Categories
Latori tabili Paitor Others

Ma se padanu emi re tori ohunkohun

Olufe: ki ore-ofe, aanu ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabo sinu ose miran ninu odun 2020. Mo gba adura pe ki ojurere Olorun je ki aye yi dun, ki o si tun larinrin fun o ninu gbogbo ose na, ni oruko Jesu. Amin.

Bi a se n bere ose tuntun miran, mo fe ran o leti pe bi o ti wu ki aye yi dun ki o si larinrin to, ibi ti Olorun ti pese sile fun awon ti o feran re dara ju u lo ni ona ti ko se fenu so. Bi o si ti wu ki aye yi buru to loju wa, ibi ti Olorun pese sile fun esu ati gbogbo awon olukorira Olorun buru ju lo ni ona ti o koja nkan ti a le se afiwe. Nitorina, a gbodo lakaka lati ri pe a ko je ki ibasepo wa pelu aye yi ati awon nkan ti o wa ninu re jawa lole ibugbe daradara ti Olorun ti pese sile fun wa ni ayeraye.

Jesu Oluwa wa, ni akoko kan ti O n ko awon eniyan, so wipe, “Nitori pe ere kin ni fun eniyan, bi o jere gbogbo aye, ti o si so emi re nu? Tabi kin ni eniyan iba fi se pasipaaro emi re?” (Matiu 16:26-27) Eyi tunmo si pe ko si ona ti a le gba fi aye yi ati gbogbo nkan daradara inu re ati ogo re we iyebiye okan kan soso niwaju Olorun. Nigbati aye yi je eyi ti o di dandan ko segbe, ki o si ma si i mo, okan eniyan kookan ti Olorun da je eyi ti yoo wa titi lailai. Nitorina, ti a ba ti le fi gbogbo aye yi jinki re, o di dandan ki o padanu re lojokan.

Fun apeere, ikawo Satani ni aye yi ati isejoba re wa, niwon ibi ti Olorun fi aye gba a mo (Luuku 4:5-7; 1Johanu 5:19). Sibesibe, dandan ni o je fun lati padanu re, ki oun gan si fi aye re sofo sinu adagun ina titi lailai, nigbati ti akoko ba to fun Olorun lati fi idi ijoba ayeraye re mule (Ifihan 20:0). Lonakanna, ti enikeni ba tile fi gbogbo aye yi se ifa je, o di dandan ki o padanu re lojokan, nitori pe aye na je eyi ti a toju fun iparun ina (2Peteru 3:10).

Sugbon pe a je ere aye yi gan ko ni iyonu. Nkan ti mo n so ni wipe pe eniyan ni gbogbo ohun daradara ti aye yi, ti o si n gbadun ara re pelu won gan ko so wipe wahala wa fun. Nkan ti o mu afiyesi wa gan ni pe ki mura lati ma je ki ohunkohun ti a ba jere ninu aye yi muwa padanu okan wa. Eyi tunmo si pe ki a ma je ki awon ibasepo alarinrin ti a ni, ise wa, oko wa, ile ise wa ati beebelo jawa lole aaye wa ninu ijoba ayeraye ti Olorun. Idi si ni pe, nigba ti gbogbo awon nkan wanyi ba ti lo tan, o si je dandan ki won lo lojokan, awa o si wa digbi ni.

Nibo gan ni a o wa wa lojo yi ati pe tani a o wa pelu re? Nje odo Olorun ni a o wa bi, ninu ile isinmi ayeraye re, abi odo esu ni a o wa, ninu ile idaamu ati ibanuje ayeraye ti Olorun ti pese sile fun? O ni i se pelu iha ti a ba ko si Olorun ninu aye yi. Ti a ba mu Olorun ni okunkundun ju aye yi ati gbogbo nkan ti o wa ninu re, a o wa pelu re titi ayeraye. Sugbon ti a mu aye yi ni okunkundun ju Olorun lo, o di dandan ki a wa pelu Esu ati awon angeli re ninu ijiya titi ayeraye.

Nibakanna, oro yi koja pe a padanu gbogbo aye yi; o tun ni i se pelu idi ti a se padanu re. Ti a ba kuna lati ni tabi gbadun awon nkan meremere aye yi nitoripe a fe jere Olorun ati ile isinmi re, eyi dara ati pe olubukunfun ni wa. Sugbon ti a ba kuna lati ni tabi gbadun awon nkan wonyi nitori aimokanmokan ati iwa ole wa tabi nitori Esu joba le wa lori, o tunmo si pe a padanu ona meji niyen. Eyi si ni o se ye ki a kobiara si bi ibasepo wa pelu awon nkan aye yi se le pa ayeraye wa lara ati si oro Jesu Oluwa wa ti o so wipe, “Bi oju otun re ba mu o kose, yo o jade, ki o si so o nu; o saa ni ere fun o, ki eya ara re kan segbe, ju ki a gbe gboogbo ara re ju si ina orun apaadi. Bi owo otun re ba mu o kose, ge e kuro, ki o si so o nu; o saa ni ere fun o, ki eya ara re kan ki o segbe, ju ki a gbe gbogbo ara re ju si ina orun apaadi.” (Matiu 5:29-30)

Nje eyi ko wa tunmo si pe ki a yo oju wa jade nitooto tabi pe ki a ge eya ara wa kuro nitoripe a ko fe padanu isinmi ayeraye Olorun. Sise eyi ko tunmo si pe a o ri nkan ti a n wa. A sa mo wipe awon afoju, odi ati aro kan wa ti won je esu kekere ode, pelu pe won je alaabo ara. Nkan ti Oluwa n so nibi ni wipe, ti ba di dandan, a gbodo gbe oju agan si ohunkohun ti o ba le je ki a padanu ipese Olorun fun wa, ki a si di ero orun apadi. Adura mi ni pe ki Olorun ko okan re lati le da awon nkan wonyi mo, ki a si tun fun o ni okun lati se ohun ti o to lori won nipase ogbon Emi Olorun.

Ose ayo o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Agemo 12, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitor | Nomba: Vol. 9, No. 9

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *