Ojo: Ebibi 02, 2021 | Nomba: Vol. 9, No. 52
Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu oṣu tuntun yi, oṣu Ebibi 2021. Adura mi si ni pe ki aṣeyọri pẹlu irọrun jẹ tirẹ ninu gbogbo iṣẹ rẹ ti o tọna ninu oṣu naa, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọrọ iyanju mi si ọ, bi a ṣe n bẹrẹ oṣu yi, ni pe ki o tunbọ fi ara rẹ jin siwaju ati siwaju si ni ṣiṣe iṣẹ Oluwa. Ki si ni idi? Akọkọ, idi ni pe ifẹ Ọlọrun fun ọ ni eyi. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Korinnti, sọ pe, “Nitori naa ẹyin ara mi olufẹ, ẹ maa duro ṣinṣin, laiyẹṣẹ, ki ẹ si maa tẹsiwaju ninu ṣiṣe iṣẹ Oluwa nigba gbogbo, niwọn bi ẹyin ti mọ pe iṣẹ yin kii ṣe asan ninu Oluwa.” (1Korinnti 15:58) Njẹ o ri bayi? Ki ni gbedeke igba ti o fi yẹ ki a ma fi ara wa jin fun iṣẹ Ọlọrun? Ko si gbedeke igba fun eyi rara. Gbogbo igba ni o ye ki a ma fi ara wa jin fun iṣẹ rẹ. Eyi tunmọ si pe nṣe ni o yẹ ki a gbajumọ nkan ti O fẹ ki a ṣe ninu ijoba rẹ, ki a si ma ti ọwọ ọlẹ tabi imẹlẹ bọ ọ.
Nkan ti mo n sọ ni pe Ọlọrun fẹ ki a ma pọ si ni iwulo ni ijọba rẹ, ki a ma si ṣe dinkun rara. Nitorina, bi o ṣe wu ki awọn nkan ti o n ṣe ninu ijọba rẹ le pọ to, o ṣi le ṣe ju bẹẹ lọ. O le bukun fun awọn eniyan pẹlu ọrọ Ọlọrun, adura rẹ, ẹbun rẹ ati bẹẹbẹẹ lọ ju bi o ti ṣe n ṣe ni akoko yi. O kan nilo lati mọ lọkan rẹ pe Ọlọrun n gboju le ọ lati ṣiṣẹ siwaju ati siwaju si fun un, ki o ṣi bẹrẹ si ni rin ni ibamu pẹlu afiyesi yi.
Idi keji ti a fi nilo lati fi ara wa jin lati ṣiṣẹ Ọlọrun siwaju ati siwaju si ni pe gbogbo igba ni Ọlọrun, Baba wa, funrarẹ gan n fi n ṣiṣẹ. Gbogbo igba ni O fi n bukun fun awọn eniyan, yi aye wọn pada, tu wọn silẹ, wo wọn san, gbe wọn soke ati bẹẹbẹẹ lọ. Ko fi igba kankan su u lati ṣe rere fun awọn eniyan ati lati ṣe idajọ ododo ni orilẹ aye. Eyi i gan ni o fun Jesu ni oriya lati ma fi gbogbo igba gbajumọ iṣẹ rẹ nigba ti O wa ni aye yi. Si ranti pe O sọ pe, “Baba mi n ṣiṣẹ titi di isinsinyi, emi si n ṣiṣẹ.” (Johanu 5:17) Niwọn igba ti awa na si jẹ ọmọ Baba, a gbọdọ tẹra mọṣẹ.
Idi kẹta ti a fi ni lati pọ si ninu iṣẹ Ọlọrun, gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe fi ye wa, ni pe iṣẹ wa ki i ṣe lasan. Ki ni itunmọ eyi? Eni, o tunmọ si pe ohun ti a n ṣe jẹ pataki si Ọlọrun. Iwaasu wa, adura wa, fifi-funni wa, ṣiṣiṣẹ lati sọ awọn eniyan di ọmọ ẹyin ati bẹẹbẹẹ lọ ṣe pataki si, nitori pe O n lo awọn nkan yi lati mu ete rẹ ṣẹ ninu aye awọn eniyan. Eji, o tunmọ si pe Ọlọrun yoo pin wa lere fun gbogbo iṣẹ ti a ba fi tọkantọkan ṣe fun un. Awọn eniyan le ma kọbiara tabi yin wa fun laalaa wa ninu ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn Ọlọrun ko ni fi igba kankan foju fo ohunkohun ti a ba ṣe fun un, bi o tilẹ jẹ pe a kan fun ọkan lara awọn ọmọ rẹ ni omi ni (Matiu 10:42). Nitorina, a ni awọn idi ti o gbamuṣe lati fi ara wa jin fun iṣẹ rẹ.
Amọ ṣe o wa ṣeeṣe fun wa lati fi ara wa jin siwaju ati siwaju si fun iṣẹ Ọlọrun, lalai ṣaarẹ tabi rẹwẹsi? Bẹẹni, o ṣeeṣe. O ṣeeṣe nitoripe a ko fi wa silẹ lati da iṣẹ rẹ ṣe. Oun gangan yoo wa pẹlu wa ati ninu wa ni gbogbo igba lati ṣe ohunkohun ti O ba fẹ ki a ṣe. Ki a tilẹ sọ otitọ, a ko le ṣe iṣẹ rẹ kankan rara, ti ko ba ti ipasẹ wa ṣe. Ohun ti o ba ṣe ninu wa, pẹlu wa ati nipasẹ wa nikan naa ni o le mu ete rẹ wa si imuṣẹ, ti O si tun le fun wa ni ere le lori. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe sọ pe, “Nitori pe Ọlọrun ni n ṣiṣẹ ninu yin, lati fẹ ati lati ṣiṣẹ fun ifẹ inu rere rẹ.” (Filipi 2:13)
Nitorina, a ko ni idi kankan lati bẹru iṣẹ rẹ ti o wa niwaju wa, bi o ti wu ki iṣẹ na dabi ẹni pọ to tabi dabi eyi ti ko le e ṣeeṣe to. A kan nilo lati ma rin pẹlu afiyesi pe a ko ni da ṣiṣẹ rẹ — Oun funrarẹ wa pẹlu wa lati ṣe e. Bi O ba si ṣe n ṣiṣẹ ninu wa ati nipasẹ wa, a le ma reti ki oniruuru iṣẹlẹ iyanu bẹrẹ si ni ṣẹlẹ ninu aye wa ati ninu aye awọn ti o wa ni awujọ wa. Gẹgẹ bi a ṣe kọ iwe rẹ: “Wọn si jade lọ, wọn si n waasu nibi gbogbo, Oluwa si n ba wọn ṣiṣẹ, o si n fi idi ọrọ naa kalẹ, nipa ami ti n tẹle e. Aami.” (Maaku 16:20) Nibakanna, ti awa na ba gbajumọ iṣẹ rẹ, lori gbedeke oore-ọfẹ rẹ lori wa, yoo ba wa ṣiṣẹ, yoo si tun mu wiwa rẹ pẹlu wa daju nipa oniruuru iṣẹ ami ati iyanu ti yoo jẹ ki awọn eniyan ma gboriyin fun.
Ki o ni oṣu Ebibi 2021 ti o larinrin.
Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)