Categories
Latori tabili Paitor

Lo ẹbun ẹmi rẹ

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Owewe 2020. Adura mi si ni pe ki Ọlọrun ṣi oju rẹ lati mọ ohun rere gbogbo ti O ti gbin sinu rẹ, ki O si tun fun ọ ni okun lati le pọ si ni wiwulo pẹlu rẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ẹnikọọkan wa, bi a ti ri kedere ninu bibeli, ni Ọlọrun ti bukunfun pẹlu, okereju, ẹbun ẹmi kan tabi omiran. Eyi tunmọ si pe ko si ọmọ Ọlọrun kan ti Ọlọrun lero lati lo lati bukufun awọn ọmọ rẹ yoku ati awọn ara aye yi ni ọna ti o ga. (Wo: 1Korinnti 12:7) O wa ṣeni laanu pe, nitori aimọkan, ọpọ awọn ọmọ rẹ ni ko fi taratara wulo ni lilo awọn ẹbun ti O fi fun wọn. Nitorina, a ri wipe, ni ọpọ awọn ijọ wa ati ni ọpọ igba, ni o jẹ wipe awọn perete ni o n lo ẹbun wọn pẹlu imura ati ni ododo lati fi ẹbun na sin awọn miran. Nse ni awọn ọmọ ijọ yoku a ma fi gbogbo igba duro de awọn ti yo sin wọn tabi misi wọn.

Boya iwọ na gan jẹ ọkan lara awọn ti o n fi gbogbo igba duro ki awọn miran wa sin wọn. Gbogbo igba ni o n fẹ ki ẹnikan gbadura fun ọ, ṣugbọn iwọ gan ko fẹ gbadura fun ẹnikankan. Tabi o n fẹ ki ẹnikan wa bẹ ọ wo, ṣugbọn iwọ gan ko ṣetan lati bẹ ẹnikẹni wo. Tabi o fẹ ẹni ti yo fun ọ ni nkan tabi ṣe iranwọ ohun kan tabi omiran fun ni aye rẹ, ti o si jẹ pe iwọ gan ko tilẹ nifẹ si a ti ran ẹnikẹni lọwọ. Mo fẹ ki o mọ pe eleyi lodi si ete Ọlọrun fun ijọ rẹ. Ko ki i ṣe aba tabi ero rẹ nigbakankan pe perete ninu awọn eniyan rẹ ni yo ma kopa ninu iṣẹ isin. Ki wa gan ni O fun ẹnikọọkan wa ni, okereju, ẹbun kan si?

Wo o, nkan ti Ọlọrun fẹ fun ẹnikọọkan wa ni ki a mọ ẹbun tabi awọn ẹbun ti O fun wa, ki a si bẹrẹ si ni kẹkọ lọdọ rẹ lori bi a se le lo wọn fun rere gbogbo awọn ti o wa ni ayika wa. Lọna yi, gbogbo wa yo dijọ ran ara wa lọwọ, a o si pese fun awọn nkan ti o ku diẹ kaato ninu igbagbọ, iwa ati nkan ini wa. Bi a ba si ṣe n ran ara wa lọwọ lọna yi, a o bẹrẹ si ni dagba si ninu imọ Jesu Kirisiti ti a ni ati ninu fifi iwa rẹ han ninu aye okunkun yi. (Wo: Efesu 4:11-16)

Idi yi gan wa ni Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Roomu, ṣe sọ wipe, “Njẹ bi awa si ti n ri ọtọọtọ ẹbun gba gẹgẹ bi oore-ọfẹ ti a fun wa, bi o ṣe ti isọtẹlẹ ni, ki a maa sọtẹlẹ gẹgẹ bi iwọn igbagbọ wa; Tabi iṣẹ iranṣẹ, ki a kọju si iṣẹ iranṣẹ wa: tabi ẹni ti n kọ awọn eniyan, ki o kọju si kikọ rẹ; Tabi ẹni ti o n gba awọn eniyan niyanju, si igbiyanju: ẹni ti o n fi funni ki o maa fi inu kan ṣe e; ẹni ti n se olori, ki o maa se e ni oju mejeeji; ẹni ti n saanu, ki o maa fi inu didun ṣe e.” (Roomu 12:6-8) Lafikun, Peteru naa, ninu lẹta rẹ akọkọ, sọ wipe, “Bi olukuluku ti ri ẹbun gba, bẹẹ ni ki ẹ maa ṣe ipinfunni rẹ laarin ara yin, bi iriju rere ti oniruuru oore-ọfẹ Ọlọrun. Bi ẹnikẹni ba n sọrọ, ki o maa sọ bi ẹni ti Ọlọrun n gba ẹnu rẹ sọrọ; bi ẹnikẹni ba n ṣe iṣẹ iranṣẹ, ki o ṣe e bi agbara ti Ọlọrun fi fun un: ki a le maa yin Ọlọrun logo ninu ohun gbogbo nipasẹ Jesu Kirisiti, ẹni ti ogo ati ijọba jẹ tirẹ lailai ati lailai. Aami.” (1Peteru 4:10-11)

Iwọ na gbe ọrọ awọn apositeli yi yẹwo. Gbogbo rẹ n tọka si pataki ki ẹnikọọkan wa mọ ẹbun tabi awọn ẹbun ẹmi ti Ọlọrun ti fun un, ki o si bẹrẹ si ni lo fun imudagbasoke awọn miran ati fun iyin Ọlọrun. Nitorina, ki ni ẹbun ẹmi tabi kini awọn ẹbun ẹmi rẹ? Ma si ṣe sọ wipe, “Emi o ma ni ẹbun kankan,”nitori lati sọrọ bi eleyi ni lati sọ wipe o ko ki i ṣe ọmọ Ọlọrun. Ti o ko ba mọ ẹbun ẹmi tabi awọn ẹbun ẹmi tirẹ, nse ni o yẹ ki o gbadura si Ọlọrun ki o si oju rẹ ki o ba le mọ wọn. Lafikun, o tun le ba awọn onigbagbọ ti o le fọkan tẹ sọrọ pe ki wọn sọ irufẹ awọn ẹbun ti wọn ba kofiri ninu aye rẹ fun ọ. Nikete ti o ba si ti mọ ẹbun tabi awọn ẹbun ẹmi rẹ, nse ni ki o bẹrẹ si ni lo wọn pẹlu ifẹ. Ọlọrun yo si bukunsi gbogbo igbesẹ igbagbọ ti o ba gbe lori lilo ẹbun rẹ, yi o si tun lo lati bukunfun awọn eniyan ni ọna ti o kọja ero ẹnikankan.

Lakotan, ma ṣe jẹ ki a fi igba kankan gbọ ki o ma sọ ohunkohun ti o ba jọ eyi, “Ẹbun temi ko ma ja mọ nkankan. Nitorina, tani yo tilẹ se bi pe wọn ri mi tabi ta gan ni ẹbun na fẹ wulo fun?” Bibeli sọ fun wa pe ko si ẹbun ẹmi ti a le ka si yẹpẹrẹ. Nkan ti o le sọ ẹbun ẹmi di yẹpẹrẹ ni ki a kọ lati lo. Dọkasi ko ki i ṣe oniwasu. Ṣugbọn awọn ọmọ ijọ rẹ ka si eniyan pataki nitoripe o lo ẹbun fififunni ti o ni pẹlu otitọ ati pẹlu akunyawọ (Ise Aposteli 9:36-42). Ti iwọ na ba ṣe amulo ẹbun rẹ, ko ni pẹ rara ti awọn ti o wa ni ayika rẹ yo fi bẹrẹ si ni fi ẹbun rẹ tọrọ lọwọ Ọlọrun. Mo si gbadura pe ki Ẹmi Ọlọrun fi okun kun ọkan rẹ ki o ba le ṣe ohun ti o tọ lori ọrọ yi. Amin.

Ọse ayọ o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owewe 13, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 19

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *