Categories
Latori tabili Paitor

Irisi idajo Olorun

Olufe: ki ore ofe ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki o kabo sinu ose ti o pari osu Agemo 2020. Adura mi si ni pe ikankan ninu ohun rere ti o ye ki o je tire losu na ko ni fo o ru, loruko Jesu. Amin.

Nje ti eniyan ba wo bi nkan se polukumusu ni orile-ede yi lakoko yi, paapajulo ti eniyan ba wo gbogbo awon esun iwa ibaje ati ti sise owo ilu ni basubasu ti a fi n kan die lara awon olori wa laipe yi, o se e se ki a fe ki Olorun gbera ni kiakia lati se idajo gbogbo awon ti oro na kan ati awon miran bi tiwon ti won n je ki o soro ki orile-ede wa ni itesiwaju. A si ri daju ninu iwe mimo pe Olorun ma n se idajo awon eniyan fun irufe awon iwa ika wonyi, eyi ti ki i se ni opin aye yi nikan sugbon ninu aye yi gan (1Samueli 3:13; 1Awon Oba 14:7-11). Sugbon awon ti a je onigbagbo, ti o si tun se e se pe awa na n fe ki Olorun mu nkan bo si otun ni kiakia ni orile-ede yi, ko gbodo gbagbe pe Olorun ko ki i se idajo bi awa eniyan ti ma n se.

Fun apeere, bi bibeli se fi han wa, bi o tile je wipe onidajo ododo ni Olorun je, ko ni ife si iku tabi iparun elese. Idi si ni yi ti o fi ma n mu suuru fun enikookan, ki won ba le ronupiwada, ki won si ma ba parun labe idajo re. (Wo: Esikieli 18:23&32; 2Peteru 3:9) Siwaju si, bi o ti le je pe Olorun ti pinu lati se idajo enikan nitori iwa ika re, O ni akoko tire lati se be. Nitorina, a ko le e kan loju lati se idajo enikeni niwon igba ti akoko ti O da ko i ti to. Bi a tile ti ri ninu iwe mimo, igba miran wa ti Olorun a duro ki iwa ika awon miran kun oju osuwon ki o to se idajo won. Nitori eyi, ekunrere idajo tabi ijiya fun ese awon wonyi le ma wa si ori won nigba aye won, ki o wa je pe ori awon aromodomo won ni yo ti farahan. (Wo: Jenesis 15:12-15; Ekisodu 34:7; 2Peteru 3:8)

Nkan miran ti o tun ye ki a kiyesi nipa idajo Olorun ni pe o ma n saba bere pelu awon eniyan re. Nigba ti iwa ika ba po ni ilu, ti a si fe ki Olorun se idajo re, ife wa ni gbogbo igba ni ki Olorun bere pelu awon ti o han gbangba si wa pe ika ni won, boya ki o tile bere pelu awon ti o buru ju lara won. Sugbon bibeli so nkan ti o yato si eyi fun wa. O so fun wa pe Olorun saba ma n bere idajo re laarin awon eniyan tire.

Fun apeere, nigba ti Olorun n pase lori idajo awon ara Juda, bi Esikieli se ko sile ninu iwe re, O so fun awon ti o ti yan fun ise yi, “E tele e la ilu lo, e si ma koluni: e ma je, ki oju yin dasi, bee ni e ma se saanu. E pa arugbo ati omode patapata, awon wundia ati omo keekeeke ati obinrin; sugbon e ma se sun mo enikan lara eni ti amin naa wa; e, si bere lati ibi mimo mi.” (Esikieli 9:5-6) Lafikun, Peteru naa, ninu leta akoko re, so wipe, “Nitori ti akoko naa de, ti idajo yoo bere lati ile Olorun wa: bi o ba si tete ti odo wa bere, opin awon ti ko gba iyinrere Olorun gbo yoo ha ti ri?” (1Peteru 4:17)

Se o ri bayi? Ti Olorun ba fe tun nkan se nibikan, yoo bere pelu awon eniyan tire ti o mo ohun ti o to ni sise. Iwo naa ro oro yi wo. Ti Olorun ko ba koko fiyaje awon eniyan tire ti o mo ohun ti o to sugbon ti ko se, ona wo logba tona fun lati bere si ni fi iya je awon ti ko gbagbo rara, ti won si n wu iwa ika? Ko si rara. Nitorina, ki Olorun ba le wa ni pipe, O koko gbodo tun ile tire to na, ki O to bere si ni fi iyaje awon ara ita.

Niwon igba ti o je bi oro se ri niyi, o ye ki awa ti a n pe Olorun lati se idajo iwa ika ni ile wa bere pelu si se idajo ara wa, ki a si ri pe ona wa to niwaju Olorun. Aijebe nigba ti idajo ti a n bere fun ba bere, awa gan ni yo koko to wo. Nitorina, e je ki a bere si ni mu oro iyanju Poolu lokunkundun ti o so wipe, “Sugbon ti awa ba wadii ara wa, a ki yoo da wa lejo. Sugbon nigba ti a ba n da wa lejo, lati owo Oluwa ni o ti n wa, ki a ma baa da wa lebi pelu aye.” (1Korinnti 11:31-32)

Ki o ni ipari osu ti o ga.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com / alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Agemo 21, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 11

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *