Wayi o, ti o ba jẹ pe o ko mọ tabi pe o ti gbagbe, mo fẹ pe akiyesi rẹ si pe awọn oniwaasu ni ojuṣe lati kọ awọn eniyan ni ohun gbogbo ti o ni i ṣe pelu ipinnu ati ifẹ Ọlọrun. Idi si ni yi ti Pọọlu ṣe sọ fun awọn ara Kolose pe, “Nisinsinyi emi n yọ ninu iya mi nitori yin, emi si n ṣe aṣepari iṣẹ ipọnju Kirisiti ti o ku lẹyin ni ara mi, nitori ara rẹ, ti i ṣe ijọ: Eyi ti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fi fun mi fun yin lati mu ọrọ Ọlọrun ṣẹ.” (Kolose 1:22) Njẹ o ri bayi? Pọọlu sọ wipe iṣẹ iriju ti oun gba lọwọ Ọlọrun ni lati mu ọrọ Ọlọrun ṣẹ. Ọna miran lati ṣo eyi ni pe iṣẹ iriju Pọọlu ni lati waaṣu ọrọ ni pipeye. O tunmọ si pe ko le ṣo pe awọn ẹka bayi ninu ọrọ Ọlọrun ni oun o fi ṣe iwaasu ati pe awọn ẹka ọrọ rẹ bayi ni oun ko ni fi ṣe iwaasu. Ko le sọ wipe iwa mimọ nikan ni a ran oun lati fi se iwaasu, ko ki ṣe fififunni, tabi pe igbagbọ ni a fi ran oun lati ṣe iwasu ko ki i ṣe idajọ ayeraye. Iṣẹ rẹ ni lati polongo ohun gbogbo ti ọrọ Ọlọrun n sọ fun awọn eniyan.
Pipolongo ohun gbogbo ti o ni i ṣe pẹlu ifẹ ati ipinnu Ọlọrun ki i wa ṣe nkan ti a le ṣe ni ọjọkan. Ọpọ igba ni o jẹ pe o le gba iṣẹ aṣekara ọpọlọpọ ọdun ati suuru lọwọ ẹni ti o n waasu ọrọ Ọlọrun ki o to le fi gbogbo ifẹ ati ipinnu Ọlọrun han si awọn ti o n kọ. Ṣugbọn o ṣe e ṣe, o si gbọdọ jẹ ṣiṣe. A si ri amudaju eleyi ninu ọrọ Pọọlu si awọn alagba ijọ Efesu, eyi ti o ka bayi: “Nitori ti emi ko fa ṣẹyin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun yi.” (Ise Awọn Apositeli 20:27) Nitorina, wiwaasu gbogbo ipinnu ati ifẹ Ọlọrun ṣe e ṣe, o si jẹ ohun ti gbogbo oniwaasu gbọdọ fi ara rẹ jin lati ṣe.
Ṣugbọn ṣa o, erongba Ọlọrun kọ ni pe ki o jẹ kiki oniwaasu ni yo fi ara rẹ jin lati ma polongo gbogbo ifẹ ati ipinnu rẹ; erongba rẹ ni pe ki awọn ti a n kọ ni ọrọ Ọlọrun naa fi ara wọn jin lati tẹwọgba gbogbo ifẹ ati ipinnu rẹ fun aye wọn. O wa ṣeni laanu pe nkan ti a ri ninu ọpọ ọmọ Ọlọrun ni pe wọn a ma yan ẹbọ ninu iha ti wọn n kọ si ọrọ Ọlọrun. Wọn fẹ yan otitọ ọrọ Ọlọrun ti awọn olukọ wọn yoo kọ wọn ati irufẹ otitọ ọrọ rẹ ti wọn yo tẹwọgba ati ti wọn yo ṣe amulo. Nitorina, wọn a ma ti ibikan de ibikan lati wa awọn oniwaasu ti yo waasu tẹwọn lọrun. Idi si ni yi ti aye wọn ko fi baradọgba.
Awa naa nilo lati ṣe agbayẹwo aye wa lati ri boya aye wa baradọgba ninu irinajo igbagbọ wa tabi ko baradọgba. A nilo lati bere lọwọ ara wa, “Njẹ ari awọn otitọ ọrọ Ọlọrun ti a n sa fun ati ti a ko tilẹ fẹ ki wọn fi bawa sọrọ rara tabi ti a ko fẹ ṣe amulo?” Ti a ba ri, a nilo lati ronupiwada, ki a si yi iha ti a kọ si wọn pada. Idi si ni pe a ko le jẹ gbogbo nkan ti Ọlọrun fẹ ki a jẹ, niwọn igba ti a ko ba mura lati mọ gbogbo ifẹ ati ipinnu rẹ fun wa, ki a si fi aye gba wọn ninu aye wa.
Lotitọ, a le ma le fi ara da ọna ti awọn kan n gba ṣe alaye tabi amulo awọn isọri ọrọ Ọlọrun kan. Eyi ko wa tunmọ si pe ki a ma ni itara lati mọ nkan ti Ọlọrun n sọ nipa awọn nkan wọnyi ati lati ṣe amulo wọn ni aye wa. Fun apẹẹrẹ, ọpọ ẹkọ odi ni o wa ni oni lori fififuni, paapaajulọ fififun awọn adari wa ninu ijọ. Sibẹsibẹ, eyi ko jasi pe ọrọ Ọlọrun ko pa a laṣẹ fun wa lati ma fi nkan ini wa ran awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa lọwọ (1Korinnti 9:14; Galatia 6:6). Ti a ba si kọ lati mu ẹkọ fififunni ati fifi ohun ini wa ran awọn ti o n fi ọrọ Ọlọrun bọ wa lọkunkundun, nitori pe awọn kan n ṣe eyi lọna aitọ, a ti n ṣe aigbọran si Ọlọrun niyẹn. Lotitọ o, o le e jẹ pe a n gbọran si lẹnu lori gbogbo ọrọ aye wa yoku. Ṣugbọn niwọn igba ti a ti n ṣe aigbọran si lẹnu ni ọna kan ni aye wa, ko si bi a ṣe le jẹgbadun gbogbo Ibukun ati ipese rẹ fun aye wa. Lafikun, o tun le wa jẹ pe abala aye wa ti a ko ti gbọran si lẹnu yi ni yoo jẹ ọna fun Satani lati fiya jẹ wa.
Nitorina, ji kuro ninu ogbe ti o n to, ki o si rẹ ara rẹ silẹ lati gba gbogbo nkan ti Ọlọrun n ba ọ sọ lori iwa mimọ, idajọ ayeraye, fififunni, ifẹ ati bẹẹbẹẹlọ nipasẹ ọrọ rẹ. Iwọ sati rẹ ara rẹ silẹ lati gba ẹkunrẹrẹ ọrọ rẹ fun ọ. Nipa eyi, gbogbo nkan ti o ku diẹ kaato ninu irinajo igbagbọ rẹ ni a o pese, aye rẹ yoo si jẹ kikọ lati gbe iwa Jesu Kirisiti yọ lẹkunrẹrẹ.
Ki o ni oṣu Ọwara 2020 idẹra.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com | alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owara 04, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 22
2 replies on “Gbogbo ipinnu ati ifẹ Ọlọrun”
I have been reading out many of your posts and i can claim pretty nice stuff. I will surely bookmark your site. Trixie Nicky Inesita
Waoo, thank you for that