Olufe: ki ore-ofe, aanu ati alaafia je tire lailodiwon lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki o kaabo sinu osu Agemo 2020, eyi ti o je osu eyi ti o bere idakeji awon osu ti o wa ninu odun yi. Adura mi si ni pe ki Olorun fi ayo re kun okan re de bi pe o ko ni ranti gbogbo ibanuje tabi adanu kankan ti o wu ki o ti ba pade ninu idakini awon osu odun yi, ni oruko Jesu. Amin.
Nibayi, mo fe gba o niyanju, bi a se n bere idajeki awon osu odun yi, pe ki o fi gbogbo ara re jin fun Olorun ninu ohun gbogbo. Eyi tunmo si pe ki o ma se fun Olorun ni aabo ijosin tabi ki isin re si ma je eyi ti o wa lekunrere. Dipo be, fi ara re jin fun patapata ni ijosin ati ni ise isin. Idi si ni pe eyi ni ona kansoso ti o fi le gbadun re ni ekun rere, ki o si tun gba oriyin lodo re.
Ki a so otito, okan lara idi ti opo ninu ijo loni ko fi ma ni irufe awon iriri ologo ti o ye ki won ma ni ninu irin won pelu Olorun ni pe won ko fi gbogbo ara won jin fun. Awon wonyi a ma yan igba ti won fe gboran si Olorun lenu ati igba ti won ko ni gboran si lenu. Won a si tun ma yan bi awon se fe sin ati igba ti awon fe sin, leyi to je pe nse ni o ye ki won ma ko lodo re bi o se ye ki won sin lona ti o pe ati ni ona ti o ye. Awon kanna yi ni yo tun wa ma se aroye pe Olorun ko mu oro won lokunkundun. Nje eyi tie le fi ona kankan je otito bi?
Dafidi, ninu okan ninu orin re, so wipe, “Fun alaaanu ni iwo o fi ara re han ni alaaanu; fun eni ti o duro sinsin ni iwo o fi ara re han ni diduro sinsin. Fun olokan mimo ni iwo o fi ara re han ni olokan mimo ati fun olokan wiwo ni iwo o fi ara re han ni onroro.” (Saamu 18:25-6) Nje o ri bayi? Iha ti a ba ko si Olorun ni yo so irufe iriri ti a o ri ninu irinajo aye wa. Ti a ba fi gbogbo okan wa jin fun Olorun, Oun na yo fi gbogbo okan re jin fun wa. Ti a ba si fi arekereke baalo, Oun na yoo fi ara re han bi alarekereke. Oun yo se eyi ki o ba le je ki o ye wa pe Oun ko ki i se eni ti enikeni le tan je. O mo ohun gbogbo nipa wa, O si le so boya okan wa wa pelu re lotito ati lati sin lododo tabi beeko.
Fun apeere, wo nkan ti a so nipa Oba Amasaya ti orile-ede Juda: “O si se eyi ti o to ni oju Oluwa, sugbon kii se pelu okan pipe.” (2Kironika 25:2) Iwo na gbe yewo. Oba yi, ni oju awon eniyan, dabi olujosin Olorun. Eyi tunmo si pe oun na n soro ati rin bi eni ti o feran Olorun ati eni ti o si je tire. Sugbon Olorun mo pe okan re ko to. Nitorina, ni iwon akoko kan, nkan ti o wa ninu okurin yi gan wa fi ara ran. O pa Olorun ti fun orisa, bi o tile je pe o ti ri agbara Olorun fun isegun ati fun orisirisi ohun daradara ni aye re. Lati igba ti o si ti wa pa Olorun ti titi di igba ti won fi pa ni ifonafonsu, igbe aye re ko ri bakana mo. (2Kironika 25)
Nitorina, se agbeyewo ara re, gege bi oro Poolu, lati ri boya okan re je ti Olorun patapata tabi beeko (2Korinnti 13:5). Dan ara re wo ki o fi mo daju pe igbagbo ti o so wipe o ni ninu Olorun ki i se iro. Ayabe, yato si pe o ko ni ni anfani lati gbadun Olorun lekunrere, nse ni wa tun fi akoko ati aye re sofo. Wo o, ti okan re ko ba ki se ti Olorun patapata, nigba ti o ba di akoko kan, ododo ibi ti okan re wa gan yoo fi ara han. Eyi ni alaye fun bi awon kan ko se si ninu ijo Olorun mo ni oni. Sugbon lara awon wonyi ni awon eniyan ti ka si Kiristiani otito tele ri. Idi si ni pe awon na n pede bi awon Kiristiani yoku se n se, won n wa si ipade ijo loorekoore, o si tun sese ki won ti sin gege bi olori lona kan tabi omiran ri. Sugbon okan won ko fi igba kankan wa pelu Olorun patapata; ibo miran ni okan won wa. Nitorina, nigba ti o ya, awon isele ti o n sele fi eyi ti o je otito han gbogbo eniyan nipa nkan ti won n lepa.
Nje ti iwo na ko ba fe ki opin re ri bi tiwon, o gbodo dabobo okan re lati ma mu Olorun pelu owo yepere ati lati ma ba lopo pelu itanje. Adura mi si ni pe ki aye re gba ipamo kuro lowo ohunkohun ti o ba le mu ibaje ba tabi si dari ni onakona. Ose ire o.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280). Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Agemo 05, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitor | Nomba: Vol. 9, No. 5