Categories
Latori tabili Paitor

Ma jẹ ki wọn fa ọ lọ

Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ keji ninu osun Owewe 2020. Ki ore-ọfẹ Oluwa wa Jesu Kirisiti ṣan nitori rẹ, ki o si jẹ ki o dara fun ọ ninu ohun rere gbogbo ninu gbogbo ọsẹ na. Amin.

Bi a se bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ gba ọ niyanju pẹlu ọrọ Apositeli Peteru ti o sọ pe, “Nitori naa ẹyin olufẹ, bi ẹyin ti mọ nnkan wọnyi tẹlẹ, ẹ maa kiyesara, ki a ma ba fi iṣina awọn eniyan buburu fa yin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ninu iduro ṣinṣin yin.” (2Peteru 3:17) Ki ni koko ilana ti Peteru fun wa nibi yi? Ohun na ni pe ki a kiyesera fun iṣina awọn eniyan buburu.

Njẹ awọn wo gan ni eniyan buburu? Wọn jẹ awọn kan ti ko bikita rara nipa ododo, iwa bi Ọlọrun, idajọ ododo, alaafia tabi ohunkohun ti o ba fi ogo fun Ọlọrun. Wọn jẹ awọn ti o ma n jẹ ki ibi dabi rere, ki rere si dabi ibi. Mo n sọrọ nipa awọn eniyan ti wọn n gbe igbe aye ti o n jẹ ki a ro wipe awọn olootọ, awọn olododo, awọn ti n wu iwa bi Ọlọrun ati awọn ti o n gbe igbe aye afarajin ya omugọ ti ko le gbadun aye yi tabi jamọ nkankan ninu rẹ ati pe awọn alarekereke, awọn alaimọlọrun, awọn onisekuse ati awọn alagabagebe nikan ni yoo gbadun aye.

Se otitọ wa ni pe iwa ododo ko lere lori pupọ ati pe iwa ika ni o lere lori julọ ninu aye yi? Bẹẹkọ, eyi ko ki ṣe otitọ rara. Lotitọ, o le dabi ẹnipe awọn ika, awọn oniṣekuṣe ati awọn alaisododo eniyan nikan ni o n jẹgbadun awọn nkan daradara ti aye yi, ti wọn si n ri awọn ipo pataki ti aye yi fi lo igba. Sugbọn eyi kan jọ bẹẹ ni; ko ri bẹẹ rara. Nitorina, ma jẹ ki a mu ọ ni omugọ tabi ki a tan ọ jẹ nipasẹ awọn igbe aye ẹtan ti ọpọ ika eniyan ti o wa ni ayika rẹ n gbe.

Ti o ba ka Saamu 73, iwọ na yo ri nkan ti ẹni ti o ko orin yi ni i sọ lori jijowu awọn eniyan ika. Bi ọkunrin yi ṣe fi ye wa, akoko kan wa ni igbesi aye rẹ ti o bẹrẹ si ni fi igbesi aye rẹ we ti awọn ika eniyan ti o wa ni ayika rẹ, awọn ti wọn n fi gbogbo igba pọ si ninu ọrọ, agbara ati iyi ninu iwa ika ati igberaga wọn. Nitori eyi, ọrọ aye rẹ su u, o ṣi bẹrẹ si ni ro wipe ofo lasan ni gbogbo ifarajin rẹ lati sin Ọlọrun ati lati rin ninu ododo rẹ. (Wo: Saamu 73:2-14)

Ṣugbọn ọpẹ si Ọlọrun ti O dari olukọ Saamu yi sinu Ile Mimọ rẹ, ti O si fi otitọ han nibẹ nipa igbe aye awọn ika eniyan. Nibẹ ni o ti wa ri funrarẹ pe ko si bi ika eniyan ti le ni ọla ati agbara to ninu ika sise ni aye yi, airoju ati irora ayeraye ni yo jẹ ipin rẹ nigbẹyingbẹyin. O tun ri ninu Ile Mimọ Ọlọrun pe ko si nkankan ti aye yi ni lati fun wa ti a le fi we nkan ti Ọlọrun ni lọkan lati jẹ si ati lati fun awọn ti o gbẹkẹle, ti wọn si tun fẹran rẹ. Nitori eyi, o wa sọ wipe, “Ta ni mo ni ni ọrun bi ko se iwọ? Ko si si ohun ti mo fẹ ni aye ayafi iwọ. Aarẹ mu ara ati ọkan mi: Ṣugbọn Ọlọrun ni agbara ọkan mi, ati ipin mi laelae.” (Saamu 73:25-26)

Wayi o, iwọ nilo lati ri Ọlọrun gẹgẹ bi agbara ọkan rẹ ati ipin (ere) rẹ ninu aye yi. Aijẹbẹ, ki o to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, o ti gbagbe ara rẹ, a o si ti fa ọ lọ lati mu o ṣina nipasẹ ikuna awọn eniyan ika ti o wa ni ayika rẹ, ti wọn o ma fi igba gbogbo gbiyanju lati tan ọ jẹ ati lati jẹ ki o ro wipe o n padanu awọn nkankan nitoripe o ko tẹle wọn lati rin irin omugọ. Ranti pe Peteru sọ fun wa pe ti a ko ba kiyesara lori ikuna awọn eniyan wọnyi, a o subu kuro ninu iduro ṣinṣin wa ninu Kirisiti. Eyi tunmọ si pe o ṣeeṣe ki eniyan jabọ kuro ni ibi ti ore-ọfẹ ati oju rere Ọlọrun wa, ki o si run aye rẹ, ti ko ba kiyesi lati pa ọkan rẹ mọ kuro ninu aiwabiọlọrun ti o wọpọ ninu aye yi. Adura mi si ni pe iwọ ko ni subu tabi sọ aaye rẹ ninu ete Ọlọrun nu. Sugbọn iwọ na gbọdọ ṣọra, ki o si ri wipe ọkan rẹ ko tele itanjẹ awọn alaiwabiọlọrun ti o n rin ni ọna iparun.

Ki o ni ọsẹ ire o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owewe 06, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 18

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *