Olufẹ: ki ore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kabọ sinu ọsẹ ti o pari osu Ogun 2020, mo si tun gbadura pe ki a pa ọ mọ kuro ninu gbogbo arekereke ibi eṣu ni gbogbo ọsẹ na ati ni gbogbo eyi ti o ku ki ọdun yi fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.
Nje bi o ti jẹ pe o dara, ti o si tun tọ fun mi lati gba aduura fun ọ ni ọna ti mo ṣe gba yi, o tun se pataki pe ki iwọ na ma gba eṣu laye lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ ki o si bori. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, sọ wipe, “Bẹni ki ẹ ma ṣe fi aye fun Eṣu.” (Efesu 4:27) Kini idi ti o fi sọ eyi? O sọ eyi nitori oye rẹ nipa iru ẹda ti Eṣu jẹ. Iru ẹda wa si ni o jẹ? Gẹgẹ bi ọrọ bibeli, o jẹ opurọ, ole, apaniyan, apanirun ati ajẹnirun (Johannu 8:44&10:10; 1Peteru 5:8).
Nitorina, ti o ba ṣe aṣiṣe pẹrẹ lati fun ni anfaani tabi aye lati ṣiṣẹ nibi ti o ba wa, ki o da ọ loju pe itanjẹ, airoju, adanu, irora ati iparun ko ni salai bẹrẹ si ni waye nibẹ. Ti o ba si lọra tabi se diẹdiẹ lati ṣe amulo agbara ati ọgbọn Ọlọrun lati le danu, o ṣeṣe ki o padanu ohun rere ati eyi ti o peye gbogbo ti o ti rigba lọwọ Ọlọrun. Wo ọrọ Adamu ati Efa, fun apẹẹrẹ. Aye melo gan ni wọn fun Esu lati ṣiṣẹ? Aye diẹ kekere ni! Akoko diẹ na ni fi silẹ fun irọ rẹ nipa Ọlọrun ati awọn aṣẹ rẹ ti ilẹkun fi ṣi silẹ fun lati ṣiṣẹ ninu aye Efa. Ki wọn si to mọ ohun ti o n ṣẹlẹ, a ti ja wọn lole gbogbo nkan rere ti Ọlọrun fi fun wọn, a si tun le wọn jade kuro ninu ọgba Edẹni rẹ. (Wo: Jenesisi 3)
Nibakanna, gbe ọrọ Judasi ọmọ Isikarioti wo. Bawo ni o ṣe padanu aye rẹ gẹgẹ bi apositeli Oluwa, ti o si tun padanu ini rẹ ninu ijọba ayeraye ti Ọlọrun? Nipasẹ fifi aye silẹ fun Esu lati ṣiṣẹ ninu aye re ni. O bẹrẹ kẹrẹkẹrẹ nipa fifi aye gba a lati jẹ ki o gbagbọ pe ko si nkan ti o buru nipa jija Oluwa lole. Nitorina o bẹrẹ si ni ran ara rẹ lọwọ pẹlu owo ti a fi si ikawọ rẹ lai gba aṣẹ (Johannu 12:6). Ki o si to mọ nkan ti o n ṣẹlẹ, o ti sọ igbagbọ rẹ ninu Oluwa ati iṣẹ iranṣẹ rẹ nu, o si tun bẹrẹ si ni ro pe o san fun oun lati ta Oluwa fun awọn ọta rẹ, ki oun ba le gba ara oun la, ju pe ki oun ṣegbe pẹlu Oluwa ati awọn apositeli toku. Sugbọn nigba ti Esu pari iṣẹ laye re ati nipasẹ rẹ tan, o han kedere si pe a ti tan jẹ, a si tun ti ba aye rẹ jẹ lati inu wa. Ero kan ti o wa ṣẹku lọkan rẹ ni bi yo ṣe gba ẹmi ara rẹ, to si jẹ pe bẹ ẹ gẹgẹ gan lo se.
Wayi o, ti Esu ba le rapala wọ inu ọgba daradara ati ọgba ti o pe ni, Edẹni, ti o si ja awọn aṣoju iran eniyan mejeji akọkọ ni ole ayọ ati ini wọn, ibo gan ni o ro pe ko ni le wọ? Lafikun, ti o ba le rapala wa inu ijọ akọkọ ti Jesu funrarẹ jẹ olusọagutan rẹ, ijọ eniyan mejila pere, ti o si ba aye ọkan lara wọn jẹ, njẹ o wa ro pe ko ni le rapala wọ ile rẹ tabi ijọ rẹ ti o ba fi aye gba? Nse ni o n tan ara rẹ jẹ ni ti o ba ro bẹ.
Wo, Esu ko ki i ṣe ẹnikan ti a kan le fi a aye gba fun idikidi. Aijẹbẹ, o di dandan ki a kabamọ rẹ titi ayeraye. Ọna kan ṣoṣo lati ma si ṣe fi aye gba lati ṣiṣẹ ninu aye wa tabi nipasẹ aye wa ni ki a mu ọrọ Ọlọrun lọkunkundun. Niwọn igba ti a ba ti mu ọrọ rẹ lọkunkundun, ti a si n gbe aye wa ni ibamu pẹlu re, Esu ko ni fi igba kankan ri wa yan jẹ. Sugbọn, fun idi kan tabi omiran, ti a ba bu aye ọrọ rẹ ku nibikibi ninu aye wa, ibẹ gan ni yo jẹ ilẹkun ti ọta wa buburu yi yo gba wọle lati ṣiṣẹ ati lati sọ nkan di rududrudu fun wa.
Ti iwọ ba wa fẹ le ti ilẹkun aye rẹ gbọingbọin mọ Esu ni gbogbo igba, o gbọdọ kọ lati mu ọrọ Ọlọrun ni ọkunkundun ninu ohun gbogbo. Adura mi si ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati fun ọrọ Ọlọrun ni aye ti o tọ si ninu aye re ati ninu awọn nkan ti o jẹ tirẹ, ni orukọ Jesu. Amin.
Ọsẹ ire o.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 23, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 16