Olufẹ: kaabọ sinu ọsẹ miran ninu oṣu Ọwara 2020. Ki oore-ọfẹ, ifẹ ati aanu Ọlọrun ma ṣan lori aye rẹ titi gbogbo ọsẹ naa yoo fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.
Bi a ṣe wa n bẹrẹ ọsẹ tuntun yi, mo fẹ ran ọ leti pe iwọ nikan kọ ni Ọlọrun lero lati fi ara rẹ, ifẹ rẹ ati agbara rẹ han ninu aye yi. Dipo eyi, ero rẹ ni lati fi ara rẹ, ifẹ rẹ ati agbara rẹ han si gbogbo eniyan. Idi si ni yi ti bibeli ṣe sọ bayi, “Nitori ti Ọlọrun fẹ araye to bẹẹ gẹ, ti o fi ọmọ bibi rẹ kan ṣoṣo fun ni, ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ ma ba ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.” (Wo: Johanu 3:16)
Njẹ o ri bayi? Iwọ nikan kọ ni Ọlọrun fẹran. Emi nikan na kọ si ni O fẹran. O fẹran gbogbo eniyan, pẹlupẹlu awọn ti o korira rẹ, ti wọn si ma n fi gbogbo igba sọ ori odi si. Nitori eyi ni O ṣe n fi ifẹ ati aanu rẹ han si wọn lojoojumọ, bi wọn ko tilẹ mọ eyi tabi fin iyin fun nitori rẹ (Matiu 5:44). Olori ifẹ rẹ si wa ni pe, lọjọkan, ki gbogbo wọn mọ irufẹ ẹni ti o jẹ gan ati bi igbayegbadun wọn ṣe mumu laya rẹ to, ki wọn ba le fi ara wọn jin fun, ki wọn si tun ba le ni iriri igbala rẹ ni ẹkun rẹrẹ. Nitorina, ti o ba ti ni iriri tabi itọwo ifẹ, didara tabi agbara rẹ ni ọna kan tabi omiran, nkan ti o kere ju ti o le ṣe ni ki iwọ na ṣe atọna bi yoo ṣe le fi ọwọ tọ awọn miran, ki awọn naa ba le ni iriri ifẹ, didara ati agbara rẹ ti iwọ ti gbadun tabi ti o n gbadun lọwọlọwọ. Eyi yo si jẹ ọkan lara awọn nkan ti yoo fi han pe ọrọ aye awọn miran jẹ iwọ na logun gẹgẹ bi ọrọ aye rẹ ṣe jẹ ẹ logun.
A wa ri apejuwe nkan ti a n sọ yi ninu ọrọ Kọniliọsi ti inu bibeli. Gẹgẹ bi a ti ṣe kọ ọ silẹ, angẹli Oluwa lo fi ara han ọkunrin yi ninu iran kan, ti o si fi nkan meji pataki kan ye. Akọkọ ni pe o jẹ ki o ye pe awọn adura rẹ ati awọn ọrẹ rẹ si awọn alaini ko ja si asan rara – Ọlọrun tẹwọgba gbogbo wọn. Ekeji ni pe o jẹ ki ọkunrin yi mọ pe, bi o tilẹ jẹ wipe inu Ọlọrun dun si gbogbo nkan ti o n ṣe, o si nilo igbala nipaṣe Kirisiti Jesu ati pe ẹni naa ti yoo sọ ọna ti yoo gba ri igbala yi ni Peteru. (Wo: Iṣe Awọn Apositeli 10:1-6)
Nitori eyi, gẹgẹ bi aṣe ti angeli Ọlọrun pa fun un, Kọniliọsi ran iṣẹ pataki si Peteru lati wa sọdọ rẹ nipasẹ awọn mẹta kan lara awọn eniyan rẹ. Ṣugbọn eyi nikan kọ ni o ṣe o. O tun ran iṣẹ pataki si awọn ibatan ati awọn ọrẹ rẹ lati wa si ile rẹ lati gbọ ọrọ lẹnu Peteru. Ki si ni idi? Idi ni pe o mọ pe Peteru yo ma ba awọn sọrọ lori nkan kan ti ṣe pataki ju ọrọkọrọ ti eniyan le ba ẹnikẹni sọ lọ — ọrọ lori igbe aye ainipẹkun pẹlu Ọlọrun – ko si fẹ ki o jẹ pe oun nikan naa ni yo ni anfanni lati gbadun ọrọ yi. Nitorina, nigba ti Peteru de ile rẹ tan, bi bibeli ṣe sọ fun wa, nkan ti o ri ya a lẹnu – o ri ọpọ eniyan ti wọn pejọ. Nigba ti yo si fi ṣetan ni biba wọn sọrọ, Ọlọrun ti gba gbogbo wọn la, O si tun ti kun gbogbo wọn fun Ẹmi Mimọ rẹ. (Wo: Iṣe Awọn Apositeli 10:24-28&44-48)
Ti Kọniliosi ko ba wa ṣe atọna bi awọn ibatan rẹ ati awọn ọrẹ rẹ ṣe le gbọ nipa Jesu lati ẹnu Peteru nkọ, njẹ Ọlọrun iba si le gba awọn eniyan yi la bi O ṣe gba wọn la lọjọ yi bi? Mi o ro bẹ rara. Lotitọ, Ọlọrun ṣi le gba gbogbo awọn eniyan yi bi Kọniliọsi ko tilẹ ṣe atọna fun un lati ṣiṣẹ ninu aye wọn. Ṣugbọn itan yi ko ba ma ti pari bi o ṣe pari yi, ọkunrin yi na ko ba si sọ oriyin ati ere yowu ti ko ba gba lati ọwọ Ọlọrun fun lila ọna silẹ fun lati fi iye fun awọn miran nu.
Ki gan wa ni koko gbogbo nkan ti a n sọ yi? Ohun na ti pe o yẹ ki awa na, ti a n fi ojoojumọ gbadun didara ati ojurere Ọlọrun, la oju inu wa lati ri awọn ọna ti a le gba lo awọn nkan ini wa, nkan amuyẹ wa tabi ohunkohun ti Ọlọrun fun wa lati la ọna fun un lati bukun fun awọn ẹlomiran. Ọpọ ni o wa ni aye loni ti o nilo iwosan, idari, itusilẹ, ifẹ, igboya ati bẹẹbẹẹlọ, ti wọn ko si mọ ọna ti wọn le gba ri awọn nkan wọnyi. Nkan ti awọn wọnyi si nilo le ma ju ẹnikan ti o dabi Kọniliọsi lọ, ẹnikan ti yo lo akoko rẹ, nkan ini rẹ tabi awọn nkan amuyẹ rẹ lati ṣe atọna bi wọn yo ṣe ba Jesu, ti o jẹ pe Oun nikan na ni o le yanju gbogbo iṣoro eniyan, pade. Njẹ o wa ṣetan lati jẹ irufẹ eniyan yi bi, bi o ṣe n lọ ni ọsẹ yi? Ṣe o ṣetan lati jẹ Kọniliọsi miran ti Ọlọrun le lo lati bukun fun ọpọ ninu aye yi ni ojumọ kọọkan ti o ba mọ? Adura mi ni pe ki o tobẹ, ki o si ju bẹẹ lẹ, ni orukọ Jesu Kirisiti Oluwa wa. Amin.
Ki o ni ọsẹ adun o.
Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Owara 11, 2020 | Atelera: Latori tabili Paitọ | Nomba: Vol. 9, No. 23