Categories
Others

Takete si agbere

Olufẹ: Kaabọ si inu ọsẹ miran ninu osu Owewe 2020. Ki alaafia ati ayọ ti o n ti ọwọ Ẹmi Ọlọrun wa kun aye rẹ titi ọsẹ na yoo fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Njẹ bi a se bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, jẹ ki n ran ọ leti ọrọ Pọọlu ti o sọ wipe, “Nitori eyi ni ifẹ Ọlọrun, pe ki ẹ wa ni mimọ, ki ẹ si takete si agbere: ki olukuluku yin mọ bi oun iba ti maa ko ara rẹ ni ijanu ni iwa-mimọ ati ni ọla; Kii ṣe ni ṣiṣe ifẹkufẹẹ, gẹgẹ bi awọn Keferi ti ko mọ Ọlọrun: Ki ẹnikẹni ma ṣe dẹṣẹ si arakunrin rẹ nipa ohunkohun: nitori Oluwa ni olugbẹsan ninu gbogbo nnkan wọnyi, gẹgẹ bi awa ti kilọ fun yin tẹlẹ ri, ti a si n jẹrii yin pẹlu.” (1Tesalonika 4:3-6) Ki si ni idi ti mo fi mu ọrọ iyanju yi tọ ọ wa ni akoko yi? Idi ni pe, gẹgẹ bi o ti ri ni igba aye Pọọlu, bẹẹ na ni o ṣe ri ni akoko yi — ẹṣẹ agbere wọpọ lode oni; ọpọ ọmọ Ọlọrun ni o si n kopa ninu rẹ (1Korinnti 7:2).

Nkan ti mo n sọ ni pe iṣekuṣe ko fi gbogbo ara ja mọ nkankan mọ loju ọpọ ọmọ Ọlọrun loni. Wọn ko ri ibaraẹnisun larin awọn ti ko ti gbeyawo tabi larin awọn ti ko ki i ṣe tọkọtaya si nkankan pataki mọ. Idi si ni pe ọda ti awọn ti aye yi fi n fi ojoojumọ kun iṣekuṣe niyẹn. O tunmọ si pe awọn iwa ti wọn n wu ati awọn ọrọ ti wọn n sọ jẹ ki o da bi ẹni pe agbere, pansaga tabi ikorajọpọ lati ṣe iṣekuṣe dara jọjọ. Wọn a si ma fun awọn ti ko darapọ mọ wọn ninu radarada ti wọn ṣe ni ero pe nkan n ṣe wọn tabi pe wọn n padanu adun ibaraẹnilopọ.

Ṣugbọn ki ni ifẹ Ọlọrun fun wa? Gẹgẹ bi Pọọlu ṣe sọ fun wa ninu ẹsẹ bibeli ti o wa ni oke yẹn, ifẹ Ọlọrun fun wa ni pe ki a takete si agbere, ki a si kọ bi a ṣe le ko ara wa nijanu ni ọna ti o mọ, ti o si niyi. Wa kiyesi pe ibaraẹnisun gan kọ ni Ọlọrun ni ki a takete si. Nkan ti O ni ki a takete si ni iṣekuṣe, eyi ti i ṣe ọna aitọ ati ọna aiyẹ lati ma ba ara ẹni lopọ.

Awọn ọna aitọ yi si ni i ṣe pẹlu ibaraẹnisun ki a to fẹ ara ẹni sile, ale yiyan, ifipabanilopọ, pansaga, biba eranko lopọ, ibalopọ ọkunrinsọkurin ati obinrinsobirin, kikorajọpọ lati ṣe agbere ati ohunkohun ti o bani i ṣe pẹlu iwa eeri laarin awọn ti ko ki i ṣe tọkọtaya. Awọn nkan wọnyi ni Ọlọrun n kilọ fun wa lati takete si. Pọọlu tilẹ sọ fun wa ninu lẹta rẹ miran pe nkan ti Ọlọrun fẹ gan ni pe ki a sa fun awọn nkan wọnyi (1Korinnti 6:18-20)

Ki wa ni idi ti Ọlọrun ṣe fẹ ki a sa fun iṣekuṣe? Lakọkọ, idi ni pe iṣekuṣe a ma sọ ara eniyan, ti i ṣe tẹnpili Ọlọrun, di alaimọ, a si sọ wọn di alaiwulo fun Ọlọrun lati lo fun ogo rẹ. Ikeji, iṣekuṣe a ma so eniyan pọ pẹlu awọn ẹlomiran ni ọna ti ko mọ, a si ṣi ilẹkun fun oniruru iṣoro ti ko yẹ ki o jẹ tirẹ silẹ lati wọle sinu aye rẹ. Ikẹta, iṣekuṣe a ma fi eniyan si abẹ idajọ ti Ọlọrun ma n ṣe ni oorekore ati idajọ rẹ ti ayeraye. Ka tilẹ so otitọ, gbogbo arun ti o ma n tankẹlẹ nipasẹ ibaraẹnisun ti a mọ loni ni o jẹ ifarahan idajọ Ọlọrun lori agbere ati iṣekuṣe laarin awọn eniyan.

Nitorina, ko si nkan ti o ṣe ọ ti o ba takete si iṣekuṣe. Ko si nkan ti o ṣe ọ ti o ba jẹ wundia, niwọn igba ti o ko ti ṣe igbeyawo. Ko si nkan ti o ṣe ọ ti o ba ma a gbe pẹlu ọkunrin tabi obinrin ti ẹ ko ti fẹ ara yin sile. Ko si si nkan ti o ṣe ọ ti o ko ba fi ara rẹ jin fun awọn aworan eeri ati oniruru nkan irira ti o n ba aye ọpọlọpọ jẹ loni.

Lotitọ, gẹgẹ bi mo ti ṣe sọ siwaju, awọn ti aye yi ti o wa ni ayika rẹ le fẹ ki o ro pe nkan ṣe ọ tabi pe o n padanu lọpọlọpọ nipa pe o ko darapọ mọ wọn ni ṣiṣe agbere. Ma ṣe da wọn lohun rara tabi ki o banujẹ nitori isọkusọ wọn. Oju ọna ti o tọ ni o wa. Ati wipe, yatọ si pe aye rẹ yo wa ni ipamọ kuro lọwọ awọn aisan buburu ati awọn aisan ti ko lorukọ, lọjọkan, Oluwa, ti o n fi gbogbo igba bu ọla fun pẹlu ara rẹ, yi o gbe ọ nija, yi o si san ọ lẹsan fun jijẹ olotitọ si.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owewe 20, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 20

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *