Ọjọ: Okudu 06, 2021 | Nọmba: Vol. 10, No. 5
Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ keji ninu oṣu Okudu 2021. Ki oore-ọfẹ ati aanu Ọlọrun maa ṣan lori aye rẹ ati nipasẹ aye rẹ laini odiwọn ninu ọsẹ naa ati ni gbogbo eyi ti o ku ninu ọdun yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Wayi o, bi o tilẹ jẹ pe o dara jọjọ lati ma gbadura ni iru ọna yi ati lati ma reti pe ki Ọlọrun dahun, a tun nilo lati jẹ ki o ye wa pe ti a ko ba ma fi imoore ti o peye han lori gbogbo awọn nkan ti O ti n ṣe fun wa, ko yẹ ki a maa reti ki O tun ṣe jubẹẹ lọ fun wa. Mi o wa sọ pe o di dandan ki Ọlọrun ma ṣe ju bi O ṣe n ṣe fun wa latẹyin wa lọ, ti a ko ba fi imoore han si fun awọn nkan ti O ti ṣe fun wa. Ọlọrun ni Oun jẹ; ko ki i ṣe eniyan. Nitorina, ko ki i fi gbogbo igba duro de wa lati dupẹ lọwọ rẹ tabi fi imoore han si fun awọn nkan ti O ti ṣe fun wa tabi ti O n ṣe fun wa ki O to o ṣe jubẹẹ lọ si fun wa.
Sibẹsibẹ, gbogbo igba ni O ma n reti pe ki a fi imoore wa han lori awọn nkan ti O n ṣe ninu aye wa tabi ti O ti ṣe fun wa. Fun apẹẹrẹ, Luuku, ninu iwe ihinrere rẹ, sọ fun wa bi awọn adẹtẹ mẹwa kan ṣe tọ Jesu Oluwa wa fun iwosan. Nigbati wọn si de, ko le wọn danu. Dipo eyi, O ṣaanu fun wọn, O si sọ fun wọn pe ki wọn lọ fi ara wọn han awọn alufa. Nitorina, wọn lọ, bi O ti ṣe paṣẹ fun wọn. Nigba ti wọn si n lọ, lojiji ni wọn ri pe a ti wẹ wọn mọ — ẹtẹ wọn ti poora. (Wo: Luuku 17:11-14)
Ki wa ni nkan ti o tọ fun awọn ọkunrin wọnyi lati ṣẹ? Pẹlu imọ kekere ti mo ni nipa bi o ṣe yẹ ki a ma ṣe nkan, mo gbagbọ pe nṣe ni o yẹ ki wọn pada tọ Jesu lọ lati kọkọ fi tọkantọkan dupẹ lọwọ rẹ fun nkan ti O ṣe fun wọn. Lotitọ, pẹlu bi nkan ṣẹ ri wọn ni akoko yẹn, wọn le ma ni oore-ọfẹ lati ni owo lọwọ tabi awọn nkan miran ti wọn le mu tọ Jesu wa lati dupẹ lọwọ rẹ. Amọ, o tilẹ wa kere ju, wọn le pada sọdọ rẹ lati dupẹ lọwọ rẹ fun iwosan wọn, ki wọn to wa bẹrẹ si ni woye nkan ti wọn fẹ ṣe pẹlu ibẹrẹ tuntun ti O ti fun aye wọn.
Njẹ wọn wa ṣe eleyi bi? Ṣe gbogbo wọn naa lo pada lọ wa Jesu ri lati fi imoore wọn han si fun nkan ti O ṣe fun wọn? O ti o! Ẹnikan ṣoṣo lara wọn, ara Samaria kan, nikan naa lo pada tọ ọ wa lati juba rẹ ati lati dupẹ lọwọ rẹ fun iwosan ti o rigba. Eyi ko si dun mọ Oluwa ninu rara tobẹ ti O fi sọ pe, “Awọn mẹwaa ki a sọ di mimọ? Awọn mẹsan yooku ha da? A ko ri ẹnikan ti o pada wa fi ogo fun Ọlọrun, bikoṣe alejo yii. O si wi fun un pe, Dide ki o si maa lọ; igbagbọ rẹ mu ọ lara da.” (Luuku 17:17-19)
Eyi tunmọ si pe Oluwa gan n reti ki awọn ọkunrin mẹwẹẹwa yi pada wa lati dupẹ lọwọ rẹ fun iwosan wọn. Ko kuku sọ pe ki wọn mu owo tabi ohun miran wa fun Oun. Bẹẹ si ni ko gba nkankan lọwọ wọn ki O to wo wọn san, nitoripe iwosan jẹ ẹbun ọfẹ Ọlọrun ni gbogbo igba. Eyi naa ko si tun wa jasi pe nkan ti ko dara ni pe ki wọn mu owo tabi ohun ini wọn miran wa lati fi imoore wọn han si i, bi o tilẹ jẹ pe o fẹrẹ daniloju pe ko ni i gba lọwọ wọn. Ko si nkan ti o buru nibẹ rara.
Ka tilẹ wa wo lati ẹgbẹ miran, gẹgẹ bi ofin Mose, awọn nkan kan wa ti ẹnikẹni ti o ba gba iwẹnumọ kuro ninu arun bi ti ẹtẹ gbọdọ ko wa si ọdọ alufa ti you ṣe iwẹnumọ ẹṣẹ fun. Idi si ni yi ti Oluwa fi sọ fun awọn ọkunrin wọnyi lati lọ fi ara wọn han awọn alufa. Bi ofin na si tun ṣe tẹsiwaju lati sọ, awọn nkankan wa lara awọn nkan ti irufẹ ẹni na ba ko wa ti yoo jẹ ti alufa ti o n ṣipẹ si Ọlọrun lori ọrọ rẹ. Ti o ba wa tọ fun alufa ti ko ṣe nkankan lori bi wọn ṣe gba ilera lati gba ọrẹ lọwọ wọn, ki wa ni ki a sọ nipa ti ẹni ti o wo wọn san? Ṣe ko lẹtọ lona ti o ga ju ti alufakalufa lọ lati gba ọrẹ ọpẹ pẹlu ijọsin lọwọ wọn? O lẹtọ. (Wo: Lẹfitiku 14:1-31)
Ṣugbọn ko tilẹ wa reti nkan miran lati ọdọ wọn ju ọrọ iyin ati ọpẹ lọ. Amọ, o wa ṣeni laanu pe ẹnikan ṣoṣo ninu wọn ni o pada wa lati fun ni eyi. Ẹnikan ti o pada wa lati fi imoore han yi nikan naa si ni o ri ọrọ Ibukun miran si gba lati ẹnu rẹ — igbagbọ rẹ mu ọ lara da. Nkan ti ọrọ ibukun miran yoo wa jasi ninu aye ọkunrin yi Ọlọrun nikan ni O le sọ. Ṣugbọn o ṣa ri nkan gba si lati ọwọ rẹ ju awọn yoku lọ nitoripe o pada wa lati dupẹ.
Ki gan wa ni itan yi n kọ wa? Ohun naa ni pe awọn nkan kan wa ti a le ma rigba lọwọ Ọlọrun, ti a ko ba kọ lati ma fi imoore han si fun awọn nkan ti O n ṣe fun wa. O ṣi n ṣe oniruuru nkan fun wa ti ọgbọn wa, owo wa, ipo wa, iyi wa tabi ẹkọ wa ko le ri fun wa. Nitorina, ẹ jẹ ki a ye jẹ abaramoorejẹ, ki a si bẹrẹ si ni fi tọkantọkan, ori pipe ati pẹlupẹlu awọn nkan ini wa fi imoore wa han si fun awọn nkan ti O n ṣe fun wa. Mo si gbadura pe ki a sọ ọkan wa ji, ki a si tun fun wọn ni okun lati ma fi gbogbo igba ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi, ni orukọ Jesu. Amin.
Ki o ni ọsẹ alarinrin.