Categories
Latori tabili Paitor

Jẹ ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ lọna gbogbo

Olufẹ: ki ore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ ku ikalẹ sinu ọjọ isinmi ti o kẹyin osu yi, mo si gbadura pe ki Ọlọrun kọ ọ, ki O si tun fi okun kun ọkan rẹ lati ma fi gbogbo igba gbe igbe aye ẹni ti o wulo ninu ibasepọ ati iṣẹ ọwọ rẹ gbogbo ni ọsẹ yi ati ni iyoku ọjọ aye rẹ. Amin.

Bi a ṣe ri ka ninu iwe mimọ, Ọlọrun ko fẹ ki awọn ọmọ re jẹ ọlẹ sugbọn ki wọn ja fafa ni ṣiṣe ohunkohun ti o ba jẹ ojuṣe wọn. A mọ ki eyi to le ribẹ ninu aye ẹnikọọkan wa, a kọkọ gbọdọ mọ ohun gbogbo ti o jẹ ojuṣe wa. Ti a ko ba mọ ojuṣe wa, o ṣe e ṣe ki a ma ṣe nkankan nipa wọn. Yatọ si pe ki a mọ ojuṣe wa, o tun yẹ ki a ni ironu to ga lati ṣe ojuṣe wa. Ọtọ ni ki eniyan mọ ojuṣe rẹ; ọtọ si ni ki o gba ojuṣe rẹ ni ojuṣe rẹ, ki o si bẹrẹ si ni tiraka lati ṣe.

Nitorina, bere lọwọ ara rẹ, “Ki ni awọn ojuṣe mi laye yi? Njẹ mo tilẹ mọ wọn? Ti mo ba si mọ wọn, ki ni mo n ṣe lati mojuto wọn?” Bi a ṣe fi ye wa ninu iwe mimọ, kọkọrọ ti o ṣilekun mimọ ati mimọyi awọn ojuṣe wa ninu aye yi ni ki a mu Ọlọrun lọkunkundun. Nkan ti mo n sọ ni wipe ojuṣe wa pataki akọkọ ni aye yi ni ki a mu Ọlọrun ni ọkunkundun, ki a si ma gbe aye lati mu inu rẹ dun. Idi niyi ti Solomọni ṣe sọ wipe, “Opin gbogbo ọrọ naa ti a gbọ ni pe: Bẹru Ọlọrun ki o si pa ofin rẹ mọ: nitori eyi ni ojuṣe gbogbo eniyan.”

Njẹ iwọ na ri bayi? Pataki julọ ninu gbogbo awọn ojuṣe wa ni ki a ma gbe ninu ibẹrun Ọlọrun, ki a si ma pa ofin rẹ mọ. Nitorina, ti o ko ba gbe ninu ibẹru Ọlọrun ati nipasẹ ọrọ rẹ, o wulo ni yẹn o. O wa ṣe e ṣe ki o wulo, ki o si ma ṣe ojuṣe rẹ ni awọn ibi kọkan ni aye rẹ. Sugbọn niwọn igba ti o ko ba mu Ọlọrun ni ọkunkundun ni aye rẹ, ko si bi o se le wulo ni gbogbo ọna. Idi si ni pe bi a ba ṣe mu Ọlọrun ni ọkunkundun to ni ọkan wa yo ṣe gba ẹkọ to lati mọ ohun gbogbo ti o jẹ ojuṣe wa ni aye yi, ki a si ṣe pẹlu akiyesi ati ifarabalẹ.

Fun apẹẹrẹ, Ọlọrun, nipaṣe ọrọ rẹ, fi awọn ojuṣe wa si ara wa, awọn aya wa, awọn ọkọ wa, awọn ọmọ wa, awọn obi wa, ijọba wa, awọn alabagbe wa ati awọn ara wa ninu ijọ Ọlọrun. Siwajusi, O tun fi han wa pe igba ti a ba to bẹrẹ si ni ṣe ojuṣe wa si gbogbo awọn eniyan wọnyi ni a to le sọ wipe a mu oun ni ọkunkundun. O wa seni laanu pe oye nkan wọnyi ko ye ọpọ eniyan rara nitoripe wọn ko ma kẹkọ lọdọ Ọlọrun. Nitorina, wọn ko ki i kọbiara si ojuṣe wọn si Ọlọrun ati si eniyan rara. Wọn kan n fi iwa ọlẹ se ayọyọ ni, ti wọn a si ma fi igba gbogbo wa awọn ti wọn yo ti ojuṣe wọn si ara wọn, ẹbi wọn ati awujọ wọn mo ni ọrun.

Bẹ gẹgẹ na si tun ni a ri awọn ti wọn n ṣe aṣiṣe fifi bi wọn ṣe gbajumọ awọn ojuṣe wọn kan ṣe awawi fun ikuna wọn lati mojuto awọn ojuṣe wọn miran. Fun apẹẹrẹ, a ri awọn ti wọn n fi ifarajin wọn fun iṣẹ Ọlọrun kẹwọ fun ikuna wa lati ṣe ojuṣe wọn si awọn ọkọ tabi aya wọn. Wọn ti wa gbagbe patapata pe Ọlọrun kanna ti wọn sọ wipe awọn n sakitiyan lati sin ti jẹ ki o ye wa bi o ṣe yẹ ki a ma ṣe si awọn ọkọ tabi aya wa. A tun wa ri awọn ti wọn n fi akitiyan wọn lati ṣiṣẹ ati lati pawo wọle fun idile wọn ṣe awawi fun aisojuṣe wọn lori titọ awọn ọmọ wọn tabi lori fifi ara wọn jin lati sin Ọlọrun. Sugbọn bi o tilẹ jẹ wipe Ọlọrun fẹ ki a wa iṣẹ ti o yẹ kan tabi omiran se, ko fẹ ki a fi eleyi kẹwọ lati ma fi ara wa jin fun lati lo wa fun Ibukun awọn miran tabi ki a fi kẹwọ gẹgẹ bi idi ti a ko fi tọ awọn ọmọ wa bi o se yẹ. Dipo eyi, O fẹ ki a to aye wa ni ọna ti a o fi se ojuṣe ohun gbogbo ti Oun yo yẹwa lọwọ wo le lori.

Pọọlu sọ eyi fun Timoti: “Sugbọn ma se pẹlẹ ninu ohun gbogbo, maa farada ipọnju, ṣe iṣẹ ajinyinrere, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ lasepe.” (2Timoti 4:5) Ṣe iwọ na ri bayi? Eniyan Ọlọrun yi sọ fun Timoti pe ki o ri wipe oun ko fi ojuṣe rẹ kankan silẹ laiṣe. Bi o tilẹ jẹ wipe nkan ti o sọ nibiyi ni i ṣe pẹlu iṣẹ iranṣẹ ọkunrin yi, alakalẹ yi jẹ eyi ti a le lo lori ohun gbogbo to ni i ṣe pẹlu aye wa. A ko gbọdọ fi nkankan ti o ba jẹ ojuṣe wa lati ṣe silẹ nitoripe Ọlọrun yoo bere lọwọ wa bi a ba ṣe ṣesi lọjọkan. Nitorina, lakọkọ, mura gidigidi lati kẹkọ lọdọ Ọlọrun lori awọn nkan ti o jẹ ojuṣe rẹ laye yi. Ekeji ni pe ki o pa ọkan rẹ pọ lati ṣe amulo ore-ọfẹ Ọlọrun lati se eyi yowu ninu ojuṣe rẹ, yala si ara rẹ ni o, si awọn ẹlomiran ni o tabi si Ọlorun. Ki Ọlọrun si ba ọ to aye rẹ ni ọna ti o fi jẹ wipe o ko ni kuna lati ṣe gbogbo nkan ti o ba jẹ ojuṣe re lati se.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 30, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 17

One reply on “Jẹ ẹni ti o n ṣe ojuṣe rẹ lọna gbogbo”

Great beat ! I would like to apprentice while you amend your web site,
how could i subscribe for a blog website? The account helped
me a acceptable deal. I had been tiny bit acquainted of this your broadcast provided bright clear idea

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *