Olufe: ki ore-ofe ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pelu idunnu ni mo se ki o kabo sinu ose miran ninu osu Agemo 2020. Mo si gbadura pe ki Olorun se ni asepe gbogbo ohun ti n se tire, ki o si tun se aye re ni aritokasi ni rere, ni oruko Jesu. Amin.
Gege bi a se ri ninu bible, oba akoko paa ti Olorun yan sori awon omo Isiraeli ni Soolu. Sugbon leyin akosile iku re, a ko so nkan miran to se pataki nipa re mo. Ki si ni idi? Idi ni wipe ko gbe igbe aye arikose si rere. Lotito, ogoji odun ni o fi joba. Sugbon gbogbo ogoji odun yi ko jamo nkankan loju Olorun nitoripe ko lowon lati bowo fun Olorun.
Sugbon oro ko ri bakanna rara fun Dafidi, eni ti o je oba leyin Soolu. Ohun fi okan re fun Olorun to be e ge ti Olorun fi bere si ni toka re si awon miran gegebi arikose. Fun apeere, nigbati O fa ijoba Solomoni ya si meji, ti O si fi eyi to poju ninu re fun Jeroboamu, O so fun lati enu Wooli Ahija pe, “Bi iwo ba si teti sile si gbogbo eyi ti mo pa lase fun o, ti iwo o si maa rin ni ona mi, ti iwo o si maa se eyi ti o to loju mi, lati pa ase mi ati ofin mi mo, gege bi Dafidi iranse mi ti se; e mi o si wa pelu re, emi o si ko ile ti o duro titi fun o, gege bi emi ti ko fun Dafidi, emi o si fi Isiraeli fun o.” (1Awon Oba 11:38-39)
Nje o ri bayi? Olorun n lo Dafidi gegebi arikose fun odomokunrin yi lati tele. Eyi tunmo si pe ti Jeroboamu ba le to isise aye re bi Dafidi ti se, ko ni ni isoro kankan pelu Olorun; dipo be, nse ni yoo ri oriyin gba lodo re. A si tun ri awon ibomiran ninu bibeli ti Olorun ti lo okunrin yi gege bi osunwon ti O fi n so bi awon oba miran se se daradara si. (Woo: 2Awon Oba 14:3, 18:1-3 & 22:1-2)
Sugbon ki gan ni idi ti Olorun fi lo Dafidi gegebi osunwon ti o fi won bi awon miran se se aseyege si? Se nitoripe o je alailese tabi eniyan pipe ni gbogbo ona ni bi? Rara o. Dafidi ko ki ni awon amuye wonyi rara. Oun na ni awon aleebu tire gege bi eniyan, o si tun da awon ese kan ti opo lara awon oba yoku ko da. Sibesibe, o je enikan ti okan re n fi gbogbo igba wa lati se nkan ti o dun mo Olorun ninu ati lati mu iyin ba oruko re. Nitori eyi, nigbati o ba dese, ti a si je ki o ye pe o ti dese, ko ki fi igba kankan ba Olorun jiyan tabi se awawi fun ese re. Dipo be, ko ni fi akoko sofo rara lati fi tokantokan ronupiwada ati lati toro fun idaraji. Eyi si je ki a ri idi ti Olorun fi nfi gbogbo igba lo gege bi osunwon ti O fi n so bi awon oba ti o tele se se daradara si.
Lonakanna, Olorun fe ki awa na gbe aye wa ni ona ti yoo je ki O le toka si wa gege bi eni ti awon miran le ti ara won keko si rere. Lotito, ko si enikankan ninu wa ti a le pe ni apeere omo eniyan to peye bi Olorun se fe ki eniyan ri. Jesu Kirisiti nikan ni o yege lona yi. Sibesibe, ti a ba fi tokantokan tele Olorun, ti si ngbe aye wa bi O se gbe tire, ko ni pe rara ti Olorun yo fi bere si ni fi wa se aritokasi irufe igbe aye ti o dun mo ninu fun awon miran (1Korinti 11:1; Filipi 3:17). Adura mi si ni pe, bi o se n tesiwaju ninu irinajo aye re, ki a fi okun kun okan re lati rin pelu afokansi lori oro yi, ki aye re ba le ma fi gbogbo igba bukun fun awon ti o wa ni ayika re.
Ose ire o.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Agemo 19, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 10