Olufẹ: ki ore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titilailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osẹ miran ninu osu Ogun 2020. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun se iṣe ti yo mu inu rẹ dun ninu aye rẹ ni osẹ na ati pe ki o ma se fi ore-ofẹ rẹ sofo, ni orukọ Jesu. Amin.
Nibayi mo gba adura yi fun ọ nitoripe ifẹ ọkan mi ni pe ki aye rẹ jẹ ifarahan ore-ofẹ ati didara Ọlọrun. Nje iwo tile ti ri ore-ọfẹ re gba bi? Ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun, a jẹ wipe o ti gba ore-ọfẹ re niyẹn. Idi si ni wipe bibeli sọ wipe nipa ore-ọfẹ rẹ ni a gbawala. Eyi tunmo si pe nitori iṣẹ ti Ọlọrun se ati nitori nkan ti O fi fun wa ni a se gbawala lọwọ ẹṣẹ wa, lọwọ esu ati lọwọ iparun ayeraye. (Wo: Efesu 2:1-10)
Amọ o, o wa yẹ ki nkan ti Ọlọrun se fun wa ati eyi ti O fun wa jẹyọ ninu aye wa. Nkan ti mo n sọ ni pe o yẹ ki o farahan pe lotitọ ni Ọlọrun ti gbawala, tunwabi, ti O si tun gba akoso aye wa. Fun apẹẹrẹ, ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika, Pọọlu sọ wipe, “Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii se lasan.” (1Tẹsalonika 1:4-10) Ki ni idi ti o fi sọ eyi si awọn ara wọnyi? Idi ni pe o ri ifarahan ore-ọfẹ Ọlọrun ninu aye wọn. Gẹgẹ bi o ti fi han wa ni ori akọkọ lẹta yi, ọrọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn gba ko wọ inu aye wọn lailai yi pada. O yi wọn pada. O jẹ ki wọn yipada kuro ninu ibọriṣa lati sin Ọlọrun ati lati duro de ipadabọ Ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Yatọ si eyi, o yi wọn pada si awokọse rere ọpọlọpọ awọn ọmọ Ọlọrun nibomiran. Nitorina, ore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn rigba ko ja si asan ninu aye wọn. (Wo: 1Tẹsalonika 1:4-10)
Lafikun, Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Korinnti, sọ eyi nipa ara rẹ: “…ore ọfẹ rẹ ti a fi fun mi ko si jẹ asan…”
(1Korinnti 15:10) Eyi tunmọ si pe ore-ọfẹ Ọlọrun mu ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye rẹ. O ṣọ di irufẹ eniyan ti Oun fẹ ki o jẹ ati pe o tun fun ni okun lati se awọn nkan ti O fẹ ki o se. Njẹ a wa le sọ eyi nipa awa na bi? Njẹ a le sọ wipe ore-ọfẹ Ọlọrun ti awa na rigba ti n sọ wa di iru eniyan ti Oun fẹ ki a jẹ bi?
Ti ore-ọfẹ Ọlọrun ti a ti rọ ojo rẹ sinu aye wa ko ba ma sọ wa di iru eniyan ti O fẹ ki a jẹ, o tunmọ si pe a n fi sofo niyẹn. Bawo si ni eyi se se e se? Yo se e se ni iwọn igba ti a ba ti kọ lati se amulo ore-ọfẹ rẹ ni ọna ti o yẹ, ti o si tun peye. Ore-ọfẹ Ọlọrun fun igbala, igbe aye ododo ati iṣẹ isin ti ẹmi ni a ti fi fun wa lọfẹ. A ti fi fun wa ninu ọrọ rẹ, ninu Ẹmi rẹ ati ninu ibasepọ awọn ọmọ rẹ. Eyi tunmọ si pe a le gbadun ore-ọfẹ Ọlọrun nipa fifi aye gba iṣẹ iranṣẹ ọrọ rẹ ati ti Ẹmi rẹ ati ti awọn eyinyan rẹ ti O ti gbin sinu aye wa.
Sugbọn, bi o tilẹ jẹ wipe a ti fun wa ni awọn nkan wọnyi lọfẹ, wọn ko ni kan dede ṣiṣẹ fun iyipada ọtun ninu aye wa ti a ko ba se amulo wọn ni ọna ti o yẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe ti a ko ba mu iṣẹ iranṣẹ ọrọ Ọlọrun lọkunkundun, ki a dirọ mọ ṣinṣin lati se nkan ti o n sọ fun wa, ki a si ma rin ninu imọlẹ rẹ, aye wa ko ni fi ore-ọfẹ Ọlọrun han. Lafikun, ti a ko ba fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati gbakoso aye wa ati awọn nkan ti a n se, ki a gbọkanle fun ohun gbogbo ti a nilo, aye wa ko ni ri bi Ọlọrun se fẹ ki wọn ri ninu aye yi. Nibakanna, ti a ko ba se amulo ti o yẹ ati ti o si peye ibasepọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni aye wa, a ko ni dagba soke bi o se yẹ ki a dagba soke lati gbe aye yi bi o se yẹ ki a gbe.
Nje gẹgẹbi mo se sọ tẹlẹ, niwọn igba ti a ko ba ti ma fi gbogbo igba dabi Ọlọrun se fẹ ki a ri, ki a si tun ma se gbogbo nkan ti O fẹ ki a ma se, a n fi ore-ọfẹ rẹ ati laala Ẹmi rẹ lori aye wa sofo niyẹn. Ṣe a wa le fi ore-ọfẹ re sofo bi eyi ki a si tun ri oriyin gba lọdọ rẹ bi? Njẹ eyi gan ko ni fẹ fihan pe a ko fi igba kankan gba ore-ọfẹ sinu aye wa ati pe a kan n dibọn ni? Laisaroye lọpọ, mo fẹ ki o mọ pe ti o ba ti ri ore-ọfẹ re gba, o yẹ ki o suyọ ninu aye rẹ. Ti ko ba si ma suyọ, o yẹ ki o bẹrẹ si ni bere awọn ibeere kan ti o se pataki lọwọ ara rẹ lori iha ti o kọ si amulo ore-ọfẹ yi. Adura mi ni pe ki Ẹmi Ọlọrun si oju re lati ri awọn ibi ti o ti n kuna, ki O si tun ran ọ lọwọ lati bẹrẹ si ni se ohun ti o tọ pẹlu ore-ọfẹ rẹ.
Ọsẹ ire o.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 09, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 13