Categories
Latori tabili Paitor

Ma fun ni aye rara lati ṣiṣẹ

Olufẹ: ki ore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ lẹkunrẹrẹ lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki ọ kabọ sinu ọsẹ ti o pari osu Ogun 2020, mo si tun gbadura pe ki a pa ọ mọ kuro ninu gbogbo arekereke ibi eṣu ni gbogbo ọsẹ na ati ni gbogbo eyi ti o ku ki ọdun yi fi pari, ni orukọ Jesu. Amin.

Nje bi o ti jẹ pe o dara, ti o si tun tọ fun mi lati gba aduura fun ọ ni ọna ti mo ṣe gba yi, o tun se pataki pe ki iwọ na ma gba eṣu laye lati ṣiṣẹ ninu aye rẹ ki o si bori. Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Efesu, sọ wipe, “Bẹni ki ẹ ma ṣe fi aye fun Eṣu.” (Efesu 4:27) Kini idi ti o fi sọ eyi? O sọ eyi nitori oye rẹ nipa iru ẹda ti Eṣu jẹ. Iru ẹda wa si ni o jẹ? Gẹgẹ bi ọrọ bibeli, o jẹ opurọ, ole, apaniyan, apanirun ati ajẹnirun (Johannu 8:44&10:10; 1Peteru 5:8).

Categories
Latori tabili Paitor

Tẹriba fun patapata

Olufẹ: ki ore-ọfẹ ati aanu wa pẹlu re titi lailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olurapada wa. Mo ki ọ kaabọ sinu ọsẹ tuntun yi, mo si gbadura pe ki a pa ọ mọ ninu gbogbo ọna re kuro ninu ewu ati idojukọ Satani gbogbo, ni orukọ Jesu. Amin

Njẹ ọna kan pataki fun wa lati ma fi igba gbogbo gbadun aabo Ọlọrun kuro ninu ewu orisirisi ni ki a ma rin ni igbọran si aṣẹ rẹ ni gbogbo igba. Gẹgẹ bi Bibeli se fi han wa kedere, ko si bi a se le yago patapata fun wahala ninu aye yi. Idi si ni pe aye na jẹ eyi ti o wa labẹ isakoso Esu, niwọn ibi ti Ọlọrun gba a laaye de (1Johanu 5:19). Nitorina, bi a ba tilẹ n fi gbogbo igba wiwa ti o tọ ati ti o si yẹ, a ko le ṣa lairi awọn kan ti yo fi ara wọn jin fun Esu lati da wahala silẹ fun wa. Ti ko ba si wa ri ẹni ti o le lo lati se eyi, o le pinu lati lo nkan ti a da tabi ilana ti a la kalẹ yowu ti o ba ri lati doju ija kọ wa.

Danieli, fun apẹẹrẹ, n gbe igbe aye ti o fi ara rẹ jin patapata lati dun Ọlọrun ninu. Sibẹsibẹ Esu se aseyọri lati lo awọn adari ilẹ Babiloni kan lati se akoba fun. Nitorina, o ba ara rẹ ninu iho Kiniun. (Wo: Danieli 6) Jobu na n kọ? Ọlọrun funrarẹ jẹwo pe ọkunrin yi jẹ ẹni ti o wa ni alailẹbi, ti iwuwasi rẹ si tọ. Sibẹsibe, akoko kan de ti Esu gbogun ti, ti o si lo oniruuru eniyan ati nkan lati pọn loju. (Wo: Jobu 1&2)

Nitorina, niwọn igba ti a ba si wa ninu aye yi, ni orekore ni a o ma ba ara wa ni awọn asiko kan ti wahala yo tọ wa wa, ti yo si fẹ bori wa, ki o si tun pa wa run. Sugbọn ni ọwọ igba ti a ba tẹriba fun Ọlọrun, ti a n gbe igbe aye iyọnda si, ti a si n fi gbogbo igba gbọkanle fun ipese rẹ, ko si irufẹ wahala ti o le tọ wa wa ti a ko ni le rin ni iṣẹgun lori rẹ (Efesu 6:10-18). Njẹ kiyesi pe nkan meji ni mo sọ pe a gbọdọ se lati le rin ni iṣẹgun lori wahala yowu ti o le de ba wa. Akọkọ ni pe ki a tẹriba patapata fun Ọlọrun. Ekeji ni pe ki a gbọkanle patapata. Ki i se pe ki a mu ọkan tabi ekeji ninu awon nkan meji yi; mejeji ni a gbọdọ se. Laijẹbẹ, a ko ni ri iru eso ti o yẹ ki a ri.

O wa seni laanu pe ọpọ ninu wa loni lo ro wipe nkan ti o se pataki ni pe ki a kan gbọkan wa le Ọlọrun ati agbara ati aṣẹ rẹ lati rin ni iṣẹgun laye yi – iha ti a kọ si ofin rẹ ko ja mọ nkankan lọtiti. Sugbọn bi a se kọ wa kọ ni eyi ninu iwe mimọ. Nkan ti a kọ wa ni eyi: “Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Eṣu, on o si sa kuro lọdọ nyin.” (Jakobu 4:7) Se iwọ na ri bayi? A le doju ija kọ Satani, ki a si le danu kuro lọdọ wa. Eyi tunmọ si pe a le kọ lati fi aye gba iṣẹ ati akitiyan Esu laye wa. Idi si ni wipe ọmọ Ọlọrun ni a jẹ ati pe ati fun wa ni aṣẹ ti a nilo lati bori gbogbo agbara Esu lati ọwọ Jesu (Luuku 10:19).

Sugbọn ki aṣẹ wa lati doju ija ko Esu ati iṣẹ rẹ ki a si bori to le ṣiṣẹ bi o ṣe tọ, Jemisi (Jakọbu) so wipe a kọkọ gbọdọ tẹriba fun aṣẹ Ọlọrun. Ti a ko ba ni tẹri wa ba fun Ọlọrun, ki a si ma rin ni igbọran si awọn ofin rẹ, nse ni a o ma fi ọpọ igba ba ara wa ni ipo ti a le ti ma le lo tabi gbadun aṣẹ ati ore-ọfẹ ti O fun wa lati rin ni iṣẹgun lori Esu ati iṣẹ rẹ.

Wo Samusoni, fun apẹẹrẹ. O jẹ ẹni ti Ọlọrun fi amin ororo yan, ti O si tun fun ni aṣẹ lati gba awọn ara Isiraẹli kuro lọwọ isakoso ati ifiyajẹni awọn Filisitini. O si mura lati se eyi. Sugbọn nitoripe o kọ lati ko ara rẹ ni ijanu lati tẹriba fun Ọlọrun ni gbogbo igbesi aye re, ọpọ igba ni o n ṣe awọn nkan ti ko tọ fun lati se, ti o si tun n lọ si awọn ibi ti ko yẹ ki o lọ. Eyi si jẹ ki o soro fun lati le seto aye rẹ, ki o si ko awọn eniyan ti a pe lati dari jọ ni iṣọkan lati dojukọ awọn ọta wọn, ki wọn si bori. O kan n se adanikanse ni. Bi o wa tilẹ jẹ wipe, ninu ainikoraẹninijanu ati aigbọran si ọna Ọlọrun rẹ, o fi ọpọlọpọ ọdun bọ ninu panpẹ awọn ọta re, akoko kan de ti o jẹ wipe ẹmi iyasọtọ Ọlọrun ati aṣẹ ti a fun lati da abo bo ara rẹ ati awọn eniyan rẹ kuro lọwọ awọn ọta wọn fi sile. Nitorina o ku ki akoko rẹ to pe, o si fi iṣẹ ti a fi le lọwọ silẹ lai pari. (Wo: Awọn Onidajọ 14-15)

Nibayi, ti awa na ko ba fẹ parun nipasẹ arekereke ati idojukọ Satani, a ko gbọdọ kọ iha ti Samusoni kọ si Ọlọrun ati si ọrọ rẹ si. Dipo bẹ, a gbọdọ tẹ ori wa ba fun patapata, ki a si fi ara wa jin lati ma rin ninu ilana rẹ. Ti a ba si ti n se eyi, ibikibi ti o wu ki a ti ba ara wa tabi ohunkohun ti o wu ki ọta lẹ mọ wa ninu irinajo wa ninu ifẹ Ọlọrun, a le mọ daju pe aabo rẹ yo daju lori wa, bi awa si ti n fi iduroṣinṣin se amulo aṣẹ ti O fi fun wa ninu Jesu Kirisiti.

Ọsẹ adun o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 16, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 15

Categories
Latori tabili Paitor

Njẹ iwo gba ore-ofẹ rẹ lasan bi?

Olufẹ: ki ore-ofẹ, aanu ati alaafia jẹ tirẹ titilailai lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki ọ kaabọ sinu osẹ miran ninu osu Ogun 2020. Mo si gbadura pe ki Ọlọrun se iṣe ti yo mu inu rẹ dun ninu aye rẹ ni osẹ na ati pe ki o ma se fi ore-ofẹ rẹ sofo, ni orukọ Jesu. Amin.

Nibayi mo gba adura yi fun ọ nitoripe ifẹ ọkan mi ni pe ki aye rẹ jẹ ifarahan ore-ofẹ ati didara Ọlọrun. Nje iwo tile ti ri ore-ọfẹ re gba bi? Ti o ba jẹ ọmọ Ọlọrun, a jẹ wipe o ti gba ore-ọfẹ re niyẹn. Idi si ni wipe bibeli sọ wipe nipa ore-ọfẹ rẹ ni a gbawala. Eyi tunmo si pe nitori iṣẹ ti Ọlọrun se ati nitori nkan ti O fi fun wa ni a se gbawala lọwọ ẹṣẹ wa, lọwọ esu ati lọwọ iparun ayeraye. (Wo: Efesu 2:1-10)

Amọ o, o wa yẹ ki nkan ti Ọlọrun se fun wa ati eyi ti O fun wa jẹyọ ninu aye wa. Nkan ti mo n sọ ni pe o yẹ ki o farahan pe lotitọ ni Ọlọrun ti gbawala, tunwabi, ti O si tun gba akoso aye wa. Fun apẹẹrẹ, ninu lẹta rẹ si awọn ara Tẹsalonika, Pọọlu sọ wipe, “Nitori ẹyin tikarayin mọ, ara, pe ibẹwo wa si yin kii se lasan.” (1Tẹsalonika 1:4-10) Ki ni idi ti o fi sọ eyi si awọn ara wọnyi? Idi ni pe o ri ifarahan ore-ọfẹ Ọlọrun ninu aye wọn. Gẹgẹ bi o ti fi han wa ni ori akọkọ lẹta yi, ọrọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn gba ko wọ inu aye wọn lailai yi pada. O yi wọn pada. O jẹ ki wọn yipada kuro ninu ibọriṣa lati sin Ọlọrun ati lati duro de ipadabọ Ọmọ rẹ, Jesu Kirisiti. Yatọ si eyi, o yi wọn pada si awokọse rere ọpọlọpọ awọn ọmọ Ọlọrun nibomiran. Nitorina, ore-ọfẹ Ọlọrun ti wọn rigba ko ja si asan ninu aye wọn. (Wo: 1Tẹsalonika 1:4-10)

Lafikun, Pọọlu, ninu lẹta rẹ si awọn ara Korinnti, sọ eyi nipa ara rẹ: “…ore ọfẹ rẹ ti a fi fun mi ko si jẹ asan…”
(1Korinnti 15:10) Eyi tunmọ si pe ore-ọfẹ Ọlọrun mu ifẹ rẹ wa si imuṣẹ ninu aye rẹ. O ṣọ di irufẹ eniyan ti Oun fẹ ki o jẹ ati pe o tun fun ni okun lati se awọn nkan ti O fẹ ki o se. Njẹ a wa le sọ eyi nipa awa na bi? Njẹ a le sọ wipe ore-ọfẹ Ọlọrun ti awa na rigba ti n sọ wa di iru eniyan ti Oun fẹ ki a jẹ bi?

Ti ore-ọfẹ Ọlọrun ti a ti rọ ojo rẹ sinu aye wa ko ba ma sọ wa di iru eniyan ti O fẹ ki a jẹ, o tunmọ si pe a n fi sofo niyẹn. Bawo si ni eyi se se e se? Yo se e se ni iwọn igba ti a ba ti kọ lati se amulo ore-ọfẹ rẹ ni ọna ti o yẹ, ti o si tun peye. Ore-ọfẹ Ọlọrun fun igbala, igbe aye ododo ati iṣẹ isin ti ẹmi ni a ti fi fun wa lọfẹ. A ti fi fun wa ninu ọrọ rẹ, ninu Ẹmi rẹ ati ninu ibasepọ awọn ọmọ rẹ. Eyi tunmọ si pe a le gbadun ore-ọfẹ Ọlọrun nipa fifi aye gba iṣẹ iranṣẹ ọrọ rẹ ati ti Ẹmi rẹ ati ti awọn eyinyan rẹ ti O ti gbin sinu aye wa.

Sugbọn, bi o tilẹ jẹ wipe a ti fun wa ni awọn nkan wọnyi lọfẹ, wọn ko ni kan dede ṣiṣẹ fun iyipada ọtun ninu aye wa ti a ko ba se amulo wọn ni ọna ti o yẹ. Nkan ti mo n sọ ni pe ti a ko ba mu iṣẹ iranṣẹ ọrọ Ọlọrun lọkunkundun, ki a dirọ mọ ṣinṣin lati se nkan ti o n sọ fun wa, ki a si ma rin ninu imọlẹ rẹ, aye wa ko ni fi ore-ọfẹ Ọlọrun han. Lafikun, ti a ko ba fi aye gba Ẹmi Ọlọrun lati gbakoso aye wa ati awọn nkan ti a n se, ki a gbọkanle fun ohun gbogbo ti a nilo, aye wa ko ni ri bi Ọlọrun se fẹ ki wọn ri ninu aye yi. Nibakanna, ti a ko ba se amulo ti o yẹ ati ti o si peye ibasepọ awọn ọmọ Ọlọrun ti o wa ni aye wa, a ko ni dagba soke bi o se yẹ ki a dagba soke lati gbe aye yi bi o se yẹ ki a gbe.

Nje gẹgẹbi mo se sọ tẹlẹ, niwọn igba ti a ko ba ti ma fi gbogbo igba dabi Ọlọrun se fẹ ki a ri, ki a si tun ma se gbogbo nkan ti O fẹ ki a ma se, a n fi ore-ọfẹ rẹ ati laala Ẹmi rẹ lori aye wa sofo niyẹn. Ṣe a wa le fi ore-ọfẹ re sofo bi eyi ki a si tun ri oriyin gba lọdọ rẹ bi? Njẹ eyi gan ko ni fẹ fihan pe a ko fi igba kankan gba ore-ọfẹ sinu aye wa ati pe a kan n dibọn ni? Laisaroye lọpọ, mo fẹ ki o mọ pe ti o ba ti ri ore-ọfẹ re gba, o yẹ ki o suyọ ninu aye rẹ. Ti ko ba si ma suyọ, o yẹ ki o bẹrẹ si ni bere awọn ibeere kan ti o se pataki lọwọ ara rẹ lori iha ti o kọ si amulo ore-ọfẹ yi. Adura mi ni pe ki Ẹmi Ọlọrun si oju re lati ri awọn ibi ti o ti n kuna, ki O si tun ran ọ lọwọ lati bẹrẹ si ni se ohun ti o tọ pẹlu ore-ọfẹ rẹ.

Ọsẹ ire o.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)
Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Ogun 09, 2020 | Atelera: Latori tabili Paito | Nomba: Vol. 9, No. 13

Categories
Latori tabili Paitor

Ona isorire ti o daju

Olufe: Olubukunfun ni Olorun ati Baba Jesu Kirisiti Oluwa wa, Eni ti O mu wa wo inu osu kejo odun yi, osu Ogun, lalaafia ninu ojurere re ti o ga. Adura mi si ni pe aye wa ko ni mo ohunkohun to yato si ilosiwaju ninu osu na, ni oruko Jesu. Amin.

Nje ona kan to daju lati ni iriri ilosiwaju ni gbogbo ona aye wa ni ki a mu oro Olorun ni okunkundun. Nkan eyokan yi ni Olorun te mo Josua leti nigba ti O n pase fun lati dari awon omo Israeli lo sinu ile ini ti O fi fun won. O so fun pe:

Categories
Latori tabili Paitor

Irisi idajo Olorun

Olufe: ki ore ofe ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Mo ki o kabo sinu ose ti o pari osu Agemo 2020. Adura mi si ni pe ikankan ninu ohun rere ti o ye ki o je tire losu na ko ni fo o ru, loruko Jesu. Amin.

Nje ti eniyan ba wo bi nkan se polukumusu ni orile-ede yi lakoko yi, paapajulo ti eniyan ba wo gbogbo awon esun iwa ibaje ati ti sise owo ilu ni basubasu ti a fi n kan die lara awon olori wa laipe yi, o se e se ki a fe ki Olorun gbera ni kiakia lati se idajo gbogbo awon ti oro na kan ati awon miran bi tiwon ti won n je ki o soro ki orile-ede wa ni itesiwaju. A si ri daju ninu iwe mimo pe Olorun ma n se idajo awon eniyan fun irufe awon iwa ika wonyi, eyi ti ki i se ni opin aye yi nikan sugbon ninu aye yi gan (1Samueli 3:13; 1Awon Oba 14:7-11). Sugbon awon ti a je onigbagbo, ti o si tun se e se pe awa na n fe ki Olorun mu nkan bo si otun ni kiakia ni orile-ede yi, ko gbodo gbagbe pe Olorun ko ki i se idajo bi awa eniyan ti ma n se.

Categories
Latori tabili Paitor Yoruba (Fire in my Bones)

Aritokasi ni rere

Olufe: ki ore-ofe ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Pelu idunnu ni mo se ki o kabo sinu ose miran ninu osu Agemo 2020. Mo si gbadura pe ki Olorun se ni asepe gbogbo ohun ti n se tire, ki o si tun se aye re ni aritokasi ni rere, ni oruko Jesu. Amin.

Gege bi a se ri ninu bible, oba akoko paa ti Olorun yan sori awon omo Isiraeli ni Soolu. Sugbon leyin akosile iku re, a ko so nkan miran to se pataki nipa re mo. Ki si ni idi? Idi ni wipe ko gbe igbe aye arikose si rere. Lotito, ogoji odun ni o fi joba. Sugbon gbogbo ogoji odun yi ko jamo nkankan loju Olorun nitoripe ko lowon lati bowo fun Olorun.

Categories
Latori tabili Paitor Others

Ma se padanu emi re tori ohunkohun

Olufe: ki ore-ofe, aanu ati alaafia je tire lati odo Olorun Baba ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabo sinu ose miran ninu odun 2020. Mo gba adura pe ki ojurere Olorun je ki aye yi dun, ki o si tun larinrin fun o ninu gbogbo ose na, ni oruko Jesu. Amin.

Bi a se n bere ose tuntun miran, mo fe ran o leti pe bi o ti wu ki aye yi dun ki o si larinrin to, ibi ti Olorun ti pese sile fun awon ti o feran re dara ju u lo ni ona ti ko se fenu so. Bi o si ti wu ki aye yi buru to loju wa, ibi ti Olorun pese sile fun esu ati gbogbo awon olukorira Olorun buru ju lo ni ona ti o koja nkan ti a le se afiwe. Nitorina, a gbodo lakaka lati ri pe a ko je ki ibasepo wa pelu aye yi ati awon nkan ti o wa ninu re jawa lole ibugbe daradara ti Olorun ti pese sile fun wa ni ayeraye.

Categories
Latori tabili Paitor Pastor's Desk

Fi gbogbo okan re jin fun Olorun

Olufe: ki ore-ofe, aanu ati alaafia je tire lailodiwon lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki o kaabo sinu osu Agemo 2020, eyi ti o je osu eyi ti o bere idakeji awon osu ti o wa ninu odun yi. Adura mi si ni pe ki Olorun fi ayo re kun okan re de bi pe o ko ni ranti gbogbo ibanuje tabi adanu kankan ti o wu ki o ti ba pade ninu idakini awon osu odun yi, ni oruko Jesu. Amin.

Nibayi, mo fe gba o niyanju, bi a se n bere idajeki awon osu odun yi, pe ki o fi gbogbo ara re jin fun Olorun ninu ohun gbogbo. Eyi tunmo si pe ki o ma se fun Olorun ni aabo ijosin tabi ki isin re si ma je eyi ti o wa lekunrere. Dipo be, fi ara re jin fun patapata ni ijosin ati ni ise isin. Idi si ni pe eyi ni ona kansoso ti o fi le gbadun re ni ekun rere, ki o si tun gba oriyin lodo re.

Categories
Latori tabili Paitor

O mo ibugbe re

Olufe: ki ore ofe ati alaafia je tire titi lailai lati odo Olorun Baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa ati Olugbala wa. Kaabo sinu ose tuntun miran ninu osu Okudu 2020. Mo si gbadura pe ki okan re gba okun lati je olododo si Oluwa titi de opin, bi o ti wu ki nkan ri nibi yowu ti o ba ti ba ara re, ni oruko Jesu Oluwa. Amin.

Okan lara nkan ti Oluwa gbe oriyin fun ijo Pagamu, okan lara awon ijo re ti o wa ni agbebe Esia aye igba ti a ko oro bibeli, si ni pe won je olotito si, bi o tile je wipe ibujoko Satani gan funrare ni won n gbe. Iwo na wo bi O se ba won soro ninu leta re si won:

“Emi mo isee re, ati ibi ti iwo n gbe, a ni ibi ti ite Satani ni wa: ati pe iwo se olooto si oruko mi sibe, ti iwo ko si se igbagbo re ninu mi, ni ojo wonyi ninu eyi ti Antipa i se olooto ajerri-iku mi, eni ti won pa ninu yin, nibi ti Satani n gbe.” (Ifihan 2:13)

Nkan akoko ti Oluwa so fun awon ara yi ni pe Oun mo ibi ti won n gbe. Eyi ko si ni i se pelu oruko ilu won. Lotito, O mo oruko ilu won, eyi ti i se Pagamu. Sugbon oruko ilu won ko ni koko oro; koko oro ni awon isele ti o n waye ninu ilu na ati ipa ti won n ko lori igbesi aye awon eniyan ti o wa nibe.

Gegebi oro Oluwa, ilu yi ni Satani n gbe ni akoko ti O n ko awon oro wonyi. Lotito, a mo nipase iwe mimo pe alarinkiri ni Satani – oun ko le fi ibikankan se ibujoko re titi lailai (Joobu 1:7 & 2:2). Amon awon igba miran a ma wa ti yo fi igba die fikale si ibikan lati se ose nibe. Ti o ba si ti fi ibikan se ile re, a le mo daju pe dandan ni ki ise emi okunkun po si ni ibe. Eyi yoo si yori si ki iwa ika, isekuse, iborisa, oso sise, ilodi si ododo, itanje, rugudu ati oniruru ibi po si ni irufe ibi be.

Boya iwo gan tile ti fi igbakan gbe iru ibi – ilu nla, ilu kekere, abule, adugbo, agbole, ile ise tabi ile iwe – ti a n soro re yi ri. Nikete ti o debe ni o ti mo pe nkan o se enure nibe. O le so tabi fura pe okunkun birimubirimu wa lori awon ti o n gbe ibe. O si tun le ri bi okunkun yi se n yi aye awon olugbe ibe po, ti o si je ki won ma se awon ohun ti ko to ati ti ko ye. Fun apeere, mo fi igbakan gbe ilu kan ri nibi ti o je wipe opolopo odomode lokunri ati lobinrin ni won ti di baba ati iya labe orule awon obi won, ti opo ko si ri nkan ti o buru ninu eyi. O wa tunmo si pe isekuse gbile ni ilu yi debi wipe awon omo kekeke na n kopa ninu re. Nitorina, ni akoko ti mo n so yi (n ko le so bi ibe se ri lowolowo yi), o soro lati to omo lati wa ni aileri. Ti iwo gan ba si de ibe gege bi eniyan mimo, ti o ko ba si sora lati rin ninu agbara Emi Olorun, ko ni i pe rara ti aye re yoo fi di idakuda ninu isekuse.

Ki wa ni idi ti ibikan se le ri bayi? Fifi ikale Esu tabi fifi ikale lara awon angeli alagbara re is ibe ni o ma n saba fa (Efesu 6:12). Awon ni won ma n fi ero, imo ati aba buburu pelu iro kun okan awon eniyan. Awon nkan wonyi si ni o ma n di alagbara mo awon eniyan lowo, ti won a si ma mu won ni eru lati se awon nkan ti o ma n mu ipalara wa. Ti awon emi buburu yi ba si ti fi ibikan se ile won, o di dandan ki awon irufe nkan buburu kan bere si ni fi ese mule ni ibe, ti won yo si bere si ni pa igbe aye awon ti o n gbe ibe lara.

Sugbon, ni ti awon ara ti o n gbe ilu Pagamu ti Oluwa n soro nipa ninu ese bible ti o wa ni oke yi, won ko gba ki nkankan pa isododo won si Oluwa lara lona kankan, bi o ti le je wipe Satani fi ilu won se ibudo. Eyi tunmo si pe won ko lati ba awon ti won jo n gbe ilu yi dogba ninu iwa aimo Olorun, bi o tile je pe a gbogun ti won lati se be. A tile ri wipe a pa okan lara won, eni ti o n je Antipa, nitori igbagbo re. Sibesibe, awon ara wonyi ko se igbagbo won ninu Jesu Kirisiti Oluwa. Be e si ni won ko yonda ara fun Esu lati ba aye won je nipase gbogbo awon nkan ti ko da ti awon ara ilu won n se. Eyi lo si je ki Olowa gbe oriyin fun won, ti O si tun je ki won mo pe Oun mo gbogbo nkan ti won n la koja ati pe, nigba ti akoko ba to, Oun yo fun won ni ere won, ti won ba je olotito si titi de opin.

Nibakanna, Oluwa mo ibi ti iwo ati emi n gbe ati awon isele ti o wopo nibe. O mo ibi ti a ti n sise, sowo tabi kawe ati awon nkan ti o wopo nibe. Sibesibe, O fe ki a je olotito si, ki a si ma baradogba pelu awon ti a n ba gbe ninu awon nkan buburu ti won ba ti fi ara won jin fun, bi o tile je wipe Esu funrare gan ni a n ba gbe. Ti ijo ti Pagamu ba si le je olotito si ninu eyi, awa na le je olotito si. Nitorina, eyi ti a o fi ma se awawi fun fifi ara wa jin lati se awon nkan buburu ti o wopo ni awujo wa, nse ni o ye ki a ma gba ohunkohun ti a ba nilo lati je olotito si Oluwa lati ibi ite ore ofe Olorun (Heberu 4:14-16). Ranti pe ti a ba je olotito si, a o gba oriyin ati ere lati owo re. Sugbon ti a ba teriba fun igbogun Esu ati aye, o sese ki awa na je alabapin ninu idajo ti o di dandan ki o wa sori aye yi. Adura mi si ni pe ki eyi ma je ipin wa ni oruko Jesu. Amin.

Ki o ni ose to larinrin.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)

Lati owo: J.O. Lawal | Ojo: Okudu 21, 2020
Atelera: Latori tabili Paitor | Nomba: Vol. 9, No. 7

Categories
Latori tabili Paitor Yoruba (Fire in my Bones)

Ona lati ma fi aye re sofo

Olufe: ki ore-ofe, aanu ati alaafia ki o je tire titi lailai lati odo Olorun baba wa ati Jesu Kirisiti Oluwa wa. Inu mi dun lati ki o kabo sinu ose miran ninu osu Okudu 2020. Adura si ni pe ki okan re kun fun imo ife Olorun to ti o ye koro ni gbogbo ona aye re ni ose yi ati ni eyi ti o ku ninu odun yi, ni oruko Jesu. Amin.

Nje ki ni idi ti o se se pataki ki o mo ife Olorun fun o ninu ohun gbogbo ti o n se? Idi ni ki o ma ba gbe igbe aye alailoye. Poolu so ninu leta re si awon ara Efesu pe, “Nitori naa e ma se je alailoye, sugbon e maa moye ohun ti ife Oluwa ja si.” (Efesu 5:17) Se iwo na ri bayi? Ailoye gba a ni o je lati ma mo okan Olorun nipa igbe aye lapapo ati bi o se ye ki a lo ni ibamu pelu ife re. Ti a ko ba mo ero Olorun nipa aye yi ati iha ti o ye ki a ko si, ko si bi a se le gbe aye wa lati te lorun. Ti a ko ba si gbe aye wa lati dun Olorun ninu, ati fi aye wa sofo ni yen.

Woo, Olorun ko da wa lati lo aye fun ara wa. Ko si enikeni ti yo seda nkan ki nkan na le lo aye re bi o ba se wu. Dipo be, ti a ba se eda ohunkohun (yala irin ise ni, ile ise ni, eto ise sise ni, ona ise sise ni ati bebelo) a se eda re lati wulo fun wa ni. Ti nkan na ba si ko lati wulo fun idi ti a fi seda ra, o di dandan ki a mu wa si opin. Be e gege na ni o se ri pelu Olorun. Olorun da wa ki a le gbe aye fun ni; O da wa ki a le gbe aye wa lati mu inu re dun ni. Nkan kan pataki ti o si ye ki eniyan kokan ti o n gbe aye yi ni lati mo niyi. A ko da o lati gbe aye fun ara re. A ko da o lati gbe aye fun oko tabi aya re. A ko da o lati gbe aye fun awon ore re, aladugbo re tabi akegbe re ni ile ise tabi ile iwe. Ni kukuru, a ko da o lati gbe aye fun eda kankan. Eni kan soso ti a da o lati gbe aye re fun ni eni ti o da o. Eni na si ni Olorun. (Woo: Roomu 14:7-8; Ifihan 4:11)

Ti o ba wa gbagbo pe Olorun ni eleda re, nje nkan ti o gbodo je pataki julo si o ni bi o se gbe aye re lati dun ninu. Lotito, bi o ba se n dun ninu na ni o ma dun awon miran ti o wa ni aye re ninu. Sugbon, pataki julo ni pe a da o ki o le dun Olorun ninu. Ti o ko ba si gbe aye re lati mu inu re dun, o ko gbe aye re lati mu idi ti o se da o wa si imuse niyen. Nitorina, o n fi aye re sofo niyi, o si wa ninu ewu pe ki Olorun pa o ti patapata ati titi ayeraye.

O wa se ni laanu pe opolopo ni o n fi aye won sofo loni laimo rara. Won n fi aye wo sofo nitoripe won ko gbe aye won fun Olorun. Won n fi aye won sofo nitoripe won ko gbe aye won ninu ife Olorun. Lotito, won le je eniyan daradara ati oniwapele, ti won si n gbiyanju lati je ki aye derun fun ara won ati fun awon miran. Sugbon niwon igba ti won ko ba gbe aye won lori igbagbo ninu Olorun ati itaara lati se ife re, aye ti ara won ni won gbe. O wa sese o ki won ma gba pe aye ti ara won ni awon n gbe, ki won ma so wipe nse ni awon gbe aye won fun igbadun awon elomiran. Otito ibe ni wipe tori itelorun ati idunnu ara won na ni won se n se gbogbo awon nkan ti won se fun awo elomiran. Niwon igba ti o si je pe itelorun ara won ni won gbe aye fun, won ko fi aye won mu ife Olorun se. Won kan n fi sofo lasan ni. Ko si si bi won yoo se gba oriyin lati odo re ni ojo ti o ba n pin ere fun gbogbo eniyan.

Nibayi emi o fe fi aye temi sofo ninu aye yi. Dipo be, mo fe gbe aye mi lati gba oriyin lodo eni ti o da mi. Mo si mo pe iwo na o ni fe ki aye re sofo sugbon ki o ni itumo niwaju Olorun nigbati ti gbogbo nkan ba wa si opin. Amo nse ni a o fi aye wa sofo ti a ko ba gbe won ninu ife re. Ti a ko ba si fe gbe aye wa laisi ninu ife Olorun, o je dandan ki a ma ife re. Eyi si tun mu wa pada lo sinu oro ti Poolu so. O so wipe, “Nitori naa e ma se je alailoye, sugbon e maa moye ohun ti ife Oluwa ja si.”

Bawo wa ni a se le mo ife Olorun fun wa ninu aye yi? Akoko, a le mo nipa biba soro ninu adura pe ki o fi ife re han won (Kolose 1:9-12). Niwon igba ti o ti so fun wa pe awon ti won bere n rigba, a won na le ni idaniloju pe ti a ba so wipe ki o fi ife re han wa, yoo fi han wa gege bi aimo wa ba se po to. Ekeji, a le mo ife re nipa fifi ara wa jin fun iwe mimo. Poolu so wipe gbogbo iwe mimo ni imisi Olorun lati ko wa, to wa sona, ba wa wi ati lati ko wa ni ona ododo, ki a ba le mu wa ye lati mo ati lati se ife Olorun ni gbogbo ona (Timoti 3:16-17). Nitorina, fi ara re jin fun iwe mimo.

Eketa, a le mo ife Olorun nipase ibalopo pelu awon omo re miran. Olorun ko pe wa lati da gbe aye sugbon lati gbe aye ninu ebi re. Bi a ba si se ba awon omo ebi re lopo lotito si ni a o se tete di pipe ninu imo Olorun ati imo ife re. Nitorina, mu ibalopo re people awon omo Olorun miran, paapajulo awon ti ijo ti o wa, lokunkundun. Bi o si se n fi ara re jin fun awon nkan wonyi, mo gba ladura pe ki imo pipe ife Olorun ninu ohun gbogbo ma fi gbogbo igba ya bi omi odo sinu okan re, ki o ma ba fi aye re sofo. (Woo: Efesu 4:9-16)

Ki o ni ose to ga.

Copyright © 2020, Reality Desk, a ministry of Alaythia Bible Church –This material is the sole property of Reality Desk. It may be copied for personal non-commercial use only in its entirety free of charge. All copies must contain this copyright notice. Please direct any questions you may have to alaythiabiblechurch@gmail.com/alaythia4all@gmail.com or call: 08037592851 (WhatsApp Number: 07085711280)