Olufe: Olubukunfun ni Olorun ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa, Eni ti O mu wa wo inu osu kejo odun yi, osu Ogun, lalaafia ninu ojurere re ti o ga. Adura mi si ni pe aye wa ko ni mo ohunkohun to yato si ilosiwaju ninu osu na, ni oruko Jesu. Amin.
Nje ona kan to daju lati ni iriri ilosiwaju ni gbogbo ona aye wa ni ki a mu oro Olorun ni okunkundun. Nkan eyokan yi ni Olorun te mo Josua leti nigba ti O n pase fun lati dari awon omo Israeli lo sinu ile ini ti O fi fun won. O so fun pe:
“Se giri, ki o si mu aya le: Nitori iwo ni yoo pin ile naa fun awon eniyan yii, ile ti mo ti bura fun awon baba won lati fi fun won. Sa se giri ki o si mu aya le gidigidi, ki iwo ki o le kiyesi ati se gege bi gbogbo ofin ti Mose iranse mi ti palase fun o: Ma se ya kuro ninu re si otun tabi si osi, ki o le dara fun o nibikibi ti iwo ba lo. Iwe ofin yii ko gbogbo kuro ni enu re, sugbon iwo o maa se asaro ninu re ni osan ati ni oru, ki o le kiye si i lati se gege bi gbogbo eyi ti a ko sinu re: nitori nigba naa ni iwo o se ona re ni rere, nigba naa ni yoo si dara fun o.” (Josua 1:6-8)
Pelu nkan ti Olorun so fun okunriin yi, o daju pe O ni ife si ilosiwaju ati aseyori re. Nitoripe O ni ife si ilosiwaju ati aseyori re ni O se n so nkan ti o nilo lati se ki o ba le saseyori, ki o si tun sorire fun. Ki si ni o ye ki o se? O ye ki o mu oro Olorun ni okunkundun. Bawo gan wa ni o se ye ki o se eyi? Akoko, o ye ki o ma ka, ki o si tun ma keko ninu re. Ekeji, o ye ki o ma ba ara re ati awon ti o n dari soro nipa re. Nkan meji yi ni o tunmo si lati ma je ki oro Olorun kuro ni enu eniyan. Eketa, Josua ye ki o ma se asaro ninu oro Olorun laaro ati lasale. Eyi tunmo si pe o nilo lati ma ronu nipa oro yi lati le mo bi o se ye ki o se amulo re ninu aye are ati lori oro aye re, ki o si ma ko ara re ninu oro yi. Ekerin, o gbodo se gege bi oro yi ti wi. O si di dandan ki o se bi oro yi ti wi, gege bi Olorun ti so fun, ti o ba teramo sise asaro ninu re.
Nje Josua wa se aseyori ati aseyege nibigbogbo ti o lo ati ninu ohun gbogbo ti o se bi? Beeni, o se aseyori ati aseyege, gege bi a ti ri ninu iwe mimo. Laise aniani, o lo lati inu isegun sinu isegun, lati inu aseyege sinu aseyege. Lawon igba ti o tile dabi eni pe o ba aisaseyori tabi ijakule pade fun igba dia, nse ni o pada to Olorun lo lati mo nkan ti o fa. Nigba ti o se eyi, a ko ni ohun ti o nilo lati se ki o ba le pada si oju ona isegun. Esi si fi ye wa pe Josua mu nkan ti Olorun so fun nipa irufe iha ti o ye ki a ko si oro re ni okunkundun. Ti ko ba je be ni, oun ko ba ma se aseyori ati aseyege, bi o tile je wipe Olorun fe ki o se aseyori ati aseyege.
Nibakanna, opo ni ko se orire loni, ti aye won si polukumusu, ti ko si n se nitoripe Olorun ko fe ki won sorire sugbon nitoripe iha ti won ko si oro re ko bo si. Oto ni ki Olorun fe ki a saseyori, ki a si tun sorire; oto ni ki a teramo sise awon nkan ti yo je ki orire ati aseyori wa bo si. A ko si ni se awon nkan ti yo yori si aseyori ati orire otito ti a ko ba mu oro Olorun ni okunkundun. Oro re ni emi wa. Oro re ni kokoro si aseyori ati orire wa.
Nitorina, ti a ba fe kuro ni ona ikuna, idamu, sisuni ati ainitelorun, ki a si bo si ipa aseyori ati isorire, awa na gbogbo se ohun ti Josua se pelu oro Olorun. A gbodo fi ara wa jin lati ka a, lati keko ninu re ati lati ma soro nipa re. Lafikun, a gbodo teramo sise asaro ninu re lowuro ati lale, ki a ma ko ara wa ninu re, ki a ba le mo bi o se ye ki a se amulo re laye wa, ki a si tun ba le se nkan ti o n kowa. Bi a si se n se eyi, awa na, laise aniani, yo ni iriri aseyori ati isorire nibikibi ti a ba lo tabi ti a ba ti ba ara wa, gege bi Olorun ti se ileri.
Wayi o, a ko gbodo gbagbe pe Olorun ko ni mu wa ni tipatipa lati mu oro re ni okunkundun tabi lati mu oro re lo. Lotito, Oun le fun wa ni okun ati iranlowo lati se eyi. Sugbo awon na gbodo pinu lati se be. Nkan ti mo n so ni wipe awa na gbodo fe irufe aseyori ati orire ti Olorun fe fun wa to be ge ti a o fi se awon nkan ti O fe ki a se. Mo si gbadura pe ki okan wa gba okun, bi a se n lo ni osu yi, lati fe ohun ti Olorun fe fun wa ati lati se ohun gbogbo ti o fe ki a se ki a ba le ni ohun ti O fe ki a ni
Ki o ni osu alarinrin
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 02, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 12