Categories
Latori tabili Paitor

Ọrọ ore-ọfẹ rẹ

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi, mo si gbadura pe ki o gba idari ati okun lati ri aye de ibi ti ipese Ọlọrun ti o dara julọ fun ọ ninu ohun gbogbo wa ati lati gbadun rẹ titi ọsẹ yi yo fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Njẹ, bi o ṣe rẹwa to lati gba iru adura yi fun ọ naa ni o si ṣe ṣe pataki to fun ọ lati mọ pe adura yi ko le rọpo ṣiṣe amulo ọrọ Ọlọrun ni aye rẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe adura ko fi igba kankan jẹ nkan ti a le fi ṣe pasiparọ fun ṣiṣe amulo ọrọ Ọlọrun. Nitorina, bi o ti lẹ jẹ pe o ṣe pataki ki a ma fi gbogbo igba gbadura ki a ba le tẹwọgba ipese Ọlọrun fun wa, ki a si tun gbadun rẹ, ti a ko ba fi ara wa jin lati ma ṣe amulo ọrọ rẹ, awọn ipese rẹ kan wa ti a ko ni le na ọwọ gan tabi gbadun.

Pọọlu, nigba ti o ba awọn adari ijọ Efesu sọrọ ninu ipade kan, sọ wipe, “Njẹ nisinsinyi, ara, mo fi yin le Ọlọrun lọwọ ati ọrọ ore-ọfẹ rẹ, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini larin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ.” (Iṣe Awọn Apositeli 20:32) Se iwọ naa ri nkan ti o sọ nipa ọrọ Ọlọrun nibiyi? Lakọkọ, o pe ni ọrọ oore-ọfẹ rẹ. Eyi tunmọ si pe ọrọ Ọlọrun a ma pọ oore-ọfẹ Ọlọrun jade. Nitorina, ti o ba fẹ ni iriri oore-ọfẹ rẹ, ki o si tun jẹ igbadun rẹ, o gbọdọ gba ọrọ rẹ, ki o dirọ mọ, ki o si tun ṣe amulo rẹ. Lotitọ, ti o ba gbadura, oore-ọfẹ Ọlọrun a di titu jade lati tan aini rẹ. Ṣugbọn niwọn igba ti o ko ba kọ lati ma rin ninu imọlẹ ọrọ rẹ, iriri ati igbadun oore-ọfẹ rẹ ti yoo jẹ tirẹ ko ni wa ni ẹkunrẹrẹ. Gbogbo igba ni yoo fi ma ni akude. Ka ti lẹ sọ otitọ, awọn akoko kan wa ti o jẹ wipe nipa ṣiṣe amulo ọrọ Ọlọrun nikan naa ni o fi le ni iriri ati igbadun oore-ọfẹ rẹ. Nkan yowu ti o ba wa ṣe, ki ba jẹ adura gbigba ni, aawẹ gbigba ni tabi ififunni ni, ko ni ṣiṣẹ.

Nkan keji ti Pọọlu sọ nipa ọrọ Ọlọrun ninu ẹsẹ bibeli yi ni pe o le kọ aye wa, ki o si tun gbe wọn ro. Ọrọ rẹ le fun aye wa ni okun ati iduro ṣinṣin lati tayọ, lalai fi idojukọ aye wa ṣe. Gẹgẹ bi Oluwa ti fi han wa ninu owe rẹ lori ọlọgbọn ọmọle ati omugọ ọmọle, a ko le se alaini ipenija ninu aye yi. Nitorina, gbogbo wa ni yo gba ẹkunrẹrẹ ipenija tirẹ. Ṣugbọn nkan kan ti yoo sọ boya a duro digbi ati ṣinṣin lẹyin ìpenija kọọkan ni iha ti a ba kọ si ọrọ Ọlọrun. (Wo: Matiu 7:24-27)

Ti a ba n kọ ọrọ rẹ, ti a si fi ara wa jin lati kọ aye wa, igbeyawo wa, okowo wa, awọn ọmọ wa ati bẹẹbẹlọ lori ipilẹ ọrọ rẹ, ko si iru idojukọ tabi anfaani ti o le ya sọdọ wa, n ṣe ni a o duro ṣinṣin, ti a o si tun tayọ loju rẹ. Ṣugbọn ti a ba kọ jalẹ lati kọ ọrọ rẹ tabi ti a ko kọbiara si ọrọ rẹ ti a n kọ, ki a ba le ṣe amulo rẹ, ki a si fi to aye wa, o di dandan ki awọn idojukọ ti o kereju gan ti o ba tọ wa wa ma bu ramuramu mọ aye wa, ki wọn si fẹ bi wo lulẹ. Ti a ba si tẹsiwaju ninu iha omugọ ti a kọ si ọrọ Ọlọrun, o di dandan ki aye wa ati nkankinkan ti a ba n gbiyanju lati kọ pẹlu rẹ da wo lulẹ lọjọkan. Ọrọ akoko diẹ na ni.

Nkan ti Pọọlu sọ nipari nipa ọrọ Ọlọrun ninu iyanju rẹ ni pe ọrọ rẹ le fun wa ni ini tiwa laarin awọn ọmọ Ọlọrun. Eyi tunmọ si pe Ọlọrun ti pese awọn nkankan fun wa lati gbadun gẹgẹ bi ọmọ rẹ. Ọrọ rẹ si ni yoo dari wa lati ri awọn nkan wọnyi, ti yoo si tun fi ọna lati gbadun wọn han wa. Fun apẹẹrẹ, ilera, alaafia, ipamọ ati itẹlọrun jẹ ini wa ninu Kirisiti. Bawo si ni a ṣe mọ eyi? Nipasẹ ọrọ Ọlọrun ni. Bawo tun wa ni a ṣe le gbadun awọn nkan wọnyi? Nipasẹ kikọ ati ṣiṣe amulo nkan ti ọrọ rẹ sọ nipa wọn ni a ṣe le gbadun wọn.

Nitorina, mo ro pe o ti ri pe aye ti Ọlọrun pe wa lati gbe jẹ eyi ti a pilẹ, ti a si kọ sori ọrọ Ọlọrun. Ti a ba si fẹ gbe igbe aye yi, ki a si gbadun rẹ lẹkunrẹrẹ, a gbọdọ mu ọrọ rẹ ni ọkunkundun ni aye wa. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ gba okun ni ojoojumọ lati ọdọ Ẹmi mimọ lati ma fi gbogbo igba ṣe ohun ti o tọ pẹlu ọrọ Ọlọrun. Amin.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owewe 27, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 21

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *