Categories
Latori tabili Paitor

Tẹriba fun patapata

Olufẹ: ki ore-ọfẹ ati aanu wa pẹlu re titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi, mo si gbadura pe ki a pa ọ mọ ninu gbogbo ọna re kuro ninu ewu ati idojukọ Satani gbogbo, ni orukọ Jesu. Amin

Njẹ ọna kan pataki fun wa lati ma fi igba gbogbo gbadun aabo Ọlọrun kuro ninu ewu orisirisi ni ki a ma rin ni igbọran si aṣẹ rẹ ni gbogbo igba. Gẹgẹ bi Bibeli se fi han wa kedere, ko si bi a se le yago patapata fun wahala ninu aye yi. Idi si ni pe aye na jẹ eyi ti o wa labẹ isakoso Esu, niwọn ibi ti Ọlọrun gba a laaye de (1Johanu 5:19). Nitorina, bi a ba tilẹ n fi gbogbo igba wiwa ti o tọ ati ti o si yẹ, a ko le ṣa lairi awọn kan ti yo fi ara wọn jin fun Esu lati da wahala silẹ fun wa. Ti ko ba si wa ri ẹni ti o le lo lati se eyi, o le pinu lati lo nkan ti a da tabi ilana ti a la kalẹ yowu ti o ba ri lati doju ija kọ wa.

Danieli, fun apẹẹrẹ, n gbe igbe aye ti o fi ara rẹ jin patapata lati dun Ọlọrun ninu. Sibẹsibẹ Esu se aseyọri lati lo awọn adari ilẹ Babiloni kan lati se akoba fun. Nitorina, o ba ara rẹ ninu iho Kiniun. (Wo: Danieli 6) Jobu na n kọ? Ọlọrun funrarẹ jẹwo pe ọkunrin yi jẹ ẹni ti o wa ni alailẹbi, ti iwuwasi rẹ si tọ. Sibẹsibe, akoko kan de ti Esu gbogun ti, ti o si lo oniruuru eniyan ati nkan lati pọn loju. (Wo: Jobu 1&2)

Nitorina, niwọn igba ti a ba si wa ninu aye yi, ni orekore ni a o ma ba ara wa ni awọn asiko kan ti wahala yo tọ wa wa, ti yo si fẹ bori wa, ki o si tun pa wa run. Sugbọn ni ọwọ igba ti a ba tẹriba fun Ọlọrun, ti a n gbe igbe aye iyọnda si, ti a si n fi gbogbo igba gbọkanle fun ipese rẹ, ko si irufẹ wahala ti o le tọ wa wa ti a ko ni le rin ni iṣẹgun lori rẹ (Efesu 6:10-18). Njẹ kiyesi pe nkan meji ni mo sọ pe a gbọdọ se lati le rin ni iṣẹgun lori wahala yowu ti o le de ba wa. Akọkọ ni pe ki a tẹriba patapata fun Ọlọrun. Ekeji ni pe ki a gbọkanle patapata. Ki i se pe ki a mu ọkan tabi ekeji ninu awon nkan meji yi; mejeji ni a gbọdọ se. Laijẹbẹ, a ko ni ri iru eso ti o yẹ ki a ri.

O wa seni laanu pe ọpọ ninu wa loni lo ro wipe nkan ti o se pataki ni pe ki a kan gbọkan wa le Ọlọrun ati agbara ati aṣẹ rẹ lati rin ni iṣẹgun laye yi – iha ti a kọ si ofin rẹ ko ja mọ nkankan lọtiti. Sugbọn bi a se kọ wa kọ ni eyi ninu iwe mimọ. Nkan ti a kọ wa ni eyi: “Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Eṣu, on o si sa kuro lọdọ nyin.” (Jakobu 4:7) Se iwọ na ri bayi? A le doju ija kọ Satani, ki a si le danu kuro lọdọ wa. Eyi tunmọ si pe a le kọ lati fi aye gba iṣẹ ati akitiyan Esu laye wa. Idi si ni wipe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ ati pe ati fun wa ni aṣẹ ti a nilo lati bori gbogbo agbara Esu lati ọwọ Jesu (Luuku 10:19).

Sugbọn ki aṣẹ wa lati doju ija ko Esu ati iṣẹ rẹ ki a si bori to le ṣiṣẹ bi o ṣe tọ, Jemisi (Jakọbu) so wipe a kọkọ gbọdọ tẹriba fun aṣẹ Ọlọrun. Ti a ko ba ni tẹri wa ba fun Ọlọrun, ki a si ma rin ni igbọran si awọn ofin rẹ, nse ni a o ma fi ọpọ igba ba ara wa ni ipo ti a le ti ma le lo tabi gbadun aṣẹ ati ore-ọfẹ ti O fun wa lati rin ni iṣẹgun lori Esu ati iṣẹ rẹ.

Wo Samusoni, fun apẹẹrẹ. O jẹ ẹni ti Ọlọrun fi amin ororo yan, ti O si tun fun ni aṣẹ lati gba awọn ara Isiraẹli kuro lọwọ isakoso ati ifiyajẹni awọn Filisitini. O si mura lati se eyi. Sugbọn nitoripe o kọ lati ko ara rẹ ni ijanu lati tẹriba fun Ọlọrun ni gbogbo igbesi aye re, ọpọ igba ni o n ṣe awọn nkan ti ko tọ fun lati se, ti o si tun n lọ si awọn ibi ti ko yẹ ki o lọ. Eyi si jẹ ki o soro fun lati le seto aye rẹ, ki o si ko awọn eniyan ti a pe lati dari jọ ni iṣọkan lati dojukọ awọn ọta wọn, ki wọn si bori. O kan n se adanikanse ni. Bi o wa tilẹ jẹ wipe, ninu ainikoraẹninijanu ati aigbọran si ọna Ọlọrun rẹ, o fi ọpọlọpọ ọdun bọ ninu panpẹ awọn ọta re, akoko kan de ti o jẹ wipe ẹmi iyasọtọ Ọlọrun ati aṣẹ ti a fun lati da abo bo ara rẹ ati awọn eniyan rẹ kuro lọwọ awọn ọta wọn fi sile. Nitorina o ku ki akoko rẹ to pe, o si fi iṣẹ ti a fi le lọwọ silẹ lai pari. (Wo: Awọn Onidajọ 14-15)

Nibayi, ti awa na ko ba fẹ parun nipasẹ arekereke ati idojukọ Satani, a ko gbọdọ kọ iha ti Samusoni kọ si Ọlọrun ati si ọrọ rẹ si. Dipo bẹ, a gbọdọ tẹ ori wa ba fun patapata, ki a si fi ara wa jin lati ma rin ninu ilana rẹ. Ti a ba si ti n se eyi, ibikibi ti o wu ki a ti ba ara wa tabi ohunkohun ti o wu ki ọta lẹ mọ wa ninu irinajo wa ninu ifẹ Ọlọrun, a le mọ daju pe aabo rẹ yo daju lori wa, bi awa si ti n fi iduroṣinṣin se amulo aṣẹ ti O fi fun wa ninu Jesu Kirisiti.

Ọsẹ adun o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 16, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 15

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *