Idi ni pe wọn ti ri mọ daju pe Oun ko ki i gba adura asan tabi agbadanu adura. O tilẹ sọ ni eti iboju Lasaru pe, “Baba mo dupẹ lọwọ rẹ, nitori ti iwọ n gbọ ti emi.” (Johannu 11:41) Eniyan melo gan lo le fi ọwọ sọya pe Ọlọrun n gbọ ti wọn. Ṣugbọn Jesu sọ eyi lai ṣẹ ẹnu ku rara. A si ri pe ododo ni.

Nitorina, ẹni to ba to nkan ṣe ni a ma n jẹ ki o se. Jesu ti fi han pe Oun mọ bi a se n gbadura si Ọlọrun ti yoo si gbọ nigbakugba. Ti a ba wa n wa ẹni ti o tọ lati kọ wa ni bi a se n gbadura, Oun ni o yẹ ki a tọ lọ. Eyi gan ni o si mu ki awọn ọmọ ẹyin rẹ tọ ọ wa ki o ba le kọ wọn bi a se n gba adura ti Ọlọrun yoo fi gbọ. A si ri ninu bible wipe, nigba ti wọn se eyi, Jesu ko ja wọn niyan rara. Bibẹ si ni, ko sọ wipe Oun ko raye ti wọn. Dipo bẹ, O bẹrẹ si ni kọ wọn, O si wipe, “Nigba ti ẹyin ba n gbadura, ẹ ma wipe…” (Luuku 11:2) Eyi tunmọ si pe ti a ba ṣetan lati kẹkọ lọdọ Ọlọrun, Oun naa ṣetan lati kọ wa. Idi ti ọpọ wa fi ya alaimoye ninu ọrọ Ọlọrun ati ninu irinajo wa gẹgẹ bi onigbagbọ ni pe a ya ọlẹ, a ko si setan lati mọ nkankan. Eyi gan lo fa ti awọn woli ati olukọ eke fi n ri aye tan ọpọlọpọ wa jẹ.

Nitori eyi, ni iwọn ọsẹ melokan ti o n bọ, ti Jesu ko ba i ti de, a o bẹrẹ si ni kẹkọ lori awọn nkan pataki ti bibeli sọ fun wa lori adura gbigba. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun fun rarẹ kọ wa, ki O si ṣiwa ni eti, ki a ba le gbọ, ki a si tun ṣe amulo ohun gbogbo ti yo kọ wa. Amin.

ỌRỌ IPARI
Adura ṣe pataki, o se koko ti a ba fẹ gbadun Ọlọrun bi o ti tọ ati bi o ti yẹ. Nitorina, o yẹ ki a mura lati kẹkọ ninu ọrọ Ọlọrun bi a se n gba adura ti Ọlọrun ko ni ṣalai dahun.

Lati ọwọ Johnson O. Lawal

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)