Categories
Latori tabili Paitor

Jẹ ki ara rẹ ya gaga si ipe rẹ –

Akori: Jẹ ki ara rẹ ya gaga si ipe rẹ – Lati owo: J.O. Lawal

Ojo: Igbe 25, 2021 | Atelera: Latori tabili Paitọ Nomba: Vol. 9, No. 51

Olufẹ: ki oore-ọfẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titilai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Kaabọ sinu ọsẹ ti o pari oṣu Igbe 2021. Adura mi ni pe ki ọkan rẹ ma fi gbogbo igba gba okun lati tẹwọgba ipe Ọlọrun lori aye rẹ, ki o si tun mu ni pataki, ki aye rẹ ba le ma fi gbogbo igba fi ẹwa rẹ han siwaju ati siwaju si ni eyi ti o ku ni ọjọ aye rẹ. Amin.

Bi a ṣe ri ninu bibeli, ko ki i ṣe awọn ti a mọ bi adari ijọ nikan ni Ọlọrun pe. Dipo eyi, ẹnikọọkan ti o jẹ onigbagbọ ninu Kirisiti Jesu ni O pe. Ki wa gan ni a pe wa si? Akọkọ, a pe wa lati wa ni idapọ pẹlu rẹ. Bibeli sọ pe, “Olododo ni Ọlọrun, nipasẹ ẹni ti a pe yin sinu idapọ Ọmọ rẹ Jesu Kirisiti Oluwa wa.” (1Korinnti 1:9) Ṣe iwọ na ri bayi? Ọlọrun pe gbogbo wa lati gbe aye wa pẹlu rẹ, ki Oun na ba le gbe pẹlu wa ninu ibadapọ mimọ. Nitorina, ni bayi, a jẹ alabapin ninu aye rẹ, ninu ohun ti o jẹ ki o jẹ Ọlọrun, ninu iṣẹ rẹ, ninu ogo rẹ, ninu ijọba ayeraye rẹ ati pẹlupẹlu ninu ikanran awọn ọmọ eniyan mọ.  

Ikeji, Ọlọrun pe wa ki O ba le fi ọgbọn rẹ ati awọn iṣẹ ara rẹ han nipasẹ wa si awọn ẹda rẹ, paapaajulọ awọn eniyan, awọn angẹli ati awọn ẹmi aimọ. Idi ni yi ti bibeli fi sọ pe, “Ki a baa le fi ọpọlọpọ oniruuru ọgbọn Ọlọrun han nisinsinyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ. Gẹgẹ bi ipinnu atayebaye rẹ, eyi ti o mu ṣe nipasẹ Kirisiti Jesu Oluwa wa.” (Efesu 3:10-11) O tun sọ pe, “Ṣugbọn ẹyin ni iran ti a yan, olu-alufaa, orilẹ-ede mimọ, eniyan ọtọ; ki ẹyin ki o le fi ọla nla ẹni ti o pe yin jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ han.” (1Peteru 2:9)

Ṣe iwọ na ri bayi? Ọlọrun pe wa jade kuro ninu okunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ, O si ṣe wa ni eniyan ara ọtọ si i. Nitorina, o jẹ ẹni ọtọ si Ọlọrun. Emi naa jẹ ẹni ọtọ si Ọlọrun. Gbogbo wa jẹ ẹni ọtọ si Ọlọrun. Ko si si ẹnikẹni ninu wa ti o jẹ ẹni ọtọ si i ju awa yoku lọ. Bakanna ni gbogbo wa ṣe jẹ pataki si to, nitoripe iye kan naa ni O san lati ra gbogbo wa pada (1Peteru 1:18-19). Ki si ni idi ti O fi ṣe wa ni ayanfẹ rẹ ni ọna yi? Idi ni pe ki O ba le bẹrẹ si ni fi oniruuru ọgbọn rẹ ati awọn iṣẹ iyanu rẹ han nipaṣẹ ẹnikọọkan wa, ti ko si ki i ṣe nipasẹ awọn paitọ, wolii ati awọn adari ijọ wa nikan.

Nitorina, nibikibi ti o ba wa ati ipo yowu ti o le wa ninu aye yi, Ọlọrun ti yan ọ, O si tun ti pe ọ lati ma gbe igbe aye ti yoo jẹ ki awọn eniyan, angẹli ati ẹmi aimọ mọ pe Ọlọrun ti o ga, ti o gbọn, ti o si tun dara ni Oun jẹ. Njẹ irufẹ igbe aye yi ni o wa n gbe bi? Ṣe igbe aye ti o ga, igbe aye ọlọgbọn ati igbe aye daradara ni o n gbe bi, igbe aye ti awọn ti o wa ni ayika rẹ ko le ṣe alaikọbiara si tabi alaifẹran? Abi igbe aye ti ko wu ni lori, igbe aye omugọ ati igbe aye ti o n rin awọn eniyan lara ni o n gbe?

Ki a sọ ododo, igbe aye ti ọpọ awọn eniyan Ọlọrun n gbe nibi ti wọn wa jẹ eyi ti ko le wu awọn ti o wa ni ayika wọn lori tabi ti o le fa wọn mọra. Nkan ti mo n sọ ni pe igbe aye ti wọn n fi ojoojumọ gbe ko wu awọn ti aye yi lori lati fẹ ni nkan ti wọn ni tabi da bi wọn ṣe da. Bawo si ni ori o ṣe wu ẹnikẹni lati fẹ ẹ dabi iru ẹni ti o jẹ ninu Kirisiti, niwọn igba ti ara iwọ gan ko ya gaga si i tabi niwọn igba ti o ro pe o kudiẹ kaato fun ọ nitoripe o ko ni awọn nkan ti wọn ni tabi nitoripe o ko wa ni awọn ipo ti wọn wa?

Bi bibeli ṣe sọ fun wa, Ọlọrun ko yan ẹnikẹni ninu wa tabi kọ ẹnikẹni ninu wa silẹ nitori ipo wa ni awujọ, yala ipo nla ni tabi ipo kekere. Ko yan tabi kọ ẹnikẹni ninu wa silẹ nitoripe ko jẹ olowo, ẹni ti o kawe rẹpẹtẹ tabi gbajumọ. Dipo bẹẹ, O yan wa lalai fi ti bi a ṣe jẹ nipa ti aye yi ṣe. O si yan wa lati ma a ṣe awọn nkan ọgbọn ati awọn nkan ti o ga, ti yoo si ja awọn eniyan, angẹli ati ẹmi aimọ laya. (Wo: 1Korinnti 1:26-31)

Nitorina, ko si idi kankan ti ko fi yẹ ki ara wa ya gaga lori ipe wa, bi o tilẹ jẹ pe ipo ti o kere julọ ni a wa ni aye yi, iyẹn ipo ẹru tabi ẹlẹwọn. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Pọọlu duro gẹgẹ bi ẹlẹwọn niwaju Ọba Agiripa, Banike ati Fẹsitusi, ti wọn jẹ ẹniyan pataki ninu aye igba naa, ko sọrọ rara bi ẹni ti ko ni laari tabi bi ẹni ti aye rẹ ti dojuru tabi bi ẹni ti ọrọ aye rẹ ti su u. Dipo eyi, o sọrọ pẹlu ara ti o ya gaga nipa igbe aye rẹ pẹlu Ọlọrun to bẹẹ gẹ ti wọn fi bẹrẹ si ni wo boya ki awọn tu u silẹ lẹsẹkẹsẹ. (Wo: Iṣe awọn apositeli 25:13-26:32)

Wayi o, nkan ti Ọlọrun n fẹ lati ọdọ wa gan an niyẹn. O fẹ ki a ma fi gbogbo igba ya awọn ara aye yi lẹnu nipa bi a ṣe n gbe ati bi a ṣe n wuwa, ki wọn ba le ma sọ pe, “Ti awọn wọnyi ko ba ki i ṣe were, a jẹ pe awọn gan ni wọn mọ nkan ti wọn n ṣe.” Nigba ti wọn ba si sunmọ wa si, awọn gan yoo wa ri aridaju pe awa gan ni a mọ nkan ti a n ṣe. Njẹ o o wa jigiri bi, ki o gbe aṣọ itiju rẹ sọnu, ki o si bẹrẹ si ni gbe igbe aye ẹni ti a da ọ lati gbe pẹlu ara ti o ya gaga? Adura mi fun ọ ni pe ki o gba iwuri ati okun lati ṣe bẹẹ gẹgẹ, ni orukọ Jesu. Amin.

Ki o ni ọsẹ alarinrin.

Copyright © 2021, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to pastor@abcministry.com  or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)